Báwo Ni Àǹfààní Tí À Ń Rí Nínú Igbó Ṣe Pọ̀ Tó?
BÍ A bá dá gbogbo ilẹ̀ tó wà láyé sọ́nà mẹ́ta, á fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá kan tí igbó wà, ṣùgbọ́n ńṣe ni ibi tí igbó wà túbọ̀ ń dín kù sí i. Ní ọdún 1998, ìwé ìròyìn Choices—The Human Development Magazine tí Ètò Ìdàgbàsókè Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ̀ jáde sọ pé, ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà nìkan, “ilẹ̀ tó fẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́rin hẹ́kítà, ìyẹn ilẹ̀ tó fẹ̀ tó déédéé orílẹ̀-èdè Switzerland, ni wọ́n ń gé igi tó wà lórí rẹ̀ lulẹ̀ lọ́dọọdún.”
Kí Nìdí Tí Pípagbórun Fi Jẹ́ Kàyéfì
Àwọn ògbógi kan sọ pé kàyéfì gbáà lọ̀rọ̀ pípa táwọn èèyàn ń pa igbó run yìí jẹ́. Ohun tó mú kí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, ńṣe làwọn èèyàn ń fi iná sun igbó tí wọ́n sì ń gé gẹdú nítorí owó tí wọ́n ń rí nídìí ẹ̀. Síbẹ̀, ìròyìn kan sọ pé igbó “níye lórí gan-an nígbà táwọn igi bá ṣì wa nínú rẹ̀ ju ìgbà tá a bá gé igi inú rẹ̀ tàbí tá a bá dáná sun ún.” Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
Ọ̀mọ̀wé Philip M. Fearnside àti Ọ̀mọ̀wé Flávio J. Luizão tí wọ́n jẹ́ olùṣèwádìí ní Ibùdó Ìwádìí ti Ìjọba Àpapọ̀ tó wà ní Amazon, ìyẹn ní ìlú Manaus lórílẹ̀-èdè Brazil sọ fún òǹkọ̀wé Jí! pé, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ o, àwọn igbó kìjikìji máa ń “ṣe aráyé láǹfààní.” Lára àwọn àǹfààní wọ̀nyí ni gbígba carbon dioxide (afẹ́fẹ́ tí ń mú kí ayé móoru) sára àti títọ́jú rẹ̀ pa mọ́, kì í tún jẹ́ kí àgbàrá gbá ilẹ̀ lọ tàbí kí omíyalé ṣẹlẹ̀, ó máa ń sọ àwọn èròjà inú ilẹ̀ dọ̀tun, ó máa ń díwọ̀n òjò, ibẹ̀ làwọn ẹranko táwọn èèyàn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa tán fi ṣelé, ó sì tún jẹ́ ààbò fáwọn irúgbìn. Igbó tún máa ń bu ẹwà kún àyíká, a sì tún lè lọ gbafẹ́ níbẹ̀. Àwọn olùṣèwádìí yẹn sọ pé, irú àwọn àǹfààní tígbó ń ṣe fún àyíká yìí ní ipa tó ń kó nínú ètò ọrọ̀ ajé.
Bí àpẹẹrẹ, wo agbára tí igbó ní láti tọ́jú afẹ́fẹ́ carbon pa mọ́. Nígbà tá a bá gé igi lulẹ̀ nínú igbó, afẹ́fẹ́ carbon tó máa ń jáde nígbà tí a bá dáná sun igbó yóò di afẹ́fẹ́ carbon dioxide tó bá dé ojú òfuurufú, tí yóò sì jẹ́ kí ayé túbọ̀ móoru. Nítorí náà, a lè mọ bí igi ṣe ń “ṣe aráyé láǹfààní” tó lórí ètò ọrọ̀ ajé tá a bá fi bó ṣe ń fi afẹ́fẹ́ carbon pa mọ́ wé iye tó ń ná àwọn èèyàn láti dín ìtújáde afẹ́fẹ́ carbon kù.
Gẹ́gẹ́ bí Marc J. Dourojeanni tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn àyíká ní ọ́fíìsì Báńkì Àjọdá ti Amẹ́ríkà tó wà ní orílẹ̀-èdè Brazil sọ, irú ìṣirò bẹ́ẹ̀ fi hàn pé “ìníyelórí igbó tó bá di ti fífi afẹ́fẹ́ carbon pa mọ́ pọ̀ fíìfíì ju ìníyelórí rẹ̀ tó bá di ti ká gé igi níbẹ̀ àti tá a bá fi dáko.” Síbẹ̀, ńṣe ni wọ́n kàn ń gé igi lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ. Kí ló fà á?
Ohun Tó Lè Mú Káwọn Èèyàn Ṣíwọ́ Pípagbórun
Àpẹẹrẹ kan nìyí: Àwọn èèyàn kan dá ilé iṣẹ́ kan tó ń pèsè iná mànàmáná sílẹ̀. Ilé iṣẹ́ yìí ń fún àwọn ìlú tó wà nítòsí ní iná mànàmáná, ṣùgbọ́n àwọn ará ìlú yìí kò san owó kankan padà. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, àwọn tó ni ilé iṣẹ́ náà rò pé, ‘Bí àwọn bá ti ilé iṣẹ́ náà pa, táwọn sì tú gbogbo ohun èlò tó wà níbẹ̀ tà, yóò mérè wá ju káwọn kàn fi ilé iṣẹ́ yẹn sílẹ̀ láìrí kọ́bọ̀ gbà lórí ẹ̀.’ Ó dà bíi pé díẹ̀ lára àwọn òṣìṣẹ́ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tí gẹdú pọ̀ sí náà rò bẹ́ẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn èèyàn ò sanwó fún àǹfààní tí wọ́n ń rí látara igbó, yóò ṣàǹfààní jù lọ nígbà náà láti pa igbó yẹn (ìyẹn, wíwó ilé iṣẹ́ iná mànàmáná náà palẹ̀, ká sọ̀ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀) káwọn sì ta àwọn igi tó wà níbẹ̀ (àwọn ohun èlò tá a tú ní ilé iṣẹ́ náà) kó lè tètè mérè ńlá wá ní kánmọ́kánmọ́, bí wọ́n ṣe ronú gan-an nìyẹn.
Gẹ́gẹ́ bí Dourojeanni ṣe sọ, ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà yí àṣà yìí padà ni pé ká mú káwọn èèyàn mọyì bí dídá igbó sí ṣe máa ń dín ìnáwó kù. Ọ̀mọ̀wé José Goldemberg, ọmọ ilẹ̀ Brazil tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ átọ́míìkì, tó tún jẹ́ ààrẹ fún Yunifásítì São Paulo nígbà kan rí sọ èrò tiẹ̀ pé ó yẹ káwọn gbé iye pàtó kan kalẹ̀ táwọn èèyàn tó ń lo epo tí à ń rí lára àkẹ̀kù ẹranko yóò máa san kárí ayé.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣagbátẹrù èrò yìí ṣe sọ, wọ́n ní iye tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan máa sàn yóò sinmi lé bí epo tí orílẹ̀-èdè yẹn ń lò ṣe pọ̀ tó àti bí àwọn afẹ́fẹ́ tí ń mú kí ayé móoru tó ń tibẹ̀ wá ṣe pọ̀ tó. Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó jẹ́ pé iye àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ tó nǹkan bí ìdá márùn-ún tá a bá dá gbogbo olùgbé ayé sí ọgọ́rùn-ún ń pèsè àwọn gáàsì amúǹkangbóná tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́rìnlélógún tá a bá dá èyí tí gbogbo ayé ń pèsè sí ọgọ́rùn-ún. Àwọn tó ń gbé ìlànà kalẹ̀ ronú pé owó tí irú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ bá san làwọn yóò lò bí owó àjẹmọ́nú fún àwọn orílẹ̀-èdè tó bá kọ̀ láti pa igbó wọn run nítorí èrè ojú ẹsẹ̀ tó wà nídìí gígé gẹdú. Lọ́nà yìí, wọ́n sọ pé àwọn èèyàn á san ‘owó iná’ wọn, èyí yóò sì jẹ́ ohun ìwúrí fáwọn tó ni ilé iṣẹ́ mànàmáná náà, yóò sì mú kí wọ́n fi ‘ilé iṣẹ́ mànàmáná’ náà sílẹ̀ láìwulẹ̀ tú ohun èlò tó wà níbẹ̀ tà mọ́.
Nígbà náà, ta ni yóò sọ iye táwọn èèyàn yóò máa san fún àwọn àǹfààní tí wọ́n ń rí látara àwọn ohun tó wà láyìíká? Ta sì ni yóò gba owó yẹn jọ tí yóò wá pín in?
Àfi Káwọn Èèyàn Yíwà Padà
Dourojeanni sọ pé: “Fífikùn lukùn níbi àpérò àgbáyé kan lórí ọ̀ràn tó jẹ mọ́ igbó lọ̀nà tó dára jù láti yanjú ọ̀rọ̀ yìí.” Irú àpérò bẹ́ẹ̀ á lè jẹ́ kí wọ́n pinnu iye táwọn orílẹ̀-èdè yóò máa san fún àǹfààní tí wọ́n ń rí látara igbó. Ó sọ síwájú sí i pé, “a wá lè gbé àjọ kan kalẹ̀ tí yóò máa bójú tó ètò tí gbogbo ayé ṣe yìí.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó lè bọ́gbọ́n mu láti lo àjọ àgbáyé kan fún bíbójú tó ìṣòro kan tó kan gbogbo ayé, síbẹ̀ Dourojeanni sọ pé: “Dídá oríṣiríṣi àjọ àti ìgbìmọ̀ sílẹ̀ láti bójú tó ọ̀ràn tó jẹ mọ́ igbó kò lè yanjú ìṣòro ọ̀hún.” Ó fi kún un pé ohun tá a nílò gan-an ni “ìyípadà kánmọ́kánmọ́ nínú ìwà àwọn èèyàn láwùjọ àti nínú ètò ọrọ̀ ajé.” Ní tòdodo, dídá igbó sí ju wíwulẹ̀ yí òfin padà lásán, ó gba káwọn èèyàn yí ìwà wọn padà.
Ǹjẹ́ irú àwọn ìṣòro báyìí lè yanjú láé? Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé ṣèlérí pé yóò yanjú. Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run ti fìdí ìjọba kan múlẹ̀ tí yóò ṣàkóso lé ayé lórí tí yóò sì yanjú gbogbo ìṣòro ayé láìpẹ́. Ìjọba yẹn ni “a kì yóò run láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Láfikún sí i, ìjọba náà yóò rí sí i pé ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn wà bó ṣe yẹ, nítorí pé àwọn olùgbé ayé yóò máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wọn, ẹni tí Bíbélì pe orúkọ rẹ̀ ní Jèhófà. (Aísáyà 54:13) Gbogbo àwọn èèyàn tó bá wà láàyè nígbà yẹn yóò mọyì ayé àti igbó tó wà nínú rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
Ricardo Beliel / SocialPhotos
© Michael Harvey/Panos Pictures