Mímú Òtítọ́ Bíbélì Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Kúrékùré
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ CAMEROON
Jákèjádò ayé, láwọn ilẹ̀ tó ju ọgbọ̀nlérúgba [230], àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbìyànjú láti mú ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ “gbogbo onírúurú ènìyàn.” (1 Tímótì 2:4; Mátíù 24:14) Lára àwọn tí wọ́n ti wàásù dé ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn Kúrékùré tó wà nílẹ̀ Áfíríkà, ìyẹn àwọn kúrúnbéte èèyàn kan tí wọn ò ga ju bíi mítà kan àti ẹ̀sún méjì sí mítà kan àti ẹ̀sùn mẹ́rìn ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin sí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin àbọ̀. Inú àwọn igbó tó wà ní orílẹ̀-èdè Central African Republic, ẹkùn ilẹ̀ Kóńgò àti ìlà oòrùn gúúsù orílẹ̀-èdè Cameroon ni wọ́n sábà máa ń gbé.
Ìgbà àkọ́kọ́ tó wà lákọọ́lẹ̀ pé àwọn àlejò fojú kan àwọn Kúrékùré yìí ni ìgbà tí Ọba Neferirkare tí í ṣe Fáráò ti ilẹ̀ Íjíbítì nígbà náà rán àwọn akọni kan kí wọ́n lọ wádìí orísun Odò Náílì. Àwọn ońṣẹ́ ọba yìí ròyìn pé nígbà táwọn dé àárín igbó réré láàárín gbùngbùn ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn ṣalábàápàdé àwọn èèyàn kan tí wọ́n kúrú jọjọ. Nígbà tó yá, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì náà, Homer àti onímọ̀ èrò orí náà, Aristotle sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kúrékùré yìí. Àwọn ara ilẹ̀ Yúróòpù ṣalábàápàdé àwọn èèyàn yìí ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún àti ìkẹtàdínlógún.
Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù nínú àwọn igbó tó wà nílẹ̀ Áfíríkà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kúrékùré yìí máa ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ akitiyan láti mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ọ̀rọ̀ náà jinlẹ̀ sí i kò kẹ́sẹ járí. Ìdí ni pé aṣíkiri làwọn Kúrékùré yìí, èyí túmọ̀ sí pé wọn kì í lò ju bí oṣù mélòó kan níbì kan tí wọ́n fi máa ń ṣí lọ sí ibòmíràn.
Èèyàn àlàáfíà làwọn Kúrékùré, wọ́n máa ń tijú, wọ́n á sì fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ tó ọ̀kẹ́ méje àbọ̀ [150,000] sí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] nílẹ̀ Áfíríkà. Àwọn ìjọba, àwọn lájọlájọ lágbàáyé àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti dá ilé ìwé sílẹ̀ fáwọn Kúrékùré yìí, bákan náà ni wọ́n tún kọ́ ilé tó bá bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn mu. Síbẹ̀, pàbó ni ọ̀pọ̀ akitiyan àwọn èèyàn láti mú kí wọ́n fìdí kalẹ̀ síbì kan ń já sí.
Ọmọ ilẹ̀ Cameroon kan tí tiẹ̀ yàtọ̀ gédégbé ni Janvier Mbaki, òun ni Kúrékùré tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀. Ó gba òtítọ́ Bíbélì lẹ́yìn tó ti ka ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye tó ní oríṣiríṣi àwòrán nínú, àtàwọn ìtẹ̀jáde mìíràn.a Janvier ṣèrìbọmi lọ́dún 2002, ó sì ń sìn báyìí bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn orúkọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pe àwọn àjíhìnrere alákòókò kíkún tí wọ́n wà láàárín wọn. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì tún ni nínú ìjọ Kristẹni tó ń dara pọ̀ mọ́ ní Mbang, ìlú kékeré kan tó wà ní ìlà oòrùn gúúsù orílẹ̀-èdè náà. Ó ṣì di ọjọ́ iwájú ká tó mọ̀ báwọn Kúrékùré púpọ̀ sí i láti orílẹ̀-èdè Cameroon bá máa yàn láti sin Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo náà tó nífẹ̀ẹ́ “gbogbo onírúurú ènìyàn.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde ṣùgbọ́n a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Janvier Mbaki, Kúrékùré tá a mọ̀ tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Cameroon, ó ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́