ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 12/8 ojú ìwé 20-23
  • Àwọn Kúrékùré—Àwọn Olùgbé Inú Igbó Jìndunjìndun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kúrékùré—Àwọn Olùgbé Inú Igbó Jìndunjìndun
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣèwádìí Nípa Àwọn Kúrékùré
  • Ìbẹ̀wò Àkọ́kọ́
  • Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́, Ìgbéyàwó, àti Ìdílé
  • Ìsìn
  • Àwọn Ènìyàn Onílàákàyè
  • Mímú Òtítọ́ Bíbélì Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Kúrékùré
    Jí!—2004
  • Àwọn Ìnira Ìgbà Ogun Mú Mi Gbára Dì fún Bá A Ṣeé Gbé Ìgbésí Ayé
    Jí!—2004
  • Pípiyẹ́ Àwọn Igbó Kìjikìji
    Jí!—1998
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 12/8 ojú ìwé 20-23

Àwọn Kúrékùré—Àwọn Olùgbé Inú Igbó Jìndunjìndun

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ OLÓMÌNIRA ÀÁRÍNGBÙNGBÙN ÁFÍRÍKÀ

Ẹ WÁ mọ àwọn BaBinga, àwọn Kúrékùré Ilẹ̀ Olómìnira Àáríngbùngbùn Áfíríkà tó jẹ́ ilé wa. Ẹ ti lè gbọ́ nípa àwọn Kúrékùré, kí ẹ sì ti kà nípa wọn, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí ẹ máà bá èyíkéyìí nínú wọn pàdé rí. Bí ẹ bá ṣèbẹ̀wò sí Bangui, tó jẹ́ olú ìlú, ìrìn àjò tí yóò gbé yín dé ibi tí wọ́n ń gbé kò tó wákàtí méjì.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní iṣẹ́ pàtàkì kan láti jẹ́ fún gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ìran, àti àwùjọ ìran. Nínú ìgbòkègbodò Kristẹni wa, a ń wàásù fún onírúurú ènìyàn láìdẹ́nìkansí. Àti àwọn Kúrékùré náà.—Ìṣípayá 14:6.

Nítorí náà, ẹ jọ̀wọ́ bá wa kálọ, ki ẹ sì wo bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé, àti bí wọ́n ṣe ń dáhùn sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tí yóò mú Párádísè wá sórí ilẹ̀ ayé. Yóò jẹ́ ọjọ́ alárinrin kan tí ń gbádùn mọ́ni gan-an fún yín.

Ṣíṣèwádìí Nípa Àwọn Kúrékùré

Ká tó gbéra, ó yẹ ká ṣèwádìí díẹ̀ nípa àwọn ènìyàn tí a óò bẹ̀ wò. Ọ̀pọ̀ ìwé ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ti gbé àárín àwọn Kúrékùré fún oṣù díẹ̀, tí wọ́n ti kọ́ nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn, ìsìn wọn, àti àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé wọn, ti kọ.

Kíkà nípa àwọn ènìyàn ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti oníwàbí-ọ̀rẹ́ wọ̀nyí, kí a sì wá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn lẹ́yìn náà yóò dáhùn àwọn ìbéèrè mélòó kan, bí: Ibo ni àwọn Kúrékùré ti wá? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára wọn? Ibo ni wọ́n ń gbé? Kí ló mú wọn yàtọ̀ sí àwọn àwùjọ ilẹ̀ Áfíríkà míràn? Báwo ni wọ́n ṣe ń bá àwọn ènìyàn tó kù gbé?

Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Webster’s Third New International Dictionary, sọ pé àwọn Kúrékùré jẹ́ “àwọn ènìyàn onírìísí kékeré tí ń gbé ibi ìlà agbedeméjì òbìrí ayé ní Áfíríkà, tí wọn kì í ga tó mítà 1.5, . . . tí wọ́n ń sọ èdè àwọn alámùúlégbè tó sún mọ́ wọn jù.” A lérò pé àwọn Kúrékùré ilẹ̀ Áfíríkà kò bá àwọn Negrito (tí ó túmọ̀ sí “Àwọn Adúláwọ̀ Kéékèèké”) ti àgbègbè Oceania àti ìhà ìlà oòrùn gúúsù ilẹ̀ Éṣíà tan.

Ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, “pygmy” [kúrékùré], wá láti inú ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì kan tó túmọ̀ sí “àlàfo àárín ìgúnpá sí ọrùn ọwọ́.” A mọ àwọn Kúrékùré sí ọdẹ àti alákòójọ. Àfojúbù àpapọ̀ iye àwọn Kúrékùré lágbàáyé lé díẹ̀ ní 200,000.

Serge Bahuchet àti Guy Philippart de Foy fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé wíwọnilọ́kàn sí i nínú ìwé wọn náà, Pygmées—peuple de la forêt (Àwọn Kúrékùré—Àwọn Olùgbé Inú Igbó). Wọ́n sọ pé àwọn Kúrékùré ń gbé inú igbó jìndunjìndun Ilẹ̀ Olómìnira Congo, Ilẹ̀ Olómìnira Olóṣèlú Congo, Gabon, Cameroon, àti Ilẹ̀ Olómìnira Àáríngbùngbùn Áfíríkà, a sì lè rí wọn ní ìhà ìlà oòrùn jíjìnnà ní Rwanda àti Burundi.

Kò sí ẹni tí ó mọ ibi tí àwọn Kúrékùré ti wá tàbí ìgbà tí wọ́n gúnlẹ̀ ní ti gidi. Wọn kò pe ara wọn ní “kúrékùré” rí. Ní Ilẹ̀ Olómìnira Àáríngbùngbùn Áfíríkà, gbogbo ènìyàn máa ń pè wọ́n ní BaBinga, ṣùgbọ́n ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn, a mọ̀ wọ́n sí BaKola, BaBongo, BaAka, BaMBènzèlè, BaTwa, àti BaMbuti.

Ìbẹ̀wò Àkọ́kọ́

A wọ ọkọ̀ Land Cruiser kan kúrò ní Bangui ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ní nǹkan bí agogo méje, lọ sí M’Baiki/Mongoumba ní ìhà gúúsù. Wọ́n da ọ̀dà sí 100 kìlómítà àkọ́kọ́ lójú ọ̀nà náà. Ó dára láti ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ń bá jíà ṣiṣẹ́, nítorí pé ọ̀nà náà ń yọ̀ lẹ́yìn òjò tó rọ̀ lálẹ́ àná.

A gba àgbègbè àrọko onígbó kìjikìji àti àárín àwọn abúlé kéékèèké níbi tí àwọn ènìyàn pàtẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹẹrẹ, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà, ọ̀pẹ̀yìnbó, pákí, àgbàdo, èso squash, àti ẹ̀pà sórí tábìlì kéékèèké lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì. Wọn kò mọ ìyàn níbí yìí. Ilẹ̀ ọlọ́ràá àti ipò ojú ọjọ́ tí ó lọ́rinrin ń mú onírúurú oúnjẹ wá lọ́pọ̀ yanturu. Wúrẹ́ la yọ sí “abúlé,” tàbí àgọ́ àkọ́kọ́, ti àwọn BaBinga.

Wọ́n ń gbé inú àwọn ahéré olórùlé-rìbìtì tí ó kéré gan-an, tí ó ní ẹnu ọ̀nà kan tí ó tóbi tó láti rá gbà kọjá. Àwọn obìnrin ló ń fi igi àti ewé tí wọ́n gé láti inú igbó ìtòsí kọ́ àwọn ahéré. Wọ́n ń to nǹkan bí ahéré 10 sí 15 sí òbírípo kan. Ibi tí wọ́n ń sùn tàbí tí wọ́n ń forí pamọ́ sí bí òjò ńlá bá ń rọ̀ lásán ni wọ́n fi ìwọ̀nyí ṣe. Ìta gbangba ni wọ́n ti ń gbé ìgbésí ayé ojoojúmọ́ wọn.

A bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà láti kí àwọn obìnrin kan tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn pọn ọmọ. Nígbà tí àwọn ọkùnrin kan gbúròó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa, wọ́n sáré wá mọ ẹni tí a jẹ́ àti ohun tí a fẹ́. Àwọn ajá bíi mélòó kan, tí wọ́n so agogo kékeré kan mọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lọ́rùn, bá wọn wá.

A rántí láti inú ìwádìí tí a ti ṣe pé ajá nìkan ni ẹran ọ̀sìn tí àwọn Kúrékùré máa ń ní. Wọ́n jẹ́ alájọṣepọ̀ wọn nínú ọdẹ ṣíṣe. Bẹ́ẹ̀ sì ni oríṣiríṣi ẹran wà tí wọ́n lè pa, yálà lórí ilẹ̀ tàbí lórí igi. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Pygmées—peuple de la forêt, ṣe ṣàlàyé, àwọn ẹyẹ, ọ̀bọ, erin, ẹfọ̀n, eku, ẹtu, ẹlẹ́dẹ̀ ẹgàn, ọ̀kẹ́rẹ́, àti àwọn mìíràn wà lára wọn. Ajá adúrótini kan jẹ́ àìgbọdọ̀mánìí fún olúkúlùkù ọdẹ.

A bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀ ní lílo ìwé náà, Iwe Itan Bibeli Mi, àti ìwé pẹlẹbẹ náà, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!a Ìwọ̀nyí fi àwòrán ṣàpèjúwe pé láìpẹ́, ilẹ̀ ayé yóò di párádísè tí ó ní igbó dáradára, níbi tí kò ti ní sí àìsàn àti ikú. (Ìṣípayá 21:4, 5) A tẹ àwọn ìtẹ̀jáde méjèèjì ní èdè Sango, èdè tí iye tí ó lé ní ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùgbé ibẹ̀, títí kan àwọn Kúrékùré, ń sọ. Àwọn ènìyàn ẹlẹ́mìí àlàáfíà wọ̀nyí, níbi yòó wù kí wọ́n máa gbé, ń sọ èdè àwọn ará Áfíríkà alámùúlégbè wọn. Èyí ṣe pàtàkì nítorí pé wọn máa ń jọ ṣòwò.

Ká tó pajú pẹ́, àwọn ọkùnrin àti obìnrin mélòó kan ti wá dúró tì wá, wọ́n ń wo àwọn àwòrán inú ìwé níkọ̀ọ̀kan tìyanutìyanu bí wọ́n ti ń gbọ́ àwọn àlàyé tí a ń ṣe. Láti inú àwọn ìbẹ̀wò tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ ní àwọn ọdún tó kọjá, wọ́n ti mọ̀ wá sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú wọn dùn láti gba àwọn ẹ̀dà àwọn ìtẹ̀jáde náà. Àmọ́, ìṣòro ibẹ̀ ni pé wọn kò lè kàwé. Tipẹ́tipẹ́ ni ìjọba àti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn ti ń sapá láti kọ́ wọn bí a ti ń kàwé tí a sì ń kọ̀wé, àmọ́ pàbó ló ń já sí. Wọ́n ṣètò ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ wọn. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà ṣiṣẹ́ fún àkókò kan, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ náà ló fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn-ò-rẹ́yìn. Olùkọ́ kan tí ó ti kọ́ àwọn Kúrékùré rí sọ pé, bí wọ́n bá wà ní kíláàsì, wọ́n ń fi ẹ̀rí hàn pé wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí ó pegedé, àmọ́ lẹ́yìn wíwá sí ilé ẹ̀kọ́ fún oṣù bíi mélòó kan, wọn óò wulẹ̀ pòórá ni. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn aláṣẹ àdúgbò àti àwọn mìíràn ṣì ń sapá láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ìwé.

A mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pa dà bẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ìfẹ́ ọkàn hàn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò. Àmọ́ a kì í retí láti bá àwọn BaBinga kan náà nígbà tí a bá pa dà wá, níwọ̀n bí wọ́n ti máa ń kó kiri jálẹ̀ ọdún. Ẹ̀ẹ̀kan tí wọ́n bá gbéra, wọ́n máa ń wọ inú igbó jìndunjìndun tí ó jẹ́ ilé wọn lọ fún ọ̀pọ̀ oṣù. Ìsapá láti fìdí wọn kalẹ̀ síbì kan kò fi bẹ́ẹ̀ kẹ́sẹ járí. Ní gidi, olùgbé inú igbó jìndunjìndun ni wọ́n. Kíkáàkiri àti ṣíṣọdẹ ni ọ̀nà ìgbésí ayé wọn, kò sì sí ohun tó lè yí i pa dà.

Ìgbésí Ayé Ojoojúmọ́, Ìgbéyàwó, àti Ìdílé

Ní pàtàkì, àwọn ọkùnrin ló máa ń ṣiṣẹ́ ọdẹ, àwọn obìnrin sì ń ṣàkójọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí ó wà nínú igbó ni wọ́n ń ṣà: olú, gbòǹgbò igi, àwọn èso oníwóóníṣu, ewé, kóró èso, kòkòrò, ikán, oyin ìgàn, ká má sì gbàgbé, kòkòrò mùkúlú tí wọ́n yàn láàyò. Wọ́n nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí fún oúnjẹ àti òwò. Àwọn ará Áfíríkà, tí a sábà máa ń pè ní les grand noirs (àwọn adúláwọ̀ gíga), tó múlé gbè àwọn Kúrékùré, gbẹ́kẹ̀ lé wọn gan-an láti lè rí àwọn nǹkan wọ̀nyí. Wọ́n máa ń fi wọ́n gba ìpààrọ̀ ìkòkò, abọ́, àdá, ohun èlò bí àáké àti ọ̀bẹ, iyọ̀, epo pupa, pákí, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà, ó ṣeni láàánú pé wọ́n tún máa ń gba tábà, ògógóró, àti igbó. Àwọn nǹkan mẹ́ta tó kẹ́yìn yẹn jẹ́ ìṣòro ńlá fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ènìyàn wọ̀nyí. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń jẹ gbèsè láti lè rà wọ́n, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ba ìgbésí ayé wọn jẹ́ díẹ̀díẹ̀.

Àwọn ọkùnrin sábà máa ń ní ìyàwó kan. Àmọ́, wọ́n máa ń tètè kọra sílẹ̀ tàbí kí wọ́n pín yà láti gbé pẹ̀lú alájọṣe mìíràn. Bàbá tàbí ẹni tí ó dàgbà jù lọ ní àgọ́ náà ni wọ́n bọ̀wọ̀ fún jù lọ. Kì í pàṣẹ, àmọ́ wọ́n sábà máa ń gba àmọ̀ràn rẹ̀. Ìwọ yóò rí i pé àwọn Kúrékùré nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn. Ìyá àti Bàbá máa ń gbé àwọn ọmọ mọ́ra lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn ọmọ kéékèèké wọ̀nyí sábà máa ń wà pẹ̀lú àwọn òbí méjèèjì níbikíbi tí wọ́n bá ń lọ àti nídìí ohunkóhun tí wọ́n bá ń ṣe, yálà wọ́n ń ṣiṣẹ́, wọ́n ń ṣọdẹ, tàbí wọ́n ń jó.

Àárín àwọn òbí ni ọmọ ọwọ́ máa ń sùn lóru. Lójú mọmọ, àwọn òbí, àwọn ẹ̀gbọ́n, àwọn àbúrò, àwọn ìbátan, àti àwọn òbí àgbà máa ń bójú tó àwọn ọmọ kéékèèké, yàtọ̀ sí ìyẹn, gbogbo àgọ́ náà máa ń kíyè sí wọn. Lemọ́lemọ́ ni àwọn òbí àti àwọn ẹbí máa ń bẹ ara wọn wò. Gbogbo èyí ń mú kí okùn àjọbí wà sẹpẹ́. Nínú ọ̀làjú ìhà Ìwọ̀ Oòrùn, okùn àjọbí sábà ń tú tàbí kí ó já, àmọ́ ọ̀ràn yàtọ̀ gan-an níhìn-ín.

Bí àwọn Kúrékùré tilẹ̀ ń dá gbé lọ́tọ̀ láìdàpọ̀ mọ́ àwọn ará Áfíríkà tó múlé gbè wọ́n, wọ́n jọ máa ń ṣòwò. Yàtọ̀ sí àjọṣe déédéé ti ìṣòwò, wọ́n ń ṣàgbàṣe lóko kọfí àti kòkó. Wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ mélòó kan, kí wọ́n gbowó, kí wọ́n sì tún wọnú igbó jìndunjìndun lọ fún sáà gígùn kan. Ta ló mọ̀? Bóyá àwọn Kúrékùré Àáríngbùngbùn Áfíríkà ti ṣiṣẹ́ lóko tí kọfí tí o mu láàárọ̀ yí ti wá.

Ìsìn

Ẹlẹ́mìí ìsìn ni àwọn BaBinga, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ní ń ṣàkóso ọ̀ràn ìsìn wọn. Wọ́n máa ń ṣe ààtò ìsìn wọn pẹ̀lú ohùn orin, orin kíkọ (ìyohùnsóhùn), àti ijó jíjó. Ìwé náà, Ethnies—droits de l’homme et peuples autochtones (Àwọn Àwùjọ Ẹ̀yà—Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn àti Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀), ṣàlàyé pé: “Ní ti àwọn olùgbé inú igbó jìndunjìndun, Ọlọ́run dá ayé, tí ó túmọ̀ sí igbó. Lẹ́yìn tí ó dá tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn kíní . . . , ó pa dà sí ọ̀run, kò sì ní ọkàn ìfẹ́ nínú àwọn àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn mọ́. Ní báyìí, ẹ̀dá ẹ̀mí gíga jù kan, ọlọ́run igbó, ló ń delé dè é.” Ó dájú pé èyí yàtọ̀ pátápátá sí àlàyé tí a rí nínú Bíbélì nípa Ọlọ́run àti ète rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì orí 1, 2; Orin Dáfídì 37:10, 11, 29.

Àwọn Ènìyàn Onílàákàyè

Lọ́nà wíwọ́pọ̀, àwọn ènìyàn kan máa ń fi àwọn Kúrékùré ṣẹ̀sín, tàbí wọ́n tilẹ̀ máa ń fojú kéré wọn, ní kíkà wọ́n sí ẹni tí ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ láwùjọ, tí làákàyè rẹ̀ kò sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n Patrick Meredith, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ipa tí ìrísí ara ń ní lórí ìrònú òun ìhùwà, ní Yunifásítì Leeds, England, wí pé: “Bí o bá bá àwọn kúrékùré ní àyíká àdánidá wọn, tí wọ́n ń fi fọ́nrán tí wọ́n yọ lára igi ṣe afárá, tí wọ́n sì ń ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé, o lè ṣe kàyéfì nípa ohun tí o ní lọ́kàn nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa làákàyè.”

A mọ̀ pé gbogbo ìran ènìyàn jẹ́ àtọmọdọ́mọ takọtabo ẹ̀dá ènìyàn kíní, Ádámù àti Éfà. Ìṣe 17:26 sọ pé: “Láti ara ọkùnrin kan [Ádámù] ni [Ọlọ́run] . . . ti ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.” Ìṣe 10:34, 35 sì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” Nítorí náà, a fẹ́ láti mú òtítọ́ Bíbélì dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí, kí àwọn pẹ̀lú lè ní ìrètí láti wà láàyè ní àkókò tí kò pẹ́ mọ́ náà, tí a óò yí gbogbo ilẹ̀ ayé pa dà di párádísè ẹlẹ́wà kan tí ọ̀pọ̀ igbó jìndunjìndun kún inú rẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

1. Bíbá àwọn Kúrékùré ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ inú Bíbélì; 2. Kúrékùré tó jẹ́ agbẹ́gilére; 3. àmúṣàpẹẹrẹ ibùgbé àwọn Kúrékùré

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́