ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 10/8 ojú ìwé 14-16
  • Bí Èèyàn Rẹ Kan Bá Lárùn Ọpọlọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Èèyàn Rẹ Kan Bá Lárùn Ọpọlọ
  • Jí!—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àárẹ̀ Ọpọlọ​—Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2023
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Má Ṣe Sọ̀rètí Nù
    Jí!—2004
  • Kíkojú Ìṣòro Kí Ìṣesí Ẹni Máa Ṣàdédé Yí Padà
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 10/8 ojú ìwé 14-16

Bí Èèyàn Rẹ Kan Bá Lárùn Ọpọlọ

BÍ OJÚMỌ́ ṣe máa ń mọ́ láràárọ̀ lojú mọ́ wọn lọ́jọ́ yìí nílé Johnson.a Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà nínú ìdílé yìí ló ti jí tí wọ́n sì ti múra iṣẹ́ ọjọ́ náà. Gail, tó jẹ́ ìyá lọ rán Matt ọmọkùnrin rẹ̀ létí pé ó ti ń pẹ́ láti lọ wọkọ̀ tó máa gbé e lọ sílé ìwé. Kò sẹ́ni tó retí ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. Láàárín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, Matt ti fín ọ̀dà sára ògiri yàrá tó ń sùn, ó gbìyànjú láti kán iná sí ibi tí wọ́n ń gbé ọkọ̀ sí, ó sì tún fẹ́ so okùn mọ́gi àjà kó lè pokùnso.

Gail àti Frank, ọkọ rẹ̀ tẹ̀ lé áńbúláǹsì tó gbé Matt lọ, wọ́n sì ń gbìyànjú lójú méjèèjì láti mọ ìtumọ̀ nǹkan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀. Àṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mẹ́yẹ bọ̀ lápò ni. Látìgbà yẹn lọ ni Matt ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí aláágànná, ó dẹni tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò bá taráyé mu mọ́, ó wá di alárùn ọpọlọ. Láàárín ọdún márùn-ún tí àrùn yìí fi jẹ ẹ́ níyà, ó ti gbìyànjú láti para ẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ti tì í mọ́lé lẹ́ẹ̀mejì, wọ́n sì ti dá a dúró sílé ìwòsàn àwọn alárùn ọpọlọ lẹ́ẹ̀méje, àìmọye ìgbà ló sì ti dé iwájú àwọn ògbógi nínú ìtọ́jú ọpọlọ. Àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ rẹ̀ kì í mọ ohun tí wọn ì bá ṣe tàbí tí wọ́n ì bá sọ nítorí pé gbogbo nǹkan ló tojú sú wọn.

Ìṣirò fi hàn pé ẹnì kan nínú ẹni mẹ́rin lára àwọn tó wà láyé, ni irú àrùn ọpọlọ kan máa sọ wò kí wọ́n tó kú. Tá a bá fi ti ìṣirò yìí pè, ó ṣeé ṣe kí òbí rẹ, ọmọ rẹ, ọmọ ìyà ẹ, tàbí ọ̀rẹ́ ẹ kan ní irú ìṣòro ọpọlọ kan tàbí òmíràn. Kí lo lè ṣe bí èèyàn rẹ kan bá lọ ní irú àrùn yìí?

● Mọ àwọn àmì rẹ̀. Ó lè pẹ́ díẹ̀ kí wọ́n tó mọ̀ pé ẹnì kan ní àrùn ọpọlọ. Tí àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí bá rí àwọn àmì tó ṣàjèjì, ohun tí wọ́n máa rò pé ó fà á ni ìyípadà nínú àgọ́ ara, ara tí ò le, àléébù nínú ìwà, tàbí ràbọ̀ràbọ̀ ohun tí ẹni tí àmì náà wà lára rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ là kọjá. Ìyá Matt ti rí àwọn àmì kan tẹ́lẹ̀ tó fi hàn pé Matt níṣòro, ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ rò pé ìṣesí rẹ̀ tó yí padà jẹ́ ara àwọn ìdààmú tó máa ń ṣẹlẹ̀ lásìkò tí ọmọ kan bá ń bàlágà, wọ́n sì rò pé kò ní pẹ́ táwọn àmì yẹn á fi kọjá lọ. Àmọ́, tó bá di pé ìyàtọ̀ púpọ̀ ti wà nínú bí ẹnì kan ṣe ń sùn, bó ṣe ń jẹun tàbí bó ṣe ń hùwà, ìyẹn lè fi hàn pé ohun tó ń ṣe é ti kúrò ní kékeré. Tẹ́ ẹ bá lọ fún àyẹ̀wò lọ́dọ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ẹ lè rí ìtọ́jú tó dáa gbà, ìyẹn sì lè mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ rọrùn fún ìbátan rẹ tó lárùn náà.

● Mọ̀ nípa rẹ̀. Ó níbi tí àwọn alárùn ọpọlọ sábà máa ń lè ṣèwádìí fúnra wọn dé nítorí àtimọ ohun tó ń ṣe wọ́n. Nítorí náà, àwọn ìsọfúnni tó o bá rí, láti orísun ìsọfúnni tó ṣì bóde mu tó sì ṣeé gbára lé, lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ìṣòro tí èèyàn rẹ ń dojú kọ. Á tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ láìfòyà tí ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ á sì mọ́gbọ́n dání. Bí àpẹẹrẹ, Gail, ìyá Matt fún àwọn òbí ọkọ rẹ̀ ní ìwé pélébé tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣègùn tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ púpọ̀ sí i nípa àrùn náà tó sì tún mú kí wọ́n lè bá wọn bójú tó ipò náà.

● Tètè tọ́jú ẹni tó bá lárùn náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àrùn ọpọlọ kan wà tí wọn kì í lọ bọ̀rọ̀, síbẹ̀ táwọn tó lárùn náà bá rí ìtọ́jú tó péye, wọ́n lè gbádùn ìgbésí ayé bí ẹni tí nǹkan ò ṣe, tí wọ́n á sì máa bá iṣẹ́ wọn lọ. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ àwọn tó lárùn yìí máa ń lálàṣí fún ọ̀pọ̀ ọdún láì rẹ́ni tọ́jú wọn. Bí ẹni tó lárùn ọkàn ṣe nílò akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó mọ̀ nípa ìtọ́jú ọkàn, bẹ́ẹ̀ lẹni tó lárùn ọpọlọ náà ṣe nílò àwọn tó mọ̀ nípa ìtọ́jú àrùn náà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ nípa ìrònú àti ọpọlọ lè fún alárùn ọpọlọ ní oògùn tó jẹ́ pé tó bá ń lò ó déédéé, á lè mú kí ìṣesí rẹ̀ wà déédéé, yóò dín àníyàn rẹ̀ kù, kò sì ní jẹ́ kó máa ronú sódì.b

● Rọ ẹni tó lárùn náà pé kó má bo ohun tó ń ṣe é mọ́ra. Àwọn tí àrùn ọpọlọ ń dà láàmú lè má mọ̀ pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́. O lè dá a lábàá pé kí aláìsàn náà lọ rí dókítà kan tó o mọ̀, kó ka àwọn àpilẹ̀kọ tó lè ràn án lọ́wọ́ tàbí fọ̀rọ̀ jẹ̀wọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tó ti kápá irú àrùn bẹ́ẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ẹni rẹ yìí kò fẹ́ fetí sí ìmọ̀ràn rẹ. Ní gbogbo ọ̀nà, o ṣáà gbọ́dọ̀ ṣe nǹkan kan bó bá dà bíi pé ẹnì kan tó ò ń tọ́jú fẹ́ ṣe ara ẹ̀ tàbí ẹlòmíràn léṣe.

● Má di ẹ̀bi ru ẹnikẹ́ni. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò tíì lè sọ̀rọ̀ pàtó lórí ipa tí apilẹ̀ àbùdá, àyíká téèyàn ń gbé àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ ń kó lórí ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ. Oríṣiríṣi nǹkan tó lè para pọ̀ fa àrùn ọpọlọ ni fífi ọpọlọ ṣèṣe, ìlòkulò oògùn, àwọn ìṣòro tójú ń rí láyìíká, ìṣiṣẹ́gbòdì àwọn èròjà inú ara àti ìṣòro àjogúnbá. Kò sí àǹfààní kankan nínú dídi ẹ̀bi ru àwọn ẹlòmíì lórí nǹkan tó o kà sí àfọwọ́fà wọn nípa àrùn náà. Ohun tá á dára kó o ṣe ni pé kó o máa sa gbogbo agbára rẹ láti ran aláìsàn náà lọ́wọ́ kó o sì fún un ní ìṣírí.

● Mọ nǹkan tó yẹ kí ẹni tó lárùn náà lè ṣe àti nǹkan tí kò lè ṣe. Tó o bá ń retí pé kí ẹni tó lárùn náà ṣe kọ́já agbára ẹ̀, o lè bà á lọ́kàn jẹ́. Ẹ̀wẹ̀, tó o bá tún fojú kéré rẹ̀, o lè sọ ọ́ di ẹni tí kò lè dá nǹkan kan ṣe. Nítorí náà, mọ ohun tó yẹ kí aláìsàn náà lè ṣe àti nǹkan tí kò lè ṣe. Ìyẹn ò wá sọ pé kó o fàyè gbàgbàkugbà o. Gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni mìíràn, àwọn tó lárùn ọpọlọ náà lè fi àbájáde nǹkan tí wọ́n bá ṣe ṣàríkọ́gbọ́n. Tó bá hùwà ipá wọ́n lè fi òfin gbé e tàbí kí wọ́n pàṣẹ fún un pé kó máà bá àwọn ẹlòmíràn ṣe nǹkan pọ̀ mọ́ fún ààbò tiẹ̀ àti tàwọn ẹlòmíràn.

● Má pa á tì. Ó ṣe pàtàkì pé kó o máa bá ẹni náà sọ̀rọ̀ déédéé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà mìíràn ó lè máa ṣi ọ̀rọ̀ rẹ lóye. O lè má mọ bí ẹni tó lárùn ọpọlọ á ṣe ṣe nígbà tó o bá ń bá a sọ̀rọ̀, bó ṣe ń ṣe lè máà bá nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ mu. Síbẹ̀síbẹ̀, tó o bá ń sọ fún alárùn ọpọlọ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò bá tayé mu, ńṣe ni wàá kàn tún máa di ẹ̀bi ru ẹni tí ọkàn rẹ̀ ti dà rú tẹ́lẹ̀. Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ ò bá wọ̀ ọ́ létí, jókòó jẹ́ẹ́ kó o sì máa fetí sí gbogbo ohun tó bá ń sọ. Bó bá ṣe ń sọ tinú ẹ̀ àti ìmọ̀lára rẹ̀ fún ọ, jẹ́ kó mọ̀ pé ò ń gbọ́ ọ, má sì dá a lẹ́bi. Gbìyànjú láti dúró jẹ́ẹ́. Ìwọ àti ẹni náà á jàǹfààní tó o bá kàn rọra ń fi hàn án ní gbogbo ìgbà pé o wà fún un. Bó ṣe ṣẹlẹ̀ lórí ọ̀ràn Matt nìyẹn. Lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó sọ nípa wọn pé “wọ́n ń ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mi ò fẹ́ ìrànlọ́wọ́.”

● Máa ronú nípa ohun táwọn tó kù nínú ìdílé nílò. Nígbà tó bá di pé ẹni tára rẹ̀ ò yá ni gbogbo wọn nínú ídílé pawọ́ pọ̀ ń tọ́jú, ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa àwọn tó kù tì. Ìgbà kan wà tí Amy tó jẹ́ àǹtí Matt ń ronú pé “àrùn tó ń ṣe àbúrò òun kò jẹ́ káwọn èèyàn ronú nípa” òun mọ́. Ó dín bó ṣe ń ṣe dáadáa tẹ́lẹ̀ kù kó má bàa di pé àwọn èèyàn ń ronú nípa rẹ̀. Àwọn òbí rẹ̀ sì ń fẹ́ kó ṣe dáadáa jù bẹ́ẹ̀ lọ, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń fẹ́ kó ṣiṣẹ́ tiẹ̀ àti ti àbúrò rẹ̀ pọ̀. Irú àwọn ọmọ tí wọ́n bá mójú kúrò lára wọn báyìí máa ń fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀ káwọn èèyàn bàa lè rántí wọn. Àwọn ìdílé tí wọ́n níṣòro nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn láti lè ṣe ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílè nílò. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìṣòro àrùn Matt gba ìdílé Johnson lọ́kàn pátápátá, àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò yẹn ran Amy lọ́wọ́ nípa fífún un láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀.

● Rọ àwọn tó wà nínú ìdílé pé kí wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan tá á jẹ́ kí ọpọlọ wọn máa jí pépé. Ó yẹ kí ẹ ní ìṣètò tá á mú kí ọpọlọ yín túbọ̀ máa jí pépé, irú bíi jíjẹ oúnjẹ tó dára, ṣíṣeré ìmárale, sísùn tó àti lílọ sí òde. Tẹ́ ẹ bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ yín ṣe àwọn nǹkan tó rọrùn, ìyẹn ò ní fi bẹ́ẹ̀ fa ìnìra. Tún rántí pé ọtí líle lè pa kún ìwà eléwu tí ẹni tó ń ṣàìsan náà ń hù ó sì lè máà jẹ́ kí oògùn ṣiṣẹ́ dáadáa. Ní báyìí, àwọn ìdílé Johnson ń gbìyànjú láti máa ṣe àwọn nǹkan tó ṣàǹfààní láti mú kí ọpọlọ gbogbo àwọn tó wà nínú ilé máa jí pépé, pàápàá jù lọ ti ọmọkùnrin wọn.

● Tọ́jú ara ẹ. Àwọn ìṣòro tó o bá dojú kọ nígbà tó ò ń tọ́jú alárùn ọpọlọ lè kó bá ìlèra tìẹ fúnra rẹ. Ó ṣe pàtàkì nígbà náà pé kó o kíyè sí ara rẹ, kó o fúnra ẹ nísinmi, kó o fira ẹ lọ́kàn balẹ̀ kó o sì máa bójú tó ipò tẹ̀mí ẹ. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n nínú ìdílé Johnson. Gail gbà pé ìgbàgbọ́ òun ló ran òun lọ́wọ́ láti fàyà rán ìṣòro ìdílé òun. Ó sọ pé: “Oògùn amáratuni làwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ fún mi, àkókò yẹn ni èèyàn máa ń lè pa àwọn ìṣòrò tó ní tì tá á sì lè máa rónú lórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù àti ìrètí ayé tuntun tó ní. Àìmọye ìgbà tí mo ti gbàdúrà fún ìtura ni nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ tí yóò mú kí ìnira náà dín kù. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run, mo ní ìbàlẹ̀ ọkàn táwọn tó bá wà nírú ipò tá a wà kì í sábà ní.”

Matt ti ń dàgbà báyìí, ó sì ti ń fojú tó dáa wo ọ̀ràn ìgbésí ayé rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo rí i pé ohun tójú mi rí ti jẹ́ kí n dẹni tó túbọ̀ dáa sí i.” Amy, tó jẹ́ àǹtí Matt sọ pé òun náà ti rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé àwọn. Ó sọ pé: “N kì í fi bẹ́ẹ̀ ta ko àwọn ẹlòmíì. O ò lè mọ ohun tó ń bá olúkúlùkù fínra lábẹ́ aṣọ. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló mọ̀ ọ́n.”

Tí ẹnì kan tó o fẹ́ràn bá lárùn ọpọlọ, máa rántí nígbà gbogbo pé tó o bá ń tẹ́tí sí i, tó ò ń ràn án lọ́wọ́, tó ò sì lérò tí ò dáa sí i, wàá lè ràn án lọ́wọ́ láti kojú ẹ̀, kódà láti lè máa gbé ìgbésí ayé ẹ̀ lọ láìsọsẹ̀.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ padà.

b Béèyàn bá ṣe ń ro ti àǹfààní tó wà nínú ìtọ́jú kan ló yẹ kó máa ro ìṣòro tó lè tìdí ẹ̀ yọ. Ìwé ìròyìn Jí! kò fọwọ́ sí ìtọ́jú ìṣègùn kankan o. Àwọn Kristẹni ní láti rí i dájú pé ìtọ́jú èyíkéyìí tí wọ́n gbà kò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwọn Àmì Tó O Fi Lè Mọ Àrùn Ọpọlọ

Bó o bá rí irú àwọn àmí wọ̀nyí lára ará ilé ẹ kan, á dáa kí onítọ̀hún kàn sí àwọn ògbógi nínú ìtọ́jú ọpọlọ:

• Tó bá ń banú jẹ́ fún àkókò gígùn tàbí tí inú bá ń bí i

• Tí kò bá fẹ́ bá àwọn èèyàn da nǹkan pọ̀

• Tí ìṣesí ẹ̀ bá ṣàdédé ń yí padà sí ìbínú tàbí ìdùnnú

• Bó bá máa ń bínú jù

• Bó bá ń hùwà ipá

• Tó bá ń lo oògùn olóró

• Bí àṣejù bá ti wọ ẹ̀rù tó ń bà á, bó ṣe ń dààmú tàbí bó ṣe ń ṣàníyàn

• Bó bá ń bẹ̀rù jù tórí kó má bàa sanra

• Bí ìyàtọ̀ tó lágbára bá wọ ọ̀nà tó ń gbà jẹun tàbí bó ṣe ń sùn

• Bó bá ń lá àlákálàá lemọ́lemọ́

• Bí ìrònú rẹ̀ bá ń dà rú

• Bó bá ń ní ìrònú èké tàbí kó máa ṣe ìrànrán

• Bó bá ń ro ikú ro ara ẹ̀ tàbí bó bá ń ronú láti pa ara ẹ̀

• Bí ìṣòro bá ń kà á láyà táwọn nǹkan tó ń ṣe lójoojúmọ́ bá ṣòro ṣe fún un

• Bó bá ń sẹ́ pé kò sí ìṣòro nígbà tó hàn gbangba pé ìṣòro wà

• Bí àwọn àìsàn tí ò ṣeé ṣàlàyé bá pọ̀ jù lára ẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Bó bá di pé ọ̀rọ̀ rẹ ò wọ aláìsàn náà létí mọ́, ṣáà jókòó jẹ́ẹ́ kó o sì máa gbọ́ ohun tó ń sọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́