ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/06 ojú ìwé 20-23
  • Kíkojú Àwọn Ìṣòro Ọjọ́ Ogbó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkojú Àwọn Ìṣòro Ọjọ́ Ogbó
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Ti Dàgbà, Síbẹ̀ Ọpọlọ Wọ́n Jí Pépé
  • Àwọn Ìṣòro Tó Jẹ Mọ́ Gbígbàgbé àti Àìlera Tó Ṣeé Wò
  • Ohun Tẹ́ni Tó Ní Ìsoríkọ́ Lè Ṣe
  • Kò Sí Ìdí Láti Máa Rò Pé O Ò Wúlò
  • Béèyàn Ṣe Lè Máa Ṣe Gbogbo Ohun Tágbára Rẹ̀ Gbé
  • Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ògo-ẹwà Orí-ewú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Ìdílé Kristian Ń Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Hùwà Sí Àwọn Àgbàlagbà?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 4/06 ojú ìwé 20-23

Kíkojú Àwọn Ìṣòro Ọjọ́ Ogbó

“ÀÁDỌ́RIN ọdún ni gbogbo ohun tí a ní—ọgọ́rin ọdún, bí a bá lágbára; síbẹ̀ gbogbo ohun tí wọ́n ń mú wá bá wa ni wàhálà àti ìbànújẹ́; láìpẹ́ ìwàláàyè yóò parí, a óò sì kọjá lọ.” (Sáàmù 90:10, Today’s English Version) Orin ewì tí wọ́n ti kọ láti ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún sẹ́yìn yìí fi hàn pé ọjọ́ pẹ́ tí ọjọ́ ogbó ti di ìṣòro. Pẹ̀lú gbogbo ibi tí ìwádìí ti dé lórí ìmọ̀ ìṣègùn, àwọn nǹkan kan ṣì ń bá ọjọ́ ogbó rìn tó ń fa “wàhálà àti ìbànújẹ́.” Àwọn nǹkan wo nìyẹn, báwo sì làwọn èèyàn kan ṣe ń kojú ìṣòro tí wọ́n ń mú wá?

Wọ́n Ti Dàgbà, Síbẹ̀ Ọpọlọ Wọ́n Jí Pépé

Bàbá kan tó ń jẹ́ Hans tọ́jọ́ orí rẹ̀ jẹ́ ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin sọ pé: “Ohun tó ń bà mí lẹ́rù jù lọ ni kéèyàn máa ṣarán.” Bíi tàwọn àgbàlagbà yòókù, bàbá yìí náà ń bẹ̀rù pé òun lè máa gbàgbé nǹkan. Ohun tó ń kó o lọ́kàn sókè ni pé ọpọlọ òun tó ṣeyebíye pẹ̀lú agbára ìrántí rẹ̀ tí ò ṣeé díye lé, tí akéwì àtijọ́ kan pè ní “àwokòtò wúrà,” ò ní jí pépé mọ́. (Oníwàásù 12:6) Bàbá Hans yìí béèrè pé, “Ṣé gbogbo ẹní bá ti dàgbà ni agbára ọpọlọ ẹ̀ á máa dín kù ni?”

Tó bá jẹ́ pé ohun tó ń ṣe Bàbá yìí ló ń ṣe ìwọ náà tàbí tó ò ń rò pé gbígbàgbé nǹkan báyẹn ni ìbẹ̀rẹ̀ pé ọpọlọ ò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, má bẹ̀rù: Tọmọdé tàgbà ló ń gbàgbé nǹkan. Nítorí náà, gbígbàgbé táwọn àgbàlagbà ń gbàgbé nǹkan ò fi hàn pé wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́.a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé téèyàn bá ń dàgbà lọ, ó lè má máa rántí àwọn nǹkan tó bẹ́ẹ̀ mọ́, síbẹ̀ Dókítà Michael T. Levy tó jẹ́ alága ẹ̀ka tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìwà èèyàn nílé ìwòsàn ilé ẹ̀kọ́ gíga Staten Island University Hospital, ní ìpínlẹ̀ New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ pé “ọ̀pọ̀ àgbàlagbà tó ti darúgbó kùjọ́kùjọ́ ló ṣì máa ń mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.”

Lóòótọ́, àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń tètè rántí àwọn nǹkan pàtó kan ju àwọn àgbàlagbà lọ. Àmọ́, Dókítà Richard Restak, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ètò iṣan ara, sọ pé: “Tó o bá yọwọ́ ti pé ẹnì kan ń yara ju ẹnì kan lọ kúrò, àwọn àgbàlagbà náà máa ń rántí nǹkan dáadáa bíi tàwọn tí kò tíì dàgbà.” Àní sẹ́, táwọn àgbà bá fi kọ́ra, ọpọlọ tiwọn náà lè máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó, kó máa rántí kó sì máa mọ àwọn nǹkan kan ṣe sí i.

Àwọn Ìṣòro Tó Jẹ Mọ́ Gbígbàgbé àti Àìlera Tó Ṣeé Wò

Àmọ́, ká wá ní ẹnì kan máa ń gbàgbé nǹkan ju bó ṣe yẹ ńkọ́? Síbẹ̀, kò yẹ kó ṣàdédé gbà kíákíá pé òun ti ń ṣarán nìyẹn. Ọ̀pọ̀ àìlera míì wà tó ṣeé wò tó lè ṣẹlẹ̀ sí èèyàn lọ́jọ́ ogbó. Irú àwọn nǹkan wọ̀nyí lè mú kéèyàn má lè rántí nǹkan dáadáa, ó sì lè mú kí ọkàn èèyàn máa dàrú ju bó ṣe yẹ lọ. Tírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀, àṣìṣe tàwọn èèyàn máa ń ṣe ni pé wọ́n á ní “ọjọ́ ogbó” ti dé sí olúwa rẹ̀ tàbí kí wọ́n ní ó ti ń “ṣarán.” Ó lè jẹ́ àwọn oníṣègùn òyìnbó tọ́rọ̀ ò yé dáadáa gan-an láá sọ bẹ́ẹ̀ nígbà míì. Kì í ṣe pé èyí máa ń tàbùkù sáwọn àgbàlagbà tó wá gba ìtọ́jú nìkan ni, àmọ́ kì í tún jẹ́ kí wọ́n rí ìtọ́jú tó yẹ gbà. Kí ló lè jẹ́ díẹ̀ lára irú àwọn àìlera yìí o?

Ara nǹkan tó lè ṣàdédé fa irú àìbalẹ̀ ọkàn bẹ́ẹ̀ ni àìjẹunrekánú, ìpàdánù omi ara, àìtó ẹ̀jẹ̀, kéèyàn fi orí pa, àìsàn ọ̀fun, àìtó fítámì, ìṣòro tó tẹ̀yìn oògùn kan wá, tàbí kéèyàn kó lọ síbòmíì kó má tíì wá mọ́ èèyàn lára. Ara nǹkan tó lè fa kéèyàn máa gbàgbé nǹkan ni másùnmáwo tí kò tètè lọ, táwọn arúgbó bá sì kárùn, ó lè mú kí ọkàn wọn máà balẹ̀. Àárẹ̀ ọkàn tún lè mú káwọn àgbàlagbà máa gbàgbé nǹkan kí ọkàn wọn má sì balẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Dókítà Levy fi gbani nímọ̀ràn pé “tó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkàn ẹnì kan tètè ń dà rú, kò yẹ káwọn èèyàn máa fojú kéré irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n máa kà á sí pé ṣe lẹni náà ń ṣarán.” Táwọn dókítà bá ṣàyẹ̀wò ẹni yẹn dáadáa, wọ́n lè ṣàwárí ohun tó ń fa ìṣòro náà.

Ohun Tẹ́ni Tó Ní Ìsoríkọ́ Lè Ṣe

Ìsoríkọ́ kì í ṣe nǹkan tuntun láwùjọ ẹ̀dá, kódà láàárín àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá ọdún sẹ́yìn báyìí tí àpọ́sítélì Pọ̀ọ́lù sọ fáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Lákòókò pákáǹleke tá a wà yìí, ó ṣe pàtàkì ju tìgbà yẹn lọ pé ká máa ṣe bó ṣe wí yẹn. Ó ṣeni láàánú pé títí di báyìí, àwọn èèyàn ò tíì máa wádìí ohun tó ń fà á táwọn àgbàlagbà fi ń sorí kọ́, bí wọ́n bá sì wádìí ẹ̀, wọn ò tíì wádìí ẹ̀ bó ṣe yẹ.

Torí èrò òdí náà tó wọ́pọ̀ pé àwọn èèyàn máa ń banú jẹ́ tí wọ́n sì máa ń dádì lọ́jọ́ alẹ́ wọn, ńṣe làwọn ẹlòmíì, tó fi mọ́ àwọn àgbàlagbà fúnra wọn, máa ń wo ìsoríkọ́ gẹ́gẹ́ bí ara ohun tí kò lè máà wáyé lọ́jọ́ ogbó. Ìwé Treating the Elderly, wá sọ pé: “Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. . . . Ìsoríkọ́ tó máa ń bá àwọn àgbà kì í ṣe ara àwọn nǹkan tó yẹ kó máa bá ọjọ́ ogbó rìn.”

Ìṣòro ńlá tí nǹkan táá tẹ̀yìn ẹ̀ wá lè burú tí kò sì yẹ ká fojú kéré ni akọ àárẹ̀ ọkàn, tí kò lọ bọ̀rọ̀. Ó yàtọ̀ sí ìbánújẹ́ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì tó máa ń bá èèyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Tá ò bá tọ́jú ẹni tó ní ìsoríkọ́ yìí, ó lè burú sí i kó sì di nǹkan míì sí wọn lára débi pé àwọn kan tó ti sọ̀rètí nù lára wọn á fẹ́ gbẹ̀mí ara wọn. Dókítà Levy sọ pé ìbànújẹ́ tó wà nínú káwọn àgbàlagbà máa sorí kọ́ ni “èyí tó ṣeé tọ́jú jù lọ lára àrùn tó jẹ mọ́ ọpọlọ àti ìrònú, òun náà ló sì léwu jù lára wọn.” Tí ìsoríkọ́ náà ò bá lọ, bóyá ni ò ní pọn dandan kẹ́ni náà lọ sọ́dọ̀ ẹni tó mọ̀ nípa ìtọ́jú àwọn tí ìṣesí wọn ṣàdédé ń yí padà.b—Máàkù 2:17.

Kí àwọn tó ní ìsoríkọ́ mọ̀ dájú pé Jèhófà “kún fun iyọ́nu, o si li ãnú.” (Jákọ́bù 5:11, Bíbélì Mímọ́) Ó “sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà.” (Sáàmù 34:18) Àní, ohun gan-an lẹni tó dìídì “ń tu àwọn tí ọkàn wọn bá rẹ̀wẹ̀sì ninu.”—2 Kọ́ríńtì 7:6, Ìròhìn Ayọ̀.

Kò Sí Ìdí Láti Máa Rò Pé O Ò Wúlò

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún sẹ́yìn, Dáfídì, olóòótọ́ Ọba náà gbàdúrà pé: “Má ṣe gbé mi sọnù ní àkókò ọjọ́ ogbó; ní àkókò náà tí agbára mi ń kùnà, má ṣe fi mí sílẹ̀.” (Sáàmù 71:9) Ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí, kò ṣàjèjì káwọn àgbàlagbà kan máa ní irú èrò yẹn torí ẹ̀rù tó ń bà wọ́n pé ọjọ́ kan ń bọ̀ táwọn èèyàn á máa wo àwọn bí ẹni tí kò wúlò mọ́. Àìlágbára láti ṣe púpọ̀ mọ́ torí ara tí kò dá ṣáṣá wà lára ohun tó máa ń mú kéèyàn máa ronú pé òun ò wúlò mọ́, tó bá sì di dandan fún èèyàn láti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, olúwarẹ̀ lè máà já mọ́ nǹkan kan mọ́ lójú ara rẹ̀.

Àmọ́ tá a bá fọkàn sí ohun tá a lè ṣe dípò tá a ó fi máa jẹ́ kí ohun tí a kò lè ṣe bà wá lọ́kàn jẹ́, ṣe ló máa mú ká mọyì ara wa á sì jẹ́ ká rí bá a ṣe wúlò tó. Lórí kókó yìí, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè dábàá pé ‘kéèyàn máa tẹ̀ síwájú nípa kíkẹ́kọ̀ọ́, bóyá ní ilé ìwé tàbí láwọn ọ̀nà míì, wọ́n ló yẹ kéèyàn máa dá sí ètò tí wọ́n ń ṣe ládùúgbò kó sì máa kópa nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn.’ Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni bàbá kan tó ń jẹ́ Ernest, ọ̀gá kan sì ni ní ilé iṣẹ́ búrẹ́dì lórílẹ̀-èdè Switzerland kó tó fẹ̀yìn tì. Ọ̀kan lára àwọn tó ń jàǹfààní nínú ‘títẹ̀síwájú nípa kíkẹ́kọ̀ọ́’ ni. Lẹ́ni àádọ́rin ọdún, bàbá yìí pinnu láti ra kọ̀ǹpútà kan ó sì kọ́ bí wọ́n ṣe ń lò ó. Kí ló dé tí bàbá yìí fi ń ṣe eléyìí lásìkò tí ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́gbẹ́ ń bẹ̀rù ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ? Ó ṣàlàyé pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, mo fẹ́ kí n máa rí nǹkan fọkàn rò bí mo ṣe ń dàgbà sí i. Yàtọ̀ síyẹn, mo fẹ́ kọ́ nípa ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ táá máa ràn mí lọ́wọ́ láti máa ṣèwádìí nínú Bíbélì àti nínú àwọn nǹkan tí mò ń ṣe nínú ìjọ.”

Ṣíṣe nǹkan tó ń mérè wá lè fáwọn àgbààgbà ní ohun tí wọ́n nílò: Á mú kí wọ́n nímọ̀lára pé ìgbésí ayé àwọn nítumọ̀ àti pé àwọn ṣàṣeyọrí, owó díẹ̀díẹ̀ sì lè máa tibẹ̀ yọ fún wọn. Sólómọ́nì, ọlọgbọ́n ọba, wòye pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni pé káwọn èèyàn “máa yọ̀ kí wọ́n sì máa ṣe rere nígbà ìgbésí ayé ẹni; pẹ̀lúpẹ̀lù, pé kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”—Oníwàásù 3:12, 13.

Béèyàn Ṣe Lè Máa Ṣe Gbogbo Ohun Tágbára Rẹ̀ Gbé

Ní ọ̀pọ̀ àwùjọ, àwọn àgbà ló máa ń jẹ́ káwọn ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn wọn ní ìmọ̀, àwọn ló ń kọ́ wọn lọ́gbọ́n tó fi mọ́ bí wọ́n ṣe ń hùwà, àwọn àgbà náà ló ń fojú àwọn ọmọdé mọ ẹ̀sìn. Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Ní báyìí tí mo ti darúgbó tí irun mi sì ti funfun, ìwọ Ọlọ́run mi, má ṣe pa mí tì! Wà pẹ̀lú mi bí mo ṣe ń polongo agbára rẹ àti okun rẹ fún gbogbo ìran tó ń bọ̀.”—Sáàmù 71:18, Today’s English Version.

Àmọ́ ká ní àgbàlagbà kan wá dẹni tí nǹkan tó lè ṣe ti dín kù torí àìlera tàbí àwọn ipò ìgbésí ayé rẹ̀ ńkọ́? Bọ́rọ̀ ìyá kan tó ń jẹ́ Sarah, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe rí nìyẹn, ó sì sọ ohun tó ń ṣe é fún alàgbà kan nínú ìjọ. Alàgbà yẹn rán an létí ìlànà Bíbélì náà pé ‘ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo lágbára púpọ̀.’ (Jákọ́bù 5:16) Ó sọ fún ìyá náà pé: “Láti ọdún yìí wá, ṣe ni àjọṣe ẹ̀yin àti Ọlọ́run ń dán mọ́rán. Ní báyìí, ẹ lè jẹ́ káwa tó kù rí àǹfààní nínú àjọṣe yẹn tẹ́ ẹ bá ń gbàdúrà fún wa ní ìdákọ́ńkọ́.” Inú ìyá yìí dùn gan-an ni nígbà tí alàgbà yìí sọ pé, “Màmá, ṣe ni kẹ́ ẹ ṣáà máa fi àdúrà ràn wá lọ́wọ́ ní tiyín.”

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wá yé màmá tó ń jẹ́ Sarah yìí, ọ̀nà kan táwọn àgbàlagbà lè gbà máa lo ara wọn tọ̀sántòru fáwọn míì ni pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún wọn. (Kólósè 4:12; 1 Tímótì 5:5) Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ sì tún lè máa ran àwọn àgbàlagbà olóòótọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tó jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà.”—Sáàmù 65:2; Máàkù 11:24.

Àwọn àgbàlagbà míì wà tó lójú ohun tí wọ́n lè ṣe àmọ́ tí wọ́n máa ń sọ ìrírí wọn fáwọn tó kéré tí wọ́n sì máa ń fún àwọn tí kò tó wọn ní nǹkan. Kòṣeémánìí ni irú wọn jẹ́ láwùjọ ibi tí wọ́n wà. Irú wọn fi hàn pé òótọ́ ni pé “orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.”—Òwe 16:31.

Àmọ́ o, kò burú tá a bá béèrè pé: Bá a ṣe ń dàgbà sí i, báwo ni ọjọ́ iwájú ṣe máa rí? Ṣé a nídìí láti máa retí pé lóòótọ́ ni alẹ́ á san wá ju òwúrọ̀ lọ?

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé “ó tó ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá gbogbo àwọn tó ti lé lẹ́ni ọdún márùnlélọ́gọ́ta láyé tí wọ́n ṣì mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” O lè rí ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa bá a ṣe lè tọ́jú àrùn tó ń mú kéèyàn má mọ ohun tó ń ṣe mọ́ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó dá lórí ọdẹ orí tó ń bá ọjọ́ ogbó rìn nínú Jí! ti September 22, 1998, lédè Gẹ̀ẹ́sì.

b Ìwé ìròyìn Jí! ò sọ pé irú ìtọ́jú kan ló dáa jù o. Àwọn Kristẹni ní láti rí i dájú pé ìtọ́jú táwọn bá máa gbà bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Jọ̀wọ́ wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tó wà lábẹ́ àkòrí náà, “Lílóye Àwọn Tí Ìṣesí Wọn Ṣàdédé Ń Yí Padà” tó jáde nínú Jí! ti January 8, 2004.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

Àwọn àgbàlagbà máa ń rò pé kòókòó jàn-án jàn-án ayé òde òní ò jẹ́ káwọn èèyàn máa rántí àwọn

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Bó O Ṣe Lè Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́

◼ Fi Ọ̀wọ̀ Wọn Wọ̀ Wọ́n. “Má ṣe fi ohùn líle bá agbalagba wí; ṣugbọn máa gbà á níyànjú bí baba rẹ. . . . Mú àwọn àgbà obìnrin bí ìyá.”—1 Tímótì 5:1, 2, Ìròyìn Ayọ̀.

◼ Máa Fetí Sílẹ̀ Dáadáa. “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.”—Jákọ́bù 1:19.

◼ Máa Fọ̀rọ̀ Wọn Ro Ara Rẹ Wò. “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú, kí ẹ má ṣe máa fi ìṣeniléṣe san ìṣeniléṣe tàbí ìkẹ́gàn san ìkẹ́gàn.”—1 Pétérù 3:8, 9.

◼ Mọ Ìgbà Tí Wọ́n Bá Nílò Ìṣírí. “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.”—Òwe 25:11.

◼ Ẹ Máa Ro Tiwọn Mọ́ Ohun Tẹ́ Ẹ Bá Ń Ṣe. “Ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.”—Róòmù 12:13.

◼ Máa Fún Wọn Ní Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Mú Lo. “Ẹnì yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yìí fún ìtìlẹyìn ìgbésí ayé, tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní, síbẹ̀ tí ó sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn, lọ́nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi dúró nínú rẹ̀? Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”—1 Jòhánù 3:17, 18.

◼ Ní Ìpamọ́ra. “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:12.

Bá a bá ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà, ṣe là ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run torí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó.”—Léfítíkù 19:32.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Àǹfààní wà nínú káwọn dókítà máa yẹ̀ wọ́n wò dáadáa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́