Kí Ni Àwọn Ohun Alààyè Kọ́ Wa?
“Jọ̀ọ́, bi àwọn ẹranko, wọ́n á sì kọ́ ọ;àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, wọ́n á sì sọ fún ọ. Tàbí kí o fiyè sí ayé, ó sì máa kọ́ ọ;àwọn ẹja inú òkun sì máa kéde rẹ̀ fún ọ.”—JÓÒBÙ 12:7, 8.
LÁWỌN ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn ẹnjiníà ti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lára ẹranko, igi àti ewéko. Ẹ̀ka ìmọ̀ kan tí wọ́n ń pè ní biomimetics ni wọ́n ń lò láti ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan alààyè, wọ́n á sì lo ọgbọ́n inú ẹ̀ láti ṣe oríṣiríṣi nǹkan. Èyí ti jẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn nǹkan tuntun jáde, kí wọ́n sì mú kí àwọn ẹ̀rọ tó ti wà tẹ́lẹ̀ dáa sí i. Bó o ṣe ń kà nípa àwọn àpẹẹrẹ tá a máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí, bi ara ẹ pé, ‘Ta ló yẹ kó gba ìyìn àti ẹ̀yẹ fún àwọn iṣẹ́ àrà yìí?’
Wọ́n Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Lẹbẹ Ẹja Àbùùbùtán
Kí làwọn tó ń ṣe ọkọ̀ òfúrufú lè rí kọ́ lára ẹja àbùùbùtán tó ní iké lẹ́yìn? Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n lè rí kọ́ lára ẹ̀. Ẹja àbùùbùtán oníké lẹ́yìn tó ti dàgbà dáadáa máa ń wúwo tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) àpò sìmẹ́ǹtì. Ara ẹ̀ yi gan-an, lẹbẹ tó wà lára ẹ̀ fẹ̀ dáadáa, ó sì dà bí apá ẹyẹ. Ẹja yìí gùn tó ogójì (40) ẹsẹ̀ bàtà, ó sì máa ń pitú gan-an lábẹ́ omi. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ti rí àgbájọ ẹja, edé àti akàn tó fẹ́ jẹ́, ó máa ń kọ́kọ́ fò sókè, á wá yí àwọn ohun tó fẹ́ jẹ náà po, á sì bẹ̀rẹ̀ sí í tú omi jáde lẹ́nu. Omi náà á wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ yí po àwọn ohun tó fẹ́ jẹ náà, omi náà máa ń ṣẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ dé ibi tó fẹ̀ tó ẹsẹ̀ bàtà márùn-ún, èyí ló sì dà bí àwọ̀n tó fi máa ń gbá ohun tó fẹ́ jẹ náà jọ. Lẹ́yìn náà, á wá la ẹnú ẹ̀ láti ìsàlẹ̀ omi tó wà, á sì gbé àwọn ohun tó fẹ́ jẹ́ náà mì káló.
Ohun pàtàkì kan tó jọ àwọn tó ń ṣèwádìí lójú ni pé pẹ̀lú bí ara ẹja àbùùbùtán oníké lẹ́yìn yìí ṣe dà bíi pé ó le gbagidi tó, ó ṣì lè yí po ní ibi tí kò fẹ̀ rárá. Ìwádìí tí wọ́n ṣe wá jẹ́ kí wọ́n rí i pé bí lẹbẹ ara ẹ̀ ṣe rí ló jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Etí lẹbẹ náà ò dán bíi ti apá ọkọ̀ òfúrufú, àmọ́ àwọn igun kan yọ síta ní eteetí rẹ̀.
Bí ẹja àbùùbùtán náà ṣe ń yí po, àwọn igun tó wà létí lẹbẹ rẹ̀ jẹ́ kó lè gbéra, láì fi bẹ́ẹ̀ sí ìdíwọ́. Báwo ló ń ṣe ń ṣe é? Ìwé kan tó ń jẹ́ Natural History sọ pé àwọn igun tó wà létí lẹbẹ náà ló máa ń jẹ́ kí omi lè kọjá lára ẹ̀ geerege, ìyẹn ló máa ń jẹ́ kó lè gbéra sókè kó sì lè yíra bó ṣe wù ú tó bá wà nínú omi. Tó bá jẹ́ pé ńṣe ni eteetí lẹbẹ náà jọ̀lọ̀ tó sì ń dán, omi ò ní lè kọjá lára ẹ̀, ìyẹn á wá jẹ́ kí omi dà rú kó sì máa ru gùdù, tó bá sì ti rí bẹ́ẹ̀, ẹja àbùùbùtán náà ò ní lè fi ìrọ̀rùn gbéra sókè, kò sì ní lè yíra pa dà láàárín ibi tí kò fẹ́ rárá yẹn.
Ọgbọ́n wo làwọn èèyàn rí kọ́ nínú ohun tí wọ́n ṣàwárí lára ẹja àbùùbùtán yìí? Tí wọ́n bá ṣe apá ọkọ̀ òfúrufú bíi lẹbẹ ẹja àbùùbùtán yìí, ìyẹn á jẹ́ kí iye páànù pélébé kan tó máa ń wà lára apá ọkọ̀ òfúrufú dín kù. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa jẹ́ kí iye ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń darí afẹ́fẹ́ apá ọkọ̀ òfúrufú dín kù. Irú àwọn apá bẹ́ẹ̀ á dín jàǹbá kù, á sì rọrùn láti bójú tó. Ọ̀jọ̀gbọ́n John Long tó máa ń ṣe ẹ̀yà ara àtọwọ́dá sọ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ láìpẹ́ tó jẹ́ pé “gbogbo ọkọ̀ òfúrufú ló máa ní apá tó dà bíi lẹbẹ ẹja àbùùbùtán oníké lẹ́yìn.”
Wọ́n Ṣe Ohun Tó Dà Bí Apá Ẹyẹ Seagull
Òótọ́ ni pé àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ti ṣe apá ọkọ̀ òfúrufú bí apá ẹyẹ, àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n tún ṣe apá ọkọ̀ òfúrufú bí apá ẹyẹ lọ́nà tó dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé “àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ tó ń ṣèwádìí ní Yunifásítì Florida ti ṣe ọkọ̀ òfúrufú kékeré kan tó ń fò láìní èèyàn kankan nínú, àmọ́ tó jẹ́ pé ilẹ̀ láwọn èèyàn tí ń darí ẹ̀. Ọkọ̀ òfúrufú náà lè rá bàbà, ó lè já ṣòòròṣò wálẹ̀, ó sì lè ṣàdédé gbéra sókè bí ẹyẹ seagull ṣe máa ń ṣe.”
Àwọn ẹyẹ seagull máa ń fara pitú lójú ọ̀run, wọ́n lè tẹ apá wọn kọdọrọ níbi ìgúnpá tàbí níbi èjìká wọn. Ìwé ìròyìn yẹn tún sọ pé àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ wo bí apá ẹyẹ seagull ṣe rọ̀ tó láti fi ṣe ẹ̀rọ kékeré kan táá máa darí àwọn irin kéékèèké tó wà ní apá ọkọ̀ òfúrufú kékeré náà. Ọkọ̀ òfúrufú náà kò gùn jù ẹsẹ̀ bàtà méjì lọ. Ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe apá ọkọ̀ òfúrufú kékeré yìí ló jẹ́ kó lè máa rá bàbà kò sì lè fò gba àárín àwọn ilé gíga. Ó wu àwọn ọmọ ogun ojú òfúrufú ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà gan-an láti ṣe irú ọkọ̀ òfúrufú tó rọrùn láti darí yìí kí wọ́n lè máa fi wá àwọn ohun ìjà tó ní àrùn aṣekúpani láwọn ìlú ńlá.
Wọ́n Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àtẹ́lẹsẹ̀ Ọmọńlé
A tún lè kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lára àwọn ẹranko. Bí àpẹẹrẹ, ọmọńlé lè pọ́n ògiri, ó sì lè lẹ̀ mọ́ àjà típẹ́típẹ́ láì jábọ́. Kódà lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n mọ̀ pé ọmọńlé ní ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Òwe 30:28) Ọgbọ́n wo ni ọmọńlé ń dá tí kì í fi í já bọ́?
Àwọn nǹkan tíntìntín tó dà bí irun ní àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé ló máa ń jẹ́ kó lè lẹ̀ mọ́ nǹkan, kódà bí ohun náà tiẹ̀ ń dán bíi gíláàsì. Kì í ṣe pé àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ ní gọ́ọ̀mù tó fi ń lẹ̀ mọ́ nǹkan, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló máa ń lo ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pè ní agbára òòlẹ̀. Agbára òòlẹ̀ yìí ló máa ń jẹ́ kí ohun méjì lẹ̀ pa pọ̀ láì tú ká. Àwa èèyàn ò lè lẹ àtẹ́lẹwọ́ wa mọ́ ògiri ká sì máa pọ́n ọn bíi ti ọmọńlé, torí pé agbára òòfà kò ní jẹ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ti ọmọńlé yàtọ̀, àwọn nǹkan tíntìntín tó dà bí irun ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ ló máa ń jẹ́ kí agbára òòlẹ̀ pọ̀ sí i táá sì mú kó borí agbára òòfà. Tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún nǹkan tíntìntín tó dà bí irun yìí bá lẹ̀ mọ́ ibì kan, ó máa ń jẹ́ kí agbára tí ọmọńlé ní láti lẹ̀ mọ́ nǹkan pọ̀ sí i, ìyẹn ni kì í sì í jẹ́ kó já bọ́.
Kí la lè fi ohun tí wọ́n ṣàwárí lára ọmọńlé ṣe? Tí wọ́n bá wo àwọn nǹkan tíntìntín tó dà bí irun ní àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé láti ṣe òòlẹ̀ onírun, ó máa dáa ju èyí tó wà báyìí tí wọ́n ń pè níVelcroa lọ. Ìwé ìròyìn The Economist sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó ń ṣèwádìí tó sọ pé tí wọ́n bá lè ṣe “òòlẹ̀ tó dà bí àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé,” ó máa wúlò gan-an nínú “ìṣègùn nígbà tí kẹ́míkà tí wọ́n fi ń lẹ nǹkan pọ̀ kò bá ṣeé lò.”
Ta Ló Yẹ Kó Gba Ìyìn àti Ẹ̀yẹ Rẹ̀?
Ní báyìí, àjọ National Aeronautics and Space Administration ti ṣe ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì ẹlẹ́sẹ̀ púpọ̀ tó máa ń rìn bí àkekèé. Àwọn ẹnjiníà ní orílẹ̀-èdè Finland ti ṣe katakata ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́fà kan tó lè gún orí àwọn ohun ìdènà ńlá tó bá wà níwájú rẹ̀ bí àwọn kòkòrò ńlá ṣe máa ń ṣe. Àwọn kan ti wo bí èso pinecones ṣe máa ń ṣí tó sì máa ń pa dé láti fi ṣe àwọn nǹkan. Àwọn kan ti wo ẹja tí wọ́n ń pè ní boxfish láti ṣe mọ́tò kan. Afẹ́fẹ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ fa mọ́tò náà sẹ́yìn tó bá ń sáré. Àwọn míì tún ṣèwádìí láti mọ ìdí tí ìkarawun òkòtó abalone kì í fi tètè fọ́ tí wọ́n bá fi nǹkan lù ú. Wọ́n fẹ́ fi ohun tí wọ́n bá rí nínú ìwádìí náà ṣe ẹ̀wù agbọta tó fúyẹ́ àmọ́ tó lágbára gan-an.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ló wà lára àwọn ohun alààyè, ìyẹn sì tí mú kí àwọn tó ń ṣèwádìí ṣàkójọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ohun alààyè tí wọ́n ti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lára wọn. Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé ìgbàkigbà làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n kó jọ yìí kí wọ́n lè rí “bí wọ́n ṣe máa lo àwọn ohun tí wọ́n rí kọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro tó wà nínú àwọn nǹkan tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀.” Ibi ti wọ́n kó ìsọfúnni nípa àwọn ohun tí wọ́n rí kọ́ yìí sí ni wọ́n pè ní “oní-nǹkan.” Bó sì ṣe máa ń rí lábẹ́ òfin, oní-nǹkan túmọ̀ sí ẹnì kan tàbí ilé iṣẹ́ kan tó dá ohun kan sílẹ̀ tàbí tó ṣe ẹ̀rọ kan. Nígbà tí ìwé ìròyìn The Economist ń sọ̀rọ̀ nípa ìsọfúnni tí wọ́n kó jọ yìí, ó ní: “Bí àwọn tó ń ṣèwádìí ṣe pe ibi tí wọ́n kó ìsọfúnni nípa àwọn ohun alààyè sí ní ‘oní-nǹkan,’ ńṣe ni wọ́n ń sọ pé àwọn ohun alààyè yẹn gangan ni oní-nǹkan.”
Ta ló fi àwọn ohun àrà yìí sínú àwọn ohun alààyè? Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé àwọn ohun kéékèèké kan ló ń yíra pa dà lọ́nà èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ, títí wọ́n fi dàgbà di àwọn ohun àrà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn yìí. Ìyẹn sì ni wọ́n ń pè ní ẹfolúṣọ̀n. Àmọ́, èrò àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì míì yàtọ̀ síyẹn. Onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè tíntìntín tó ń jẹ́ Michael Behe sọ nínú ìwé ìròyìn The New York Times lọ́dún 2005 pé: “Àwọn iṣẹ́ àrà tá à ń rí lára àwọn ohun alààyè yìí ti jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé wọn ò ṣàdédé wà.” Ó wá lo àkànlò èdè kan tí wọ́n máa lò lédè Gẹ̀ẹ́sì láti kín ọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́yìn, ó ní: “Tó bá rí bíi pẹ́pẹ́yẹ, tó ń rìn bíi pẹ́pẹ́yẹ, tó sì ń dún bíi pẹ́pẹ́yẹ, ìyẹn ò tún ní iyàn jíjá nínú mọ́, pẹ́pẹ́yẹ náà ni.” Kí wá ni èrò Michael Behe? Ó sọ pé: “Tá a bá rí iṣẹ́ àrà kan, ó yẹ ká gbà pé ẹnì kan ló ṣe é, kò yẹ ká gbà pé ó ṣàdédé wà ni.”
Ó dájú pé tí ẹnjiníà kan bá ṣe apá ọkọ̀ òfúrufú tó lè dín jàǹbá kù, ó yẹ ká gbóṣùbà fún un. Bákan náà, tẹ́nì kan bá ṣe báńdéèjì tó tura tí wọ́n fi ń di ojú ọgbẹ́ tàbí tó ṣe mọ́tò kan tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa, ó yẹ kí onítọ̀hún gba ìyìn àti ẹ̀yẹ. Òótọ́ kan ni pé, tí ẹnjiníà kan bá lo ohun tẹ́lòmíì ṣe láti fi ṣe nǹkan tiẹ̀, tí kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ ẹni tó pilẹ̀ nǹkan ọ̀hún, tí kò sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni náà, ọ̀daràn la máa pe ẹnjiníà náà.
Ṣó bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì yẹn kàn máa fi àwọn ohun tí wọ́n wò lára àwọn ohun alààyè yanjú àwọn ìṣòro tí wọ́n rí lẹ́nu iṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa wá sọ pé ńṣe làwọn ohun alààyè yẹn ṣàdédé wà, pé kò sẹ́ni tó dá wọn? Tó bá jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé kó tó lè wo ohun tẹ́lòmíì ṣe láti fi ṣe nǹkan tiẹ̀, ẹni tó ṣe ohun tó wò yẹn wá ńkọ́ o? Tá a bá ní ká sọ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, ṣé ọmọ tó ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń ya àwòrán tó sì ń wo ohun tí ọ̀gá ẹ̀ ń ṣe láti fi ṣe iṣẹ́ tìẹ ló yẹ kó gba ìyìn àti ẹ̀yẹ ni àbí ọ̀gá ẹ̀ tó jẹ́ àgbà ayàwòrán?
Èrò Tó Bọ́gbọ́n Mu
Ọ̀pọ̀ àwọn onílàákàyè ló gbà pé ẹnì kan ló dá àwọn ohun alààyè, èyí wá mú kí wọ́n máa sọ bíi ti onísáàmù náà pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà!Gbogbo wọn lo fi ọgbọ́n ṣe. Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe.” (Sáàmù 104:24) Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ ohun kan náà, ó ní: “Nítorí àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí kò ṣeé fojú rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, torí à ń fi òye mọ̀ wọ́n látinú àwọn ohun tó dá, títí kan agbára ayérayé tó ní àti bó ṣe jẹ́ Ọlọ́run.”—Róòmù 1:19, 20.
Àmọ́, àwọn kan wà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọkàn, tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún Bíbélì, tí wọ́n sì gba Ọlọ́run gbọ́, síbẹ̀ wọ́n ṣì gbà pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá àwọn ohun kéékèèké kan, táwọn nǹkan náà sì wá yíra pa dà dí oríṣiríṣi ohun alààyè tó jẹ́ ohun àrà. Kí ni Bíbélì sọ nípa ìyẹn?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ewéko burdock ni wọ́n wo fi ṣe òòlẹ̀ onírun tí wọ́n n pè níVelcro.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí]
Ta ló fi àwọn ohun àrà sínú àwọn ohun alààyè?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí]
Ta ló dá àwọn ohun alààyè?
[Àpótí/Àwòrán]
Tó bá jẹ́ pé èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ ọlọ́pọlọ pípé kó tó lè wo ohun tẹ́lòmíì ṣe láti fi ṣe nǹkan tiẹ̀, ẹni tó ṣe ohun tó wò yẹn wá ńkọ́ o?
Apá ẹyẹ seagull ni wọ́n wò fi ṣe apá ọkọ̀ òfúrufú tó rọrùn láti darí yìí
Àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé kì í dọ̀tí, èèyàn ò lè rí ipa ẹsẹ̀ rẹ̀, kò síbi tí kò lè lẹ̀ mọ́, àfi ara ohun kan tí wọ́n ń pè ní Teflon, wẹ́rẹ́ ni ọmọńlé máa ń lẹ̀ mọ́ ara nǹkan, wẹ́rẹ́ báyìí náà ló sì máa ń ṣí kúrò lára ohun tó bá lẹ̀ mọ́. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó jọ èyí
Ẹja boxfish tó máa ń lọ geerege nínú omi ni wọ́n wò fi ṣe mọ́tò yìí
[Àwọn Credit Line]
Ọkọ̀ òfúrufú: Kristen Bartlett/University of Florida; àtẹ́lẹsẹ̀ ọmọńlé: Breck P. Kent; ẹja box fish àti mọ́tò: Mercedes-Benz USA
[Àpótí/Àwòrán]
ỌGBỌ́N ÀDÁMỌ́NI KÌ Í JẸ́ KÁWỌN OHUN ALÀÀYÈ ṢÌNÀ
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ohun alààyè tó ń rìn káàkiri láyé ló ní “ọgbọ́n àdámọ́ni.” (Òwe 30:24, 25) Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ méjì.
◼ Bí Àwọn Èèrà Ṣe Ń Lọ Lọ́wọ̀ọ̀wọ́ Táwọn èèrà bá wá oúnjẹ lọ, báwo ni wọ́n ṣe máa ń mọ̀nà ilé? Ìwádìí táwọn kan ṣe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi hàn pé yàtọ̀ sí pé àwọn èèrà máa ń tú omi kan tó ń ta sánsán jáde bí wọ́n ṣe ń rìn lọ, àwọn kan tún máa ń fàlà sílẹ̀ kó lè rọrùn fún wọn láti mọ̀nà ilé. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìwé New Scientist ń sọ̀rọ̀ nípa èèrà kan tí wọ́n ń pè ní pharaoh ants, ó ní “àwọn èèrà yìí máa ń fa ìlà látinú ihò wọn síta, tí wọ́n bá fà á débì kan, wọ́n á jẹ́ kí ìlà náà pín sí méjì.” Kí ló mú kí ìlà tí wọ́n ń fà yìí gbàfiyèsí? Tí ọ̀kan lára àwọn kòkòrò yìí bá ń pa dà lọ sínú ihò wọn, tó sì dé ibi tí ìlà ti pín sí méjì yẹn, ọgbọ́n àdámọ́ni tó ní máa jẹ́ kó tọ orí èyí tí kò dagun púpọ̀ nínú ìlà méjì yẹn, ìyẹn gangan sì ni ọ̀nà ilé rẹ̀. Ìwé yẹn sọ pé, “ọ̀nà tó pín sí méjì yẹn máa ń jẹ́ kí àwọn èèrà náà máa lọ, kí wọ́n sì máa bọ̀ láì síṣòro, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n ṣìnà.”
◼ Ohun Tó Ń Jẹ́ Kí Ẹyẹ Mọ̀nà Àwọn ẹyẹ kì í ṣìnà rárá tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò tó jìn gan-an kódà láwọn ojú ọjọ́ tó yàtọ̀ síra. Kí ló jẹ́ kí ìyẹn ṣeé ṣe? Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé agbára òòfà inú ayé ni àwọn ẹyẹ máa ń lò tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò. Àmọ́ ṣá o, ìwé ìròyìn Science sọ pé “agbára òòfà inú ayé máa ń yàtọ̀ láti ibì kan sí ibòmíì, wọ́n kì í sì í fìgbà gbogbo kọjú sí apá àríwá ayé. Èyí sì lè mú káwọn ẹyẹ ṣìnà. Kí wá ni kì í jẹ́ káwọn ẹ̀yẹ tó ń ṣí lọ síbi tó jìnnà gan-an ṣìnà? Ó jọ pé ohun kan wà ní inú àwọn ẹyẹ tó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú ọjọ́ lè mú kí ìgbà tí oòrùn ń wọ̀ yí pa dà, síbẹ̀ àwọn ẹyẹ máa ń mọ̀gbà tó yẹ kí wọ́n gbéra ìrìn àjò. Àwọn tó ń ṣèwádìí wá gbà pé, bí ìwé ìròyìn Science ṣe sọ, ó ní láti jẹ́ pé, “ohun kan wà nínú wọn tó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn àkókò àti ìgbà inú ọdún.”
Ta ló kọ́ àwọn èèrà láti mọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbà pa dà dé inú ihò wọn? Ta ló fún àwọn ẹyẹ ní ohun tí wọ́n fi ń mọ ìgbà? Ta ló sì fún wọn ní ọpọlọ tó ń jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe? Ṣé gbogbo àwọn nǹkan yẹn kàn ṣàdédé wà ni àbí Ẹlẹ́dàá ló fi ọgbọ́n dá wọn?
[Credit Line]
© E.J.H. Robinson 2004