Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ní Aago Báyìí Ni Mo Gbọ́dọ̀ Máa Wọlé?
Ilẹ̀ ti ṣú kó o tó wọlé látibi àríyá kan tíwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ lọ. Aago tí wọ́n ní o gbọ́dọ̀ máa wọlé ti kọjá, àfi kó o sọ nǹkan tó mú kó o pẹ́. O kọ́kọ́ dúró díẹ̀ kó o tó wọlé. O ronú pé, ‘ó ṣeé ṣe kí Dádì àti Mọ́mì ti lọ sùn.’ Lo bá rọra ṣílẹ̀kùn, àmọ́ àwọn lo kọ́kọ́ rí tí wọ́n ń wo aago, tí wọ́n sì ń retí pé kó o sọ tẹnu ẹ.
ṢÉRÚ nǹkan tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Ṣéwọ àtàwọn òbí ẹ ti jọ jiyàn rí lórí aago tí wọ́n ní kó o máa wọlé? Debora tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé: “Kò fi bẹ́ẹ̀ sí wàhálà níbi tá à ń gbé, àmọ́ tí aago méjìlá alẹ́ bá fi lè lù kí n tó wọlé báyìí, ẹ̀rù á ti máa ba àwọn òbí mi.”a
Kí nìdí tó fi lè ṣòro láti máa wọlé ní aago tí wọ́n ní o gbọ́dọ̀ máa wọlé? Ṣó burú kéèyàn fẹ́ láti ṣe ohun tó wù ú? Kí lo lè ṣe táwọn òbí ẹ bá fi dandan lé aago tó o gbọ́dọ̀ máa wọlé?
Bó Ṣe Máa Ń Ṣẹlẹ̀
Báwọn òbí ẹ bá dá aago tó o gbọ́dọ̀ máa wọlé fún ẹ, ó lè tán ẹ ní sùúrù, àgàgà tí kò bá jẹ́ kó o ráyè báwọn ọ̀rẹ́ ẹ ṣeré. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Natasha sọ pé: “Ńṣe ni inú máa ń bí mi tí n bá ti ń rántí pé aago báyìí ni wọ́n ní mo gbọ́dọ̀ máa wọlé. Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà táwọn òbí mi mọ̀ pé ibi tí mo ti ń wo fíìmù pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi ò jìnnà sílé. Síbẹ̀ bí aago tí wọ́n ní mo gbọ́dọ̀ máa wọlé ṣe kọjá ìṣẹ́jú méjì báyìí ni wọ́n ti pè mí sórí fóònù alágbèéká pé kí ló dé tí mi ò tíì wọlé!”
Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Stacy tún sọ ìṣòro míì tóun máa ń ní. Ó ní: “Dádì àti mọ́mì mi sọ pé mo gbọ́dọ̀ ti máa wà nílé káwọn tó lọ sùn. Bí wọ́n bá sì ní àfi kí n dé káwọn tó lọ sùn, a jẹ́ pé ó ti máa rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, inú á sì ti máa bí wọn.” Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀? Stacy sọ pé: “Ṣe ni wọ́n máa dá mi lẹ́bi, ìyẹn sì máa ń bí mi nínú. Mi ò mọ nǹkan tí wọ́n ń ṣe tí wọn ò lè lọ sùn!” Tíwọ náà ò bá fara mọ́ aago táwọn òbí ẹ ní kó o máa wọlé, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti Katie tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] tó sọ pé: “Ó wù mí pé káwọn òbí mi túbọ̀ fọkàn tán mi, kó má lọ dà bíi pé ṣe ni mò ń fipá mú wọn láti túbọ̀ máa gbà mí láyè.”
Ó ṣeé ṣe kírú àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí máa ṣẹlẹ̀ síwọ náà. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, bi ara ẹ pé:
◼ Kí nìdí tí kì í fi í wù mí láti máa wà nílè? (Fàmì sí ọ̀kan.)
□ Ó máa ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sí ohun tó ń ká mi lọ́wọ́ kò.
□ Ó máa ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀.
□ Kí n lè máa wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi.
Kò sí nǹkan tó burú nínú gbogbo nǹkan tá a tò sókè yìí. Ó máa ń wùùyàn láti lómìnira púpọ̀ sí i béèyàn bá ṣe ń dàgbà, ara sì máa ń tuni téèyàn bá gbafẹ́ lọ́nà tó gbámúṣé. Bíbélì fi kún un pé, àwọn tó lè nípa rere lórí ẹ ni kó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́. (Sáàmù 119:63; 2 Tímótì 2:22) Ìyẹn kì í rọrùn bó bá jẹ́ pé ilé lèèyàn ń wà látàárọ̀ ṣúlẹ̀!
Báwo lo wá ṣe lè nírú òmìnira tá a sọ̀ yìí báwọn òbí ẹ bá sọ pé aago báyìí lo gbọ́dọ̀ máa wọlé? Gbé àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
Ìṣòro Kìíní: Ó máa ń jẹ́ kó dà bíi pé ọmọdé ni mí. Andrea, tó ti pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] rántí pé, “Ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé ọmọdé ni mí, àfi kẹ́nì kan máa fi nǹkan tó ń ṣe sílẹ̀ lálaalẹ́, kó lè máa wá gbé mi lọ sílé kílẹ̀ tó ṣú jù.”
Ohun tó o lè ṣe: Ká sọ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ gbàwé àṣẹ láti máa wakọ̀. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, òfin ló máa sọ ibi tó o lè wakọ̀ lọ, ìgbà tó o lè wakọ̀, tàbí ẹni tó o lè fọkọ̀ gbé, títí tó o fi máa tó iye ọjọ́ orí kan. Ṣé wàá wá torí ẹ̀ sọ pé o ò ní gbàwé àṣẹ yẹn mọ́, kó o wá ní: “Mi ò tiẹ̀ wakọ̀ mọ́, bí wọn ò bá ti lè fún mi lómìnira tó bí mo ṣe fẹ́”? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Ṣe ni wàá fojú pàtàkì wo gbígba ìwé àṣẹ yẹn.
Bákan náà, ṣe ni kó o fojú pé ò ń tẹ̀ síwájú, lọ́nà tó tọ́, wo dídá tí wọ́n dá aago tó o gbọ́dọ̀ máa wọlé fún ẹ. Má wò ó bíi pé ó ń ká ẹ lọ́wọ́ kò, àmọ́ àwọn àǹfààní tó ń tibẹ̀ wá ni kó o gbájú mọ́. Ṣé òmìnira tó o ní báyìí ò pọ̀ ju èyí tó o ní nígbà tó o wà lọ́mọdé lọ?
Àǹfààní tó wà ńbẹ̀: Aago tí wọ́n ní o gbọ́dọ̀ máa wọlé túbọ̀ máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn tó o bá ń wo àwọn àǹfààní tó wà ńbẹ̀ dípò kó o máa wò ó bíi pé ó ń ká ẹ lọ́wọ́ kò. Tó o bá ń wọlé lákòókò táwọn òbí ẹ dá pé o gbọ́dọ̀ máa dé, ó ṣeé ṣe kí wọ́n fún ẹ lómìnira púpọ̀ sí i.—Lúùkù 16:10.
Ìṣòro Kejì: O ò mọ̀dí tí wọ́n fi ní o gbọ́dọ̀ máa tètè dé. Ìgbà kan wà tínú Nikki ò dùn pé wọ́n dá aago tó gbọ́dọ̀ máa wọlé fun un, ó ní: “Mo rántí pé mo máa ń ronú pé ṣe ni mọ́mì mi kan ṣòfin ṣáá, torí pé ó kàn wù wọ́n bẹ́ẹ̀.”
Ohun tó o lè ṣe: Fi ìlànà tó wà nínú ìwé Òwe 15:22 sílò pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” Fara balẹ̀ jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú àwọn òbí rẹ. Gbìyànjú láti mọ ìdí tí wọ́n fi yan aago tí wọ́n ní o gbọ́dọ̀ máa dé yẹn.b
Àǹfààní tó wà ńbẹ̀: Ọ̀rọ̀ náà á túbọ̀ yé ẹ dáadáa tó o bá fetí sóhun táwọn òbí ẹ bá bá ẹ sọ. Stephen sọ pé: “Dádì mi sọ fún mi pé Mọ́mì ò kì í lè sùn, àfi tí wọ́n bá rí i pé mo ti wọlé lálàáfíà. Mi ò tiẹ̀ ronú bẹ́ẹ̀ rí.”
Rántí pé: Ó máa ń dáa láti fi sùúrù yanjú ọ̀rọ̀ ju pé kéèyàn kàn máa fìbínú sọ̀rọ̀ lọ, ó sì dájú pé ìbínú ò lè ṣe kó máà lẹ́yìn. Natasha tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan yẹn sọ pé: “Mo ti wá rí i pé bí mo bá bínú sáwọn òbí mi, wọ̀n kì í tìtorí ẹ̀ fún mi láyè láti ṣàwọn nǹkan míì tí n bá fẹ́ ṣe.”
Ìṣòro Kẹta: Ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí ẹ ló ń darí ẹ. Àwọn òbí máa ń sọ pé àǹfààní tìẹ làwọn òfin táwọn bá ṣe wà fún, tó fi mọ́ òfin tó ní í ṣe pẹ̀lú aago tó o gbọ́dọ̀ máa wọlé. Ọmọ ogún ọdún [20] kan tó ń jẹ́ Brandi sọ pé: “Nígbà táwọn òbí mi sọ bẹ́ẹ̀, ṣe ló dà bíi pé wọn ò fẹ́ kí n ṣohun tó wù mí tàbí kí n sọ tẹnu mi.”
Ohun tó o lè ṣe: O lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú Mátíù 5:41 pé: “Bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.” Ashley àti ẹ̀gbọ́n ẹ̀ máa ń fi ìmọ̀ràn yẹn sílò dáadáa. Ó ní: “A sábà máa ń délé tó bá ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sí aago tí wọ́n dá pé a gbọ́dọ̀ máa wọlé. Ṣéwọ náà á ṣe bíi tiwọn?
Àǹfààní tó wà ńbẹ̀: Ó máa ń rọrùn láti ṣe nǹkan tó bá wu èèyàn ṣe ju pé kí wọ́n fipá mú un ṣe é lọ! Rò ó wò ná: Bó o bá yàn láti máa dé sílé ṣáájú aago tí wọ́n dá pé o gbọ́dọ̀ máa wọlé, ó túmọ̀ sí pé ìwọ lò ń darí ara ẹ nìyẹn. Ìyẹn sì tún lè rán ẹ létí ìlànà yìí pé: “Kí ìṣe rẹ dídára má bàa jẹ́ bí ẹni pé lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe láti inú ìfẹ́ àtinúwá ti ìwọ fúnra rẹ.”—Fílémónì 14.
Tó o bá ń tètè pa dà wọlé, ìyẹn á tún jẹ́ káwọn òbí ẹ túbọ̀ fọkàn tán ẹ. Wade tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ pé: “Báwọn òbí ẹ bá ti lè fọkàn tán ẹ báyìí, wọ́n á túbọ̀ máa fún ẹ lómìnira sí i.”
Kọ àwọn ìṣòro míì tó ò ń ní pẹ̀lú aago tí wọ́n ní o gbọ́dọ̀ máa wọlé.
․․․․․
Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí?
․․․․․
Àǹfààní wo lo rò pé ó wà nínú kó o yanjú ìṣòro yìí lọ́nà yẹn?
․․․․․
Bó pẹ́ bó yá, ìwọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé, wàá sì lómìnira láti ṣohun tó bá wù ẹ́. Àmọ́ ní báyìí ná, ní sùúrù. Tiffany, tó ti di ọmọ ogún [20] ọdún báyìí sọ pé: “O lè máà ní gbogbo òmìnira tó ò ń fẹ́, àmọ́ tó o bá lè kọ́ láti máa fojú tó tọ́ wo ìkálọ́wọ́kò, o ò ní kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó o fìgbà èwe ẹ ṣe.”
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ wọn gan-an kọ́ nìyí.
b Àbá síwájú sí i wà nínú àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Àwọn Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù Bí?” nínú Jí! January–March 2007.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Báwo ni dídá táwọn òbí ẹ dá aago tó o gbọ́dọ̀ máa wọlé fún ẹ ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ ẹ jẹ wọ́n lọ́kàn?
◼ Bó o bá ti kọjá aago tí wọ́n ní o gbọ́dọ̀ máa wọlé, báwo lo ṣe lè mú káwọn òbí ẹ pa dà fọkàn tán ẹ?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
NǸKAN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ
“Mo gbà pé bí wọ́n ṣe dá aago tí mo gbọ́dọ̀ máa wọlé fún mi yẹn dáa, torí pé tí mi ò bá tètè sùn, ṣe ni màá máa kanra!”—Gabe, ọmọ ọdún 17.
“Àìmọye ìgbà ni aago tí wọ́n dá fún mi pé kí n máa wọlé ti gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ wàhálà. Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà táwọn ọ̀dọ́ kan tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré láti máa mu ọtí gbé ọtí wá síbi àríyá. Bí wọ́n ṣe gbé e dé báyìí, èmi àti ọ̀rẹ́ mi yáa fi aago tí wọ́n ti ní a gbọ́dọ̀ máa délé kẹ́wọ́ ká bàa lè kúrò níbẹ̀.”—Katie, ọmọ ọdún 18.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Ẹ FẸNU KÒ SÍBÌ KAN
O ò ṣe báwọn òbí ẹ jíròrò nípa aago tí wọ́n ní kó o máa wọlé, bóyá ẹ lè fẹnu kò síbì kan lórí ọ̀rọ̀ náà?
◼ Màá máa wọlé ní aago ․․․․․ ní alẹ́: ․․․․․, màá sì máa wọlé ní aago ․․․․․ ní alẹ́: ․․․․․.
◼ Bí mi ò bá délé lásìkò tẹ́ ẹ dá, mo fara mọ́ ọn pé kẹ́ ẹ sọ aago náà di ․․․․․ ó kéré tán fún ọ̀sẹ̀ ․․․․․.
◼ Bí mo bá ń wọlé déédéé ní aago tẹ́ ẹ dá, fún oṣù ․․․․․ ó kéré tán, ẹ máa sún aago náà sókè.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
BÓ O BÁ FẸ́ KÁWỌN ÒBÍ Ẹ SÚN AAGO TÍ WÀÁ MÁA WỌLÉ SÓKÈ . . .
◼ Wá àkókò tó yẹ láti bá wọn jíròrò ọ̀rọ̀ náà.—Oníwàásù 3:1, 7.
◼ Ṣe ara ẹ lọ́mọ gidi nípa wíwọlé lásìkò.—Mátíù 5:37.
◼ Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè ní káwọn òbí ẹ jẹ́ kó o pẹ́ níta, kó o lè fi bó o ṣe jẹ́ ọmọlúwàbí tó hàn wọ́n.—Mátíù 25:23.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ
◼ Aago tó o ní kọ́mọ ẹ ọkùnrin máa wọlé ti kọjá ọgbọ̀n ìṣẹ́jú báyìí, àfi bó o ṣe gbọ́ tẹ́nì kan rọra ṣílẹ̀kùn àbáwọlé. O rò ó sínú pé, ‘Ó rò pé mo ti lọ sùn nìyẹn o.’ O ò kúkú tíì sùn. Kódà, látìgbà tó ti yẹ kó wọlé lo ti lọ jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀kùn. Bó ṣe ṣílẹ̀kùn báyìí, ńṣe lojú ìwọ àti ẹ̀ ṣe mẹ́rin. Kí lo máa sọ? Kí lo máa ṣe?
Ohun tó o lè ṣe pọ̀. O lè fọwọ́ tí ò tó nǹkan mú ọ̀rọ̀ náà. Bóyá kó o rò ó lọ́kàn ẹ pé, ‘Ọmọdé ò lè ṣe kó má hùwà ọmọdé o jàre.’ O sì lè gba ọ̀rọ̀ náà kanrí, kó o wá sọ pé: “Òní lo jáde nílé yìí mọ.” Dípò kó o gbaná jẹ, kọ́kọ́ gbọ́ ohun tó máa sọ, bóyá ó nídìí tó fi pẹ́ kó tó dé. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá lè lo àìgbọràn tó ṣe láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì. Lọ́nà wo?
Àbá: Sọ fún ọmọ rẹ pé tó bá di ọjọ́ kejì, wàá jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ wáyè, kẹ́ ẹ sì jọ jókòó yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ìwọ wo ọgbọ́n táwọn òbí kan dá. Bí ọmọ wọn bá wọlé lẹ́yìn aago tí wọ́n dá, wọ́n á ní kó máa tètè dé ní ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ṣáájú ti tẹ́lẹ̀. Bó bá sì jẹ́ pé ọmọ náà máa ń wọlé lákòókò, tó sì ṣeé fọkàn tán, ẹ dà á rò bóyá ẹ lè fi kún òmìnira rẹ̀, kẹ́ ẹ sì máa jẹ́ kó pẹ́ díẹ̀ sí i lóde. Ó ṣe pàtàkì pé kí ọmọ yín ní òye tó ṣe kedere nípa aago tẹ́ ẹ fẹ́ kó máa wọlé àti ohun tẹ́ ẹ máa ṣe fún un bí kò bá wọlé ní aago yẹn. Kẹ́ ẹ sì rí i dájú pé ẹ ṣe ohun tẹ́ ẹ sọ bó bá pẹ́ kó tó wọlé.
Ọ̀rọ̀ Ìṣọ́ra: Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀.” (Fílípì 4:5) Kẹ́ ẹ tó dá aago tọ́mọ á máa wọlé, ẹ kọ́kọ́ bá a jíròrò ọ̀rọ̀ náà, ẹ jẹ́ kó dábàá aago pàtó kan, kó sì sọ ìdí tó fi mú aago yẹn. Kẹ́ ẹ wá gba ohun tó sọ rò. Bí ìwà ọmọ yín bá fi hàn pé ó ṣeé fọkàn tán, ó máa dáa kẹ́ ẹ gbé ohun tó sọ yẹ wò tó bá mọ́gbọ́n dání.
Ká sọ̀rọ̀ ká bá a bẹ́ẹ̀ ni iyì ọmọlúwàbí. Torí náà, kọ́mọ má bàa pẹ́ lóde nìkan kọ la ṣe ń dá aago tó gbọ́dọ̀ wọlé fún un. Ẹ̀kọ́ àtàtà tó máa ṣe é láǹfààní nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé ló jẹ́.—Òwe 22:6.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àmì ìtẹ̀síwájú ni dídá tí wọ́n dá aago tó o gbọ́dọ̀ máa wọlé fún ẹ, ṣe ló dà bí ìgbà tó o gbàwé àṣẹ ìwakọ̀