ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/09 ojú ìwé 20
  • Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Kékeré

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Kékeré
  • Jí!—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Tẹlifíṣọ̀n Ń Jani Lólè Àkókò Lóòótọ́?
    Jí!—2006
  • Lílo Tẹlifíṣọ̀n Tìṣọ́ratìṣọ́ra
    Jí!—2000
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Béèyàn Ṣe Lè Pinnu Ìwọ̀n Táá Máa Wò
    Jí!—2006
Àwọn Míì
Jí!—2009
g 7/09 ojú ìwé 20

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Kékeré

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KÁNÁDÀ

◼ Ìwé ìròyìn The New York Times ṣàlàyé pé: “Ohun àgbàyanu tó máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ni tẹlifíṣọ̀n.” Àmọ́ ṣá o, “káwọn ọmọdé wulẹ̀ jókòó gẹlẹtẹ sídìí tẹlifíṣọ̀n fún wákàtí tí kò lóǹkà ti ń nípa búburú lórí ara àti ọkàn wọn,” ó ń dù wọ́n ní àǹfààní tí wọ́n ní láti lo ìdánúṣe, kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì ní ìfararora pẹ̀lú àwọn míì.

Lẹ́yìn táwọn olùṣèwádìí nílé ìwòsàn àwọn ọmọdé, ìyẹn Children’s Hospital, nílùú Seattle, ní ìpínlẹ̀ Washington, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, gbé ìwádìí wọn karí bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ [2,500] àwọn ọmọdé ṣe ń wo tẹlifíṣọ̀n sí, wọ́n “rí i pé báwọn ọmọ kéékèèké bá ṣe ń wo tẹlifíṣọ̀n sí nígbà tí wọ́n wà láàárín ọmọ ọdún kan sí mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa ṣòro fún wọn tó láti máa pọkàn pọ̀ nígbà tí wọ́n bá pé ọmọ ọdún méje,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The New York Times ṣe sọ. Irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ń ya ìpáǹle, wọn kì í ní sùúrù, wọn kì í sì í lè pọkàn pọ̀ fún ìgbà pípẹ́. Onímọ̀ nípa ìwà àti ìṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́, Ọ̀mọ̀wé Jane M. Healy sọ pé: “Ọ̀pọ̀ òbí àwọn ọmọ tí àyẹ̀wò ìṣègùn fi hàn pé wọn kì í lè pọkàn pọ̀ ti rí i pé ìṣòro náà dẹwọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ lẹ́yìn tí wọn ò jẹ́ káwọn ọmọ náà wo tẹlifíṣọ̀n mọ́.”

Kí làwọn òbí lè ṣe láti dín àkókò táwọn ọmọ wọn fi ń wo tẹlifíṣọ̀n kù? Ìwé ìròyìn náà dábàá pé: Jẹ́ kọ́mọ rẹ mọ ìgbà tó lè wo tẹlifíṣọ̀n lóòjọ́ àti bó ṣe yẹ kó pẹ́ tó nídìí ẹ̀. Má máa lé àwọn ọmọ rẹ lọ sídìí tẹlifíṣọ̀n. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa fáwọn ọmọ rẹ níṣẹ́ ṣe nínú ilé. Jẹ́ kọ́mọ rẹ mọ irú eré táá máa wò, kó o sì pa tẹlifíṣọ̀n bó bá ti wò ó tán. Bó bá ṣeé ṣe, ìwọ àtọmọ ẹ ni kẹ́ ẹ jọ wó eré náà, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ohun tẹ́ ẹ rí níbẹ̀. Lákòótán, kí ìwọ náà dín tẹlifíṣọ̀n wíwò kù.

Béèyàn bá fẹ́ kọ́ àwọn ọmọ láti máa lo ìdánúṣe, kí wọ́n sì máa ní ìfararora pẹ̀lú àwọn míì, ó máa gba àkókò, ìpinnu àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Àǹfààní tó wà níbẹ̀ ò sì kéré rárá. Ńṣe ló rí bí òwe àtijọ́ kan tó sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Kéèyàn máa kọ́ àwọn ọmọ láti níwà rere jẹ́ apá pàtàkì lára ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lo ìwé tí wọ́n ṣe, ìyẹn ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, láti kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ tó jíire. Ó dájú pé báwọn òbí bá ń báwọn ọmọ jíròrò ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń jẹ́ kọ́rọ̀ wọn jẹ àwọn lógún láti kékeré jòjòló, wọ́n á jàǹfààní tó wà pẹ́ títí. Àbí, kí ló lè gbádùn máwọn òbí bíi kí wọ́n rí i pé àwọn ọmọ wọn dàgbà di ẹni táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún tí wọ́n sì ṣeé fọkàn tán?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́