ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/11 ojú ìwé 12-13
  • Ọlọ́run Tù Mí Nínú Nígbà Tí Mo Wà Nínú Ìṣòro

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Tù Mí Nínú Nígbà Tí Mo Wà Nínú Ìṣòro
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Rí Ojúlówó Ìtùnú
  • Mo Fara Da Ọ̀pọ̀ Ìṣòro
  • Ìgbésí Ayé Mi Lérè, Ọkàn Mi sì Balẹ̀
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Ń Bá A Lọ Ní Gbígbilẹ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Sísìn Tọkàntọkàn Lójú Onírúurú Àdánwò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Mi Ò Ṣi Iṣẹ́ Tí Màá Ṣe Láyé Mi Yàn
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 1/11 ojú ìwé 12-13

Ọlọ́run Tù Mí Nínú Nígbà Tí Mo Wà Nínú Ìṣòro

Gẹ́gẹ́ bí Victoria Colloy ṣe sọ ọ́

Dókítà kan sọ fún màámi pé: “Kò sóhun tá a tún lè ṣe sọ́rọ̀ ọmọ rẹ mọ́. Láti ìsinsìnyí lọ, àfi kó máa fi igi rìn, a sì máa fi nǹkan di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú kí ẹsẹ̀ rẹ̀ lè máa dúró ṣánṣán.” Ọ̀rọ̀ yìí dà mí lọ́kàn rú gidigidi! Kí ni màá lè ṣe tí mi ò bá lè rìn?

WỌ́N bí mi ní November 17, 1949, ni ìlù Tapachula, ìpínlẹ̀ Chiapas, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Nígbà tí wọ́n bí mi, ara mi dá ṣáṣá, èmi sì ni àkọ́bí nínú àwa ọmọ mẹ́rin tí màámi bí. Àmọ́, nígbà tí mo fi máa pé ọmọ oṣù mẹ́fà, mi ò lè rá mọ́, agbára káká sì ni mo fi máa ń sún kúrò níbi tí mo bá wà. Oṣù méjì lẹ́yìn náà, mi ò tiẹ̀ wá lè kúrò lójú kan mọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí rú àwọn dókítà àdúgbò wa lójú, torí pé àwọn ọmọdé míì ní ìlú Tapachula náà ní irú ìṣòro yìí. Torí náà, dókítà kan tó jẹ́ olùtọ́jú egungun wá láti Mexico City kó bàa lè ṣàyẹ̀wò ohun tó fa ìṣòro yìí. Àyẹ̀wò náà fi hàn pé, àrùn rọpárọsẹ̀ ló ń ṣe wá.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ta, wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ kan fún mi ní ìgbáròkó, orúnkún àti kókósẹ̀. Nígbà tó yá, èjìká mi ọ̀tún náà di ahẹrẹpẹ. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́fà, wọ́n gbé mi lọ sí Mexico City kí n lè máa gba ìtọ́jú lọ níbẹ̀. Torí pé màámi ń ṣiṣẹ́ ní oko kan ní ìpínlẹ̀ Chiapas, mò ń gbé lọ́dọ̀ ìyá àgbà ní Mexico City. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ilé ìwòsàn ni mo máa ń wà.

Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́jọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ẹsẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, ńṣe ló wá burú sí i, mi ò tiẹ̀ wá lè gbé ẹsẹ̀ mọ́ rárá. Àwọn dókítà wá sọ pé, láti ìgbà náà lọ, àfi kí n máa fi igi rìn, wọ́n sì máa fi nǹkan di ẹsẹ̀ mi mú kó bàa lè dúró ṣánṣán.

Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], ìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ fún mi. Àwọn ibi tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ náà fún mi ni, eegun ẹ̀yìn, ẹsẹ̀, kókósẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀. Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ kọ̀ọ̀kan, mo ní láti ṣe àwọn ohun tó máa mú kí ara mi lè pa dà bọ̀ sípò. Lẹ́yìn ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ abẹ náà, wọ́n mọ nǹkan kan sí mi lẹ́sẹ̀ láti fi gbé ẹsẹ̀ mi dúró. Nígbà tí wọ́n ṣí i kúrò, mo ní láti ṣe àwọn eré ìmárale tó nira gan-an.

Mo Rí Ojúlówó Ìtùnú

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá, màámi wá wò mí lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ kan fún mi. Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jésù wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì mú kí àwọn arọ rìn. Wọ́n fún mi ní ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n ti kọ́ ẹ̀kọ́ yìí, ìyẹn ìwé ìròyìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ jáde. Mo tọ́jú ìwé náà sí abẹ́ ìrọ̀rí mi, àmọ́ mi ò mọ bí ìwé náà ṣe di àwátì. Àṣé àwọn nọ́ọ̀sì ló mú ìwé náà. Wọ́n bá mi wí, wọ́n sì ní mi ò gbọ́dọ̀ kà á mọ́.

Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, màámi tún wá wò mí láti ìpínlẹ̀ Chiapas. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà. Wọ́n mú ìwé kan wá fún mi, orúkọ ìwé náà ni, Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada.a Wọ́n wá sọ fún mi pé, “Tó o bá fẹ́ gbé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, níbi tí Jésù ti máa wò ẹ́ sàn, àfi kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Láìka bí ìyá àgbà ṣe ń ta kò mí sí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́rìnlá. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ní kí n kúrò ní ilé ìwòsàn náà torí pé àwọn ọmọdé nìkan ló wà fún.

Mo Fara Da Ọ̀pọ̀ Ìṣòro

Ọkàn mi gbọgbẹ́ gidigidi. Torí bí ìyá àgbà ṣe ń ta kò mí torí pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo ní láti pa dà lọ máa gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí mi ní ìpínlẹ̀ Chiapas. Síbẹ̀, wàhálà pọ̀ nílé wa torí pé dádì mi máa ń mu ọtí àmujù. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí ayé sú mi pátápátá. Ó ń ṣe mí bíi pé kí n gbé májèlé jẹ. Àmọ́, bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó, ìrònú mi yí pa dà. Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì pé òun máa sọ ayé di Párádísè máa ń mú inú mi dùn.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn ẹlòmíì nípa ìrètí àgbàyanu tó wà nínú Bíbélì. (Aísáyà 2:4; 9:6, 7; 11:6-9; Ìṣípayá 21:3, 4) Ní May 8, 1968, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18], mo ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé èmi náà ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láti ọdún 1974, àádọ́rin [70] wákàtí ni mo fi ń wàásù lóṣooṣù nípa ìrètí tó mú kí n ṣì máa wà láàyè.

Ìgbésí Ayé Mi Lérè, Ọkàn Mi sì Balẹ̀

Nígbà tó yá, èmi àti màámi kó lọ sí ìlú Tijuana nítòsí ààlà orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àti Amẹ́ríkà. Ibi tá à ń gbé rọ̀ wá lọ́rùn gan-an ni. Mo ṣì máa ń fi igi rìn ní àyíká ilé, ohun tí wọ́n fi di ẹsẹ̀ mi mú náà ṣì wà níbẹ̀. Orí kẹ̀kẹ́ náà ni mo máa ń wà tí mó bá ń dáná, tí mó bá ń fọṣọ àti nígbà tí mo bá ń lọ àwọn aṣọ mi. Mo tún ní kẹ̀kẹ́ tó ń lo iná, tí wọ́n dìídì ṣe fún mi, òun ni mo máa ń gbé jáde tí mo bá fẹ́ lọ wàásù.

Láfikún sí bí mo ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní òpópónà àti nínú ilé wọn, gbogbo ìgbà ni mo tún máa ń lọ sí ilé ìwòsàn kan tí kò jìnnà sílé wa, mo sì máa ń jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn tó ń dúró níta láti gba ìtọ́jú. Tí mo bá ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, màá wa kẹ̀kẹ́ mi lọ sí ọjà láti ra àwọn nǹkan tá a nílò, màá wá pa dà sílé láti bá màámi se oúnjẹ kí n sì ṣe àwọn iṣẹ́ ilé.

Ká bàa lè máa rówó gbọ́ bùkátà wa, mo máa ń ta àwọn aṣọ àlòkù. Màámi ti pé ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rin [78] báyìí, ìwọ̀nba sì ni ohun tí wọ́n lè ṣe, torí pé ẹ̀ẹ̀mẹta ni àrùn ọkàn ti kọ lù wọ́n. Torí náà, mo máa ń bójú tó bí wọ́n ṣe ń lo oògùn àti bí wọ́n ṣe ń jẹun. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara wa kò le, a máa ń sapá láti lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Ó ti lé ní ọgbọ̀n [30] èèyàn tí mo ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látọdún yìí wá, àwọn pẹ̀lú sì ti ń wàásù fáwọn ẹlòmíì báyìí.

Ó dá mi lójú pé ohun tí Bíbélì sọ yìí máa ní ìmúṣẹ: “Ní àkókò yẹn, [ìyẹn nínú ayé tuntun Ọlọ́run] ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.” Títí dìgbà náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tù mí nínú pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”—Aísáyà 35:6; 41:10.b

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é ní ọdún 1958, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ jáde mọ́.

b Arábìnrin Victoria Colloy kú ní November 30, 2009, ní ẹni ọgọ́ta [60] ọdún. Màmá rẹ̀ kú ní July 5, 2009.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Èmi rèé nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje, ńṣe ni wọ́n fi nǹkan gbé ẹsẹ̀ mi dúró

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Kẹ̀kẹ́ tó ń lo iná tí wọ́n dìídì ṣe fún mi ni mo máa ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́