Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé
Ṣé Ìpinnu Tó Dára Ni Wọ́n Ṣe?
Ka Númérì 13:1, 2, 25-33; 14:3, 6-12. Wo àwòrán yìí, kó o sì kọ àwọn ìdáhùn rẹ sórí àwọn ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí.
1. Kí nìdí tí èyí tó pọ̀ jù lára àwọn amí náà fi pinnu láti mú ìròyìn tí kò dára wá?
․․․․․
2. Kí ló ṣẹlẹ̀ nítorí pé àwọn amí mẹ́wàá náà mú ìròyìn burúkú wá?
AMỌ̀NÀ: Ka Númérì 14:26-38.
․․․․․
3. Kí nìdí tó fi dá Jóṣúà àti Kálébù lójú pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa ṣẹ́gun?
․․․․․
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Bí ìdílé yín bá ń kojú ìṣòro kan, báwo lo ṣe lè yẹra fún títẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn amí mẹ́wàá náà, àmọ́ tí wàá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jóṣúà àti Kálébù?
KÍ LO MỌ̀ NÍPA ÀPỌ́SÍTÉLÌ PÉTÉRÙ?
4. Àwọn orúkọ márùn-ún wo ni wọ́n pe Pétérù nínú Bíbélì?
AMỌ̀NÀ: Ka Mátíù 10:2; 16:16; Jòhánù 1:42; Ìṣe 15:14.
․․․․․
5. Ǹjẹ́ Pétérù fẹ́ ìyàwó?
AMỌ̀NÀ: Ka 1 Kọ́ríńtì 9:5.
․․․․․
FÚN ÌJÍRÒRÒ:
Sọ ìtàn kan tó o gbádùn nípa Pétérù. Ànímọ́ wo ni Pétérù ní tó wu ìwọ náà pé kó o ní, báwo lo ṣe lè ṣe é?
NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.
OJÚ ÌWÉ 6 Kí ló yẹ ká máa bá àwọn aládùúgbò wa sọ? Éfésù 4:________
OJÚ ÌWÉ 8 Kí ni òtítọ́ máa ṣe fún ẹ? Jòhánù 8:________
OJÚ ÌWÉ 11 Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ọ̀tá ìkẹyìn? 1 Kọ́ríńtì 15:________
OJÚ ÌWÉ 24 Kí ló yẹ kó o sá fún? 1 Kọ́ríńtì 6:________
ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ
1. Ẹ̀rù bà wọ́n, wọn kò sì lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.—Númérì 14:3, 11.
2. Gbogbo àwọn ọkùnrin láti ogún [20] ọdún sókè ló kú sínú aginjù, àyàfi Jóṣúà àti Kálébù.
3. Wọ́n gbà gbọ́ pé Jèhófà máa ti àwọn lẹ́yìn.—Númérì 14:9.
4. Símónì, Pétérù, Símónì Pétérù, Kéfà àti Símíónì.
5. Bẹ́ẹ̀ ni.