ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/11 ojú ìwé 6-9
  • Ǹjẹ́ Ìgbà Kan Ń bọ̀ Tí Àwọn Apániláyà Ò Ní Sí mọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ìgbà Kan Ń bọ̀ Tí Àwọn Apániláyà Ò Ní Sí mọ́?
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwé Kan Tó Lè Yíni Lọ́kàn Pa Dà
  • Ẹgbẹ́ Ará Kan tí Ìfẹ́ So Pọ̀
  • A Lè Fi Ohun tí Jésù Kọ́ni Ṣèwàhù
  • Àǹfààní Wà Nínú Fífi Àwọn Ẹ̀kọ́ Bíbélì Sílò
  • Ó Dájú Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dára
  • Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ń hùwà Ipá
    Jí!—2011
  • “Mo Kàn Ní Kí N gba Ohun Tí Wọ́n Fi Ránṣẹ́ Sí Mi Ni”
    Jí!—2011
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Kí Lẹ Máa Fi Ìgbésí Ayé Yín Ṣe? (Apá Kìíní)
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Mo Rí Ojúlówó Ìfẹ́ àti Àlàáfíà
    Jí!—2012
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 7/11 ojú ìwé 6-9

Ǹjẹ́ Ìgbà Kan Ń bọ̀ Tí Àwọn Apániláyà Ò Ní Sí mọ́?

‘IṢẸ́ kékeré kọ́ ló máa gbà kéèyàn tó lè yí ìrònú àti ìmọ̀lára àwọn apániláyà pa dà.’ Ohun táwọn olùwádìí kan sọ nìyẹn, lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ogún ọdún ṣàyẹ̀wò ìwà àwọn apániláyà.

Àmọ́, kí lohun tó lè yí àwọn tó ti jingíri sínú ìwà ipá àti ẹ̀mí ìgbẹ̀san lọ́kàn pa dà?

Ìwé Kan Tó Lè Yíni Lọ́kàn Pa Dà

Láàárín ọdún 1990 sí 1999, Hafeni bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí ẹ̀sìn rẹ̀ fi ń kọ́ni, ó sì pinnu láti ní Bíbélì. Ó sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere nínú Bíbélì, [ìyẹn Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù], níbi tí ìtàn ìgbésí ayé Jésù wà. Bí mo ṣe ń kà á, kò pẹ́ rárá tí àwọn ànímọ́ Jésù fi fà mí mọ́ra, àti bó ṣe fi inúure àti àìṣe ojúsàájú bá àwọn èèyàn lò. Èyí múnú mi dùn gan-an ni.”

Nígbà tí Hafeni ń ka Bíbélì síwájú sí i, ó sọ pé “mo ka ibì kan nínú Bíbélì tó jẹ́ kí n túbọ̀ mọ irú ẹni tí Ọlọrun jẹ́, ìyẹn Ìṣe 10:34 àti 35.” Ó kà pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”

Ó wá sọ pé: “Mo wá rí i pé àwọn èèyàn fúnra wọn ni wọ́n ń kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ẹ̀tanú sílẹ̀. Mo ti wá mọ̀ pé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lè yí ìrònú àwọn èèyàn pa dà, àti pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé ní pé kéèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Èyí ṣe pàtàkì ju ká máa jà nítorí àwọn ẹ̀yà, ìran tàbí àwọ̀ pàtó kan.”

Joseba tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, jẹ́ olórí ẹgbẹ́ kan tó fẹ́ lọ dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá kan. Ọkùnrin náà sọ pé: “Kó tó di pé a ṣe ohun tá a fẹ́ ṣe yìí, àwọn ọlọ́pàá mú mi, mo sì ṣẹ̀wọ̀n ọdún méjì.” Nígbà tó yá, ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Luci, bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Joseba, ọkọ rẹ̀ náà dara pọ̀ mọ́ ọn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Joseba sọ pé: “Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jésù, ó wá di àwòkọ́ṣe fún mi. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ Jésù wọ̀ mí lọ́kàn gan-an ni, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tó sọ pé: ‘Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.’ Mo mọ̀ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí.” (Mátíù 26:52.) Ó sọ pé: “Bí èèyàn bá pa ẹni kan, ńṣe ni èyí máa ń gbin ẹ̀mí ìkórìíra sọ́kàn àwọn ẹbí ẹni náà, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe gbẹ̀san. Ìbànújẹ́ ni ìwà ipá máa ń fà, kò sì lè mú kí ayé dára sí i.” Joseba wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtúnṣe sí ìrònú rẹ̀.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hafeni àti Joseba ti jẹ́ kí wọ́n rí i pé ẹ̀kọ́ Bíbélì lè ní ipá tó dára lórí ìgbésí ayé ẹni lọ́nà tó lágbára. Bíbélì sọ pé, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára,” ó tún lè fi òye mọ “àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sa agbára nínú ayé ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì ti mú kí wọ́n yí ìrònú àti ìwà wọn pa dà. Àmọ́, ǹjẹ́ ẹ̀rí wà pé àwọn tó ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣèwàhù kárí ayé wà níṣọ̀kan lóòótọ́?

Ẹgbẹ́ Ará Kan tí Ìfẹ́ So Pọ̀

Nígbà tí Hafeni bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, orí rẹ̀ wú gan-an bó ṣe rí ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn èèyàn tí wọn kì í ṣe ẹ̀yà kan náà. Ó sọ pé: “Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi pé mo lè jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ aláwọ̀ funfun. Mi ò tiẹ̀ lálàá ẹ̀ rí pé mo lè dẹni tó ń pe aláwọ̀ funfun ní arákùnrin mi. Èyí mú kó túbọ̀ dá mi lójú pé ìsìn tòótọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, torí pé àárín wọn ni mo ti rí irú ìṣọ̀kan tí mo ti ń wá, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá.”

Jésù sọ pé ohun téèyàn á fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ mọ̀ ni pé wọ́n á ní ‘ìfẹ́ láàárín ara wọn.’ (Jòhánù 13:34, 35) Jésù kò tún gbà láti lọ́wọ́ sí wàhálà ìṣèlú, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 6:15; 15:19; Mátíù 22:15-22) Ìfẹ́ àti àìdásí ìṣèlú jẹ́ ohun tí wọ́n fi dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ nígbà yẹn, bó sì ṣe rí lóde òní náà nìyẹn.

A Lè Fi Ohun tí Jésù Kọ́ni Ṣèwàhù

Ǹjẹ́ àwọn èèyàn lè ní ìfẹ́ láàárín ara wọn nígbà tó jẹ́ pé ìpániláyà àti ìwà ipá ló wọ́pọ̀, tí èyí sì ń fa ìyapa? Nígbà tí ọ̀ràn ìṣèlú bá di wàhálà, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbè sẹ́yìn ìran, orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà wọn, ńṣe ni èyí sì máa ń dá rògbòdìyàn sílẹ̀.

Àpẹẹrẹ kan ni ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914, ẹ̀mí ẹ̀yà tèmi ló dáa jù mú kí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Gavrilo Princip ṣekú pa Ọmọọba Francis Ferdinand, tó jẹ́ ọba lọ́la ní ilẹ̀-ọba Austria ati Hungary. Princip jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Black Hand, òfin ẹgbẹ́ yìí sọ pé “jíja àjàgbara dára ju kéèyàn máa fa wàhálà lórí àṣà ìbílẹ̀ lọ” nítorí kí ọwọ́ ẹni lè tẹ ohun tó fẹ́. Ìpànìyàn to ṣẹlẹ̀ yìí fa ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó pe ara wọn ní Kristẹni, èyí sì yọrí sí Ogun Àgbáyé Kìíní, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn tó jagun náà ni ẹ̀mí wọn lọ sí i, bẹ́ẹ̀, wọ́n sọ pé Jésù, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” làwọn ń tẹ̀ lé.—Aísáyà 9:6.

Lẹ́yìn tí ogun yẹn parí, àlùfáà kan tó lókìkí tó ń jẹ́ Harry Emerson Fosdick, bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó pera wọn ní aṣáájú ẹ̀sìn Kristẹni fún ṣíṣàì kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ó sọ pé: “A kọ́ àwọn èèyàn láti jagun. A fi àwọn jagunjagun ṣe àwọn akọni wa, kódà a tún gbé àwọn àsíá ogun sínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wa.” Ohun tí Fosdick fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: “Ẹnu tá a fi ń yin Ọmọ Aládé Àlàáfíà náà la tún fi ń gbé ogun lárugẹ.”

Àmọ́ àwọn èèyàn kan wà tí tiwọn yàtọ̀, ìwé kan tó dá lórí ìwádìí lórí àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí wọ́n ṣe lọ́dún 1975, sọ pé: “Ìgbà gbogbo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń yẹra fún ìwà ipá ‘nítorí pé Kristẹni ni wọ́n, wọn kò sí dá sí ọ̀ràn ogun,’ jálẹ̀ ogun àgbáyé méjì tó fa kíki àtàwọn ìgbà tí ìforígbárí wáyé láàárín àwọn ológun, èyí tó ṣẹlẹ̀ nígbà ‘Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀’.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n hùwà ìkà sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n, “kò sígbà kankan tí wọ́n fi ìwà ipá gbèjà ara wọn.” Ìwádìí yẹn parí báyìí pé: “Ẹ̀kọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ni fi hàn pé ó dá wọn lójú pé Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí.”

Àǹfààní Wà Nínú Fífi Àwọn Ẹ̀kọ́ Bíbélì Sílò

Nígbà tí olórí ìjọba orílẹ̀-èdè Belgium tẹ́lẹ̀ rí gba ìwé kan tó dá lórí ìtàn ìgbésí ayé Jésù lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀ kan, ìyẹn ìwé tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́, Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, ohun tó kà níbẹ̀ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an ni. Ó wá kọ̀wé sí aládùúgbò rẹ̀ náà pé: “Kò sí àní-àní pé bí gbogbo èèyàn bá lè fara balẹ̀ ka àwọn ìwé Ìhìn Rere, kí wọ́n sì máa fi àwọn ìlànà tí Jésù Kristi fi kọ́ni sílò, ayé kò ní rí bó ṣe rí yìí.”

Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “A ò ní nílò Ìgbìmọ̀ Ààbò tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè dá sílẹ̀, kì bá má sí àwọn apániláyà, ìwà ipá gan-an ò tiẹ̀ ní sí láyé.” Ibi tó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ni pé: “Àlá tí kò lè ṣẹ ni gbogbo èyí.” Àmọ́, ṣé àlá tí kò lè ṣẹ ni lóòótọ́? Kódà ní báyìí tó jẹ́ pé ìwà ipá ló gba ayé kan, Bíbélì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá látinú ipò tó yà tọ̀ síra lọ́wọ́ láti má ṣe hùwà ipá, kí wọ́n sì borí ìbínú kíkorò táwọn èèyàn máa ń fi hàn nítorí ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó kọjá àfẹnusọ tí wọ́n ti ń fojú rí láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, díẹ̀ ló kù kí bọ́ǹbù pa Andre, ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ pé inú rẹ̀ láwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan kú sí. Àwọn ajàjàgbara kan ló kẹ́ bọ́ǹbù náà síbẹ̀. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ràn kan nínú Bíbélì tó sọ pé ‘ká máa dárí ji ara wa ní fàlàlà.’ (Kólósè 3:13) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí bọ́ǹbù yẹn pa àwọn èèyàn, Hafeni di ara àwọn ajàjàgbara tó kẹ́ bọ́ǹbù náà, àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwàhù, ó sì jáwọ́ nínú ìwà ipá. (Sáàmù 11:5) Ní báyìí, Hafeni àti Andre ti wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà kan.

Ó Dájú Pé Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dára

Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló ń rí i pé bí àwọn ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn wọn ń ba lẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan, Andre ń wàásù fún aládùúgbò rẹ̀ kan nípa ìrètí tó wà nínú Bíbélì pé ayé tuntun òdodo ń bọ̀. (Aísáyà 2:4; 11:6-9; 65:17, 21-25; 2 Pétérù 3:13) Lójijì, àwọn sójà dé pẹ̀lú ìbọn arọ̀jò ọta, wọ́n yí ilé náà ká, wọ́n sì ní kí Andre bọ́ síta, pé wọ́n fẹ́ bi í láwọn ìbéèrè kan. Nígbà táwọn sójà yẹn rí i pé ńṣe ni Andre ń kọ́ aládùúgbò rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì tún rí i pé inú aládùúgbò náà ń dùn sóhun tó ń kọ́, bí wọ́n ṣe fi í sílẹ̀ nìyẹn tí wọ́n bá tiwọn lọ.

Ohun tí Andre sọ fún aládùúgbò rẹ̀ ni pé, Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ àwa èèyàn, gẹ́gẹ́ bó ti ṣe nígbà ayé Nóà nígbà tí ‘ilẹ̀ ayé kún fún ìwà ipá.’ (Jẹ́nẹ́sísì 6:11) Ńṣe ni Ọlọ́run fi àkúnya omi pa àwọn èèyàn yẹn run, ó sì pa Nóà tó fẹ́ràn àlàáfíà mọ́ pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Jésù sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:37-39.

Jésù, tó jẹ́ “Ọmọ ènìyàn,” ni Ọlọ́run ti yàn láti jẹ́ Alákoso ìjọba kan tó wà ní ọ̀run, tí à ń pé ní Ìjọba Ọlọ́run, kò ní pẹ́ mọ́ tó fi máa kó àwọn ọmọ ogun ọ̀run jọ láti wá pa àwọn tó ń hùwà ipá run láyé. (Lúùkù 4:43) Gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run, Jésù máa ‘ṣe ẹ̀tọ́ fún gbogbo èèyàn, àlááfíà sì máa wà.’ Ó máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ “lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 72:7, 14, Contemporary English Version.

Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ òdodo tí wọ́n sì di ọmọ abẹ́ ìṣàkóso Ọba ọ̀run yìí á rí i bí ayé á ṣe yí pa da di Párádísè ẹlẹ́wà, tí àlàáfíà sì máa jọba. (Lúùkù 23:42, 43) Bíbélì sọ pé: “Àlàáfíà àti òdodo yóò ṣàkóso lórí àwọn òkè ńláńlá àti òkè kéékèèké.”—Sáàmù 72:1-3, Contemporary English Version.

Ǹjẹ́ ayé kò ní gbádùn mọ́ni lábẹ́ ìṣàkóso irú ọba yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn apániláyà kankan kò ní sí nínú ayé náà.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hafeni àti Joseba ti jẹ́ kí wọ́n rí i pé ẹ̀kọ́ Bíbélì lè ní ipa tó dára lórí ìgbésí ayé ẹni lọ́nà tó lágbára

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

‘Bí gbogbo èèyàn bá lè máa fi àwọn ìlànà tí Jésù Kristi fi kọ́ni sílò, ayé yìí kò ní rí bó ṣe rí yìí. A ò ní nílò Ìgbìmọ̀ Ààbò tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè dá sílẹ̀, kó ní sí àwọn apániláyà, ìwà ipá gan-an kò tiẹ̀ ní sí láyé.’—Olórí ìjọba orílẹ̀-èdè Belgium tẹ́lẹ̀ rí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Nítorí pé Hafeni àti Andre fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwàhù, èyí mú kí wọ́n ní ìfẹ́ tòótọ́ sí ara wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́