“Mo Kàn Ní Kí N gba Ohun Tí Wọ́n Fi Ránṣẹ́ Sí Mi Ni”
ANDRE ọkùnrin aláwọ̀ funfun kan tí wọ́n bí lórílẹ̀-èdè South Africa, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Nàmíbíà, sọ pé: “Mi ò lè gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tá à ń wí yìí ní ilé ìfìwéránṣẹ́. Ọjọ́ Monday lọjọ́ náà, àwọn èèyàn pọ̀ lọ bìbà nílé ìfìwéránṣẹ́ náà. Mo rí báàgì kan tí wọ́n gbé sílẹ̀ tí kò sẹ́nì kankan tó dúró tì í, èyí sì mú ìfura lọ́wọ́. Mo gba ohun tí mo fẹ́ gbà, mo sì kúrò níbẹ̀. Lẹ́yìn tí mo ti wakọ̀ fún nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ta, mo gbọ́ tí ohun kan bú gbàù. Mo wá gbọ́ lẹ́yìn náà pé bọ́ǹbù kan ló bú gbàù nítòsí ibi tí mo dúró sí nílé ìfìwéránṣẹ́ náà.”
Andre ṣàlàyé pé: “Mo kàn ní kí n gba ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ni, àmọ́ ẹ̀rù bà mí gan-an nígbà tí mo gbọ́ pé àwọn èèyàn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ ni àdó olóró náà já ara wọn jálajàla, mo sì mọ àwọn kan lára wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, ẹ̀rù ṣì máa ń bà mí tí mo bá rántí. Nígbà míì, mo máa ń rántí bí òkú àwọn èèyàn ṣe wà nílẹ̀ bẹẹrẹbẹ, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì fara pa, mo sì máa ń rò ó pé èmi náà ì bá ti kú báyìí.”
Ìṣòro Tó Kárí Ayé
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè máà tíì fojú ara rẹ rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sábà máa ń wáyé jákèjádò ayé. Ńṣe ni àwọn èèyàn tó ń hùwà ipá, èyí tí wọ́n sábà máa ń pè ní ìpániláyà, túbọ̀ ń pọ̀ sí i, kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá.—Wo àpótí náà “Àwọn Wo Ni Apániláyà?” lójú ìwé tó tẹ̀ lé èyí.
Ìwádìí kan tí akọ̀ròyìn kan tó máa ń fọ̀rọ̀ wáni lẹ́nu wò ṣe fi hàn pé, ní ọdún 1997, “orílẹ̀-èdè mẹ́rin péré ni ìpániláyà tó ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn rẹpẹtẹ ti ń wáyé léraléra.” Àmọ́ lọ́dún 2008, akọ̀ròyìn yìí tún kọ̀wé pé, “yàtọ̀ sí ilẹ̀ Australia àti Antarctica, ó ti lé ní ọgbọ̀n orílẹ̀-èdè báyìí káàkiri ayé tó ti kàgbákò ìwà ìpániláyà tó burú jáì, tó sì gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn.” Ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé “ńṣe ni àwọn àjọ tó ń ṣagbátẹrù irú ìwà ìpániláyà tó ń gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́dọọdún túbọ̀ ń pọ̀ sí i.”—The Globalization of Martyrdom.
Ṣàgbéyẹ̀wò ìpániláyà tá a ròyìn rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Àwọn tó kẹ́ bọ́ǹbù náà síbẹ̀ sọ pé òmìnira làwọn ń jà fún. Wọ́n fẹ́ gba òmìnira lọ́wọ́ ìjọba tó ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè wọn lákòókò yẹn. Ṣùgbọ́n, kí ló máa ń mú kí àwọn èèyàn hu irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hafeni.
Ọmọ orílẹ̀-èdè Sáńbíà ni Hafeni, àmọ́ àgọ́ àwọn tó ń wá ibi ìsádi tó wà ní orílẹ̀-èdè kan nítòsí wọn ló gbé dàgbà. Ó sọ pé: “Ìwà ìkà àti ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù sí àwọn mọ̀lẹ́bí mi àtàwọn ẹlòmíì ń bí mi nínú gan-an ni.” Torí náà, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ajàjàgbara kan táwọn òbí rẹ̀ ń ṣe.
Nígbà tí Hafeni ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àkókò yẹn, ó ṣàlàyé pé: “Ohun tó bani nínú jẹ́ jù lọ ni ipa tí gbígbé ní àgọ́ àwọn tó ń wá ibi ìsádi ń ní lórí mi. Àwọn ọmọdé kò lé gbé pẹ̀lú àwọn òbí, ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò wọn. . . . Ọ̀pọ̀ ló bógun lọ. Mi ò rí bàbá mi rí, kódà mi ò rí fọ́tò rẹ̀. Gbogbo ohun tí mo kàn mọ̀ ni pé ó ti bógun lọ. Ọgbẹ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà dá sí mi lọ́kàn kò tíì kúrò títí dòní.”
Ó ṣe kedere pé, oríṣiríṣi nǹkan ló ń fa ìpániláyà. Tá a bá mọ àwọn nǹkan náà, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí ìpániláyà dópin.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
ÀWỌN WO NI APÁNILÁYÀ?
Olùṣèwádìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mark Juergensmeyer ṣàlàyé pé: “Yálà ẹnì kan pe ìwà ipá ní ‘ìpániláyà’ tàbí kò pè é bẹ́ẹ̀, èyí sinmi lórí bóyá ẹni náà gbà pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ bẹ́tọ̀ọ́ mu tàbí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu. Ohun kan ni pé èrò téèyàn bá ní nípa bó ṣe yẹ kí ayé yìí rí ló máa pinnu irú ìwà téèyàn máa pè ní ìpániláyà: Béèyàn bá ní èrò pé ibi àlàáfíà ló yẹ kí ayé yìí jẹ́, ìpániláyà ní irú ẹni bẹ́ẹ̀ á ka ìwà jàgídíjàgan tó bá ṣẹlẹ̀ sí. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé èrò tí ẹnì kan ní ni pé ogun lọ̀rọ̀ ayé yìí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ka ìwà ipá sí nǹkan burúkú.”
Torí náà, nígbà tí wọ́n bá lo gbólóhùn náà, “ìpániláyà,” ó sábà máa ń ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ìṣèlú. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń hùwà ipá ló sọ pé òmìnira làwọn ń jà fún, wọn ò ka ara wọn sí apániláyà. Bí òǹkọ̀wé kan ṣe sọ, ìpániláyà ní í ṣe pẹ̀lú (1) híhùwà ìkà sáwọn aráàlú àti (2) lílo ìwà ipá láti mú àwọn èèyàn láyà pami. Torí náà, yálà àwọn ajàjàgbara náà jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ tàbí ìjọba ìlú, wọ́n sábà máa ń lo ìpániláyà kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́.