Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ń hùwà Ipá
WỌ́N ní kí Joseba tó ń gbé orílẹ̀-èdè Sípéènì sọ ìdí tó fi di ọmọ ẹgbẹ́ ajàjàgbara. Ohun tó sọ ni pé: “Ìnira àti ìwà ìrẹ́jẹ tá à ń kojú nígbà yẹn ti kọjá àfaradà. Ní ìlú Bilbao tí mò ń gbé nígbà yẹn, àwọn ọlọ́pàá á já wọlé àwọn aráàlú, wọ́n á lù wọ́n, wọ́n á sì mú wọn lọ.”
Joseba ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Wọ́n mú mi láàárọ̀ ọjọ́ kan torí pé mo sọ bí ìwà táwọn ọlọ́pàá yẹn ń hù ṣe rí lára mi. Inú bí mi gan-an dé bi pé, mo ṣáà fẹ́ wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà, bó bá tiẹ̀ gba pé kí n hùwà ipá.”
Ìnilára àti Ìgbẹ̀san
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ pé ó dára kéèyàn máa hùwà ipá, síbẹ̀ ó sọ pé “ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí,” ìyẹn ni pé, kéèyàn hùwà láìronú jinlẹ̀. (Oníwàásù 7:7) Ọ̀pọ̀ ló máa ń bínú gan-an nígbà tí wọ́n bá ń hùwà ìkà sí wọn nítorí ìran, ẹ̀sìn tàbí orílẹ̀-èdè wọn.
Bí àpẹẹrẹ, Hafeni tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ sọ pé: “Wọ́n fipá gba ilẹ̀ wa. Àwọn ẹranko pàápàá máa ń jà kí àwọn ẹranko míì má bàa gba ìpínlẹ̀ wọn, torí náà kò sóhun tó burú ńbẹ̀ táwa náà bá jà nítorí ilẹ̀ wa àti ẹ̀tọ́ wa.” Ajàjàgbara kan tó gbé bọ́ǹbù sára tó fi pa ara rẹ̀ àtàwọn ẹlòmíì sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí wọ́n tẹ̀ jáde lẹ́yìn tó kú pé: “A ò ní dáwọ́ ìjà yìí dúró, àyàfi tẹ́ ẹ bá jáwọ́ nínú fífi bọ́ǹbù àti gáàsì pa àwọn èèyàn mi, tí ẹ kò jù wọ́n sẹ́wọ̀n mọ́, tẹ́ ò sì fìyà jẹ wọ́n mọ́.”
Ìjà Ẹ̀sìn
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tí kò jẹ mọ ìsìn ló sábà máa ń mú kí àwọn kan di ajàjàgbara, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń hùwà jàgídíjàgan nítorí ẹ̀sìn. Agbẹnusọ fún àwọn ajàjàgbara kan tẹ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí alákòóso kan pé: “Kì í ṣe pé orí wa dàrú, kì í sì í ṣe pé a fẹ́ gbàjọba. Iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run là ń ṣe, ìdí sì nìyẹn tá ò fi dáwọ́ ìjà náà dúró.”
Nínú ìwé kan tí Daniel Benjamin àti Steven Simon kọ, ìyẹn, The Age of Sacred Terror, wọ́n sọ nípa ìjà ẹ̀sìn pé: “Nínú ayé tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti wá ń di ẹlẹ́sìn yìí, àwọn onígbàgbọ́ látinú àwọn ẹ̀sìn ńláńlá àtàwọn ẹ̀sìn tuntun, tó fi mọ́ àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i gbà pé ó yẹ kí ìwà ipá jẹ́ ara ìjọsìn àwọn.” Lẹ́yìn tí olùṣèwádìí míì ti ṣàkọsílẹ̀ ohun mélòó kan tó pè ní “ohun tó gbàfiyèsí nínú ọ̀ràn ìpániláyà jákèjádò ayé,” ó sọ pé: “Gbogbo àwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ìjà ẹ̀sìn ló gbà pé Ọlọ́run lọ́wọ́ sí ohun tí àwọn ń ṣe, kódà Ọlọ́run ló pa á láṣẹ fún àwọn.”
Àmọ́ èrò òdì ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ja ìjà ẹ̀sìn ní, èrò wọn sì ta ko ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀kọ́ ìsìn wọn àti ohun tí ẹ̀sìn wọn kà sí pàtàkì.
Ìwà Ipá Ti Gbilẹ̀ Lọ́kàn Wọn
Wọ́n ṣe Joseba tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí bí ọṣẹ ṣe ń ṣe ojú nígbà tí àwọn ọlọ́pàá mú un. Ó sọ pé: “Bí wọ́n ṣe hùwà ìkà sí mi jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé ẹ̀mí ìkórìíra tó wà lọ́kàn mi tọ́, ó sì yẹ. Tó bá gba pé kí n fi ẹ̀mí ara mi dí i kí àyípadà lè wà, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí wọ́n máa ń kọ́ àwọn ajàjàgbara nínú ẹgbẹ́ wọn máa ń mú kí wọ́n túbọ̀ rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa hùwà ipá. Hafeni sọ pé: “Nígbà tá a wà ní àgọ́ àwọn tó ń wá ibi ìsádi, a máa ń kóra jọ síbì kan, wọ́n sì máa ń kọ́ wa níbẹ̀ pé ńṣe ni àwọn aláwọ̀ funfun ń wá ọ̀nà tí wọ́n á fi máa jẹ gàba lé àwa aláwọ̀ dúdú lórí.” Kí ló wá jẹ́ àbájáde rẹ̀?
Hafeni sọ pé: “Èyí mú kí n túbọ̀ wá kórìíra àwọn aláwọ̀ funfun gan-an. Mi ò fọkàn tán èyíkéyìí lára wọn. Nígbà tó yá, ara mi ò gbà á mọ́, mo ronú pé a gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe sí i lásìkò tiwa.”
Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé, láìka bí ìkórìíra yẹn ṣe gbilẹ̀ lọ́kàn wọn sí, Joseba àti Hafeni dẹni tó mú ìkórìíra àti àìfọkàntánni kúrò lọ́kàn wọn. Kí ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Àpilẹ̀kọ tó kàn á ṣàlàyé.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Bí wọ́n ṣe hùwà ìkà sí mi jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé ẹ̀mí ìkórìíra tó wà lọ́kàn mi tọ́, ó sì yẹ. Tó bá gba pé kí n fi ẹ̀mí ara mi dí i kí àyípadà lè wà, ó tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”—Joseba