ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/12 ojú ìwé 4-8
  • Kí Ló Ń Fẹ́ Àtúnṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ń Fẹ́ Àtúnṣe?
  • Jí!—2012
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìṣòro Tó Kárí Ayé
  • Àdéhùn Láàárín Ìjọba Àtàwọn Ará Ìlú
  • Àwọn Tí Òṣì Dì Nígbèkùn
    Jí!—1998
  • Ọ̀ràn Ìlera Ti Sunwọ̀n Sí i Jákèjádò Ayé—Àmọ́ Gbogbo Èèyàn Kọ́ Ló Ń Jàǹfààní Rẹ̀
    Jí!—1999
  • Kí Ni Ìwọ Ń Fẹ́ Kó Dáa?
    Jí!—2012
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—2012
g 10/12 ojú ìwé 4-8

Kí Ló Ń Fẹ́ Àtúnṣe?

“Ìjọba kọ́ ló máa tán ìṣòro wa, ìjọba gan-an ni ìṣòro wa.”​—Ọ̀gbẹ́ni Ronald W. Reagan ló sọ bẹ́ẹ̀ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ogójì ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Ó TI lé ní ọgbọ̀n ọdún báyìí tí Ọ̀gbẹ́ni Ronald Reagan ti sọ ọ̀rọ̀ yìí. Lásìkò yẹn, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ìṣòro kan tó le gan-an. Ọ̀gbẹ́ni Reagan pe ìṣòro yìí ní “ìṣòro ọrọ̀ ajé tó lé kenkà.” Ó tún sọ pé: “Kò tíì sí irú ìṣòro ọ̀wọ́n gógó ọjà tó le tó báyìí tàbí tó tíì burú tó èyí rí nínú ìtàn orílẹ̀-èdè wa. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, a ti jẹ gbèsè lórí gbèsè, a sì ti fi ọjọ́ iwájú wa àti tàwọn ọmọ wa tàfàlà torí pé á fẹ́ tẹ́ ara wa lọ́rùn nísinsìnyí. Bí gbogbo nǹkan bá ń bá a lọ báyìí, ìṣòro kékeré kọ́ ló máa dá sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn, láàárín àwọn olóṣèlú títí kan ipò ọrọ̀ ajé.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀gbẹ́ni Reagan ń kọminú sí bí nǹkan ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú, kì í ṣe pé ó ti sọ̀rètí nù pátápátá. Ó sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ tá a ti wà lẹ́nu ìṣòro ọrọ̀ ajé wa yìí. Kì í ṣe ọjọ́ kan tàbí ọ̀sẹ̀ kan tàbí oṣù kan ni àwọn ìṣòro yìí máa yanjú, àmọ́ ṣá, lọ́jọ́ kan gbogbo rẹ̀ máa dópin.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.

Báwo ni ipò nǹkan ṣe wá rí lónìí? Ìròyìn kan tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ilé Gbígbé àti Ìdàgbàsókè Ìlú Lórílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà gbé jáde lọ́dún 2009 sọ pé: “Ó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i láti mú ìyípadà bá ìgbésí ayé wọn àti ipò ọrọ̀ ajé wọn, àmọ́ wọn ò lè ṣe é torí pé wọn ò ní àwọn ohun kòṣeémáàní, irú bí ilé gbígbé àti ètò ìlera tó péye. Kódà, ìgbìmọ̀ kan tó ń ṣojú fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lórí ọ̀rọ̀ ilé gbígbé, ìyẹn UN-HABITAT, sọ pé tó bá fi máa tó ọgbọ̀n ọdún, èèyàn kan nínú mẹ́ta ni yóò máa ronú pé àwọn ìṣòro kan wà tí àwọn ní, àmọ́ tí kò lè yanjú, irú bí ìṣòro àyíká tó dọ̀tí, àìsí omi tó mọ́ tónítóní àtàwọn ìṣòro tí àyípadà ojú ọjọ́ ń fà, èyí sì lè yọrí sí àìsàn àti àjàkálẹ̀ àrùn.

Àwọn Ìṣòro Tó Kárí Ayé

Ibi yòówù kó o máa gbé, jọ̀wọ́ gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò:

● Ǹjẹ́ ò ń rí owó tí ó tó gbọ́ bùkátà rẹ ná ju ti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn lọ?

● Ǹjẹ́ o rò pé ìwọ àti ìdílé rẹ ń rí ìtọ́jú tó péye gbà dáadáa?

● Ǹjẹ́ àyíká ibi tó o wà mọ́ tónítóní, ṣé ipò nǹkan sì ti sunwọ̀n sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

● Bó o ṣe ń ronú nípa ọjọ́ iwájú, ǹjẹ́ o rò pé nǹkan máa sunwọ̀n sí i lọ́dún mẹ́wàá, ogún ọdún tàbí ọgbọ̀n ọdún sígbà tá a wà yìí?

Àdéhùn Láàárín Ìjọba Àtàwọn Ará Ìlú

Àdéhùn sábà máa ń wà láàárín ìjọba àtàwọn ará ìlú. Irú àdéhùn bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ èyí tó wà lákọsílẹ̀ tàbí èyí tí wọ́n kàn jọ fohùn ṣọ̀kan lé lórí nípa ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ àti ojúṣe kálukú. Ìjọba retí pé kí àwọn ará ìlú máa hùwà tó bá òfin ìlú mu, kí wọ́n san owó orí wọn, kí wọ́n sì ti ìjọba lẹ́yìn kí ààbò tó péye lè wà nílùú. Ní ti àwọn alákòóso, wọ́n sábà máa ń ṣèlérí pé àwọn á pèsè ètò ìlera tó jíire, àwọn kò ní ṣe ẹ̀tanú sí ẹnikẹ́ni, àwọn á sì mú kí ipò ọ̀rọ̀ ajé túbọ̀ fara rọ.

Ǹjẹ́ àwọn ìjọba ti mú àwọn ìlérí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣẹ? Jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀rí tó wà yẹ̀ wò ní ojú ìwé mẹ́ta tó tẹ̀ lé èyí.

Ètò Ìlera Tó Jíire

Ohun táwọn èèyàn ń fẹ́: Ètò ìwòsàn tó péye tí kò wọ́n ju ohun tí agbára wọ́n ká.

Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an:

● Ìròyìn kan tí Báńkì Àgbáyé gbé jáde nípa ìmọ́tótó sọ pé: “Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọmọ ló ń kú lójoojúmọ́ nítorí àwọn àrùn tí ìdọ̀tí àti omi tí kò mọ́ tónítóní ń fà. Kódà ọmọ kọ̀ọ̀kan ló ń kú láàárín ogún [20] ìṣẹ́jú àáyá nítorí àrùn ìgbẹ́ gbuuru.”

● Ìwádìí kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé ṣe lọ́dún 2008 nípa bí àwọn èèyàn ṣe ń rí ìtọ́jú àìsàn gbà “láwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ àtàwọn orílẹ̀-èdè tó kúṣẹ̀ẹ́,” fi hàn pé “àwọn olówó ń rí ìtọ́jú ìlera gbà dáadáa ju àwọn òtòṣì lọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò rí ìtọ́jú tó jíire tí wọ́n nílò, tó wà fún tẹrú tọmọ, tówó wọn ká gbà.”

Ọdún méjì lẹ́yìn náà, Àjọ Ìlera Àgbáyé tún rí i pé “kò rọrùn fún àwọn ìjọba láti máa san owó tó máa lè kájú gbogbo ètò ìlera. Bí iye àwọn èèyàn ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tí wọ́n ń ṣàìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí, tí ìtọ́jú tí wọ́n ń fún wọn sì túbọ̀ ń gbówó lórí sí i, ṣe ni owó tí wọ́n fi ń tọ́jú àwọn aláìsàn ń pọ̀ sí i.”

● Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nípa ètò ìlera ti wá ń kọni lóminú báyìí, torí pé àwọn oògùn tó máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa tẹ́lẹ̀ lè má ṣiṣẹ́ mọ́. Wọ́n ti fi àwọn oògùn apakòkòrò àrùn inú ara, tí wọ́n ṣe láàárín ọdún 1941 sí 1949, gbógun ti àwọn àrùn tó ń ranni bí ẹ̀tẹ̀ àti ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ì bá ti gbẹ̀mí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Àmọ́ ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé jáde, èyí tí wọ́n pè ní World Health Day 2011, sọ pé: “Àwọn kòkòrò àrùn tí kò gbóògùn túbọ̀ ń pọ̀ sí í, wọ́n sì ń gbèèràn. Agbára àwọn oògùn táwọn èèyàn ń lò tẹ́lẹ̀ kò sì ká wọn mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe ni àrùn túbọ̀ ń pọ̀ sí i, àwọn oògùn tá a fi ń gbógun tì wọ́n kò sì tó nǹkan mọ́.”

Ohun tó ń fẹ́ àtúnṣe: Ó yẹ ká rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní “sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

Ìdájọ́ Òdodo àti Ìbánilò-Lọ́gbọọgba

Ohun táwọn èèyàn ń fẹ́: Kí àwọn èèyàn yéé ṣe ẹ̀tanú sí àwọn ẹ̀yà tí kò tó nǹkan mọ́, kí wọ́n sì máa ṣe dáadáa sí àwọn obìnrin, kó máà sí ìyàtọ̀ kankan láàárín àwọn olówó àti tálákà.

Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an:

● Níbi àpérò kan, àjọ tó ń ṣagbátẹrù dídá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ìyẹn Leadership Conference on Civil Rights Education Fund, sọ pé: “Híhu ìwà ìkà sí àwọn èèyàn, bíba ilé ìjọsìn jẹ́ àti dídá rògbòdìyàn sílẹ̀ ládùúgbò nítorí ẹ̀tanú táwọn èèyàn ní sí àwọn ẹ̀yà kan tàbí ẹ̀sìn àti nítorí kèéta sí àwọn obìnrin tàbí ọkùnrin tàbí sí ẹnì kan nítorí ìlú tó ti wá, túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ó sì ń kọni lóminú gan-an.”

● Ìwé kan tó dá lórí ohun tí àwọn obìnrin ń ṣe láti rí ìdájọ́ òdodo gbà, ìyẹn Progress of the World’s Women: In Pursuit of Justice, tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé jáde sọ pé: “Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn obìnrin kárí ayé ni àwọn èèyàn ń rẹ́ jẹ, tí wọ́n sì ń hùwà ìkà àti kèéta sí nínú ilé wọn, níbi iṣẹ́ àti láwọn ibòmíì.” Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Afghanistan, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó obìnrin mẹ́jọ nínú mẹ́wàá tí kì í rí ìtọ́jú kankan gbà nílé ìwòsàn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bímọ. Ní orílẹ̀-èdè Yemen, kò sí òfin kankan tó de àwọn tí wọ́n ń hùwà ipá sáwọn èèyàn lábẹ́ òrùlé wọn. Ní orílẹ̀-èdè olómìnira ti Kóńgò, ó kéré tán, ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àwọn obìnrin tí wọ́n ń fipá bá lòpọ̀ lójoojúmọ́.

● Ní oṣù October 2011, ọ̀gbẹ́ni Ban Ki-moon tó jẹ́ ọ̀gá àgbà Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ pé: “Ọ̀rọ̀ ayé yìí wá tojú súni gbáà. Oúnjẹ pọ̀ rẹpẹtẹ nílùú, síbẹ̀ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni ebi ń hàn léèmọ̀. Àwọn kan ń náwó yàfùnyàfùn, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ òtòṣì paraku. Ìmọ̀ ìṣègùn ti tẹ̀ síwájú gan-an, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ aláboyún ló ń kú lọ́jọ́ ìkúnlẹ̀ . . . Ọ̀pọ̀ owó ló ń lọ sórí ríra àwọn nǹkan ìjà tí wọ́n fi ń pa àwọn èèyàn dípò kí wọ́n máa lò ó fún ààbò aráàlú.”

Ohun tó ń fẹ́ àtúnṣe: Ó yẹ kí àwọn èèyàn máa ṣe dáadáa sí àwọn ẹ̀yà tí kò tó nǹkan àtàwọn obìnrin, kó máà sí àwọn tó ń “lọ́ ìdájọ́ òdodo gbà lọ́wọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́” mọ́.—Aísáyà 10:1, 2.

Ọrọ̀ Ajé Tó Fara Rọ

Ohun táwọn èèyàn ń fẹ́: Kí gbogbo èèyàn níṣẹ́ lọ́wọ́, kí wọ́n sì máa rí owó ná.

Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an:

● Àjọ kan tó ń rí sí bí àwọn nǹkan ṣe ń lọ lágbàáyé, ìyẹn Worldwatch Institute, sọ pé: “Òṣìṣẹ́ pọ̀ nígboro tó lè ṣiṣẹ́ táa mú kí ọ̀rọ̀ ajé túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí, àmọ́ iṣẹ́ tó wà kò tó nǹkan. Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé sọ pé ó lé ní ọgọ́rùn-ún méjì mílíọ̀nù èèyàn tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ lọ́dún 2010, torí ọ̀rọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀.”

● Ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC kéde “ìkìlọ̀ tí Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé sọ pé àìní iṣẹ́ lọ́wọ́ tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ń ṣàkóbá fún ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ kárí ayé, èyí sì lè yọrí sí rògbòdìyàn. Bí iṣẹ́ ṣe túbọ̀ ń dín kù fi hàn pé iye iṣẹ́ tó máa wà kò ní ju ìdajì èyí tí àwọn èèyàn nílò lọ. . . . Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé tún sọ pé inú àwọn èèyàn kò dùn sí bí kò ṣe sí iṣẹ́ nígboro, wọ́n sì ń bínú torí pé àwọn ọ̀bàyéjẹ́ túbọ̀ ń dá kún ìṣòro yìí. Ó ṣeé ṣe kí rògbòdìyàn ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, pàápàá ní àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nílẹ̀ Yúróòpù àti ní àgbègbè ilẹ̀ Arébíà.”

● Ìwé The Narcissism Epidemic tó dá lórí ìṣòro jíjọ ara ẹni lójú, tó jáde lọ́dún 2009 sọ pé, ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, “gbèsè tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń jẹ lórí káàdì tí wọ́n fi ń rajà láwìn ti lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá owó dọ́là [$11,000], ìyẹn sì fi ìlọ́po mẹ́ta ju ti ọdún 1990 lọ.” Àwọn tó ṣe ìwé yẹn tún sọ pé ṣekárími ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn tọrùn bọ gbèsè. Wọ́n ní: “Táwọn ará Amẹ́ríkà bá ti rí ẹni tó ń lo ọkọ̀ bọ̀gìnnì àti aṣọ olówó ńlá, wọ́n ti gbà pé olówó lẹni náà. Àmọ́ ohun tó yẹ kí wọ́n fi sọ́kàn ni pé onígbèsè ló pọ̀ jù nínú wọn.”

Ohun tó ń fẹ́ àtúnṣe: Ó yẹ kí gbogbo èèyàn níṣẹ́ lọ́wọ́, kí wọ́n má sì ná owó ní ìná àpà. Bíbélì sọ pé “owó jẹ́ fún ìdáàbòbò” àmọ́ ó tún kìlọ̀ pé “ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.”—Oníwàásù 7:12; 1 Tímótì 6:10.

Tá a bá wo ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 4 sí 8, kò dà bíi pé ohun rere kankan lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ ká má sọ̀rètí nù. Ayé yìí ṣì ń bọ̀ wá dáa, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìjọba èèyàn ló máa tún un ṣe.

[Àpótí/Graph tó wà ní ojú ìwé 5]

Àtúnṣe wo ni àwọn ọmọdé sọ pé àwọn máa fẹ́ kó bá ayé yìí? Lórí Ìkànnì 4children.org, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láàárín ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] àwọn ọmọdé tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin sí mẹ́rìnlá [14], fi hàn pé àwọn àtúnṣe tó wà nísàlẹ̀ yìí ni wọ́n fé:

[Graph]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

100%

KÓ MÁÀ SÍ EBI MỌ́

KÍ OGUN KÓ MÁÀ SÍ

DÓPIN ÀÌLÓWÓ LỌ́WỌ́

75%

KÓ MÁÀ SÍ

KÍ AYÉ MÁ ṢE Ẹ̀TANÚ MỌ́

MÓORU MỌ́

[Àpótí/Graph tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìwádìí tí àjọ Bertelsmann tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì ṣe lọ́dún 2009 jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ àwọn ọ̀dọ́ kan lógún, ìyẹn àwọn ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́rìnlá [14] sí méjìdínlógún [18].

Lára ohun táwọn ọ̀dọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí ni ìwà ìpániláyà àti bí àwọn èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i láyé. Kódà wọ́n rò pé àwọn nǹkan míì wà tó ṣe pàtàkì ju ọrọ̀ ajé tó ń dẹnu kọlẹ̀ lọ. Látinú ìwádìí tí àjọ Bertelsmann ṣe, ohun tó lè mú kí àwọn ọ̀dọ́ yẹn rò bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn ìṣòro yìí kò tíì kan àwọn fúnra wọn.

[Graph]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

100%

75% ÀÌLÓWÓ LỌ́WỌ́

ÀÌSÍ OÚNJẸ ÀTI OMI ÌṢÒRO ÌBÀYÍKÁJẸ́ ÀTI

TÓ ṢEÉ MU OJÚ ỌJỌ́ TÓ Ń YÍ PA DÀ

50% ÀJÀKÁLẸ̀ ÀRÙN

ÀTI ÀÌSÀN

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́