KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ
Bá A Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Àkókò Wa
“Áà, ọjọ́ ti yáá lọ, a ò mà rọ́jọ́ mú so lókùn!” Ṣé ìwọ náà ti sọ bẹ́ẹ̀ rí? Tó bá dọ̀rọ̀ àkókò, àparò kan ò ga ju ọ̀kan lọ torí pé olówó ò ní in ju tálákà lọ. Yàtọ̀ síyẹn, àtolówó àti tálákà ò lè tọ́jú àkókò pa mọ́, tó bá ti lọ, ó lọ nìyẹn. Torí náà, ohun tó dáa jù ni pé ká fọgbọ́n lo àkókò wa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ohun mẹ́rin tó ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti fọgbọ́n lo àkókò wọn.
Àkọ́kọ́: Ṣètò Ara Ẹ
Mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Kọ àwọn ohun tó o fẹ́ ṣe sílẹ̀, lára wọn ni àwọn ohun tó ṣe pàtàkì tó o sì gbọ́dọ̀ tètè ṣe. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ohun míì wà tó ṣe pàtàkì àmọ́ tí kò gba kánjúkánjú, irú bíi lílọ sọ́jà lọ ra oúnjẹ. Bákan náà, àwọn nǹkan míì wà tó lè dà bíi pé ó jẹ́ kánjúkánjú, àmọ́ tí kò ṣe pàtàkì, irú bíi wíwo eré kan tá a fẹ́ràn lórí tẹlifíṣọ̀n látìbẹ̀rẹ̀.a
Ronú ohun tó o máa ṣe ṣáájú. Oníwàásù 10:10 sọ pé: “Tí irinṣẹ́ kan kò bá mú, tí ẹni tó fẹ́ lò ó kò sì pọ́n ọn, ó máa ní láti lo agbára tó pọ̀ gan-an. Àmọ́ ọgbọ́n ń mú kéèyàn ṣe àṣeyọrí.” Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ wa? Pọ́n irinṣẹ́ rẹ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ní ti pé kó o máa ronú ṣáájú ọ̀nà tó dáa jù tó o máa gbà lo àkókò rẹ. Má fàkókò ṣòfò lórí àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Tó o bá tètè parí iṣẹ́ tó o ní, o ò ṣe mú iṣẹ́ míì tó o ronú pé wàá ṣe tó bá yá? Tó o bá ń ronú ohun tó o fẹ́ ṣe ṣáájú, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wàá lè ṣe bíi ti ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tó pọ́n irinṣẹ́ ẹ̀ dáadáa.
Má ṣe ju agbára ẹ lọ. Má tọwọ́ bọ àwọn nǹkan tí kò ṣe pàtàkì tó sì máa gbàkókò ẹ. Kò yẹ kí èèyàn ki igi tó pọ̀ jù bọná, ìyẹn ni pé tó bá jẹ́ gbogbo nǹkan lo fẹ́ ṣe, ó lè kó àárẹ̀ bá ẹ, o ò sì ní láyọ̀.
Ìkejì: Yẹra Fáwọn Nǹkan Tó Lè Mú Kó O Fàkókò Ṣòfò
Má ṣe máa fi nǹkan falẹ̀. “Ẹni tó bá ń wojú afẹ́fẹ́ kò ní fún irúgbìn; ẹni tó bá sì ń wo ṣíṣú òjò kò ní kórè.” (Oníwàásù 11:4) Kí la rí kọ́? Ẹni tó bá ń fi nǹkan falẹ̀ máa fàkókò ṣòfò, ohun tó sì máa lè ṣe kò ní tó nǹkan. Àgbẹ̀ tí kò bá lọ sóko torí ojú ọjọ́ kò ní fúnrúgbìn, kò sì ní rí nǹkan kan kórè. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń dúró dìgbà tí gbogbo nǹkan máa tò, táá sì ṣe rẹ́gí bá a ṣe fẹ́, a ò ní gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Òótọ́ ni pé a gbọ́dọ̀ ṣèwádìí, ká sì ronú jinlẹ̀ ká tó ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, ó ṣe tán Òwe 14:15 sọ pé “aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.” Síbẹ̀, ká fi sọ́kàn pé kò sí bá a ṣe ṣèwádìí tó, tá a máa mọ gbogbo ibi tọ́rọ̀ kan máa já sí.—Oníwàásù 11:6.
Má ṣe jẹ́ adára-má-kù-síbì-kan. Jémíìsì 3:17 sọ pé: “Ọgbọ́n tó wá láti òkè [tàbí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run] . . . ń fòye báni lò.” Òótọ́ ni pé ó yẹ ká máa ṣe nǹkan lọ́nà tó dáa, àmọ́ tá a bá jẹ́ adára-má-kù-síbì-kan, a máa ní ẹ̀dùn ọkàn tá a bá ṣe àṣìṣe kékeré. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó ń kọ́ èdè tuntun gbọ́dọ̀ mọ̀ pé òun máa ṣàṣìṣe, òun sì máa kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe náà. Àmọ́ téèyàn bá jẹ́ adára-má-kù-síbì-kan, kò ní fẹ́ ṣe àṣìṣe kankan, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó tẹ̀ síwájú. Ẹ ò rí i pé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn mọ̀wọ̀n ara ẹ̀! Òwe 11:2 sọ pé: “Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.” Bákan náà, àwọn tó mọ̀wọ̀n ara wọn tí wọ́n sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kì í ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ, wọn kì í sì í sọ àṣìṣe wọn di nǹkan bàbàrà.
“Kì í ṣe owó nìkan la fi ń ra nǹkan, a tún máa ń lo àkókò.” Ìwé What to Do Between Birth and Death
Ìkẹta: Wà ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Má sì Ṣe Jura Ẹ Lọ
Máa ṣiṣẹ́ kó o sì máa wáyè sinmi. “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílé ohun tó jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.” (Oníwàásù 4:6) Téèyàn bá ń ṣiṣẹ́ bí aago, ìgbà wo ló fẹ́ ráyè gbádùn “ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára” rẹ̀? Kò ní ráyè sinmi, kò sì ní gbádùn ìgbésí ayé ẹ̀. Lọ́wọ́ kejì, ṣe ni àwọn ọ̀lẹ máa ń fi gbogbo ayé wọn sinmi, wọ́n sì máa ń fi àkókò ṣòfò. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó ní ká ṣiṣẹ́ kára ká sì gbádùn èrè iṣẹ́ wa. Kódà ó fi kún un pé “ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Oníwàásù 5:19.
Máa sùn dáadáa. Òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Màá dùbúlẹ̀, màá sì sùn ní àlàáfíà.” (Sáàmù 4:8) Ó yẹ kí àwọn tó ti dàgbà máa sùn fún nǹkan bí wákàtí mẹ́jọ lójoojúmọ́ kí ara wọn lè le dáadáa, kí ọpọlọ wọn sì jí pépé. Téèyàn bá ń sùn dáadáa, á lè pọkàn pọ̀, á tètè máa rántí nǹkan, nǹkan á sì tètè máa yé e. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní fàkókò ṣòfò. Lọ́wọ́ kejì, téèyàn ò bá sùn dáadáa, nǹkan ò ní tètè máa yé e, á máa ṣàṣìṣe, ara á sì máa kan án.
Nǹkan tí ọwọ́ ẹ lè tẹ̀ ni kó o máa lé. “Ó sàn kéèyàn máa gbádùn ohun tí ojú rẹ̀ rí ju kó máa dààmú lórí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́.” (Oníwàásù 6:9) Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ? Ẹni tó gbọ́n kì í lé ohun tó mọ̀ pé ọwọ́ òun ò lè tẹ̀. Torí náà, kì í jẹ́ kí ìpolówó ọjà kó sí òun lórí kì í sì í tọrùn bọ gbèsè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń jẹ́ kí “ohun tí ojú rẹ̀ rí,” ìyẹn ohun tó ní tẹ́ ẹ lọ́rùn.
Ìkẹrin: Máa Hùwà Rere
Àwọn nǹkan tó dáa ni kó o nífẹ̀ẹ́ sí. Ohun tó o bá nífẹ̀ẹ́ sí ló máa pinnu ohun tó o máa kà sí ohun tó dáa, tó ṣe pàtàkì, tó sì yẹ kó o fàkókò ṣe. Ohun téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ sí ló máa pinnu ohun tó máa fi ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe. Torí náà, tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tó dáa lo nífẹ̀ẹ́ sí, ó dájú pé àwọn nǹkan tó nítumọ̀ lo máa fayé ẹ ṣe, o ò sì ní fàkókò ẹ ṣòfò rárá. Kí ló máa jẹ́ kó o mọ àwọn ohun tó dáa tó o lè fàkókò ẹ ṣe? Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé Bíbélì ló lè kọ́ wa torí ọgbọ́n inú ẹ̀ kò láfiwé.—Òwe 2:6, 7.
Máa wáyè fáwọn tó o nífẹ̀ẹ́. Kólósè 3:14 sọ pé ìfẹ́ jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” A ò lè láyọ̀, ọkàn wa ò sì lè balẹ̀ tá ò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn pàápàá àwọn tó wà nínú ìdílé wa. Tẹ́nì kan bá ń lé owó tàbí ọrọ̀, tó sì pa àwọn èèyàn ẹ̀ tì, kò ní láyọ̀. Kò sí àní-àní pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ló ṣe pàtàkì jù, abájọ tó fi mẹ́nu kàn án ní ọ̀pọ̀ ìgbà.—1 Kọ́ríńtì 13:1-3; 1 Jòhánù 4:8.
Máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Dókítà ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Geoff, iṣẹ́ ẹ̀ ń mówó gidi wọlé, ó níyàwó tó dáa, ọmọ méjì àti àwọn ọ̀rẹ́ gidi. Àmọ́ iṣẹ́ tó ń ṣe máa ń jẹ́ kó rí àwọn tó ń jìyà àtàwọn tó ń kú. Ó máa ń ronú pé “Ṣé bó ṣe yẹ kí ìgbésí ayé rí nìyí?” Lọ́jọ́ kan, ó ka àwọn ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, ó sì rí ìdáhùn sí ìbéèrè ẹ̀.
Geoff ṣàlàyé ohun tó ń kọ́ fún ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀, àwọn náà sì nífẹ̀ẹ́ sí i. Gbogbo ìdílé yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn sì mú kí ìgbésí ayé wọn nítumọ̀, kí wọ́n sì lo àkókò wọn lọ́nà tó tọ́. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì tún jẹ́ kí wọ́n nírètí láti gbé títí láé nínú ayé kan tí ò ti ní sí ìyà àti ìrora mọ́.—Ìfihàn 21:3, 4.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Geoff jẹ́ ká rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.” (Mátíù 5:3) Ṣé ìwọ náà máa wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sí àní-àní pé wàá rí bó o ṣe lè fọgbọ́n lo àkókò rẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ìgbésí ayé ẹ máa nítumọ̀.
a Wo àpilẹ̀kọ náà “20 Ways to Create More Time” nínú Jí! April 2010 lédè Gẹ̀ẹ́sì.