Ìwé Àtijọ́ Kan Tó Wúlò Lóde Òní
Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló mọyì Bíbélì, wọ́n sì gbà pé ìwé mímọ́ pàtàkì kan tí wọ́n ń lò nínú ẹ̀sìn ni. Àmọ́ Bíbélì kì í ṣe ìwé ẹ̀sìn nìkan, ó tún ń fúnni nímọ̀ràn tó lè jẹ́ kéèyàn gbé ìgbé ayé tó dára.
Bí àpẹẹrẹ, wo díẹ̀ lára àǹfààní táwọn kan ti rí torí pé wọ́n ń ka Bíbélì, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn inú rẹ̀.
“Ayé mi ti túbọ̀ lójú. Mo ti ń ronú lọ́nà tó tọ́, ìlera mi sì ti sunwọ̀n sí i. Mo ti wá ń láyọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”—Fiona.
“Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀.”—Gnitko.
“Bíbélì ti tún ayé mi ṣe gan-an. Ní báyìí, mo ti dín àkókò tí mo fi ń ṣiṣẹ́ kù, mo sì máa ń wá àyè láti gbọ́ ti ìdílé mi.”—Andrew.
Díẹ̀ lèyí jẹ́ lára àwọn èèyàn tí Bíbélì ti ràn lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ti rí i pé Bíbélì wúlò gan-an, ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sì ṣàǹfààní.
Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ . . .
Láti ní ìlera tó dáa
Láti jẹ́ onísùúrù
Láti ní ìdílé aláyọ̀ àti ọ̀rẹ́ àtàtà
Láti máa rówó gbọ́ bùkátà
Láti sún mọ́ Ọlọ́run
Àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ kó o rí i pé kì í ṣe ìjọsìn nìkan ni Bíbélì wúlò fún, ó tún lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ.