Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀
Oríṣiríṣi nǹkan ló lè fìyà jẹni láyé, a ò sì ríbi yẹ̀ ẹ́ sí. Ó lè jẹ́ ogun, àìsàn, jàǹbá tàbí àwọn àjálù bí àkúnya omi àti ìjì líle.
Àwọn èèyàn fẹ́ mọ ìdí tá a fi ń jìyà.
Àwọn kan sọ pé wọ́n kádàrá ìyà mọ́ wa ni, kò sì sóhun tẹ́nì kankan lè ṣe nípa ẹ̀.
Àwọn míì gbà gbọ́ pé tẹ́nì kan bá ń jìyà, á jẹ́ nítorí pé ẹni náà ti ṣe ohun tí kò dáa láyé yìí tàbí nígbà tó kọ́kọ́ wáyé.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ mọ ìdí tí ìyà fi ń jẹ aráyé, àmọ́ wọn ò rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn.