ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 3 ojú ìwé 10-11
  • Yan Onírúurú Èèyàn Lọ́rẹ̀ẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yan Onírúurú Èèyàn Lọ́rẹ̀ẹ́
  • Jí!—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro
  • Ìlànà Bíbélì
  • Àǹfààní Wà Nínú Ká Yan Onírúurú Èèyàn Lọ́rẹ̀ẹ́
  • Ohun To O Lè Ṣe
  • Wọ́n Borí Ìkórìíra
    Jí!—2020
  • Máa Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Èèyàn
    Jí!—2020
  • Ṣó Yẹ Kí N Mú Àwọn Míì Lọ́rẹ̀ẹ́ Yàtọ̀ Sáwọn Tá A Ti Jọ Ń Ṣọ̀rẹ́?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Bá A Ṣe Lè Rẹ́ni Bá Ṣọ̀rẹ́
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 3 ojú ìwé 10-11
Àwọn obìnrin mẹ́rin tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ síra ń rẹ́rìn-ín bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀. Àwọn ọmọ wọn náà sì jọ ń ṣeré.

Yan Onírúurú Èèyàn Lọ́rẹ̀ẹ́

Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro

Tá a bá ń fojú burúkú wo àwọn kan, a ò ní fẹ́ sún mọ́ wọn, ńṣe nìyẹn á sì mú ká túbọ̀ máa kórìíra wọn. Tó bá sì jẹ́ pé àwọn tá a gbà pé a jọ mọwọ́ ara wa nìkan là ń bá ṣọ̀rẹ́, ńṣe làá máa rò pé èrò, ìwà àti ìṣe wa ló dáa jù.

Ìlànà Bíbélì

“Ẹ ṣí ọkàn yín sílẹ̀ pátápátá.”​—2 KỌ́RÍŃTÌ 6:13.

Kí la rí kọ́? “Ọkàn” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ni bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Tó bá jẹ́ pé àwọn tá a gbà pé a jọ mọwọ́ ara wa nìkan la máa ń fìfẹ́ hàn sí, ọkàn wa ò ní ṣí sílẹ̀, ìyẹn ni pé kò ní fàyè gba àwọn tó yàtọ̀ sí wa. Kí ìṣòro yẹn má bàa wáyé, a gbọ́dọ̀ múra tán láti máa bá àwọn tó yàtọ̀ sí wa ṣọ̀rẹ́.

Àǹfààní Wà Nínú Ká Yan Onírúurú Èèyàn Lọ́rẹ̀ẹ́

Tá a bá ń gbìyànjú láti sún mọ́ àwọn èèyàn, àá mọ ìdí tí wọ́n fi ń ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀. Bá a bá ṣe ń sún mọ́ wọn sí i, tó bá yá, a ò tiẹ̀ ní rántí mọ́ pé inú ẹ̀yà míì ni wọ́n ti wá. Àá wá mọyì wọn gan-an, àá sì máa gba tiwọn rò.

Wo àpẹẹrẹ obìnrin kan tó ń jẹ́ Nazaré. Nígbà kan, ó kórìíra àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Ó ṣàlàyé ohun tó mú kó yí èrò ẹ̀ pa dà, ó ní: “Mo máa ń bá wọn ṣeré, mo sì tún máa ń bá wọn ṣiṣẹ́. Mo wá rí i pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sóhun táwọn èèyàn sọ pé wọ́n jẹ́. Tó o bá sún mọ́ àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tìẹ, o ò ní máa fojú tí ò dáa wò wọ́n. Wàá nífẹ̀ẹ́ wọn, wàá sì mọyì wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

Ṣọ́ra O!

Àwọn kan máa ń hùwà tó lè ṣàkóbá fún ara wọn àtàwọn ẹlòmíì. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra tá a bá ń yan ọ̀rẹ́. A ò lè sọ pé ẹnì kan lẹ́mìí ìkórìíra torí pé kò yan oníṣekúṣe tàbí oníbékebèke èèyàn lọ́rẹ̀ẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò ní ṣàìdáa sáwọn oníwàkiwà tàbí ka fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n, àmọ́ kò yẹ ká máa bá wọn ṣọ̀rẹ́.​—Òwe 13:20.

Ohun To O Lè Ṣe

Máa wá ọ̀nà láti bá àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà tàbí èdè tó yàtọ̀ sí tìẹ sọ̀rọ̀. Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe rèé:

  • Sọ pé kí wọ́n sọ díẹ̀ nípa ara wọn fún ẹ.

  • Pè wọ́n láti wá bá ẹ jẹun.

  • Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa tí wọ́n bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa ara wọn, kó o sì mọ ohun tó jẹ wọ́n lógún.

Tó o bá mọ ohun tójú wọn ti rí, wàá mọ ìdí tí wọ́n fi ń hu àwọn ìwà kan, ìyẹn lè wá jẹ́ kó o fẹ́ràn àwọn tó wá látinú ẹ̀yà yẹn.

Ohun Tí Ẹnì Kan Sọ: Kandasamy àti Sookammah (Kánádà)

“Orílẹ̀-èdè South Africa la dàgbà sí. Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà sì wà níbẹ̀ nígbà yẹn. Wọ́n ní kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa gbé níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn sì mú káwọn ẹ̀yà kan kórìíra àwọn ẹ̀yà míì. Àwa kì í ṣe aláwọ̀ funfun, a sì kórìíra àwọn aláwọ̀ funfun gan-an torí pé àwọn kan lára wọn ti ṣàìdáa sí wa. Nígbà yẹn, bí wọ́n ṣe kórìíra wa nìkan la máa ń sọ, láìmọ̀ pé àwa náà lẹ́mìí ìkórìíra.

“Ohun tó mú ká yí èrò wa pa dà ni pé a bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn tó wá látinú oríṣiríṣi ẹ̀yà àti èdè ṣọ̀rẹ́. Bá a ṣe ń bá àwọn aláwọ̀ funfun rìn, a wá rí i pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà la gbà jọra. Àwọn nǹkan tá a kà sí pàtàkì àtàwọn ìṣòro wa sì jọra.

“Ìgbà kan tiẹ̀ wà tá a gba tọkọtaya kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun sílé wa, wọ́n sì pẹ́ gan-an lọ́dọ̀ wa. A wá mọ̀ wọ́n dáadáa. Kò pẹ́ rárá tá a fi dọ̀rẹ́ tá a sì wá rí i pé ọ̀kan náà ni wá. Nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, a bẹ̀rẹ̀ sí í fojú tó dáa wo gbogbo àwọn aláwọ̀ funfun.”

Wọ́n di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́

Johny àti Gideon ń kí àwọn ọmọdé níwájú ilé ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Johny àti Gideon, tí wọ́n sì wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nígbà kan, ní báyìí wọ́n ti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.

Wo fídíò Johny àti Gideon: Ọ̀tá Ni Wọ́n Tẹ́lẹ̀, Wọ́n Ti Di Arákùnrin Báyìí. Wá fídíò náà lórí ìkànnì jw.org.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́