ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 34
  • Irú Oúnjẹ Tuntun Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Irú Oúnjẹ Tuntun Kan
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jíjàǹfààní Látinú “Ọkà Ọ̀run”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ejò Bàbà
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 34
Ìyá kan àti ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ń kó mánà

ÌTÀN 34

Irú Oúnjẹ Tuntun Kan

ṢÓ O lè sọ ohun táwọn èèyàn wọ̀nyí ń kó ní ilẹ̀? Ńṣe ló dà bí èérún yìnyín. Ó funfun, ó fẹ́lẹ́ ó sì máa ń rún bí ìpékeré. Ṣùgbọ́n kì í ṣe èérún yìnyín o; ohun kan tó ṣeé jẹ ni.

Ó ti tó nǹkan bí oṣù kan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti kúrò ní Íjíbítì. Inú aginjù ni wọ́n wà. Ohun jíjẹ kì í fi bẹ́ẹ̀ hù níbí yìí, èyí ló fà á táwọn èèyàn náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í kùn, pé: ‘Ì bá sàn ká ní Jèhófà ti pa wá ní Íjíbítì. A ṣáà ń rí gbogbo oúnjẹ tó wù wá jẹ nígbà tá a wà níbẹ̀.’

Nítorí náà, Jèhófà wí pé: ‘Màá mú kí oúnjẹ rọ̀ dà sílẹ̀ bí òjò láti ojú sánmà.’ Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí nǹkan funfun tó rọ̀ dà sílẹ̀ yìí, wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé: ‘Kí lèyí?’

Mósè wí pé: ‘Èyí ni oúnjẹ tí Jèhófà fi fún yín láti máa jẹ.’ Àwọn èèyàn náà pè é ní MÁNÀ. Bó o bá tọ́ ọ wò, ńṣe ló dà bí àkàrà olóyin pẹlẹbẹ.

Mósè sọ fáwọn èèyàn náà pé: ‘Kí olúkúlùkù yín kó ìwọ̀n tó máa tó fún un.’ Wọ́n sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láràárọ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ọ̀sán bá pọ́n, mánà tó bá ṣẹ́ kù nílẹ̀ á yọ́ dà nù.

Mósè tún sọ pé: ‘Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ tọ́jú mánà kankan pa mọ́ di ọjọ́ kejì bó ti wù kó kéré mọ.’ Ṣùgbọ́n àwọn kan lára àwọn èèyàn náà kò jẹ́ gbọ́. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Nígbà tó fi máa di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, mánà tí wọ́n tọ́jú náà á ti yọ ìdin, á sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í rùn!

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kó mánà

Àmọ́, ọjọ́ kan wà láàárín ọ̀sẹ̀ tí Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n máa kó ìlọ́po méjì ìwọ̀n mánà tí wọ́n ń kó tẹ́lẹ̀. Èyí ni ọjọ́ kẹfà. Jèhófà sọ pé kí wọ́n tọ́jú díẹ̀ di ọjọ́ kejì, nítorí pé òun kì yóò rọ mánà kankan sílẹ̀ ní ọjọ́ keje. Nígbà tí wọ́n bá tọ́jú mánà náà di ọjọ́ keje, kì í yọ ìdin rárá bẹ́ẹ̀ sì ni kì í rùn! Iṣẹ́ ìyanu mìíràn ni èyí!

Mánà ni Jèhófà fi bọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ọdún tí wọ́n fi wà nínú aginjù.

Ẹ́kísódù 16:1-36; Númérì 11:7-9; Jóṣúà 5:10-12.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́