Jíjàǹfààní Látinú “Ọkà Ọ̀run”
KÉTÉ lẹ́yìn ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lọ́nà ìyanu, wọ́n fi àìní ìgbàgbọ́ lọ́nà tó ré kọjá ààlà hàn nínú Jèhófà, Olùdáǹdè wọn. Nítorí ìdí èyí, Jèhófà mú kí wọn máa rìn kiri nínú aginjù Sínáì fún ogójì ọdún. Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata” tí wọ́n jẹ́ àtìpó tó dara pọ̀ mọ́ wọn jẹ, wọ́n sì mu “tẹ́rùntẹ́rùn.” (Ẹ́kísódù 12:37, 38) Sáàmù 78:23-25 sọ bí èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀ fún wa pé: “[Jèhófà] sì tẹ̀ síwájú láti pàṣẹ fún sánmà ṣíṣú dẹ̀dẹ̀ lókè, àní ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ọ̀run. Ó sì ń rọ̀jò mánà lé wọn lórí ṣáá láti jẹ, ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run. Àní àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn alágbára; ó fi ìpèsè oúnjẹ ránṣẹ́ sí wọn tẹ́rùntẹ́rùn.”
Mósè tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó jẹ mánà náà ṣàpèjúwe bí oúnjẹ àrà ọ̀tọ̀ yìí ṣe rí. Ó kọ̀wé pé ní òwúrọ̀, lẹ́yìn tí “ipele ìrì náà gbẹ . . . , lórí ilẹ̀ aginjù ni ohun fúlẹ́fúlẹ́ kíkúnná kan wà, ó kúnná bí ìrì dídì wínníwínní lórí ilẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: ‘Kí ni èyí?’” tàbí ní ṣangiliti “man huʼ?” lédè Hébérù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ gbólóhùn yìí ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀rọ̀ náà “mánà,” orúkọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún oúnjẹ náà. Mósè sọ pé: “Ó sì funfun bí irúgbìn ewéko kọriáńdà, adùn rẹ̀ sì dà bí ti àkàrà pẹlẹbẹ olóyin.”—Ẹ́kísódù 16:13-15, 31, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.
Bí àwọn kan ṣe sọ, mánà kì í ṣe oúnjẹ kan lásán. Agbára tó ju ti ẹ̀dá lọ ló mú kó ṣeé ṣe. Fún àpẹẹrẹ, ó wà káàkiri, kò sì ní àkókò kan tí a kì í rí i. Bí wọ́n bá fi sílé mọ́jú, yóò yọ ìdin, yóò sì máa rùn; àmọ́, ìlọ́po méjì tí ìdílé kọ̀ọ̀kan ń kó ní ọjọ́ Sábáàtì kọ̀la kì í bàjẹ́, kí ó lè ṣeé jẹ ní ọjọ́ Sábáàtì—ìyẹn ọjọ́ tí mánà kò ní í bọ́. Dájúdájú, mánà náà jẹ́ ìpèsè ìyanu.—Ẹ́kísódù 16:19-30.
Mímẹ́nu kan “àwọn alágbára” tàbí “àwọn áńgẹ́lì,” nínú Sáàmù kejìdínlọ́gọ́rin fi hàn pé Jèhófà ti ní láti lo àwọn áńgẹ́lì láti pèsè mánà náà. (Sáàmù 78:25, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Bó ti wù kí ọ̀ràn náà rí, kò sídìí tí kò fi yẹ kí àwọn ènìyàn náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún inú rere rẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló fi ìwà àìmoore hàn sí Ẹni náà gan-an tó gbà wọ́n kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì. Àwa pẹ̀lú lè ṣàìka ìpèsè Jèhófà sí tàbí kí a tilẹ̀ di aláìmoore bí a kò bá ṣàṣàrò lórí àwọn inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. Nítorí náà, a dúpẹ́ pé Jèhófà mú kí ìtàn ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn wà lákọsílẹ̀ fún “ìtọ́ni wa.”—Róòmù 15:4.
Ohun Tó Jẹ́ Ẹ̀kọ́ fún Ísírẹ́lì Ṣàǹfààní fún Àwọn Kristẹni
Nígbà tí Jèhófà pèsè mánà náà, ohun tó ní lọ́kàn ju wíwulẹ̀ pèsè ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣaláìní nípa ti ará fún wọn, àwọn èèyàn tí wọ́n tó nǹkan bí àádọ́jọ ọ̀kẹ́. Ó fẹ́ ‘rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, kó sì dán wọn wò’ kí ó lè yọ́ wọn mọ́, kí ó sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ fún àǹfààní ara wọn. (Diutarónómì 8:16; Aísáyà 48:17) Bí wọ́n bá tẹ́wọ́ gba ìyọ́mọ́ àti ìtọ́ni yẹn, inú Jèhófà yóò dùn láti ‘ṣe rere fún wọn lẹ́yìnwá ọ̀la’ nípa fífún wọ́n ní àlàáfíà, jíjẹ́ kí wọ́n láásìkí, kí wọ́n sì ní ayọ̀ ní Ilẹ̀ Ìlérí náà.
Ohun pàtàkì kan tí wọ́n ní láti mọ̀ ni pé: “ènìyàn kì í tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni ènìyàn fi ń wà láàyè.” (Diutarónómì 8:3) Ká ní Ọlọ́run kò pèsè mánà náà ni, ebi ni ì bá pa àwọn ènìyàn náà kú—àwọn pàápàá kúkú sọ bẹ́ẹ̀. (Ẹ́kísódù 16:3, 4) Ojoojúmọ́ là ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó moore létí pé ó yẹ kí wọ́n gbára lé Jèhófà pátápátá, látàrí èyí, a mú kí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá dé Ilẹ̀ Ìlérí náà, tó kún fún ọ̀pọ̀ yanturu ohun ìní ti ara, wọn ò ní gbàgbé Jèhófà àti bí wọ́n ṣe gbára lé e.
Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa rántí nígbà gbogbo pé Ọlọ́run làwọn gbẹ́kẹ̀ lé fún ìpèsè àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé—nípa tara àti nípa tẹ̀mí. (Mátíù 5:3; 6:31-33) Nígbà tí Jésù Kristi ń fèsì ọ̀kan nínú àwọn àdánwò Èṣù, ó ṣàyọlò àwọn ọ̀rọ̀ Mósè tí a rí nínú Diutarónómì 8:3, pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’” (Mátíù 4:4) Dájúdájú, a ń fi kíka àwọn àsọjáde Jèhófà, èyí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́. Láfikún sí i, ìgbàgbọ́ wọn yóò túbọ̀ lókun sí i, nígbà tí wọ́n bá ń rí àwọn àǹfààní tó wà nínú àsọjáde wọ̀nyí nínú ìgbésí ayé wọn, bí wọ́n ti ń bá Ọlọ́run rìn, tí wọ́n sì ń fi ire Ìjọba rẹ̀ sí ipò kìíní.
Tí nǹkan bá ti ń di gbogbo ìgbà, ènìyàn aláìpé lè má mọrírì rẹ̀ mọ́—kódà báwọn nǹkan wọ̀nyí bá fi hàn pé Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ bìkítà nípa wa. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀nà tó ju ti ẹ̀dá lọ táa gbà pèsè mánà kọ́kọ́ ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kàyéfì, ó sì mú wọn kún fún ìmoore níbẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwáwí. Ìwà àìlọ́wọ̀ mú kí wọ́n ráhùn pé: ‘ọkàn wa ti fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra oúnjẹ játijàti yìí’—tó fi hàn pé wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí “lọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.” (Númérì 11:6; 21:5; Hébérù 3:12) Nítorí náà, àpẹẹrẹ tiwọn jẹ́ “ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.”—1 Kọ́ríńtì 10:11.
Báwo la ṣe lè fi àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ yìí sílò? Ọ̀nà kan ni pé kí a má ṣe jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tàbí àwọn ìpèsè tí à ń rí gbà nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye di ohun yẹpẹrẹ, tàbí ohun tí kò jọ wá lójú mọ́. (Mátíù 24:45) Gbàrà tí a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ẹ̀bùn Jèhófà sí ohun yẹpẹrẹ tàbí tó di èyí tó ń sú wa, a jẹ́ pé iná ìbátan wa pẹ̀lú rẹ̀ ti ń jó rẹ̀yìn nìyẹn.
Abájọ tí Jèhófà kì í fi í rọ̀jò àwọn ohun tuntun tó lè máa rùmọ̀lára ẹni sókè dà lé wa lórí nígbà gbogbo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló túbọ̀ ń tan ìmọ́lẹ̀ si Ọ̀rọ̀ rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, àti ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. (Òwe 4:18) Èyí ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀ láǹfààní láti ronú lórí àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́, kí wọ́n sì fi wọ́n sílò. Jésù tẹ̀lé àpẹẹrẹ Bàbá rẹ̀ nígbà tí ó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Ó ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn “bí wọ́n ti lè fetí sílẹ̀ tó,” tàbí “lóye to,” gẹ́gẹ́ bí àwọn olùtúmọ̀ kan ṣe sọ ọ́.—Máàkù 4:33; fi wé Jòhánù 16:12.
Mú Kí Ìmọrírì Tí O Ní fún Ìpèsè Ọlọ́run Lágbára Sí I
Jésù tún lo títẹ ọ̀rọ̀ mọ́ni lọ́kàn gbọnmọ-gbọnmọ. Fún àpẹẹrẹ, ó dájú pé a lè tẹ́wọ́ gba àwọn kókó kan láìjanpata—ó lè jẹ́ ìlànà kan nínú Bíbélì—àmọ́, ó lè pẹ́ kí ó tó wọ ọkàn-àyà kí ó sì di apá kan “àkópọ̀ ìwà tuntun” ti Kristẹni, pàápàá jù lọ tí àwọn ìwà ayé tó ti wà tipẹ́ àti ẹ̀mí ìrònú ibẹ̀ bá ti ta gbòǹgbò sínú ẹni náà. (Éfésù 4:22-24) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gan-an nìyẹn, nígbà tó kan ọ̀ràn àtiṣẹ́pá ìgbéraga, kí wọ́n sì gbé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀. Jésù ní láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrẹ̀lẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, gbogbo ìgbà wọ̀nyí ló sì máa ń fa kókó náà yọ ní ọ̀nà tó yàtọ̀ síra, kí ó bàa lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn, bẹ́ẹ̀ ló sì rí níkẹyìn.—Mátíù 18:1-4; 23:11, 12; Lúùkù 14:7-11; Jòhánù 13:5, 12-17.
Lóde òní, àwọn ìpàdé Kristẹni àti àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù nípa títẹ ọ̀rọ̀ mọ́ni lọ́kàn dáadáa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a mọyì èyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń fi ìfẹ́ tó ní sí wa hàn, kí a má sì jẹ́ kí ohun tí a ń rí gbà sú wa láé, bí mánà ṣe sú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Láìṣe àní-àní, bí a ṣe ń fi sùúrù fi ara wa fún àwọn ìránnilétí Jèhófà déédéé, a óò rí èrè tó dára gbà nínú ìgbésí ayé wa. (2 Pétérù 3:1) Irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ fi hàn ní tòótọ́ pé a ‘ń ní òye’ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ọkàn-àyà wa àti nínú èrò inú wa pẹ̀lú. (Mátíù 13:15, 19, 23) Láti ṣe èyí, a lè mú àpẹẹrẹ dídára ti Dáfídì, onísáàmù lò, ẹni tó jẹ́ pé kò rí onírúurú oúnjẹ tẹ̀mí táa ń rí lónìí gbà, síbẹ̀ ó ṣàpèjúwe àwọn òfin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí èyí tó “dùn ju oyin àti oyin ṣíṣàn ti inú afárá”!—Sáàmù 19:10.
“Mánà” Tó Ń Fúnni Ní Ìyè Àìnípẹ̀kun
Jésù sọ fún àwọn Júù pé: “Èmi ni oúnjẹ ìyè. Àwọn baba ńlá yín jẹ mánà ní aginjù, síbẹ̀ wọ́n kú. . . . Èmi ni oúnjẹ ààyè tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run; bí ẹnikẹ́ni bá jẹ nínú oúnjẹ yìí, yóò wà láàyè títí láé . . . Oúnjẹ tí èmi yóò fi fúnni ni ẹran ara mi nítorí ìyè ayé.” (Jòhánù 6:48-51) Oúnjẹ lásán tàbí mánà kò lè fúnni ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́, àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù yóò gbádùn ìbùkún ìyè àìnípẹ̀kun bópẹ́bóyá.—Mátíù 20:28.
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí yóò jàǹfààní nínú ìràpadà Jésù ni yóò gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” wọ̀nyí—tí “àwùjọ onírúurú ènìyàn púpọ̀ jaburata,” tí wọ́n jẹ́ àtìpó, tó dà pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà Ìjádelọ wọn kúrò ní Íjíbítì ṣàpèjúwe—yóò la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ já, èyí tí yóò mu gbogbo ìwà ibi pátá kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 7:9, 10, 14; Ẹ́kísódù 12:38) Èrè tó tún jù ìyẹn lọ ni àwọn ẹni tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fúnra wọ́n ṣàpèjúwe yóò gbádùn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ àwọn wọ̀nyí, tí wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, gẹ́gẹ́ bí àwọn tó para pọ̀ jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. Èrè wọn nígbà tí wọ́n bá kú ni àjíǹde sí ìyè ti ọ̀run. (Gálátíà 6:16; Hébérù 3:1; Ìṣípayá 14:1) Ibẹ̀ ni Jésù yóò ti fún wọn ni mánà àrà ọ̀tọ̀ kan.
Ìtumọ̀ “Mánà Tí A Fi Pa Mọ́”
Jésù tí a jí dìde sọ fún àwọn Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fún ní díẹ̀ nínú mánà tí a fi pa mọ́.” (Ìṣípayá 2:17) Mánà ìṣàpẹẹrẹ tí a fi pa mọ́ yìí múni rántí mánà tí Ọlọ́run pàṣẹ fún Mósè láti fi sínú ìgò oníwúrà nínú àpótí májẹ̀mú ọlọ́wọ̀. Wọ́n gbé Àpótí náà sí iyàrá ìkélé ibi Mímọ́ Jù Lọ ti àgọ́ ìsìn náà. A kò lè rí i, ká kúkú sọ pé a gbé e pa mọ́. Mánà ìṣàpẹẹrẹ yìí dúró gẹ́gẹ́ bí ohun ìrántí, kò sì bà jẹ́ nígbà tó wà nínú Àpótí náà, ìdí nìyẹn tí yóò fi jẹ́ àmì ìpèsè oúnjẹ kan tí kò lè bà jẹ́. (Ẹ́kísódù 16:32; Hébérù 9:3, 4, 23, 24) Fífún àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà ní mánà tí a fi pa mọ́ túmọ̀ sí pé Jésù fún wọn ní ẹ̀rí ìdánilójú pé wọn yóò rí àìleèkú àti àìdíbàjẹ́ gbà gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Ọlọ́run.—Jòhánù 6:51; 1 Kọ́ríńtì 15:54.
Onísáàmù sọ pé: “Ọ̀dọ̀ rẹ [Jèhófà] ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Ẹ wo bí ìpèsè mánà náà—àti gidi àtèyí tó jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ—ṣe túbọ̀ fi ìdí òtítọ́ yẹn múlẹ̀! Àti mánà tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì ìgbàanì ni o, àti mánà tó pèsè nípasẹ̀ ara tí Jésù fi lélẹ̀ nítorí tiwa ni o, títí kan mánà ìṣàpẹẹrẹ tí a fi pa mọ́, èyí tó tipasẹ̀ Jésù fún àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì pàápàá ń rán gbogbo wa létí gbígbé tí a gbára lé Ọlọ́run pátápátá fún ìwàláàyè. (Sáàmù 39:5, 7) Ẹ jẹ́ ká máa fi ìrẹ̀lẹ̀ òun ẹ̀mí àìjọra-ẹni-lójú hàn nígbà gbogbo pé òun la gbára lé. Lẹ́yìn náà, Jèhófà yóò ‘ṣe rere fún wa lẹ́yìnwá ọ̀la wa.’—Diutarónómì 8:16.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Gbogbo ènìyàn gbara lé “oúnjẹ ààyè tí ó sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run” kí wọ́n lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Wíwá sí gbogbo ìpàdé Kristẹni ń fi ìmọrírì táa ní fún àwọn ìránnilétí Jèhófà hàn