Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ṣé wàláà òkúta méjì nìkan lohun tó wà nínú àpótí májẹ̀mú, àbí àwọn nǹkan míì tún wà níbẹ̀?
Nígbà tí wọ́n ń ṣe ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ lọ́dún 1026 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, “kò sí nǹkan mìíràn nínú Àpótí náà ju wàláà méjì tí Mósè fi fúnni ní Hórébù, nígbà tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú nígbà tí wọ́n ń jáde kúrò ní Íjíbítì.” (2 Kíróníkà 5:10) Àmọ́ o, àwọn ìgbà kan wà tí àwọn nǹkan mìíràn tún wà nínú rẹ̀.
“Ní oṣù kẹta lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,” wọ́n wọ aginjù Sínáì. (Ẹ́kísódù 19:1, 2) Lẹ́yìn èyí ni Mósè gòkè lọ sórí Òkè Sínáì láti lọ gba wàláà òkúta méjì náà tí Òfin wà nínú rẹ̀. Mósè sọ pé: “Lẹ́yìn náà ni mo yí padà, tí mo sì sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òkè ńlá náà, tí mo sì fi àwọn wàláà náà sí inú àpótí tí mo ṣe, kí wọ́n lè máa wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún mi gan-an.” (Diutarónómì 10:5) Èyí jẹ́ àpótí kan tàbí ohun kan téèyàn lè kó nǹkan sí, tí Mósè lò fún àkókò kúkúrú, Jèhófà ló sì ní kó ṣe é kó lè fi àwọn wàláà òfin náà sínú rẹ̀. (Diutarónómì 10:1) Ìgbà tí ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ń parí lọ ni Mósè parí àpótí májẹ̀mú.
Kò pẹ́ rárá tí Ọlọ́run gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí kùn nítorí oúnjẹ. Jèhófà sì fún wọn ní Mánà. (Ẹ́kísódù 12:17, 18; 16:1-5) Lákòókò yẹn, Mósè wí fún Áárónì pé: “Mú ìṣà kan, kí o sì fi mánà ẹ̀kún òṣùwọ̀n ómérì kan sínú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ níwájú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ní láti pa mọ́ jálẹ̀ ìran-ìran yín.” Ìtàn náà fi yé wa pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè, Áárónì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé e kalẹ̀ síwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí [ìyẹn ibi tí wọ́n ń kó àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì sí] gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ní láti pa mọ́.” (Ẹ́kísódù 16:33, 34) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àní-àní pé Áárónì kó mánà sínú ìṣà kan nígbà náà, ìgbà tí Mósè kan Àpótí Ẹ̀rí tó sì kó wàláà sínú rẹ̀ ni wọ́n tó gbé ìṣà náà síwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí.
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, apá ìparí ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Mósè ṣe àpótí májẹ̀mú. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n tó fi ọ̀pá Áárónì sínú Áàkì náà, ìyẹn lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ Kórà àtàwọn mìíràn. Númérì 17:10 sọ pé: “Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: ‘Dá ọ̀pá Áárónì padà síwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ó pa mọ́ fún àmì fún àwọn ọmọ ìṣọ̀tẹ̀, kí ìkùnsínú wọn sí mi lè kásẹ̀ nílẹ̀, kí wọ́n má bàa kú.’” Lẹ́yìn èyí ni wọ́n wá kó gbogbo ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn sínú àpótí májẹ̀mú náà. Àwọn ohun náà sì ni “ìṣà wúrà . . . tí ó ní mánà àti ọ̀pá Áárónì tí ó rudi àti àwọn wàláà májẹ̀mú.”—Hébérù 9:4.
Ọlọ́run ló pèsè mánà náà nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rin ìrìn ogójì ọdún nínú aṣálẹ̀. Ìgbà tí wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí jẹ nínú àmújáde ilẹ̀” ìlérí ni kò fún wọn ní mánà mọ́. (Jóṣúà 5:11, 12) Ìdí pàtàkì tí wọ́n fi fi ọ̀pá Áárónì sínú àpótí ẹ̀rí ni pé, ọ̀pá náà yóò jẹ́ àmì tàbí ẹ̀rí láti fi hàn pé ohun tí ìran ọlọ̀tẹ̀ náà ṣe kò dára. Èyí fi hàn pé ó kéré tan, gbogbo àkókò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń rìn nínú aginjù ni ọ̀pá náà fi wà níbẹ̀. Nítorí náà, ó jọ pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àárín ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí àti ìgbà tó kù díẹ̀ kí wọ́n ṣe ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ ni wọ́n kó ọ̀pá Áárónì àti ìṣà wúrà tí mánà wà nínú rẹ̀ kúrò nínú àpótí ẹ̀rí náà.