ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 46
  • Odi Jẹ́ríkò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Odi Jẹ́ríkò
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ráhábù Gba Jèhófà Gbọ́
    Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • A “Polongo Rẹ̀ Ní Olódodo Nípa Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 46
Jóṣúà ń darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí wọ́n ṣe ń pariwo tí wọ́n sì ń fun ìwo wọn, tí odi Jẹ́ríkò sì wó lulẹ̀

ÌTÀN 46

Odi Jẹ́ríkò

KÍ LÓ ń mú kí odi tó yí Jẹ́ríkò ká yìí wó lulẹ̀? Ṣe ló dà bíi pé bọ́ǹbù ńlá kan já lù ú. Ṣùgbọ́n nìgbà yẹn lọ́hùn-ún, wọn ò mọ ohun tó ń jẹ́ bọ́ǹbù; wọn ò tiẹ̀ ní ìbọn pàápàá. Iṣẹ́ ìyanu Jèhófà kan tún nìyí o! Jẹ́ ká gbọ́ bó ṣe ṣẹlẹ̀ ná.

Gbọ́ ohun tí Jèhófà sọ fún Jóṣúà: ‘Kí ìwọ àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ yan yí ìlú náà ká. Ẹ yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà. Kẹ́ ẹ gbé àpótí ẹ̀rí dání. Káwọn àlùfáà méje máa rìn lọ níwájú kí wọ́n sì máa fun ìwo wọn.

‘Ní ọjọ́ keje kẹ́ ẹ yan yí ìlú náà ká ní ìgbà méje. Kẹ́ ẹ wá fun àwọn ìwo náà kíkan-kíkan, kí gbogbo yín sì ké ní ohùn rara. Odi yẹn á sì wó lulẹ̀ bẹẹrẹ!’

Odi Jẹ́ríkò wó lulẹ̀, ilé Ráhábù tí okùn pupa wà nìkan ni kò wó

Jóṣúà àtàwọn èèyàn náà ṣe ohun tí Jèhófà wí. Bí wọ́n ti ń yan, olúkúlùkù wọn pa rọ́rọ́. Kò sẹ́ni tó dún pínkín. Gbogbo ohun téèyàn lè gbọ́ ni ìró ìwo àti ẹsẹ̀ àwọn tó ń yan. Ó dájú pé ẹ̀rù ti ní láti máa ba ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà ní Jẹ́ríkò gidigidi. Ǹjẹ́ o rí okùn pupa tí wọ́n so rọ̀ sí ojú fèrèsé yẹn? Ojú fèrèsé ta nìyẹn? Kò sí àní-àní pé Ráhábù ti ṣe ohun táwọn amí náà sọ pé kó ṣe. Gbogbo ìdílé rẹ̀ wà nínú ilé náà pẹ̀lú ẹ̀ tí wọ́n ń wo ohun tó máa ṣẹlẹ̀.

Nígbà tí ọjọ́ keje pé, tí wọ́n ti yan yí ìlú náà ká ní ìgbà méje, ìró ìwo dún, àwọn jagunjagun ọkùnrin kígbe ní ohùn rara, odi náà sì wó lulẹ̀. Jóṣúà wá wí pé: ‘Ẹ pa olúkúlùkù ẹni tó wà nínú ìlú náà kẹ́ ẹ sì fi iná sun ún. Gbogbo rẹ̀ ni kẹ́ ẹ sun. Kìkì fàdákà, wúrà, bàbà àti irin ni kẹ́ ẹ pa mọ́, kẹ́ ẹ sì kó wọn wá sí ilé ìṣúra àgọ́ Jèhófà.’

Jóṣúà wí fún àwọn amí méjì náà pé: ‘Ẹ lọ sí ilé Ráhábù, kẹ́ ẹ sì mú òun àti gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde.’ Wọn ò pa Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlérí táwọn amí náà ti ṣe fún un.

JJóṣúà 6:1-25.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́