ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • we ojú ìwé 7-13
  • Ó Ha Bójúmu Láti Nímọ̀lára Lọ́nà Yìí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Bójúmu Láti Nímọ̀lára Lọ́nà Yìí Bí?
  • Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Wọnnì Tí Wọ́n Sọkún Nínú Bibeli
  • Láti Sọkún Tàbí Láti Máṣe Sọkún
  • Bí Àwọn kan Ṣe Ń Hùwàpadà
  • Bí Ìbínú àti Ẹ̀bi Ṣe Lè Nípalórí Rẹ
  • Nígbà Tí O Bá Ṣòfò Alábàáṣègbéyàwó
  • “Máṣe Jẹ́ Kí Àwọn Ẹlòmíràn Pinnu fún Ọ . . .”
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbé Pẹ̀lú Ẹ̀dùn-Ọkàn Mi?
    Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Da Ẹ̀dùn Ọkàn Téèyàn Mi Bá Kú?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ṣé Ó Burú Kéèyàn Ṣọ̀fọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Báwo Ni Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́?
    Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
Àwọn Míì
Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ́ Fẹ́ràn Bá Kú
we ojú ìwé 7-13

Ó Ha Bójúmu Láti Nímọ̀lára Lọ́nà Yìí Bí?

ẸNÌKAN tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé kan ní England, a kọ́ mi láti máṣe fi àwọn ìmọ̀lára mi hàn ní gbangba. Mo lè rántí bí baba mi tí ó jẹ́ ológun tẹ́lẹ̀rí, tí ń bá mi sọ̀rọ̀ ni pípahínkeke pé, ‘Máṣe sọkún!’ nígbà tí ohun kan bá fa ìbànújẹ́ fún mi. N kò lè rántí bóyá ìyá mi fi ìgbà kan rí fẹnuko èyíkéyìí nínú awa ọmọ lẹ́nu tàbí gbá wa mọ́ra (mẹ́rin ni wá). Ẹni ọdún 56 ni mí nígbà tí baba mi kú. Mo nímọ̀lára òfò ńláǹlà. Síbẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́, n kò lè sọkún.”

Nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, àwọn ènìyàn máa ń fi ìmọ̀lára wọn hàn ní gbangba. Bóyá wọ́n láyọ̀ ni tàbí banújẹ́, àwọn mìíràn yóò mọ bí ìmọ̀lára wọn ṣe rí. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ní àwọn apá ibìkan nínú ayé, pàápàá ní àríwá Europe àti Britain, àwọn ènìyàn, ní pàtàkì àwọn ọkùnrin ní a ti tọ́ láti fi àwọn ìmọ̀lára wọn pamọ́, láti tẹ èrò-ìmọ̀lára wọn rì, láti ṣe bí ọkùnrin, àti láti ṣara gírí. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ti pàdánù olólùfẹ́ kan, ó ha lòdì lọ́nà kan ṣáá láti fi ẹ̀dùn-ọkàn rẹ hàn bí? Kí ni ohun tí Bibeli wí?

Àwọn Wọnnì Tí Wọ́n Sọkún Nínú Bibeli

Bibeli, ni a kọ láti ọwọ́ àwọn Heberu tí wọ́n gbé ní àgbègbè ìlà-oòrùn Mediterranean, àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìfìmọ̀lára pamọ́. Ó ní àwọn àpẹẹrẹ àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi ẹ̀dùn-ọkàn wọn hàn ní gbangba. Ọba Dafidi ṣọ̀fọ̀ òfò Amnoni ọmọkùnrin rẹ̀ tí a ṣekúpa. Níti gidi, ó “sọkún ńláǹlà.” (2 Samueli 13:28-39) Ó tilẹ̀ tún kẹ́dùn nítorí òfò Absalomu ọmọkùnrin rẹ̀ aládàkàdekè, ẹni tí ó ti gbìyànjú láti gbapò ọba. Àkọsílẹ̀ Bibeli sọ fún wa pé: “Ọba [Dafidi] sì kẹ́dùn púpọ̀, ó sì gòkè lọ sí ìyẹ̀wù tí ó wà lórí òkè bodè, ó sì sọkún; báyìí ni ó sì ń wí bí ó ti ń lọ, ọmọ mi Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi Absalomu! áà! ìbáṣepé èmi ni ó kú ní ipò rẹ, Absalomu ọmọ mi, ọmọ mi!” (2 Samueli 18:33) Dafidi ṣọ̀fọ̀ gẹ́gẹ́ bí baba èyíkéyìí yóò ti ṣe. Ẹ sì wo iye ìgbà tí ó ti jẹ́ ìfẹ́ àwọn òbí pé kí ó jẹ́ àwọn ni ó kú dípò àwọn ọmọ wọn! Ó dàbí ohun tí kò bá ìwà ẹ̀dá mu rárá pé kí ọmọ kú ṣáájú òbí.

Báwo ni Jesu ṣe hùwàpadà sí ikú Lasaru ọ̀rẹ́ rẹ̀? Ó sọkún nígbà tí ó súnmọ́ ibojì rẹ̀. (Johannu 11:30-38) Lẹ́yìn náà Maria Magdalene sọkún bí ó ti súnmọ́ sàréè Jesu. (Johannu 20:11-16) Nítòótọ́, Kristian kan tí ó lóye ìrètí àjíǹde ti inú Bibeli kìí kẹ́dùn láì gba ìtùnú, bí àwọn kan tí kò ni ìpìlẹ̀ Bibeli ṣíṣekedere fún àwọn èrò ìgbàgbọ́ wọn nípa ipò àwọn òkú ti máa ń ṣe. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó ní àwọn ìmọ̀lára tí ó bójúmu, Kristian tòótọ́ náà, tí ó tilẹ̀ ní ìrètí àjíǹde pàápàá, ń kẹ́dùn, tí ó sì ń ṣọ̀fọ̀ òfò ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ràn.​—1 Tessalonika 4:13, 14.

Láti Sọkún Tàbí Láti Máṣe Sọkún

Níti ìhùwàpadà wa lónìí ńkọ́? Ìwọ ha rí fífi àwọn ìmọ̀lára rẹ hàn jáde gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó nira tàbí tí ń kó ìtìjú báni bí? Kí ni ohun tí àwọn olùgbaninímọ̀ràn dámọ̀ràn? Ojú-ìwòye wọn òde-òní wulẹ̀ sábà máa ń ṣe àtúnsọ ọgbọ́n ìjímìjí inú Bibeli tí a mísí. Wọ́n sọ pé a gbọ́dọ̀ fi ẹ̀dùn-ọkàn wa hàn, kí a máṣe tẹ̀ ẹ́ rì. Èyí rán wa létí àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ ìgbà àtijọ́ bíi Jobu, Dafidi, àti Jeremiah, àwọn tí ọ̀rọ̀ ẹ̀dùn-ọkàn wọn wà nínú Bibeli. Wọn kò dí ìmọ̀lára wọn pa. Nítorí náà, kò bá ọgbọ́n mu láti ya araàrẹ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn. (Owe 18:1) Nítòótọ́, ṣíṣọ̀fọ̀ ní a ń fihàn ní onírúurú ọ̀nà ní onírúurú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, ó tún sinmilé àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn tí ó gbalẹ̀.a

Ká ní ó ṣe ọ bíi pé kí o sọkún ńkọ́? Ó jẹ́ apákan ìwà ẹ̀dá láti sọkún. Tún rántí àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ ikú Lasaru, nígbà tí Jesu “kérora ní ọkàn rẹ̀ . . . Jesu [sì] sọkún.” (Johannu 11:33, 35) Ó fihàn nígbà náà pé sísọkún jẹ́ ìhùwàpadà bíbójúmu sí ikú olólùfẹ́ kan.

Àwọn èèyàn tó ń sunkún

Ó bójúmu láti kẹ́dùn àti láti sọkún nígbà tí olólùfẹ́ kan bá kú

Èyí ni ọ̀ràn ìyá kan, Anne, tì lẹ́yìn, ẹni tí ó ti pàdánù Rachel ọmọ rẹ̀ nítorí SIDS (Àkópọ̀ Àmì Àrùn Ikú Òjijì Ọmọdé Jòjòló). Ọkọ rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ohun kan tí ó yanilẹ́nu ni pé èmi àti Anne kò ké níbi ìsìnkú náà. Gbogbo àwọn yòókù ní ó sọkún.” Anne dáhùnpadà sí èyí pé: “Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n mo tí sún ẹkún lọ́pọ̀lọpọ̀ fún àwa méjèèjì. Mo gbàgbọ́ pé ó dùn mi wọra ní àwọn ọ̀sẹ̀ mélòókan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbanínújẹ́ náà, nígbà tí ó ku èmi nìkan sílé ní ọjọ́ kan. Mo sọkún ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà. Ṣùgbọ́n mo gbàgbọ́ pé ó ṣèrànwọ́. Ó mú ara mi yágágá síi. Mo níláti ṣọ̀fọ̀ òfò ọmọ mi. Mo gbàgbọ́ níti gidi pé ó yẹ kí a fi àwọn tí ń kẹ́dùn sílẹ̀ láti sọkún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ ìhùwàpadà tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu fún àwọn ẹlòmíràn láti sọ pé, ‘Má sọkún mọ́,’ ìyẹn kò ṣèrànlọ́wọ́ níti gidi.”

Bí Àwọn kan Ṣe Ń Hùwàpadà

Báwo ni àwọn kan ti ṣe hùwàpadà nígbà tí ìbànújẹ́ bá bá wọ́n gidigidi nítorí òfò olólùfẹ́ kan? Fún àpẹẹrẹ, gbé Juanita yẹ̀wò. Ó mọ bí ṣíṣòfò ọmọ ṣe ń rí lára. Ìgbà márùn-⁠ún ni oyún tí ṣẹ́ lára rẹ̀. Nísinsìnyí ó tún ti lóyún. Nítorí náà nígbà tí ìjàm̀bá mọ́tò mú kí ó di dandan láti gbé e lọ sí ilé-ìwòsàn, ìdààmú rẹ̀ yéni. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, obí tẹ̀ ẹ́​—láìpóṣù. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ó bí Vanessa kóńkóló​—tí ó fi díẹ̀ tẹ̀wọ̀n ju 0.9 kìlógírámù. “Ayọ̀ mí kún,” ni Juanita rántí. “Mo di ìyá ọlọ́mọ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín!”

Ṣùgbọ́n ayọ̀ rẹ̀ kò pẹ́. Ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn náà Vanessa kú. Juanita rántí pé: “Mo nímọ̀lára pé tèmi ti tán pátápátá. Ipò jíjẹ́ tí mo jẹ́ abiyamọ ni a ti gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Mo nímọ̀lára pé mo ṣàṣetì. Ó ro mí lára láti wá sílé sí iyàrá tí a ti pèsè sílẹ̀ fún Vanessa kí ń sì wo àwọn ẹ̀wù péńpé tí mo ti rà fún un. Fún àwọn oṣù bíi mélòókan tí ó tẹ̀lé e, mo ń ronú ṣáá lórí ọjọ́ ìbí rẹ̀. N kò fẹ́ láti ṣe ohunkóhun pẹ̀lú ẹnikẹ́ni.”

Ìhùwàpadà aláṣerégèé ha ni bí? Ó lè nira fún àwọn ẹlòmíràn láti lóye, ṣùgbọ́n àwọn bíi Juanita, tí wọ́n ti faragbá a ṣàlàyé pé wọ́n ní ẹ̀dún-ọkàn fún ọmọ-ọwọ́ wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí wọn yóò ti ṣe fún ẹni tí ó ti gbáyé fún ìgbà díẹ̀. Wọ́n sọ pé tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí a tó bí ọmọ kan, ni àwọn òbí rẹ̀ ti fẹ́ràn rẹ̀. Ìdè àrà-ọ̀tọ̀ kan wà pẹ̀lú ìyá náà. Nígbà tí ọmọ-ọwọ́ náà bá kú, ìyá náà nímọ̀lára pé òun ti pàdánù ẹni gidi kan. Ohun tí àwọn mìíràn sì níláti lóye nìyẹn.

Bí Ìbínú àti Ẹ̀bi Ṣe Lè Nípalórí Rẹ

Ìyá mìíràn sọ ìmọ̀lára rẹ̀ jáde nígbà tí a sọ fún un pé ọmọkùnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́fà ti kú lójijì nítorí ìṣòro ọkàn-àyà tí ó ti ní láti ìgbà tí wọ́n ti bí i. “Oríṣiríṣi ọ̀nà ni mo fi hùwàpadà​—⁠iyè ríra, àìgbàgbọ́, ẹ̀bi, àti ìfìbínúhàn sí ọkọ mi àti dókítà náà fún kíkùnà láti mọ bi ipò rẹ̀ ti le koko tó.”

Ìbínú lè jẹ́ àmì mìíràn fún ẹ̀dùn-ọkàn. Ó lè jẹ́ bíbínú sí àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì, ní ríronú pé ó yẹ kí wọ́n tí ṣe púpọ̀ síi ní bíbójútó ẹni tí ó di aláìsí náà. Tàbí ó lè jẹ́ bíbínú sí àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn mọ̀lẹ́bí tí, ó lè dàbí ẹni pé wọ́n sọ tàbí ṣe ohun tí ó lòdì. Àwọn mìíràn máa ń bínú sí olóògbé náà fún ṣíṣàìbìkítà nípa ìlera rẹ̀. Stella rántí pé: “Mo rántí bíbínú sí ọkọ mi nítorí mo mọ̀ pé nǹkan ìbá ti yàtọ̀. Ó ti ń ṣàìsàn gidigidi, ṣùgbọ́n ó kọ etíikún sí àwọn ìkìlọ̀ dókítà.” Ní àwọn ìgbà mìíràn kẹ̀ a ń fi ìbínú hàn sí ẹni tí ó di olóògbé náà nítorí ìnira tí ikú rẹ̀ yóò mú wa sórí àwọn aláṣẹ̀yìndè.

Àwọn kan nímọ̀lára ẹ̀bi nítorí ìbínú​—⁠ìyẹn ni pé, wọ́n lè dá araawọn lẹ́bi nítorí tí inú bí wọn. Àwọn mìíràn ń dẹ́bi fún araawọn fún ikú olólùfẹ́ wọn. “Òun ìbá má ti kú, kí a sọ pé mo ti tètè jẹ́ kí ó rí dókítà” tàbí “kí ń ti jẹ́ kí ó rí dókítà mìíràn” tàbí “kí ń ti rí síi pé ó bìkítà dáradára nípa ìlera rẹ̀,” ni àwọn kan máa ń mú un dá araawọn lójú.

Ìyá kan ń rántí bó ṣe gbé ọmọ rẹ̀ mọ́ra

Òfò ọmọ kan jẹ́ ìdààmú ńláǹlà​—ojúlówó ìbánikẹ́dùn àti ẹ̀mí ìfọ̀rànrora-ẹni-wò lè ran àwọn òbí náà lọ́wọ́

Fún àwọn mìíràn ẹ̀bi náà lọ jìnnà ju bẹ́yẹn lọ, pàápàá bí ẹni tí wọ́n fẹ́ràn bá kú lójijì, láìròtẹ́lẹ̀. Wọn a wá bẹ̀rẹ̀síí rántí iye ìgbà tí wọ́n ti bínú sí olóògbé náà tàbí iye ìgbà tí wọ́n ti bá a ṣawuyewuye. Tàbí wọ́n lè ronú pé wọn kò jẹ́ gbogbo ohun tí ó yẹ kí wọ́n jẹ́ sí aláìsí náà.

Bí ọ̀nà ìgbà kẹ́dùn àwọn ìyá kan ti máa ń pẹ́ tó ṣètìlẹyìn fún ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ògbógi sọ pé òfò ọmọ kan máa ń fa àlàfo tí ó wà títílọ nínú ìgbésí-ayé àwọn òbí, ní pàtàkì ìyá náà.

Nígbà Tí O Bá Ṣòfò Alábàáṣègbéyàwó

Òfò ẹnìkejì ẹni nínú ìgbéyàwó jẹ́ irú ohun adaniláàmú mìíràn, pàápàá bí àwọn méjèèjì bá ti jọ gbé ìgbésí-ayé wọléwọ̀de. Ó lè túmọ̀sí òpin àṣà ìgbésí-ayé kan tí wọ́n ti jọ ṣàjọpín, ìrìn-àjò, iṣẹ́, eré-ìnàjú, àti ìgbáralé ẹnìkínní kejì.

Eunice ṣàlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àìsàn àìṣiṣẹ́ déédéé ọkàn-àyà mú ọkọ rẹ̀ lọ lójijì. “Fún ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́, iyè mi parẹ́ mọ́ mi nínú, bí ẹni pé mo ti dòkú. N kò tilẹ̀ lè mọ adùn nǹkan tàbí gbọ́ òórùn. Síbẹ̀, agbára ìrònú mi ń dánìkan ṣíṣẹ lọ. Nítorí tí mo wà pẹ̀lú ọkọ mi nígbà tí wọ́n ń gbìyànjú láti mú un lókun nípa lílo CPR (ọ̀nà ìgbàmú ẹ̀dọ̀fóró àti ọkàn-àyà padà ṣiṣẹ́) àti àwọn oògùn, n kò nírìírí àwọn àmì aláìbáradé ti sísẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí ó ti sábà máa ń rí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo ní ìmọ̀lára ìjákulẹ̀ ńláǹlà, bí ẹni pé mo ń wo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí ń wọ kòtò lọ tí kò sì sí ohun tí mo lè ṣe nípa rẹ̀.”

Ó ha sọkún bí? “Mo ṣe bẹ́ẹ̀ níti gidi, pàápàá nígbà tí mo ka ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn káàdì ìbánikẹ́dùn tí mo rí gbà. Mo sọkún lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó ràn mi lọ́wọ́ láti kojú ìyókù ọjọ́ náà. Ṣùgbọ́n kò sí ohun tí ó ṣèrànwọ́ nígbà tí a bi mí léraléra nípa bí ìmọ̀lára mi ṣe rí. Ní kedere, ìdààmú ọkàn bá mi.”

Kí ni ó ran Eunice lọ́wọ́ láti la ẹ̀dùn-ọkàn rẹ̀ já? “Láìmọ̀, mo pinnu láìpète láti máa bá ìgbésí-ayé mi lọ,” ni òun sọ. “Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí ń dùn mí jùlọ ni nígbà tí mo bá rántí pé ọkọ mi, tí ó fẹ́ràn ìwàláàyè lọ́pọ̀lọpọ̀, kò sí níhìn-⁠ín láti gbádùn rẹ̀.”

“Máṣe Jẹ́ Kí Àwọn Ẹlòmíràn Pinnu fún Ọ . . .”

Òǹkọ̀wé ìwé náà Leavetaking​—When and How to Say Goodbye gbani nímọ̀ràn pé: “Máṣe jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn pinnu bí o ṣe níláti hùwà tàbí nímọ̀lára fún ọ. Ọ̀nà ìgbà fi ẹ̀dùn-ọkàn hàn ń ṣiṣẹ́ ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pẹ̀lú ẹnìkọ̀ọ̀kan. Àwọn mìíràn lè ronú​—⁠kí wọn sì mú kí o mọ̀ pé wọ́n ronú​—pé o ń kẹ́dùn ju bí ó ti yẹ lọ tàbí pé ó kò kẹ́dùn tó. Dáríjì wọ́n kí o sì gbàgbé nípa rẹ̀. Nípa gbígbìyànjú láti fi ipá mú araàrẹ wá sínú ipò tí àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹgbẹ́ àwùjọ lápapọ̀ gbékalẹ̀, o ń dí ìdàgbàsókè rẹ sí ìhà ìlera èrò-ìmọ̀lára jíjípépé lọ́wọ́.”

Níti tòótọ́, àwọn ènìyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń bójútó ẹ̀dùn-ọkàn wọn ní àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. A kò gbìyànjú láti dábàá fún gbogbo ènìyàn pé ọ̀nà kan fi dandan dára ju òmíràn. Bí ó ti wù kí ó rí, ewu máa ń dìde nígbà tí ìpòkúdu-ọkàn bá wáyé, nígbà tí ẹni tí ẹ̀dùn-ọkàn kọlù kò bá lè ṣàtúnṣe sí bí nǹkan ti rí. Nígbà náà ìrànlọ́wọ́ ni a lè nílò láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ oníyọ̀ọ́nú. Bibeli sọ pé: “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n arákùnrin ni a bí fún ìgbà ìpọ́njú.” Nítorí náà máṣe bẹ̀rù láti wá ìrànlọ́wọ́, láti sọ̀rọ̀, àti láti sọkún.​—Owe 17:17.

Ẹ̀dùn-ọkàn jẹ́ ìhùwàpadà bíbójúmu sí òfò, kò sì lòdì fún ẹ̀dùn-ọkàn rẹ láti di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n àwọn ìbéèrè síwájú síi ń fẹ́ àwọn ìdáhùn: ‘Báwo ni mo ṣe lè gbé pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn mi? Ó ha bójúmu láti nírìírí ìmọ̀lára ẹ̀bi àti ìbínú bí? Báwo ni mo ṣe níláti kojú àwọn ìhùwàpadà wọ̀nyí? Kí ni ó lè ràn mí lọ́wọ́ láti foríti òfò àti ẹ̀dùn-ọkàn náà?’ Ẹ̀ka tí ó tẹ̀lé e yóò dáhùn ìwọ̀nyí àti àwọn ìbéèrè mìíràn.

a Fún àpẹẹrẹ, àwọn Yorùbá ní Nigeria ní ìgbàgbọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ nínú àtúnwáyé ọkàn. Nítorí náà nígbà tí ìyá kan bá ṣòfò ọmọ, yóò ní ẹ̀dùn-ọkàn jíjinlẹ̀ ṣùgbọ́n kìkì fún sáà kúkúrú kan, nítorí gẹ́gẹ́ bí ègbè-orin Yorùbá kan ti wí: “Omi ló dànù. Agbè kò fọ́.” Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn Yoruba, èyí túmọ̀sí pé agbè tí ó gba omi ró, ìyá náà, lè bí ọmọ mìíràn​—bóyá àtúnwáyé ẹni náà tí ó kú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kìí tẹ̀lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ èyíkéyìí tí a gbékarí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí ó wá láti inú èrò èké nípa àìlèkú ọkàn àti àtúnwáyé, èyí tí kò ní ìpìlẹ̀ nínú Bibeli.​—Oniwasu 9:​5, 10; Esekieli 18:​4, 20.

Àwọn Ìbéèrè Láti Ronú Lé Lórí

  • Báwo ni àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn kan ṣe ń nípalórí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kẹ́dùn?

  • Àwọn àpẹẹrẹ wo ni a ní nínú Bibeli níti àwọn wọnnì tí wọ́n fi ẹ̀dùn-ọkàn wọn hàn ní gbangba?

  • Báwo ni àwọn kan ti ṣe hùwàpadà sí òfò olólùfẹ́ kan? Báwo ni ìwọ ti ṣe hùwàpadà nínú àwọn ipò jíjọra kan náà?

  • Kí ni ó mú kí òfò alábàáṣègbéyàwó ẹni jẹ́ ìrírí tí ó yàtọ̀?

  • Báwo ni ọ̀nà ìgbà fi ẹ̀dùn-ọkàn hàn ṣe ń ṣiṣẹ́? Ó ha lòdì láti kẹ́dùn bí?

  • Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀ka ọ̀nà ìgbà fi ẹ̀dùn-ọkàn hàn? (Wo àpótí ní ojú-ìwé 9.)

  • Àwọn ipò àrà-ọ̀tọ̀ wo ni ó máa ń nípalórí àwọn òbí nínú ọ̀ràn ikú òjijì ọmọdé jòjòló? (Wo àpótí ní ojú-ìwé 12.)

  • Báwo ni ìṣẹ́nú tàbí bíbí ọmọ lókùú tí ṣe nípalórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyá? (Wo àpótí ní ojú-ìwé 10.)

Ọ̀nà Ìgbà Kẹ́dùn

Ọ̀rọ̀ náà “ọ̀nà ìgbà” kò dọ́gbọ́n túmọ̀sí pé ẹ̀dùn-ọkàn ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tàbí ètò èyíkéyìí tí ó fìdí múlẹ̀. Àwọn ìhùwàpadà sí ẹ̀dùn-ọkàn lè ga gègèrè kí ó sì gba àkókò gígùn yíyàtọ̀ síra, ní sísinmi lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Àkọsílẹ̀ yìí kò pé tán. Àwọn ìhùwàpadà mìíràn ni a tún lè fihàn. Àwọn ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àmì ẹ̀dùn-ọkàn tí ẹnìkan lè nírìírí rẹ̀.

Àwọn ìhùwàpadà ní ìbẹ̀rẹ̀: Ìgbọ̀nrìrì àkọ́kọ́; àìgbàgbọ́, sísẹ́; iyè píparẹ́ mọ́ni nínú; ìmọ̀lára ẹ̀bi; ìbínú.

Ẹ̀dùn-Ọkàn lílekoko lè ní nínú: Àìrántí nǹkankan mọ́ àti àìróorunsùn; àárẹ̀ lílégbákan; ìhùwàsí yíyípadà lójijì; àṣìṣe nínú ìdájọ́ àti ìrònú; ẹkún àsun-dàábọ̀; ìyípadà nínú ìfẹ́-ọkàn sí oúnjẹ, tí ń yọrísí títóbi si tàbí fífọn; onírúurú àwọn àmì ìlera tí a ti dabarú; àìnímìí nínú; agbára àtiṣiṣẹ́ tí ó dínkù; ṣíṣèràn-⁠àn-rán​—nínímọ̀lára, gbígbọ́ ohùn, rírí olóògbé náà; nínú òfò ọmọ kan, ìfìbínúhàn láìnídìí sí alábàáṣègbéyàwó rẹ.

Àkókò ìwàdéédéé: Ìbànújẹ́ àti àárò; ìrántí ẹni tí ó di aláìsí náà lọ́nà gbígbádùnmọ́ni, kódà tí a fi ẹ̀rín kún un.

Ìṣẹ́nú àti Bíbí Ọmọ Lókùú​—Ẹ̀dùn-Ọkàn Àwọn Ìyá

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn ọmọ mìíràn, Monna fi pẹ̀lú ìháragàgà wọ̀nà fún ìbí ọmọ rẹ̀ tí ó tẹ̀lé e. Kódà ṣáájú ìbí rẹ̀ pàápàá, ó jẹ́ ọmọ tí ó ń “bá ṣeré, bá sọ̀rọ̀, tí ó sì ń lálàá nípa rẹ̀.”

Ìdè tí ó wà títí lọ lọ́nà àdánidá láàárín ìyá àti ọmọ tí a kò tíì bí lágbára gan-an ni. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Rachel Anne jẹ́ ọmọ tí ó máa ń ti ìwé kúrò lórí ikùn mi, ó máa ń jí mi kalẹ̀ ní òru. Mo ṣì lè rántí àwọn ìtamínípàá jẹ́jẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́, bí ìfọwọ́tọ́ni jẹ́jẹ́ lọ́nà onífẹ̀ẹ́. Ní gbogbo ìgbà tí ó bá mira, mo máa ń kún fún irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ púpọ̀púpọ̀. Mo mọ̀ ọ́ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí mo fi mọ ìgbà tí ó wà nínú ìrora, nígbà tí araarẹ̀ kò dá.”

Monna ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Dókítà kò gbà mi gbọ́ títí di ìgbà tí nǹkan tí bọ́sórí. Ó sọ fún mi pé kí ń má dààmú mọ́. Mo gbàgbọ́ pé mo nímọ̀lára pé ó ti kú. Ó ṣàdédé yírapadà lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀. Ní ọjọ́ kejì ó ti kú.”

Ìrírí Monna kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí kò wọ́pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn òǹkọ̀wé náà Friedman àti Gradstein ti sọ nínú ìwé wọn Surviving Pregnancy Loss, nǹkan bí million kan àwọn obìnrin lọ́dún ní United States nìkanṣoṣo ní wọ́n ń jìyà oyún tí ó bàjẹ́. Níti tòótọ́, iye náà jákèjádò ayé fi púpọ̀ púpọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn ènìyàn sábà máa ń kùnà láti mọ̀ pé ìṣẹ́nú tàbí bíbí ọmọ lókùú jẹ́ ìbànújẹ́ fún obìnrin kan ó sì jẹ́ ọ̀kan tí ó máa ń rántí​—⁠bóyá ní gbogbo ìgbésí-ayé rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Veronica, tí ó ti dàgbà dáadáa nísinsìnyí, rántí àwọn ìṣẹ́nú rẹ̀ àti ní pàtàkì ó rántí ọmọ tí ó bí lókùú tí ó ṣì wàláàyè títí di oṣù kẹ́sàn-án nínú oyún tí ó sì bí i ní wíwọn ìwọ̀n kìlógírámù mẹ́fà. Ó gbé e sínú lókùú fún ọ̀sẹ̀ méjì tí ó kẹ́yìn. Ó sọ pé: “Láti bí òkú ọmọ jẹ́ ohun búburú gbáà fún ìyá kan.

Ìhùwàpadà àwọn ìyá wọ̀nyí tí wọ́n ní ìjákulẹ̀ ni àwọn obìnrin mìíràn pàápàá kìí sábà lóye. Oníṣègùn ọpọlọ kan tí ó pàdánù ọmọ rẹ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́nú kọ̀wé pé: “Ohun tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́nà lílekoko ni pé ṣáájú kí èyí tó ṣẹlẹ̀ sí mi, n kò ni èrò kankan níti gidi níti ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ mi ti níláti faradà. Mo ti jẹ́ ọ̀dájú àti aláìmòye sí wọn gẹ́gẹ́ bí mo ti rò pé àwọn ènìyàn jẹ́ sí mi báyìí.”

Tọkọtaya kan gbá ara wọn mọ́ra bí wọ́n ṣe ń sunkún

Ìṣòro mìíràn fún ìyá tí ń kẹ́dùn ni ìmọ̀lára náà pé ọkọ rẹ̀ lè má mọ òfò náà lára bí òun ti ṣe. Aya kan sọ ọ lọ́nà yìí pé: “Ọkọ mi já mi kulẹ̀ gidi gan-an ni ní àkókò yẹn. Níbi tí ó yé e mọ ní tirẹ̀, oyún kò fìgbàkan sí ni. Kò mọ ẹ̀dùn-ọkàn tí mo ń faragbá. Òun jẹ́ alábàákẹ́dùn fún àwọn ìbẹ̀rù tí mo ní ṣùgbọ́n kìí ṣe fún ẹ̀dùn-ọkàn tí mo ní.”

Ó ṣeéṣe kí ìhùwàpadà yìí jẹ́ ìwà ẹ̀dá ọkọ kan​—⁠òun kò nírìírí ìdè kan náà níti èrò-ìmọ̀lára àti ti ara èyí tí aya rẹ̀ tí ó lóyún ní. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, òun jìyà òfò kan. Ó sì ṣe pàtàkì pé kí ọkọ àti aya mọ̀ pé wọ́n jọ ń jìyà papọ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ni àwọn ọ̀nà tí ó yàtọ̀. Wọ́n níláti ṣàjọpín ẹ̀dùn-ọkàn wọn. Bí ọkọ bá fi tirẹ̀ pamọ́, aya rẹ̀ lè rò pé ó jẹ́ ọ̀dájú. Nítorí náà ẹ jọ ṣàjọpín omije, èrò yín, kí ẹ sì gbárayínmọ́ra. Ẹ fihàn pé ẹ nílò araayín lẹ́nìkínní kejì ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Bẹ́ẹ̀ni ẹ̀yin ọkọ, ẹ fi ìbákẹ́dùn yín hàn.

Àkópọ̀ Àmì Àrùn Ikú Òjijì Ọmọdé Jòjòló​—Dídojúkọ Ẹ̀dùn-Ọkàn Náà

Ikú òjijì ọmọ-ọwọ́ jẹ́ ìbànújẹ́ ńláǹlà. Ní ọjọ́ kan ọmọ-ọwọ́ kan tí ó jọ pé ara rẹ̀ le dáradára, kò jí mọ́ lójú orun. A kò retí èyí rárá, àbí ta ni jẹ́ ronú pé ọmọdé jòjòló kan tàbí ọmọ kan yóò kú ṣáájú àwọn òbí rẹ̀? Ọmọ-ọwọ́ kan tí ó ti di orísun ìfẹ́ aláìláàlà fún ìyá kan lójijì wá di orísun ẹ̀dùn-ọkàn aláìláàlà rẹ̀.

Àwọn ìmọ̀lára ẹ̀bi bẹ̀rẹ̀síí rọ́ wọlé. Àwọn òbí lè nímọ̀lára pé àwọn ní ó fa ikú náà, bí ẹni pé àwọn àìbìkítà kan níhà ọ̀dọ̀ wọn ni ó fà á. Wọ́n bi araawọn léèrè pé, ‘Kí ni à bá ti ṣe láti dènà èyí?’b Nínú àwọn ọ̀ràn kan ọkọ náà, láìní àwọn ìdí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀, lè máa dá aya rẹ̀ lẹ́bi láìmọ̀. Nígbà tí ó lọ sí ibi iṣẹ́, ọmọ náà wàláàyè ara rẹ̀ sì le. Nígbà tí ó padà délé, ó ti kú lórí ibùsùn rẹ̀ kékeré! Kí ni aya rẹ̀ ń ṣe? Ibo ni ó wà ní àkókò yẹn? Àwọn ìbéèrè ajónilára wọ̀nyí ní a níláti yanjú kí wọn má baà fi ìgbéyàwó náà sínú ewu.

Èèṣì àti àwọn ìpò tí a kò retí ni ó fa ìbànújẹ́ náà. Bibeli sọ pé: “Mo padà, mo sì rí lábẹ́ oòrùn pé iré-ìje kìí ṣe ti ẹni tí ó yára, bẹ́ẹ̀ ni ogun kìí ṣe ti alágbára, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kìí ṣe ti ọlọ́gbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kìí ṣe ti ẹni òye, bẹ́ẹ̀ ni ojúrere kìí ṣe ti ọlọ́gbọ́n-⁠inú; ṣùgbọ́n ìgbà àti [èèṣì] ń ṣe sí gbogbo wọn.”​—Oniwasu 9:11.

Báwo ni àwọn ẹlòmíràn ṣe lè ṣèrànwọ́ nígbà tí ìdílé kan bá ṣòfò ọmọ-ọwọ́ kan? Ìyá kan tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ dáhùnpadà pé: “Ọ̀rẹ́ kan wá ó sì pa ilé mi mọ́ tónítóní láìjẹ́ pé mo sọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan. Àwọn mìíràn se oúnjẹ fún wa. Àwọn mìíràn wulẹ̀ ṣèrànlọ́wọ́ nípa rírọ̀ mọ́ mi lọ́rùn​—⁠wọn kò sọ̀rọ̀, wọ́n wulẹ̀ rọ̀ mọ́ mi lọ́rùn. Èmi kò fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Èmi kò fẹ́ láti máa sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àsọtúnsọ. Èmi kò fẹ́ àwọn ìbéèrè ìtọpinpin, bí ẹni pè mo ti kùnà láti ṣe ohun kan. Ìyá rẹ̀ ni mo jẹ́; ǹ bá ti ṣe gbogbo ohun ti mo lè ṣe láti gba ọmọ mi là.”

b Àkópọ̀ Àmì Àrùn Ikú Òjijì Ọmọdé Jòjòló (SIDS), tí ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ-ọwọ́ tí wọ́n wà láàárín oṣù kan sí mẹ́fà, ni èdè-ọ̀rọ̀ náà tí a ń lò nígbà tí àwọn ọmọ-ọwọ́ ti ara wọn le bá ṣàdédé kú láìsí okùnfà èyíkéyìí tí ó ṣeé ṣàlàyé. Nínú àwọn ọ̀ràn kan a gbàgbọ́ pé ṣíṣeéṣe náà ni a lè yẹ̀ sílẹ̀ bí a bá jẹ́ kí ọmọ-ọwọ́ náà dẹ̀yìn délẹ̀ tàbí fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ sùn ṣùgbọ́n kí ó máṣe danú délẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí ipò sísùn tí yóò dènà gbogbo ọ̀ràn SIDS.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́