ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 16 ojú ìwé 135-ojú ìwé 138 ìpínrọ̀ 5
  • Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbàlẹ̀ Ọkàn
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Tó Dáńgájíá?
    Jí!—2004
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìtara
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Wíwo Ojú Àwùjọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 16 ojú ìwé 135-ojú ìwé 138 ìpínrọ̀ 5

Ẹ̀KỌ́ 16

Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o dúró jẹ́jẹ́, kí o rìn jẹ́jẹ́, kí o sì sọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ lọ́nà tó ń buyì kúnni tí yóò fi hàn pé ọkàn rẹ balẹ̀.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Bí ọkàn rẹ bá balẹ̀, yóò túbọ̀ ṣeé ṣe kí àwọn olùgbọ́ rẹ pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ò ń sọ dípò kí wọ́n máa ronú nípa ìwọ fúnra rẹ.

KÌ Í ṣe ohun tuntun pé kí ẹ̀rù ba olùbánisọ̀rọ̀ nígbà tó bá fẹ́ sọ̀rọ̀, pàápàá tó bá jẹ́ ẹni tí kì í sábàá ní iṣẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ. Ẹ̀rù lè ba akéde kan nígbà tó bá kọ́kọ́ ya àwọn ilé mélòó kan bó ṣe jáde òde ẹ̀rí. Nígbà tí Ọlọ́run yan Jeremáyà láti jẹ́ wòlíì, Jeremáyà dáhùn pé: “Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.” (Jer. 1:5, 6) Jèhófà ran Jeremáyà lọ́wọ́, yóò sì ran ìwọ pẹ̀lú lọ́wọ́. Bí àkókò ti ń lọ, wàá lè di ẹni tí ọkàn rẹ̀ máa ń balẹ̀.

Olùbánisọ̀rọ̀ tí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ kì í bẹ̀rù. Ìdúró onítọ̀hún á fi hàn pé ọkàn rẹ̀ balẹ̀. Yóò dúró bí ó ṣe máa ń dúró nígbà gbogbo, lọ́nà tó bá ohun tó ń ṣẹlẹ̀ mu. Kò kàn ní máa ju ọwọ́ láìnídìí. Ohùn rẹ yóò ṣe ketekete, yóò sì dùn-ún gbọ́ létí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè rò pé ọkàn rẹ kì í balẹ̀ bíi ti irú ẹni tí ibí yìí ń ṣàpèjúwe, o ṣì lè ṣàtúnṣe. Lọ́nà wo? Jẹ́ ká gbé ìdí tí olùbánisọ̀rọ̀ kan fi lè máa bẹ̀rù tí ọkàn rẹ̀ kò sì ní balẹ̀ yẹ̀ wò. Ó lè jẹ́ ìṣesí ara ló fà á.

Nígbà tí o bá dojú kọ ohun kan tí o fẹ́ ṣe tí o sì fẹ́ ṣe dáadáa nínú nǹkan ọ̀hún ṣùgbọ́n tí kò dá ọ lójú pé wàá lè ṣe dáadáa, àyà rẹ á máa já. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ọpọlọ á mú kí ara rẹ túbọ̀ pèsè omi inú ara tó máa ń mú kí àwọn ẹ̀ya ara ṣiṣẹ́ lákọlákọ. Ìpèsè omi inú ara yìí lè mú kí ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí yára lù kìkì, kí ó mú kí bí èèyàn ṣe ń mí yí padà, kí èèyàn máa làágùn lákọlákọ, ó sì lè mú kí ọwọ́ àti orúnkún ẹni máa gbọ̀n kí ohùn ẹni sì máa gbọ̀n pẹ̀lú. Ńṣe ni ara rẹ ń gbìyànjú láti mú kí agbára rẹ pọ̀ sí i láti lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ipò tí o wà. Ohun tó wà níbẹ̀ ni pé kí o mọ bí o ṣe lè lo agbára tó dé sí ọ lára yìí fún ríronú lọ́nà tí yóò ṣàǹfààní àti láti fi máa sọ̀rọ̀ tìtaratìtara.

Bí O Ṣe Lè Dín Àyà Jíjá Kù. Rántí pé kò sóhun tó burú nínú pé kí àyà ẹni já díẹ̀. Ṣùgbọ́n, kí ọkàn rẹ lè balẹ̀, o gbọ́dọ̀ mú àyà rẹ tó ń já yìí wálẹ̀ kí o sì fi pẹ̀lẹ́tù bójú tó ọ̀ràn rẹ lọ́nà tó wuyì. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Múra sílẹ̀ dáadáa. Wá àyè dáadáa láti múra ọ̀rọ̀ rẹ. Rí i dájú pé kókó ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ yé ọ yékéyéké. Bí ọ̀rọ̀ tó o máa sọ bá jẹ́ èyí tó o máa ṣa àwọn kókó rẹ̀ jọ ni, ronú nípa ohun tí àwọn olùgbọ́ rẹ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa kókó ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ àti ohun tí o fẹ́ kí wọ́n ṣe. Èyí yóò jẹ́ kí o lè múra ọ̀rọ̀ tó dára jù lọ. Bí ìyẹn bá kọ́kọ́ ṣòro fún ọ láti ṣe, bá olùbánisọ̀rọ̀ tó nírìírí jíròrò nípa ìṣòro rẹ. Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àyẹ̀wò tó gbéṣẹ́ nípa ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ àti àwọn olùgbọ́ rẹ. Bí ó bá ti dá ọ lójú pé ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ yóò ṣe àwọn olùgbọ́ rẹ láǹfààní, tí ọ̀rọ̀ ọ̀hún sì yé ọ dáadáa, fífẹ́ tí o fẹ́ láti sọ ọ́ fún àwọn olùgbọ́ rẹ yóò borí ohunkóhun tó lè fa àyà jíjá nípa bí wàá ṣe sọ ọ́.

Fún ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ ní àfiyèsí àkànṣe. Mọ bí wàá ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. Bí o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó dájú pé bí àyà rẹ ṣe ń já yóò dín kù.

Ohun kan náà yìí lo ní láti ṣe bí o bá ń múra fún òde ẹ̀rí. Kì í ṣe kókó ọ̀rọ̀ tí o múra sílẹ̀ láti jíròrò nìkan ni kí o gbé yẹ̀ wò, ṣùgbọ́n tún ronú nípa irú àwọn èèyàn tó o máa wàásù fún. Fara balẹ̀ múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀. Kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí àwọn akéde tó dàgbà dénú.

O lè máa rò ó pé ọkàn rẹ yóò túbọ̀ balẹ̀ bó bá jẹ́ pé ńṣe lo ń ka ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ níwájú àwùjọ. Ní ti gidi, èyí lè mú kí o túbọ̀ máa jáyà ní gbogbo ìgbà tí o bá níṣẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ. Òótọ́ ni pé àkọsílẹ̀ àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan máa ń gùn púpọ̀, nígbà tó jẹ́ pé ti àwọn ẹlòmíràn á sì kúrú. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó o kọ sórí bébà ni yóò mú kí ohun tí ò ń rò yí padà kí àyà rẹ má sì fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ bí kò ṣe ìdánilójú tí o bá ní pé ohun tó o múra láti bá àwùjọ sọ jẹ́ ohun tó yẹ kí wọ́n gbọ́ lóòótọ́.

Fi ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ dánra wò, kí o sọ ọ́ síta. Irú ìdánrawò yìí ni yóò jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀ pé o lè sọ ohun tó ń bẹ lọ́kàn rẹ jáde. Bí o ti ń dánra wò, ọ̀rọ̀ yẹn á bẹ̀rẹ̀ sí wọ̀ ọ́ ní ọpọlọ tó fi jẹ́ pé nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ ọ̀hún, wàá kàn máa rántí ni. Nígbà tí o bá ń ṣe ìfidánrawò, jẹ́ kí ó dà bíi pé ṣe lo ti ń sọ̀rọ̀ ọ̀hún. Fojú inú wo àwọn olùgbọ́ rẹ. Jókòó sídìí tábìlì kan tàbí kí o dìde dúró, bí wàá ti ṣe nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ọ́ lọ́wọ́. Ṣé á dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀? “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòh. 5:14) Bí o bá fẹ́ láti bọlá fún Ọlọ́run kí o sì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó dájú pé òun yóò dáhùn àdúrà rẹ. Ìdánilójú yẹn lè fún ọ lókun gidigidi láti ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún ọ. Síwájú sí i, bí o ti ń fi èso ti ẹ̀mí kọ́ra, ìyẹn ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu, wàá dẹni tó mọ bí a ṣe ń fi ọkàn bíbalẹ̀ pẹ̀sẹ̀ bójú tó àwọn nǹkan.—Gál. 5:22, 23.

Di ẹni tó ní ìrírí. Bí o ti ń jáde òde ẹ̀rí tó, bẹ́ẹ̀ ni ìjayà rẹ yóò máa dín kù. Bí o bá sì ṣe ń dáhùn ní àwọn ìpàdé ìjọ tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe túbọ̀ máa rọrùn fún ọ láti sọ̀rọ̀ níwájú àwọn ẹlòmíràn. Bí iye ìgbà tí ò ń ṣe iṣẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ ní ìpàdé ìjọ bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni àyà rẹ tó ń já kí o tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yóò ṣe máa dín kù. Ṣé ó wù ọ́ pé kí o túbọ̀ lè máa láǹfààní láti sọ̀rọ̀? Ńṣe ni kí o máa yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣiṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ nígbà tí àwọn ẹlòmíràn kò bá lè wá ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún wọn.

Lẹ́yìn tí o bá ti ṣe àwọn ohun tí a sọ lókè yìí, wàá rí i pé ó ṣàǹfààní láti ṣàyẹ̀wò àwọn àmì tó ń fi hàn gbangba pé ọkàn rẹ kò balẹ̀. Mímọ àwọn àmì ọ̀hún àti kíkọ́ bí o ṣe lè borí wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀. Àwọn àmì ọ̀hún lè hàn nínú ìṣesí ara tàbí ti ohùn.

Àwọn Àmì Tó Ń Hàn Nínú Ìṣesí Ara. Bí ọkàn rẹ bá balẹ̀ tàbí bí kò bá balẹ̀, ìdúró rẹ àti bí o ṣe ń gbé ọwọ́ yóò fi hàn. Kọ́kọ́ ronú nípa ti ọwọ́ ná. Téèyàn bá káwọ́ sẹ́yìn, tó bá pa ọwọ́ mẹ́gbẹ̀ẹ́ pinpin, tàbí tó di tábìlì ìbánisọ̀rọ̀ mú pin-pin-pin; tó bá ń ki ọwọ́ bọ àpò léraléra, tó ń de bọ́tìnnì aṣọ tó ń tú u, tó ń fọwọ́ kan ẹ̀rẹ̀kẹ́, imú, tàbí awò ojú ṣáá; tó bá ń fọwọ́ pa aago ọwọ́, pẹ́ńsù, òrùka, tàbí ìwé; tó bá ń fara ṣàpèjúwe lódìlódì tàbí láàbọ̀láàbọ̀, gbogbo ìwọ̀nyí ń fi hàn pé ọkàn onítọ̀hún kò balẹ̀.

Sísún ẹsẹ̀ nílẹ̀ ṣáá, kéèyàn máa tẹ̀ ara síhìn-ín sọ́hùn-ún, dídúró gbágbáágbá, dídẹranù, pípọ́n ètè lá lóòrèkóòrè, gbígbé itọ́ mì léraléra, àti mímí lókèlókè tún lè fi hàn pé ọkàn onítọ̀hún kò balẹ̀.

Béèyàn bá sapá dáadáa, yóò lè borí gbogbo àmì àìbalẹ̀ ọkàn wọ̀nyí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ni kí o máa ṣiṣẹ́ lé wọn lórí. Mú èyí tó bá jẹ́ ìṣòro rẹ lára wọn kí o sì ronú ṣáájú nípa ohun tó yẹ kí o ṣe láti dènà rẹ̀. Bí o bá sapá lọ́nà yẹn, ìdúró rẹ yóò fi hàn pé ọkàn rẹ balẹ̀.

Àwọn Àmì Tó Jẹ Mọ́ Ohùn. Kí ohùn máa há tàbí kí ohùn máa gbọ̀n lè jẹ́ ara ẹ̀rí pé àyà ẹni ń já. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe lo máa ń ha ọ̀nà ọ̀fun léraléra tàbí kí o máa yára sọ̀rọ̀ jù. Tó o bá ń sapá gidigidi láti máa tún ohùn rẹ ṣe wàá lè borí àwọn ìṣòro àti àṣà wọ̀nyí.

Bí àyà rẹ bá ń já, sinmẹ̀dọ̀ kí o sì mí kanlẹ̀ nígbà mélòó kan ṣáájú kí o tó gorí pèpéle. Gbìyànjú láti jẹ́ kí ara tù ọ́. Dípò ríronú nípa àyà rẹ tó ń já, pọkàn pọ̀ sórí ìdí tí o fi fẹ́ sọ ohun tí o ti múra sílẹ̀ fún àwọn olùgbọ́ rẹ. Ṣáájú kí o tó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, kọ́kọ́ wo ojú àwùjọ, wo ẹni tí ojú rẹ̀ fà ọ́ mọ́ra kí o sì rẹ́rìn-ín músẹ́. Rọra máa sọ̀rọ̀ nígbà tí o bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, lẹ́yìn náà kí o wá máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ ní pẹrẹu.

Ohun Tí O Lè Retí. Má ṣe ronú pé àyà rẹ kò ní máa já mọ́ rárá. Ọ̀pọ̀ olùbánisọ̀rọ̀ tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni àyà wọ́n ṣì máa ń já kó tó di pé wọ́n bọ́ síwájú àwùjọ. Ṣùgbọ́n, wọ́n ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè kápá ìjayà yẹn.

Bí o bá sapá tọkàntọkàn láti dènà àwọn àmì tó lè fi hàn sójú táyé pé àyà rẹ ń já, àwọn olùgbọ́ rẹ yóò kà ọ́ sí olùbánisọ̀rọ̀ tọ́kàn rẹ̀ balẹ̀. Àyà rẹ ṣì lè máa já o, ṣùgbọ́n ó lè má hàn sí wọn rárá.

Rántí pé omi inú ara tó ń mú kí àwọn ẹ̀ya ara ṣiṣẹ́ lákọlákọ tí ń fa àyà jíjá yìí tún máa ń mú kí agbára ẹni pọ̀ sí i. Lo ìyẹn láti fi sọ̀rọ̀ tìtaratìtara.

Kò yẹ kó ṣẹ̀ṣẹ̀ dìgbà tó o bá dórí pèpéle kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí fi nǹkan wọ̀nyí dánra wò. Nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ máa kọ́ bí èèyàn ṣe ń fọkàn balẹ̀ tó sì ń káwọ́ ara rẹ̀, àti béèyàn ṣe lè máa fi bí ọ̀ràn ṣe rí lára rẹ hàn bó ṣe yẹ. Bí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ gidigidi láti mú kí o ní ìbàlẹ̀ ọkàn nígbà tí o bá wà lórí pèpéle àti lóde ẹ̀rí, àwọn ibẹ̀ wọ̀nyẹn sì ni ìbàlẹ̀ ọkàn ti ṣe pàtàkì jù lọ.

BÍ O ṢE LÈ DI ẸNI TÍ ỌKÀN RẸ̀ MÁA Ń BALẸ̀

  • Múra sílẹ̀ dáadáa.

  • Sọ̀rọ̀ sókè nígbà tí o bá n fi ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ dánra wò.

  • “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà,” ìyẹn nípa gbígbàdúrà.—Sm. 55:22.

  • Máa lọ sí òde ẹ̀rí déédéé, máa dáhùn lóòrèkóòrè ní àwọn ìpàdé, kí o sì yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe àfikún iṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́.

  • Mọ àwọn àmì tó ń fi hàn pé ọkàn rẹ kò balẹ̀, kí o sì kọ́ bí o ṣe lè dènà tàbí kápá wọn.

ÌDÁNRAWÒ: Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún oṣù kan, sapá láti dáhùn ju ẹ̀ẹ̀kan lọ nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Kíyè sí i pé nígbà tó bá di pé ò ń dáhùn lẹ́ẹ̀kejì tàbí lẹ́ẹ̀kẹta nínú ìpàdé kan náà àyà rẹ kò ní fi bẹ́ẹ̀ já mọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́