ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 35 ojú ìwé 206-ojú ìwé 208 ìpínrọ̀ 4
  • Sísọ Àsọtúnsọ Láti Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sísọ Àsọtúnsọ Láti Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mú Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Ìparí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ṣíṣe Ìlapa Èrò
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 35 ojú ìwé 206-ojú ìwé 208 ìpínrọ̀ 4

Ẹ̀KỌ́ 35

Sísọ Àsọtúnsọ Láti Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o sọ kókó pàtàkì tí o fẹ́ kí àwọn olùgbọ́ rẹ rántí ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Yàtọ̀ sí pé àsọtúnsọ máa ń jẹ́ kí èèyàn rántí ọ̀rọ̀, a tún lè lo àsọtúnsọ láti fi gbé àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ọ̀rọ̀ yọ lọ́nà tó múná dóko kí wọ́n lè yé àwùjọ yékéyéké.

LÍLO àsọtúnsọ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí à ń gbà kọ́ni lọ́nà tó mọ́yán lórí. Bí a bá tún kókó pàtàkì kan sọ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, àwọn tó ń gbọ́ ọ kì í sábà gbàgbé. Tí a bá tún gba onírúurú ọ̀nà tún kókó yẹn sọ, ó lè túbọ̀ yé wọn kedere sí i.

Bí àwọn olùgbọ́ rẹ kò bá rántí ohun tí o sọ, ọ̀rọ̀ rẹ kò ní nípa lórí ìgbàgbọ́ wọn tàbí bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn. Àwọn kókó tó o tẹnu mọ́ dáadáa ló ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú lé lórí.

Jèhófà, Olùkọ́ni Atóbilọ́lá tó ń kọ́ wa, fi àpẹẹrẹ bí a ṣe ń lo àsọtúnsọ lélẹ̀ fún wa. Ó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní Òfin Mẹ́wàá. Ó kọ́kọ́ lo áńgẹ́lì agbọ̀rọ̀sọ láti sọ àwọn òfin yẹn fún wọn lórí Òkè Sínáì. Lẹ́yìn náà, ó tún kọ àwọn òfin yẹn, ó sì fi wọ́n lé Mósè lọ́wọ́. (Ẹ́kís. 20:1-17; 31:18; Diu. 5:22) Jèhófà darí Mósè láti tún àwọn òfin yẹn sọ fún orílẹ̀-èdè yẹn kí wọ́n tó wọnú Ilẹ̀ Ìlérí, ẹ̀mí mímọ́ sì tún darí Mósè láti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú Diutarónómì 5:6-21. Lára ohun tí òfin pa láṣẹ fún Ísírẹ́lì ni pé kí wọ́n fẹ́ràn Jèhófà kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn-àyà àti gbogbo ọkàn àti gbogbo okunra wọn sìn ín. Àsọtúnsọ la sì sọ èyí pẹ̀lú. (Diu. 6:5; 10:12; 11:13; 30:6) Kí nìdí rẹ̀? Ìdí ni pé òun ni “àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní” gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ. (Mát. 22:34-38) Ó ju ogún ìgbà lọ tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Jeremáyà rán àwọn èèyàn Júdà létí nípa bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n gbọ́ràn sí òun lẹ́nu kí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ fún wọn. (Jer. 7:23; 11:4; 12:17; 19:15) Ó sì ju ọgọ́ta ìgbà lọ tí Ọlọ́run gbẹnu Ìsíkíẹ́lì sọ ọ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè “yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”—Ìsík. 6:10; 38:23.

Àkọsílẹ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Jésù ṣe tún jẹ́ ká rí bí a ṣe lè lo àsọtúnsọ lọ́nà tó múná dóko. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìhìn Rere tó wà jẹ́ mẹ́rin, ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí a tún lè rí nínú ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìwé Ìhìn Rere yòókù, tó sì jẹ́ pé ọ̀nà tó yàtọ̀ díẹ̀ ni wọ́n tún gbà ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà yẹn. Bí Jésù ṣe ń kọ́ni, ló ń sọ àwọn ìtọ́ni pàtàkì kan lásọtúnsọ, àmọ́ onírúurú ọ̀nà ló gbà sọ ọ́. (Máàkù 9:34-37; 10:35-45; Jòh. 13:2-17) Nígbà tí Jésù sì wà lórí Òkè Ólífì ní nǹkan bí ọjọ́ mélòó kan ṣáájú kí wọ́n tó pa á, ó sọ kókó pàtàkì yìí lásọtúnsọ láti lè tẹnu mọ́ ọn, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.”—Mát. 24:42; 25:13.

Ní Òde Ẹ̀rí. Nígbà tí o bá wàásù fáwọn èèyàn, o kò ní fẹ́ kí wọ́n gbàgbé ohun tó o bá wọn sọ. Sísọ̀rọ̀ lásọtúnsọ lọ́nà tó mọ́yán lórí ni yóò jẹ́ kí wọ́n lè máa rántí rẹ̀.

Sísọ ọ̀rọ̀ ní àsọtúnsọ sábà máa ń mú kéèyàn má gbàgbé ọ̀rọ̀ yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, bí o bá ka ẹsẹ Bíbélì kan tán, láti tẹnu mọ́ ọn o lè tọ́ka sí apá tó ṣe kókó níbẹ̀ kó o wá béèrè pé, “Ǹjẹ́ o kíyè sí àwọn gbólóhùn tí a lò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí?”

O tún lè lo àwọn gbólóhùn tí o fẹ́ fi kásẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan nílẹ̀ láti fi sọ àsọtúnsọ ọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Kókó pàtàkì tí màá fẹ́ kó o fi sọ́kàn nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa ni . . . ” Kí o wá tún kókó yẹn sọ ní ṣókí. Ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ bí: “Ète Ọlọ́run ni pé kí ayé yìí yí padà di Párádísè. Ó sì dájú pé ète yẹn máa ṣẹ.” Tàbí bóyá: “Bíbélì fi hàn kedere pé ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí là ń gbé báyìí. Bí a bá máa là á já ní ìkẹyìn, a ní láti mọ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe.” A sì tún lè sọ pé: “Ó ti wá yé wa kedere pé Bíbélì fún wa nímọ̀ràn tó wúlò nípa bí a ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro ìdílé.” Ní àwọn ìgbà mìíràn, o lè tún ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì kan sọ láti fi ṣe kókó tó yẹ kí wọ́n fi sọ́kàn. Àmọ́ ṣá o, ó gba kéèyàn ti ronú nípa rẹ̀ ṣáájú kéèyàn tó lè ṣe é lọ́nà tó múná dóko.

Nígbà ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè jẹ́ àwọn ìbéèrè tí o fi ń ṣàtúnyẹ̀wò lo máa lò láti fi tún ọ̀rọ̀ sọ.

Tí ìmọ̀ràn Bíbélì kan kò bá tètè yé ẹnì kan tàbí pé ó ṣòro fún un láti fi í sílò, ó lè dára pé kó o sọ̀rọ̀ nípa kókó yẹn ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ. Gbìyànjú láti gba onírúurú ọ̀nà ṣàlàyé rẹ̀. Àlàyé tó o máa ṣe nípa rẹ̀ lè má gùn púpọ̀, àmọ́ ó yẹ kó mú kí akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ọ̀ràn náà. Rántí pé Jésù lo irú àsọtúnsọ bẹ́ẹ̀ láti fi ran àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀mí fífẹ́ láti máa jẹ́ ẹni àkọ́kọ́.—Mát. 18:1-6; 20:20-28; Lúùkù 22:24-27.

Nígbà Tí O Bá Ń Sọ Àsọyé. Bí o bá ń sọ àsọyé fún ìjọ látorí pèpéle, ojúṣe rẹ ju pé kí o kàn sọ̀rọ̀ sétígbọ̀ọ́ àwùjọ nìkan. Wàá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yé àwùjọ, kí wọ́n má gbàgbé ohun tó o sọ, kí wọ́n sì tún fi í sílò. Láti lè ṣe èyí, ńṣe ni kó o máa sọ̀rọ̀ lásọtúnsọ.

Àmọ́ ṣá o, bí o bá kàn ń tún àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ sọ léraléra, àwùjọ tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ lè má pọkàn pọ̀ sórí ohun tó ò ń sọ mọ́. Ńṣe ni kí o fara balẹ̀ yan àwọn kókó tó yẹ kí o tẹnu mọ́ yàtọ̀. Wọ́n sì sábà máa ń jẹ́ kókó pàtàkì tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé lórí, ṣùgbọ́n o tún lè fi àwọn kókó mìíràn tó wúlò fún àwọn olùgbọ́ rẹ ní pàtàkì kún un pẹ̀lú.

Láti sọ àsọtúnsọ ọ̀rọ̀, o lè kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ yẹn nígbà ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀. Sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ṣókí tó máa kó ohun tí o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí pọ̀ tàbí kí o lo ìbéèrè tàbí àwọn àpẹẹrẹ kúkúrú tó máa nasẹ̀ ohun kan tó ń fẹ́ àlàyé. O lè mẹ́nu kan iye kókó pàtàkì tí ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yẹn, kí o tò wọ́n ní ení, èjì. Kí o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé wọn lọ́kọ̀ọ̀kan bí o ṣe ń bọ̀rọ̀ lọ. O lè túbọ̀ tẹnu mọ́ wọn láàárín ọ̀rọ̀ rẹ nípa títún kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan sọ kí o tó kọjá sí èyí tó tẹ̀ lé e. O sì tún lè lo àpẹẹrẹ kan tó sọ bí kókó pàtàkì kan ṣe wúlò láti fi tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀. O lè túbọ̀ tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ nípa lílo ìparí ọ̀rọ̀ láti fi tún wọn sọ, o tún lè fi gbé àwọn kókó náà yọ nípa fífi ìyàtọ̀ tó wà láàárín kókó pàtàkì àti kókó mìíràn hàn, o sì tún lè fi dáhùn ìbéèrè tí wọ́n béèrè tàbí kí o fi ṣàlàyé ohun kan tó o ti sọ ṣáájú tó ń fẹ́ àlàyé.

Láfikún sí ohun tí a sọ lókè yìí, olùbánisọ̀rọ̀ tó gbó ṣáṣá máa ń fara balẹ̀ kíyè sí irú àwọn èèyàn tó wà nínú àwùjọ tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ kan kò bá yé àwọn kan lára wọn, olùbánisọ̀rọ̀ yìí á ti mọ̀. Bó bá jẹ́ kókó tó ṣe pàtàkì ni, yóò tún padà ṣàlàyé rẹ̀. Ṣùgbọ́n, tó bá kàn tún ọ̀rọ̀ tó ti sọ tẹ́lẹ̀ sọ nìkan, ó lè máà yé wọn síbẹ̀síbẹ̀. Ohun tó wé mọ́ ọ̀ràn kí á kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kọjá kí á kàn tún ohun tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ sọ. Olùbánisọ̀rọ̀ ní láti mọ ọwọ́ yí padà. Ó lè gba pé kí ó ṣe àfikún àlàyé tí kò rò tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Mímọ ọwọ́ yí padà láti lè yanjú ohun tó jẹ́ ìṣòro àwùjọ rẹ lọ́nà báyìí ni ohun tó túbọ̀ ń fi hàn dáadáa pé o jẹ́ olùkọ́ tó pegedé.

ÌGBÀ TÍ O LÈ SỌ ÀSỌTÚNSỌ

  • O lè sọ ọ́ ní kété tí o bá ti sọ kókó pàtàkì kan tán tàbí lẹ́yìn tí o bá ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa èrò pàtàkì kan.

  • O lè sọ ọ́ níparí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ tàbí níparí àsọyé rẹ.

  • O lé sọ ọ́ nígbà tí o bá kíyè sí i pé àwọn kókó pàtàkì kan kò tètè yé àwọn olùgbọ́ rẹ.

  • Tó bá jẹ́ níbi ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè sọ ọ́ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, bóyá ní ọjọ́ mélòó kan tàbí ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan síra wọn.

ÌDÁNRAWÒ: (1) Bí o ṣe ń parí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tí o bá pàdé lóde ẹ̀rí fún ìgbà àkọ́kọ́, tún kókó pàtàkì kan sọ lára ohun tí o bá a sọ tí o kò fẹ́ kí onítọ̀hún gbàgbé. (2) Bí o ṣe ń parí ọ̀rọ̀ nígbà ìpadàbẹ̀wò, tún kókó kan tàbí méjì sọ tí o fẹ́ kí olùfìfẹ́hàn náà máa rántí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́