Orin 77
Ẹ Máa Dárí Jini
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà tipasẹ̀
Ọmọ rẹ̀ fìfẹ́ ṣètò
Láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì,
Kó sì mú ikú kúrò.
Táa bá ti ronú pìwà dà,
Yóò dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì
Lọ́lá ìràpadà Kristi,
La ńtọrọ ìdáríjì.
2. Aó rí àánú bẹ́ẹ̀ gbà,
Táa bá jọ Ọlọ́run wa
Táa ńdárí jini fàlàlà,
Táa ńfìfẹ́ àtàánú hàn.
Ká máa fara dàá fúnra wa,
Ká má ṣe foró yaró;
Ká máa bọlá fáwọn ará,
Ká fìfẹ́ ṣohun gbogbo.
3. Aláàánú ló yẹ kí
Gbogbo wa pátá máa jẹ́.
Kò ní jẹ́ ká níkòórìíra,
Kò ní jẹ́ ká máa ránró.
Táa bá ńfara wé Jèhófà,
Tó ní ìfẹ́ tó ta yọ,
Aó máa dárí jini lóòótọ́;
Aó fìwà jọ Ọlọ́run.
(Tún wo Mát. 6:12; Éfé. 4:32; Kól. 3:13.)