Orin 11
Mímú Ọkàn Jèhófà Yọ̀
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọlọ́run àwa ti jẹ́jẹ̀ẹ́;
Láti fọgbọ́n ṣe iṣẹ́ rẹ.
Ìgbà náà làwa lè nípìn-ín
Nínú mímú ọkàn rẹ yọ̀.
2. Ẹrú rẹ olóòótọ́ láyé,
Ńkéde ọlá ńlá rẹ fáyé.
Ó ńbọ́ wa lákòókò tó yẹ,
Ká lókun láti ṣèfẹ́ rẹ.
3. Fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ,
Ká lè máa rin ọ̀nà òótọ́,
Ká máa sèso fún ìyìn rẹ,
Ká lè mọ́kàn rẹ yọ̀ láéláé.
(Tún wo Mát. 24:45-47; Lúùkù 11:13; 22:42.)