Orin 39
Àlàáfíà Tó Wà Láàárín Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Fi ìyìn fún Jèhófà,
Ọba àlàáfíà.
Yóò mú kógun kásẹ̀ ńlẹ̀,
Ìṣọ̀kan yóò wà.
Aládé Àlàáfíà ni
Jésù Ọmọ rẹ̀;
Àlàáfíà pípé yóò dé,
Tó bá ti ṣẹ́gun.
2. A kò fàyè gba aáwọ̀,
Àlàáfíà la wà.
Idà wa ti di dòjé,
Kò sí ìjà mọ́.
Ìdáríjì ló máa ńjẹ́
Kí àlàáfíà wà.
Àwa àgùntàn Jésù,
Ká wà lálàáfíà.
3. Ara èso òdodo
Ni àlàáfíà,
Ẹ̀rí ọgbọ́n látòkè,
Táa ńgbàdúrà fún.
A ńfìwà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́,
A ńwá àlàáfíà
Títí dìgbà tálàáfíà
Yóò kárí ayé.
(Tún wo Sm. 46:9; Aísá. 2:4; Ják. 3:17, 18.)