Orin 67
Máa Gbàdúrà sí Jèhófà Lójoojúmọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Gbàdúrà sí Jáà, tí ńgbọ́ àdúrà.
Àǹfààní àwa táa ńjóókọ rẹ̀ ni.
Ṣí ọkàn rẹ payá fúnun bí ọ̀rẹ́,
Fọkàn rẹ balẹ̀ kóo sì gbẹ́kẹ̀ lée.
Gbàdúrà lójoojúmọ́.
2. Gbàdúrà sí Jáà, dúpẹ́ ẹ̀mí wa,
Tọrọ ’dáríjì báa ti ńdárí jì.
Ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún Ọlọ́run wa.
Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ pé èèpẹ̀ ni wá.
Gbàdúrà lójoojúmọ́.
3. Gbàdúrà sí Jáà bíṣòro bá dé.
Òun ni Baba wa, ẹ̀gbẹ́ wa ló ńwà.
Tọrọ ààbò àti ìrànwọ́ rẹ̀;
Má bẹ̀rù rárá, ṣáà ti gbẹ́kẹ̀ lée.
Gbàdúrà lójoojúmọ́.
(Tún wo Mát. 6:9-13; 26:41; Lúùkù 18:1.)