Orin 79
Agbára Inú Rere
Bíi Ti Orí Ìwé
1. A dúpẹ́ pé a ti mọ Jèhófà,
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀
Pé bó ṣe lọ́gbọ́n àtagbára tó,
Ó tún nífẹ̀ẹ́ òun inúure.
2. Jésù ké sáwọn tọ́kàn wọn dà rú
Pé, ‘Ẹ má dààmú mọ́.’
Àjàgà àti ẹrù rẹ̀ fúyẹ́,
Kristi sì máa ńtuni lára.
3. A mọ Ọlọ́run a sì mọ Jésù,
A fẹ́ fìwà jọ wọ́n.
Ní gbogbo ọ̀nà, la ti fẹ́ jọ wọ́n
Nínú inúure òun àánú.
(Tún wo Míkà 6:8; Mát. 11:28-30; Kól. 3:12; 1 Pét. 2:3.)