ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rk apá 4 ojú ìwé 10-11
  • Ta Ni Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Ọlọ́run?
  • Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ “Ẹ̀mí Fún Iṣẹ́ Ìsìn Gbogbo Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ohun Tí Àwọn Áńgẹ́lì Ń Ṣe fún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Áńgẹ́lì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
rk apá 4 ojú ìwé 10-11

APA 4

Ta Ni Ọlọ́run?

ORÍṢIRÍṢI ọlọ́run ni àwọn èèyàn ń jọ́sìn. Àmọ́ Ìwé Mímọ́ kọ́ni pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. Ọlọ́run tòótọ́ yìí yàtọ̀ gedegbe, ó ju ohun gbogbo lọ, ó ti wà ṣáájú ohun gbogbo, yóò sì máa wà títí ayé. Òun ló dá ohun gbogbo ní ọ̀run àti ayé, òun ló sì dá àwa èèyàn. Nítorí náà, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló yẹ kí á máa sìn.

Mósè gbé wàláà òkúta tá a kọ Òfin Mẹ́wàá sí dání

Ọlọ́run fún wòlíì Mósè ní Òfin pé kí ó fún àwọn èèyàn rẹ̀, Òfin náà jẹ́ “ọ̀rọ̀ tí a tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì sọ”

Ọlọ́run ní orúkọ oyè tó pọ̀ tí wọ́n fi ń ṣàpọ́nlé rẹ̀, àmọ́ orúkọ kan ṣoṣo péré ni orúkọ rẹ̀ gangan. Orúkọ yẹn ni JÈHÓFÀ. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Èyí ni ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù, ni ó rán mi sí yín.’ Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” (Ẹ́kísódù 3:15) Ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà tí orúkọ yìí, Jèhófà, fara hàn nínú Ìwé Mímọ́. Ohun tí Sáàmù 83:18 sọ nípa Ọlọ́run ni pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

Orúkọ Ọlọ́run ló funfun yàtọ̀ nínú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú yìí

Orúkọ Ọlọ́run wà nínú ìwé àtijọ́ kan tó ń jẹ́ Àkájọ Ìwé Òkun Òkú

Kò sí èèyàn kankan tó fojú rí Ọlọ́run rí. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Ìwọ kò lè rí ojú mi, nítorí pé kò sí ènìyàn tí ó lè rí mi kí ó sì wà láàyè síbẹ̀.” (Ẹ́kísódù 33:20) Ọ̀run ni Ọlọ́run ń gbé, àwa èèyàn kò lè fi ojú wa rí i. Ó lòdì láti ṣe ère tàbí àwòrán tàbí àmì tàbí ohunkóhun mìíràn pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ Ọlọ́run, kò sì tọ̀nà láti máa gbàdúrà sí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run fi rán Mósè wòlíì rẹ̀, ó pàṣẹ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” (Ẹ́kísódù 20:2-5) Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run tún fi iṣẹ́ rán wòlíì Aísáyà pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún àwọn ère fífín.”—Aísáyà 42:8.

Àwọn èèyàn kan gba Ọlọ́run gbọ́, àmọ́ wọ́n gbà pé kò sẹ́ni tó lè mọ̀ ọ́n àti pé Ọlọ́run kò ṣeé sún mọ́. Wọ́n gbà pé kàkà kí a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ṣe ló yẹ ká máa sá fún un. Kí lèrò tìrẹ? Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ rẹ jẹ Ọlọ́run lógún? Ǹjẹ́ o tiẹ̀ lè mọ Ọlọ́run lóòótọ́, débi pé wàá sún mọ́ ọn dáadáa? Jẹ́ ká wo àwọn ìwà dáadáa tí Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run ní.

Kí Ni Ìdáhùn Ìbéèrè Yìí?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sin Ọlọ́run?

  • Kí ni orúkọ Ọlọ́run?

  • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká lo ère, àmì tàbí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ láti fi jọ́sìn Ọlọ́run?

  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ṣe ohun tó bá fẹ́ ṣe?

Àwọn Áńgẹ́lì Ọlọ́run àti Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ń ṣe ohun tó bá fẹ́ kó di ṣíṣe? Ọ̀nà kan ni pé ó máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣe é. Ẹ̀mí mímọ́ yìí kì í ṣe ẹ̀dá abẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe áńgẹ́lì (Malaika). Ẹ̀mí mímọ́ yìí jẹ́ agbára tó bùáyà, tí kò lópin, tí kò sì ṣeé fojú rí, èyí tí Ọlọ́run fi ń ṣe gbogbo ohun tó bá fẹ́ kó di ṣíṣe níbikíbi. Agbára yìí ni Ọlọ́run fi dá ọ̀run àti ayé. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà ni a ṣe ọ̀run, nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ sì ni a ṣe gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.” (Sáàmù 33:6) Jẹ́nẹ́sísì 1:2 nínú Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé pé nígbà tí omi ṣì bo ilẹ̀ ayé, tí Ọlọ́run ń ṣètò bí ayé yóò ṣe di ibi tí èèyàn á máa gbé, ‘ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ń lọ síwá-sẹ́yìn lójú omi.’ Ọlọ́run wá fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dá oríṣiríṣi ẹ̀dá tí ń bẹ ní ayé.

Ọlọ́run tún máa ń rán àwọn áńgẹ́lì (Malaika) láti ṣe àwọn ohun tó fẹ́ kó di ṣíṣe. Ọlọ́run dá wọn kí wọ́n máa gbé ní ọ̀run níbi tí òun wà. Àwọn áńgẹ́lì ní agbára púpọ̀. Wọ́n máa ń lọ jíṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì míì. Bí àpẹẹrẹ, Ìwé Mímọ́ pe Òfin tí Ọlọ́run fi rán wòlíì Mósè ní “ọ̀rọ̀ tí a tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì sọ.” Àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run tún máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà ní ayé lọ́wọ́. Kódà Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn áńgẹ́lì jẹ́ “ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà.”—Hébérù 1:14; 2:2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́