ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • T-32 ojú ìwé 1-3
  • Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?
  • Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?
    Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?
  • Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
    Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
  • Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?
    Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?
  • Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì?
    Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì?
Àwọn Míì
Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?
T-32 ojú ìwé 1-3

Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?

Ṣé o rò pé . . .

  • ìfẹ́ ni?

  • àbí owó?

  • àbí nǹkan míì?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Aláyọ̀ ni àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”​—Lúùkù 11:28, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ

Wàá rí ìfẹ́ tòótọ́.​—Éfésù 5:​28, 29.

Wàá gbádùn ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀.​—Éfésù 5:33.

Ọkàn rẹ á balẹ̀ pẹ̀sẹ̀.​—Máàkù 10:​6-9.

Àwọn ìdílé tó láyọ̀: Ìyá àti ọmọ rẹ̀ obìnrin, tọkọtaya, àwọn òbí àti ọmọ wọn ọkùnrin

ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ọlọ́run ló dá ìdílé sílẹ̀. Bíbélì sọ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run ni “gbogbo ìdílé . . . ti gba orúkọ rẹ̀.” (Éfésù 3:14, 15) Ìyẹn túmọ̀ sí pé Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn kọ́ wa?

    Rò ó wò ná: Tó o bá ń jẹ oúnjẹ aládùn kan, tó o sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n fi sè é, ọwọ́ ta ló yẹ kó o ti béèrè? Ṣebí ọwọ́ ẹni tó sè é ni?

    Bákan náà, tá a bá fẹ́ mọ àwọn ohun tó máa mú kí ayọ̀ wà nínú ìdílé, ọ̀dọ̀ Jèhófà ló yẹ ká yíjú sí, torí pé òun ló dá ìdílé sílẹ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24.

  • Ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún. Àwọn ìdílé tó bá jẹ́ ọlọgbọ́n máa ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tí Jèhófà ń fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. ‘Nítorí ó ń bójú tó wa.’ (1 Pétérù 5:6, 7) Ohun tó dáa ni Jèhófà ń fẹ́ fún wa, àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ sì máa ń wúlò nígbà gbogbo!​—Òwe 3:5, 6; Àìsáyà 48:17, 18.

RÒ Ó WÒ NÁ

Tọkọtaya kan ń gbọ́ ìmọ̀ràn tí Kristẹni alàgbà kan ń gbà wọ́n; wọ́n jọ ń ka Bíbélì

Báwo lo ṣe lè jẹ́ ọkọ rere, aya rere tàbí òbí rere?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé ÉFÉSÙ 5:1, 2 àti KÓLÓSÈ 3:18-21.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́