ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • snnw orin 146
  • Èmi Lẹ Ṣe É Fún

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èmi Lẹ Ṣe É Fún
  • Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Ti Ṣe É fún Mi
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àdúrà Ẹni Tó Ní Ẹ̀dùn Ọkàn
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àdúrà Ẹni Rírẹlẹ̀
    Kọrin sí Jèhófà
  • Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
Àwọn Míì
Kọrin sí Jèhófà—Àwọn Orin Tuntun
snnw orin 146

Orin 146

Èmi Lẹ Ṣe É Fún

Bíi Ti Orí Ìwé

(Mátíù 25:34-40)

  1. Jésù ní àgùntàn mìíràn tó ń  sìn pẹ̀lú

    àwọn tó f’ẹ̀mí yàn, táá jẹ́ aya rẹ̀.

    Gbogbo ohun tá  a bá ṣe

    kára lè tù wọ́n

    Jésù máa san èrè rẹ̀ fún wa pátá.

    (ÈGBÈ)

    “Tẹ́  ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe  é fún.

    Ẹ ti ṣe  é fún wọn; ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.”

  2. “Ebi pa mí, òùngbẹ gbẹ mí, ẹ tọ́jú mi,

    gbogbo ohun tí mo nílò lẹ fún mi.”

    Wọ́n bi  í pé: “Sọ fún wa

    ìgbà wo la ṣe bẹ́ẹ̀?”

    Ọba wá fèsì ó dá wọn lóhùn pé:

    (ÈGBÈ)

    “Tẹ́  ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe  é fún.

    Ẹ ti ṣe  é fún wọn; ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.”

  3. “Ẹ j’ólóòótọ́ sí mi, iṣẹ́ rere lẹ̀ ń  ṣe,

    ẹ̀ ń  wàásù pẹ̀l’áwọn arákùnrin mi.”

    Ọba máa sọ f’áwọn

    àgùntàn ọ̀tún rẹ̀:

    “Ẹ jogún ayé àti ìjẹ́pípé.”

    (ÈGBÈ)

    “Tẹ́  ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe  é fún.

    Ẹ ti ṣe  é fún wọn; ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.”

(Tún wo Òwe 19:17; Mát. 10:​40-42; 2 Tím. 1:16, 17.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́