ORIN 26
Ẹ Ti Ṣe É fún Mi
1. Àwọn arákùnrin Kristi tó wà láyé
ni àwọn àgùntàn mìíràn ńbá ṣiṣẹ́.
Gbogbo ìsapá wọn
láti ràn wọ́n lọ́wọ́
Ni Jésù sọ pé wọ́n máa gba èrè rẹ̀.
(ÈGBÈ)
“Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.
Ohun tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.
Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.
Bẹ́ ẹ ṣe ṣe é fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.
Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.”
2. “Nígbà tébi ń pa mí, tí òùngbẹ sì ń gbẹ mí,
gbogbo ohun tí mo nílò lẹ pèsè.”
Wọ́n béèrè pé: “Ìgbà wo
la ṣe nǹkan wọ̀nyí?”
Ọba náà máa dá wọn lóhùn, yóò sọ pé:
(ÈGBÈ)
“Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.
Ohun tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.
Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.
Bẹ́ ẹ ṣe ṣe é fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.
Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.”
3. “Ẹ ti dúró tì mí, iṣẹ́ rere lẹ̀ ń ṣe.
Ẹ̀ ń wàásù pẹ̀l’áwọn arákùnrin mi.”
Ọba máa sọ fáwọn
tó wà lọ́tùn-ún rẹ̀ pé:
“Ẹ di pípé, kí ẹ sì jogún ayé.”
(ÈGBÈ)
“Tẹ́ ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.
Ohun tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.
Iṣẹ́ tẹ́ ẹ ṣe fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.
Bẹ́ ẹ ṣe ṣe é fún wọn, èmi lẹ ṣe é fún.
Tẹ́ ẹ bá ti ṣe é fún wọn, ẹ ti ṣe é fún mi.”
(Tún wo Òwe 19:17; Mát. 10:40-42; 2 Tím. 1:16, 17.)