ORÍ 15
Àǹfààní Tá À Ń Rí Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Darí Wa
Ó ṢE pàtàkì ká gbà kí Jèhófà tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run máa darí wa tá a bá fẹ́ wà létòlétò bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà. A gbà pé Ọmọ rẹ̀ ni orí ìjọ, a sì mọrírì ètò tí Ọlọ́run ṣe pé kí àwọn kan máa múpò iwájú láwọn apá míì nígbèésí ayé. Àǹfààní ńlá la máa rí tá a bá tẹ̀ lé ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí.
2 Ọgbà Édẹ́nì ni Ọlọ́run ti kọ́kọ́ jẹ́ kí àwa èèyàn mọ ẹni tí á máa darí wa àtàwọn tí àwa náà á máa darí. Èyí ṣe kedere nínú àṣẹ tí Ọlọ́run pa nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:28 àti 2:16, 17. Àwa èèyàn á máa darí àwọn ẹranko, Ádámù àti Éfà á fi ara wọn sábẹ́ ìdarí Ọlọ́run, wọ́n á sì máa tẹ̀lé àṣẹ rẹ̀. Tí wọ́n bá ń ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run yìí, àlàáfíà á wà, nǹkan á sì máa lọ déédéé. Ìlànà ipò orí yìí kan náà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé rẹ̀ nínú 1 Kọ́ríńtì 11:3. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí gbogbo ọkùnrin ni Kristi; bákan náà, orí obìnrin ni ọkùnrin; bákan náà, orí Kristi ni Ọlọ́run.” Èyí fi hàn pé yàtọ̀ sí Jèhófà, kò sẹ́ni tí kò ní olórí.
3 Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ nípa ìlànà ipò orí yìí, àwọn míì ò sì tẹ̀ lé e. Kí ló fà á? Inú ọgbà Édẹ́nì ni wàhálà yìí ti bẹ̀rẹ̀, ìyẹn nígbà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ mọ̀ọ́mọ̀ mú ara wọn kúrò lábẹ́ ìdarí Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. (Jẹ́n. 3:4, 5) Síbẹ̀, òmìnira tí wọ́n ní ò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n sọ ara wọn di ẹrú áńgẹ́lì búburú náà, Sátánì Èṣù. Bí ọ̀tẹ̀ àkọ́kọ́ ṣe sọ aráyé di àjèjì sí Ọlọ́run nìyẹn o. (Kól. 1:21) Àbájáde rẹ̀ ni pé lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.—1 Jòh. 5:19.
4 Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a ń kọ́ tá a sì ń fi sílò ti mú ká kúrò lábẹ́ ìdarí Sátánì. Torí pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí, tá a ti ya ara wa sí mímọ́, tá a sì ti ṣèrìbọmi, a gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ tó yẹ kó máa darí wa. Àwa náà gbà pẹ̀lú Ọba Dáfídì tó sọ pé Jèhófà ni “olórí lórí ohun gbogbo.” (1 Kíró. 29:11) Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ la fi jẹ́wọ́ pé: “Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run. Òun ló dá wa, tirẹ̀ la sì jẹ́. Àwa ni èèyàn rẹ̀ àti àgùntàn ibi ìjẹko rẹ̀.” (Sm. 100:3) A gbà pé Jèhófà tóbi lọ́ba àti pé ó yẹ ká fi ara wa fún un pátápátá, torí pé òun ló dá ohun gbogbo. (Ìfi. 4:11) Òjíṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ni wá, torí náà, àpẹẹrẹ pípé tí Jésù Kristi fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká tẹrí ba fún Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé.
5 Kí ni Jésù kọ́ látinú ìyà tó jẹ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé? Hébérù 5:8 dáhùn pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ni, ó kọ́ ìgbọràn látinú ìyà tó jẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń ṣe ohun tí Baba rẹ̀ ọ̀run fẹ́, kódà nígbà ìpọ́njú. Síwájú sí i, Jésù kì í dá nǹkan kan ṣe lérò ara rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi ràn án ló máa ń sọ, kì í sọ tara rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò wá ògo ara rẹ̀. (Jòh. 5:19, 30; 6:38; 7:16-18) Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ìfẹ́ Baba rẹ̀ ló máa ń fẹ́ ṣe nígbà gbogbo, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn mú káwọn èèyàn ta kò ó, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí i. (Jòh. 15:20) Láìka àtakò àti inúnibíni sí, ìfẹ́ Ọlọ́run ni Jésù ṣe. Jésù “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀” kódà títí dójú “ikú lórí òpó igi oró.” Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú bí Jésù ṣe fi gbogbo ayé rẹ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó mú kí aráyé rí ìgbàlà ayérayé, ó mú kí Jèhófà gbé e ga, ó sì mú ògo wá fún Baba rẹ̀.—Fílí. 2:5-11; Héb. 5:9.
ÀWỌN IBI TÓ TI YẸ KÁ JẸ́ KÍ ÌLÀNÀ ỌLỌ́RUN MÁA DARÍ WA
6 Tá a bá gbà kí Ọlọ́run máa darí wa, tá a sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, àá bọ́ lọ́wọ́ wàhálà àti ìdààmú ọkàn tó máa ń bá àwọn tí kò gbà kí Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run máa darí àwọn. Elénìní wa Èṣù ń wá bó ṣe máa pa wá jẹ. A ò ní kó sọ́wọ́ ẹni ibi yẹn tá a bá kọjú ìjà sí i tá a sì rẹ ara wa sílẹ̀ lábẹ́ Jèhófà, tá a gbà kí Jèhófà máa darí wa, tá a sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tinútinú.—Mát. 6:10, 13; 1 Pét. 5:6-9.
7 Nínú ìjọ Kristẹni, a gbà pé Kristi ni orí ìjọ, a sì mọ̀ pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ló yàn láti máa bójú tó wa. Èyí mú ká máa kíyè sí ìwà wa àti bá a ṣe ń ṣe síra wa. Bí àwa tá a wà nínú ìjọ bá gbà kí Ọlọ́run máa darí wa, àá máa ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú gbogbo apá tí ìjọsìn wa pín sí. Èyí gba pé ká máa tẹ̀ lé ìtọ́ni lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ká máa lọ sí ìpàdé déédéé, ká sì máa kópa níbẹ̀, ká máa fi ojú tó tọ́ wo àwọn alàgbà, ká sì máa kọ́wọ́ ti àwọn ètò tí ẹrú olóòótọ́ náà ṣe.—Mát. 24:45-47; 28:19, 20; Héb. 10:24, 25; 13:7, 17.
8 Bá a ṣe gbà kí Jèhófà máa darí wa ń mú kí àlááfíà jọba láàárín wa, ọkàn wa balẹ̀, nǹkan sì wà létòletò nínú ìjọ. Àwa èèyàn Jèhófà fìwà jọ Ọlọ́run wa. (1 Kọ́r. 14:33, 40) Ìrírí wa nínú ètò Jèhófà ti jẹ́ káwa náà lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ ti Ọba Dáfídì. Lẹ́yìn tí Dáfídì kíyè sí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà àtàwọn ẹni burúkú, tayọ̀tayọ̀ ló fi kọrin pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—Sm. 144:15.
9 Nínú ìdílé, “orí obìnrin ni ọkùnrin.” Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn ọkùnrin gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún Kristi, nígbà tó sì jẹ́ pé Ọlọ́run ni orí Kristi. (1 Kọ́r. 11:3) Àwọn aya gbọ́dọ̀ tẹrí ba fáwọn ọkọ wọn, káwọn ọmọ sì tẹrí ba fáwọn òbí wọn. (Éfé. 5:22-24; 6:1) Tí kálukú bá ń bọ̀wọ̀ fún ipò orí nínú ìdílé, àlàáfíà máa jọba.
10 Ó yẹ káwọn ọkọ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ lo ipò orí wọn. (Éfé. 5:25-29) Tí ọkọ kan bá ń ṣe ojúṣe rẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, tí kò sì lo ipò orí rẹ̀ nílòkulò, á yá ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ lára láti máa ṣègbọràn sí i. Bíbélì sọ pé olùrànlọ́wọ́ tàbí ẹnì kejì ni aya jẹ́ fún ọkọ rẹ̀. (Jẹ́n. 2:18) Tí aya bá ń fi sùúrù ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́, tó sì ń bọ̀wọ̀ fún un, á rí ojúure ọkọ rẹ̀, á sì mú inú Ọlọ́run dùn. (1 Pét. 3:1-4) Tí àwọn tọkọtaya bá ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìlànà ipò orí, àwọn ọmọ á kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ káwọn náà máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run.
Ó yẹ ká jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí wa nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe
11 Láti fi hàn pé à ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ó yẹ ká máa fi ojú tó tọ́ wo “àwọn aláṣẹ onípò gíga” tí Ọlọ́run “gbé sí àwọn ipò wọn tó ní ààlà.” (Róòmù 13:1-7) Torí pé àwa Kristẹni jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè rere, a máa ń san owó orí, ìyẹn ni pé à ń “san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì,” a sì ń “fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mát. 22:21) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ètò tá a máa ń ṣe láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù kì í ta ko òfin tó wà fún dídáàbò bo ìsọfúnni ara ẹni. Bá a ṣe ń bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ, tá a sì ń ṣègbọràn sí wọn nínú àwọn ohun tí kò ta ko òfin òdodo Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún wa láti lo gbogbo okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.—Máàkù 13:10; Ìṣe 5:29.
12 Ó yẹ ká jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí wa nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. A nígbàgbọ́ pé láìpẹ́, gbogbo èèyàn yíká ayé á máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 15:27, 28) Ó dájú pé àwọn tó gba Jèhófà ní Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i títí ayé á rí ojúure Jèhófà àti ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún!