Ọhun ti Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun Ń Beere Lọwọ Wa
“Nitori naa ẹ tẹriba fun Ọlọrun.”—JAKỌBU 4:7.
1. Ki ni a lè sọ nipa iru Ọlọrun ti awa ń jọsin?
IRU agbayanu Ọlọrun wo ni Jehofa jẹ́! Alailẹgbẹ, alailojugba, alailafiwe, ara-ọtọ ni ọpọlọpọ ọ̀nà! Oun ni Ẹni Giga Julọ, Ọba-alaṣẹ Agbaye, ninu ẹni ti gbogbo ọla-aṣẹ tootọ wà. Ó wà lati ayeraye de ayeraye o si lógo tobẹẹ ti ó fi jẹ́ pe kò sí eniyan kan ti ó lè rí i ki ó walaaye sibẹ. (Eksodu 33:20; Romu 16:26) Ó jẹ́ alailopin ni ọgbọ́n ati agbara, pípé patapata ni idajọ-ododo, ati ogidi apẹẹrẹ-ifẹ. Oun ni Ẹlẹdaa wa, Onidaajọ wa, Afunnilofin wa, Ọba wa. Gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ọrẹ-ẹbun ń wá lati ọ̀dọ̀ rẹ̀.—Orin Dafidi 100:3; Isaiah 33:22; Jakọbu 1:17.
2. Ki ni awọn ohun ti itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun ní ninu?
2 Loju-iwoye gbogbo awọn otitọ iṣẹlẹ wọnyi, kò lè sí tabi-ṣugbọn kankan nipa aigbọdọmaṣe wa lati wà ni itẹriba si i. Ṣugbọn ki ni eyi ní ninu fun wa? Ọpọlọpọ nǹkan. Niwọn bi a kò ti lè rí Jehofa Ọlọrun lẹnikọọkan, itẹriba fun un ní ninu ṣiṣegbọran si ohùn ẹ̀rí-ọkàn ti a kọ́ lẹkọọ, ni fifọwọsowọpọ pẹlu eto-ajọ Ọlọrun ti ori ilẹ̀-ayé, ní dídá awọn alaṣẹ ayé mọ̀, ati bibọwọ fun ilana ipo ori ninu iṣeto idile.
Dídi Ẹ̀rí-ọkàn Rere Mú
3. Lati di ẹ̀rí-ọkàn rere mu, a gbọdọ jẹ́ onigbọran si iru awọn ilana wo?
3 Lati pa ẹ̀rí-ọkàn rere mọ, a gbọdọ jẹ́ onigbọran si awọn ohun aláìṣeéfipámúniṣe—iyẹn ni pe, si awọn ofin tabi ilana ti awọn eniyan kò lè fipamuniṣe. Fun apẹẹrẹ, ofin kẹwaa ninu Ofin Mẹwaa, ti a dari lodisi ṣiṣoju kokoro, ni awọn alaṣẹ eniyan kò lè fipamuniṣe. Lọna ti ó ṣe kongẹ, eyi jẹrii si ipilẹṣẹ atọrunwa Ofin Mẹwaa, nitori pe kò sí ẹgbẹ́ aṣofin eniyan kan ti ó ti lè ṣe ofin kan ti a kò ni lè fipamuniṣe nipasẹ ifiyajẹni bi a bá tàpá si i. Nipasẹ ofin yii, Jehofa Ọlọrun fun awọn ọmọ Israeli kọọkan ni ẹrù-iṣẹ́ lati jẹ́ ọlọpaa tirẹ funraarẹ—bi oun bá fẹ́ lati ni ẹ̀rí-ọkàn rere. (Eksodu 20:17) Ni ifarajọra, lara awọn iṣẹ ti ara ti yoo dí ẹnikan lọna jijogun Ijọba Ọlọrun ni “owú” ati “ilara” wà—awọn tí ihuwapada lodisi wọn kò lè mú kí á fipa fúnni ní ijiya lati ọwọ́ awọn onidaajọ eniyan. (Galatia 5:19-21) Ṣugbọn lati di ẹ̀rí-ọkàn rere mu, a gbọdọ yẹra fun iwọnyi.
4. Lati di ẹ̀rí-ọkàn rere mú, nipa awọn ilana Bibeli wo ni a gbọdọ maa gbe igbesi-aye?
4 Bẹẹni a gbọdọ maa gbé nipasẹ awọn ilana Bibeli. Iru awọn ilana bẹẹ ni a lè kopọ ninu awọn ofin meji ti Jesu Kristi ṣalaye ni kínníkínní ni idahun si ibeere naa niti ewo ni ó jẹ́ ofin titobi ju ninu akojọ ofin Mose. “Ki iwọ ki o fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo inu rẹ, fẹ́ Ọlọrun Oluwa rẹ. . . . Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi araarẹ.” (Matteu 22:36-40) Eyi ti ó ṣapejuwe ohun ti ekeji ninu awọn ofin wọnyi ní ninu ni awọn ọ̀rọ̀ Jesu ti a kọsilẹ ninu Matteu 7:12 pe: “Nitori gbogbo ohunkohun ti ẹyin bá fẹ ki eniyan ki o ṣe si yin, bẹẹ ni ki ẹyin ki o sì ṣe si wọn gẹgẹ; nitori eyi ni ofin ati awọn wolii.”
5. Bawo ni a ṣe lè pa ipo-ibatan rere mọ́ pẹlu Jehofa Ọlọrun?
5 A gbọdọ ṣe ohun ti a mọ pe ó tọ́ ki a sì yẹra kuro ninu ṣiṣe ohun ti a mọ̀ pe kò tọ́, boya awọn miiran kiyesi i tabi bẹẹkọ. Eyi rí bẹẹ àní bi o ba tilẹ jẹ pe a lè lọ laijiya yala laiṣe ohun ti a gbọdọ ṣe tabi ní ṣiṣe ohun ti a kò gbọdọ ṣe. Ó tumọ si pipa ipo-ibatan rere mọ́ pẹlu Baba wa ọrun, ni fifi ikilọ ti aposteli Paulu sọ ni Heberu 4:13 sọkan pe: “Kò sì sí ẹ̀dá kan ti kò farahan niwaju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo ni ó wà nihoho ti a sì ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹni ti awa ni iba lo.” Titẹramọ ọn ni ṣiṣe ohun ti ó tọ́ yoo ràn wá lọwọ lati jijakadi lodisi awọn ète ọlọgbọn-ẹwẹ ti Eṣu, lati yẹra fun awọn ikimọlẹ ayé, ati lati gbejako itẹsi ajogunba siha imọtara-ẹni-nikan.—Fiwe Efesu 6:11.
Itẹriba fun Eto-ajọ Ọlọrun
6. Awọn ipa-ọna ibanisọrọpọ wo ni Jehofa lò ni akoko ti o ṣiwaju ìgbà Kristian?
6 Jehofa Ọlọrun kò fun wa ni ẹ̀tọ́ lati pinnu lẹnikọọkan bi a ṣe nilati fi awọn ilana Bibeli silo ninu igbesi-aye wa. Lati ibẹrẹ ìtàn iran eniyan, Ọlọrun ti lo eniyan gẹgẹ bi ipa-ọna ibanisọrọpọ. Nipa bẹẹ, Adamu jẹ́ agbẹnusọ Ọlọrun fun Efa. Àṣẹ nipa eso ti a kà léèwọ̀ naa ni a fi fun Adamu ṣaaju ki a tó da Efa, nitori naa Adamu ti gbọdọ fun Efa ni isọfunni nipa ifẹ-inu Ọlọrun fun un. (Genesisi 2:16-23) Noa jẹ́ wolii Ọlọrun fun idile rẹ̀ ati fun ayé ti ó ṣaaju ìkún-omi naa. (Genesisi 6:13; 2 Peteru 2:5) Abrahamu jẹ́ agbẹnusọ Ọlọrun fun idile rẹ̀. (Genesisi 18:19) Wolii Ọlọrun ati ipa-ọna ibanisọrọpọ fun orilẹ-ede Israeli ni Mose jẹ́. (Eksodu 3:15, 16; 19:3, 7) Lẹhin rẹ̀, titi di ìgbà Johannu Arinibọmi, ọpọlọpọ awọn wolii, alufaa, ati awọn ọba ni Ọlọrun lo lati sọ ifẹ-inu rẹ̀ fun awọn eniyan rẹ̀.
7, 8. (a) Pẹlu dídé Messia naa, awọn wo ni a ti lò gẹgẹ bi agbẹnusọ Ọlọrun? (b) Ki ni itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun ń beere lọwọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii?
7 Pẹlu dídé Messia naa, Jesu Kristi, Ọlọrun lo oun ati awọn aposteli ati ọmọlẹhin rẹ̀ ti wọn wà timọtimọ pẹlu rẹ̀ lati ṣiṣẹsin g̣ẹgẹ bi agbẹnusọ Rẹ̀. Lẹhin naa, awọn ọmọlẹhin Jesu Kristi ẹni-ami-ororo oluṣotitọ ni wọn nilati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu” ni bíbá awọn eniyan Jehofa sọrọpọ nipa bi wọn yoo ṣe fi awọn ilana Bibeli silo ninu igbesi-aye wọn. Itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun tumọ si dídá irin-iṣẹ ti Jehofa Ọlọrun ń lò mọyatọ.—Matteu 24:45-47, NW; Efesu 4:11-14.
8 Awọn otitọ naa fihàn pe lonii “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa” sopọ mọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí Ẹgbẹ́ Oluṣakoso ti awọn Ẹlẹ́rìí wọnyi sì jẹ asoju fun un. Ẹgbẹ́ yẹn, ni ipa tirẹ̀, ń yan awọn alaboojuto ni oniruuru ipò iṣẹ́—gẹgẹ bi awọn alagba ati awọn aṣoju arinrin-ajo—lati dari iṣẹ naa ni adugbo. Itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun ń beere lọwọ Ẹlẹ́rìí oluṣeyasimimọ kọọkan lati wà ni itẹriba fun awọn alaboojuto wọnyi ni pipa ọ̀rọ̀ ti ó wà ninu Heberu 13:17 mọ pe: “Ẹ maa gbọ́ ti awọn tí ń ṣe olori yin, ki ẹ sì maa tẹriba fun wọn: nitori wọn ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nitori ọkàn yin, bi awọn ti yoo ṣe iṣiro, ki wọn ki o lè fi ayọ ṣe eyi, ni aisi ibinujẹ, nitori eyi yoo jẹ́ ailere fun yin.”
Titẹwọgba Ibawi
9. Itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun sábà maa ń jẹ́ ọ̀ràn ki ni?
9 Itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun sábà maa ń jẹ ọ̀ràn titẹwọgba ibawi lati ọ̀dọ̀ awọn wọnni ti wọn ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto. Bi a kò bá maa fi ìgbà gbogbo fun araawa ni ibawi ti o yẹ, a lè nilati di ẹni ti a fun ni imọran ti a sì báwí lati ọwọ́ awọn ti wọn ní iriri ati ọla-aṣẹ lati ṣe bẹẹ, iru bi awọn alagba ijọ. Lati tẹwọgba iru ibawi bẹẹ jẹ ipa-ọna ọgbọ́n.—Owe 12:15; 19:20.
10. Iṣẹ-aigbọdọmaṣe wo ni awọn wọnni ti ń funni ni ibawi ní?
10 Lọna ti ó ṣe kedere, awọn alagba ti wọn ń funni ni ibawi funraawọn gbọdọ jẹ apẹẹrẹ itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun. Bawo? Ni ibamu pẹlu Galatia 6:1, kìí ṣe kiki pe wọn nilati ni ọ̀nà rere niti fifunni ni imọran nikan ni ṣugbọn wọn nilati jẹ awofiṣapẹẹrẹ: “Ará, bi a tilẹ mu eniyan ninu iṣubu kan, ki ẹyin tii ṣe ti ẹmi ki o mú iru ẹni bẹẹ bọsipo ni ẹmi iwatutu; ki iwọ tikaraarẹ maa kiyesara, ki a má baa dán iwọ naa wo pẹlu.” Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, imọran alagba naa gbọdọ wà ni ibamu pẹlu apẹẹrẹ rẹ̀. Iru eyiini wà ni iṣọkan pẹlu iṣileti ti a fi fun wa ninu 2 Timoteu 2:24, 25 ati ninu Titu 1:9. Bẹẹni, awọn ti wọn ń funni ni ibawi tabi atunṣe gbọdọ ṣọra gidigidi lati maṣe lekoko lae. Wọn nilati maa jẹ́ ẹni pẹlẹ, oninurere, ati sibẹ ti o duro gbọnyin nigba gbogbo ninu didi awọn ilana ti wọn wà ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mú. Wọn gbọdọ jẹ́ olufetisilẹ aláìṣègbè, ni títu awọn wọnni ti wọn ń ṣiṣẹẹ ti a sì di ẹ̀rù wuwo lé lara.—Fiwe Matteu 11:28-30.
Itẹriba fun Awọn Alaṣẹ Onipo Giga
11. Ki ni a beere lọwọ awọn Kristian ninu ibatan wọn pẹlu awọn alaṣẹ ayé?
11 Itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun tún ń beere lọwọ wa lati ṣegbọran si awọn alasẹ ayé. A fun wa nimọran ninu Romu 13:1 pe: “Ki olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti ó wà ni ipo giga. Nitori kò si àṣẹ kan, bikoṣe lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun wa: awọn alaṣẹ ti ó sì wà, lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti lana rẹ̀ wa.” Laaarom awọn nǹkan miiran, ọ̀rọ̀ wọnyi ń beere lọwọ wa, lati ṣegbọran si awọn ofin ọ̀nà rírìn ati lati jẹ ẹni ti ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ ń ṣiṣẹ niti sisan owo-ori ati owo-ode, gẹgẹ bi aposteli Paulu ti sọ ni Romu 13:7.
12. Ni ero itumọ wo ni itẹriba wa si Kesari fi jẹ eyi ti o láàlà?
12 Ni kedere, bi o ti wu ki o ri, gbogbo iru itẹriba bẹẹ fun Kesari gbọdọ jẹ eyi ti o ni ààlà. A gbọdọ maa fi ilana ti Jesu Kristi sọ, gẹgẹ bi a ṣe ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Matteu 22:21 sọkan pe: “Ǹjẹ́ ẹ fi ohun tii ṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun tii ṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.” Alaye ẹsẹ-iwe kan fun Romu 13:1 ninu iwe Oxford NIV [New International Version] Scofield Study Bible ṣalaye pe: “Eyi kò tumọsi pe o nilati ṣegbọran si awọn ilana ti ó jẹ ti oniwa-palapala tabi ti ó lodisi ti Kristian. Ni iru awọn ọ̀ràn bẹẹ ó jẹ́ iṣẹ rẹ lati ṣe igbọran si Ọlọrun dipo eniyan (Iṣe 5:29; fiwe Dan. 3:16-18; 6:10 siwaju sii).”
Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun Ninu Agbo Idile
13. Itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun laaarin agbo idile ń beere ki ni lọwọ awọn mẹmba rẹ̀?
13 Ninu agbo idile, ọkọ ati baba ni ó ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi ori. Eyi beere pe ki awọn aya kọbiara si imọran ti a fifunni ninu Efesu 5:22, 23 pe: “Ẹyin aya, ẹ maa tẹriba fun awọn ọkọ yin, gẹgẹ bi fun Oluwa. Nitori pe ọkọ nii ṣe ori aya, gẹgẹ bi Kristi tii ṣe ori ijọ eniyan rẹ̀.”a Niti awọn ọmọ, wọn kìí ṣe ofin tiwọn funraawọn ṣugbọn wọn jẹ baba ati ìyá ni itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun, gẹgẹ bi Paulu ti ṣalaye ninu Efesu 6:1-3 pe: “Ẹyin ọmọ, ẹ maa gbọ ti awọn òbí yin ninu Oluwa: nitori eyi ni ó tọ́. Bọ̀wọ̀ fun baba ati ìyá rẹ (eyi tii ṣe ofin ìkínní pẹlu ileri), ki o lè dara fun ọ, ati ki iwọ ki o lè wà pẹ́ ni ayé.”
14. Itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun ń beere ki ni lọwọ awọn olori idile?
14 Nitootọ, ó mu ki o tubọ rọrun fun awọn aya ati ọmọ lati funni ni iru itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun bẹẹ nigba ti awọn ọkọ ati baba funraawọn bá fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn. Wọn ń ṣe eyi nipa lilo ipo ori wọn ni ibamu pẹlu awọn ilana Bibeli, gẹgẹ bi iwọnyi ti a ri ninu Efesu 5:28, 29 ati 6:4 pe: “Bẹẹ ni ó tọ́ ki awọn ọkunrin ki o maa fẹran awọn aya wọn gẹgẹ bi ara awọn tikaraawọn. Ẹni ti ó bá fẹran aya rẹ̀, ó fẹran oun tikaraarẹ nitori kò sí ẹnikan ti ó tii koriira araarẹ; bikoṣe pe ki o maa bọ́ ọ ki o sì maa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹgẹ bi Kristi sì ti ń ṣe si ijọ.” “Ẹyin baba, ẹ maṣe mú awọn ọmọ yin binu: ṣugbọn ẹ maa tọ́ wọn ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa.”
Awọn Aranṣe Ninu Fifi Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun Hàn
15. Eso ti ẹmi wo ni yoo ràn wá lọwọ lati fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn?
15 Ki ni yoo ràn wá lọwọ lati fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn ninu oniruuru ẹ̀ka wọnyi? Ekinni, ifẹ alainimọtara-ẹni-nikan wà nibẹ—ifẹ fun Jehofa Ọlọrun ati fun awọn wọnni ti o ti fi ṣe olori wa. A sọ fun wa ninu 1 Johannu 5:3 pe: “Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki awa ki o pa ofin rẹ̀ mọ́: ofin rẹ̀ kò sì nira.” Jesu sọ koko ọ̀rọ̀ kan-naa ní Johannu 14:15 pe: “Bi ẹyin bá fẹran mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́.” Nitootọ, ifẹ —eso ti o gbawájú julọ ti ẹmi—yoo ràn wá lọwọ lati mọriri gbogbo ohun ti Jehofa ti ṣe fun wa yoo sì tipa bẹẹ ràn wá lọwọ lati lo itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun.—Galatia 5:22.
16. Iranlọwọ wo ni ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun ń ṣe ni fifi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn?
16 Ekeji, ibẹru oniwa-bi-Ọlọrun wà nibẹ. Bibẹru lati mú Jehofa Ọlọrun binu yoo ràn wá lọwọ nitori pe ó tumọsi “ikoriira ibi.” (Owe 8:13) Laisi tabi-ṣugbọn, ibẹru mímú Jehofa binu yoo pa wá mọ́ kuro ninu jijuwọsilẹ fohunsọkan nitori ibẹru eniyan. Yoo sì tun ràn wá lọwọ lati ṣegbọran si awọn itọni Ọlọrun ohun yoowu ki ipo lilekoko tí wọn nilati koju jẹ́. Siwaju sii, yoo pa wá mọ kuro ninu jijuwọsilẹ fun awọn adanwo tabi awọn itẹsi siha iwa-aitọ. Iwe Mimọ fihàn pe ibẹru Jehofa ni ó sún Abrahamu lati gbidanwo lati fi Isaaki ọmọkunrin rẹ̀ olufẹ rubọ, ati pe ibẹru mimu Jehofa binu ni ó sún Josefu lati dena awọn igbegbeesẹ oniwa-palapala ti aya Potifari lọna ti ó yọrisirere.—Genesisi 22:12; 39:9.
17. Ipa wo ni igbagbọ ń kó ninu lilo itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun wa?
17 Aranṣe kẹta jẹ igbagbọ ninu Jehofa Ọlọrun. Igbagbọ yoo mu ki a o ṣeeṣe fun wa lati kọbiara si imọran ti a fi funni ninu Owe 3:5, 6 pe: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹkẹle Oluwa; má sì ṣe tẹ̀ si ìmọ̀ araarẹ. Mọ̀ ọ́n ni gbogbo ọ̀nà rẹ: oun ó sì maa tọ́ ipa-ọna rẹ.” Igbagbọ yoo ràn wá lọwọ ni pataki julọ nigba ti ó bá dabi ẹni pe a ń jiya lọna aitọ tabi ti a nimọlara pe a dẹ́yẹ si wa nitori ìran wa tabi orilẹ-ede tabi nitori awọn iforigbari akopọ-animọ-iwa kan. Awọn kan tun lè nimọlara pe awọn ni a ti gbojufoda lọna aitọ nigba ti a kò bá damọran wọn lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alagba tabi iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ kan. Bi a bá ni igbagbọ, awa yoo duro de Jehofa lati mú ki awọn ọ̀ràn tọ́ ni akoko rẹ̀ ti ó yẹ. Laaarin akoko naa ó le jẹ́ pe a nilati mú ifarada onisuuru dagba.—Ẹkún Jeremiah 3:26.
18. Ki ni aranṣe kẹrin ninu fifi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun wa hàn?
18 Aranṣe kẹrin jẹ́ irẹlẹ. Onirẹlẹ kan kò ni iṣoro rara lati fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn nitori pe ‘ninu irẹlẹ ọkàn ó ka awọn ẹlomiran si ẹni ti o sàn ju oun lọ.’ Onirẹlẹ kan ń muratan lati mú araarẹ huwa gẹgẹ bi ‘ẹni ti ó kéré ju.’ (Filippi 2:2-4; Luku 9:48) Ṣugbọn agberaga ń di kùnrùngbùn lodisi hihuwa ni itẹriba ó sì maa ń binu nipa rẹ̀. A ti maa ń sọ pe iru eniyan bẹẹ ni iyin yoo parun dipo ki iṣelameyitọ gbigba a là.
19. Apẹẹrẹ rere ti irẹlẹ wo ni aarẹ Watch Tower Society tẹlẹri kan pese?
19 Apẹẹrẹ rere ti irẹlẹ ati itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun ni a fifunni lẹẹkan sii nipasẹ Joseph Rutherford, aarẹ keji Watch Tower Bible and Tract Society. Nigba ti Hitler fofinde iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Germany, awọn arakunrin ti wọn wà nibẹ kọwe sí i ni bibeere ohun ti wọn nilati ṣe ni oju-iwoye ifofinde naa lori awọn ipade wọn ati igbokegbodo iwaasu wọn. O mẹnukan eyi fun idile Beteli ó sì jẹwọ ni ṣako pe oun kò mọ ohun ti oun yoo sọ fun awọn ara ni Germany, ni pataki julọ ni oju-iwoye awọn ijiya lilekenka ti o ni ninu. O sọ pe bi ẹnikan bá mọ ohun ti ó yẹ lati sọ fun wọn, inu oun yoo dun lati gbọ ọ. Ẹ wo iru ẹmi irẹlẹ ti iyẹn jẹ́!b
Awọn Anfaani Lati Inu Fifi Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun Hàn
20. Awọn ibukun wo ni o jẹ jade lati inu fifi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn?
20 A lè fi ẹ̀tọ́ beere pe, Ki ni awọn anfaani fifi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn? Ọpọlọpọ ni, nitootọ. A bọ́ ninu awọn aniyan ati ijakulẹ tí awọn wọnni ti wọn ń gbegbeesẹ lọna idadurolominira ń niriiri rẹ̀. A ń gbadun ibatan rere pẹlu Jehofa Ọlọrun. A ni ibakẹgbẹpọ ti o dara julọ pẹlu awọn Kristian ará wa. Siwaju sii, nipa mímú araawa wà lọna ti o bá ofin mu, a yẹra fun nini awọn iṣoro alainidii pẹlu awọn alaṣẹ ayé. A tun ń gbadun igbesi-aye idile alayọ kan gẹgẹ bi ọkọ ati aya, gẹgẹ bi òbí ati ọmọ. Siwaju sii, nipa pipa itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun mọ́, a ń gbegbeesẹ ni ibamu pẹlu imọran ti a funni ninu Owe 27:11 pe: “Ọmọ mi, ki iwọ ki o gbọ́n, ki o si mú inu mi dùn; ki emi ki o le dá ẹni ti ń gàn mi lohun.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ojiṣẹ aṣaaju-ọna kan sọrọ iyin nipa itẹriba ati itilẹhin onifẹẹ aya rẹ̀ fun aṣaaju-ọna àpọ́n kan. Aṣaaju-ọna àpọ́n naa lero pe ọ̀rẹ́ ounìbá ti sọ ohun kan nipa awọn animọ miiran nipa aya rẹ̀. Ṣugbọn ni ọpọ ọdun lẹhin naa, nigba ti aṣaaju-ọna àpọ́n naa funraarẹ gbeyawo, ó mọ bi itilẹhin onifẹẹ lati ọ̀dọ̀ aya ṣe jẹ́ eyi ti o ṣe koko tó fun ayọ̀ lọ́kọláya.
b Lẹhin ọpọlọpọ adura ati ikẹkọọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Joseph Rutherford rí èsì ti oun nilati fifun awọn ará ni Germany kedere. Kìí ṣe tirẹ̀ lati sọ fun wọn ohun ti wọn nilati ṣe tabi nilati ma ṣe. Wọn ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun eyi ti o sọ fun wọn ni kedere ohun ti wọn nilati ṣe niti pipadepọ ati jijẹrii. Nitori naa awọn ará ni Germany ń ṣiṣẹ labẹlẹ ṣugbọn wọn ń baa lọ ni ṣiṣegbọran si awọn ofin Jehofa lati padepọ ati lati jẹrii nipa orukọ ati Ijọba rẹ̀.
Awọn Ibeere Atunyẹwo
◻ Awọn ọkunrin wo ni Ọlọrun ti lò gẹgẹ bi ipa-ọna ibanisọrọpọ, ki sì ni awọn iranṣẹ rẹ̀ jẹ wọn ni gbese rẹ̀?
◻ Ninu oniruuru ipo-ibatan wo ni ọ̀ràn ti kan itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun?
◻ Awọn animọ wo ni yoo ràn wá lọwọ lati fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn?
◻ Itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun ń yọrisi awọn ibukun wo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ọlọrun lo eto-ajọ tẹmpili Jerusalemu lati ta àtaré ifẹ-inu rẹ̀ si awọn eniyan rẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Awọn agbegbe ti a ti lè fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun han