ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 2/1 ojú ìwé 9-14
  • Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun—Eeṣe ati Lati Ọwọ́ Ta Bi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun—Eeṣe ati Lati Ọwọ́ Ta Bi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Idi Ti A Fi Jẹ Jehofa Ọlọrun ni Gbèsè Itẹriba
  • Jesu Kristi, Apẹẹrẹ Pipe ti Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun
  • Awọn Apẹẹrẹ Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun Igbaani
  • Apẹẹrẹ Itẹriba Paulu
  • Ọhun ti Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun Ń Beere Lọwọ Wa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àǹfààní Tá À Ń Rí Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Darí Wa
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìtẹríba Aya—Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí?
    Jí!—1996
  • Ki Ni Itẹriba Ninu Igbeyawo Tumọsi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 2/1 ojú ìwé 9-14

Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun—Eeṣe ati Lati Ọwọ́ Ta Bi?

“Oluwa! Emi mọ pe, ọ̀nà eniyan kò si ni ipa araarẹ: kò sí ni ipá eniyan ti ń rin, lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀.”—JEREMIAH 10:23.

1. Iru idadurolominira wo ni a ti kà si iyebiye ni gbogbogboo?

LÁRA eyi ti o gba afiyesi julọ ninu iwe   akọsilẹ eniyan ni Ipolongo Isọdomini   ra, nipasẹ eyi ti awọn ilẹ 13 ni Ariwa America tí Britain ń gbókèèrè ṣakoso lé lori ni ọrundun kejidinlogun polongo isọdominira wọn kuro lọwọ orilẹ-ede ti n jọba lé wọn lori, Britain. Wọn fẹ́ ominira, isọdominira kuro lọwọ iṣakoso okeere ati ominira sì ń rìn ni ifẹgbẹkẹgbẹ. Isọdominira ti oṣelu ati ti ọrọ-aje lè jẹ anfaani kan ti o ga. Ni awọn akoko ẹnu aipẹ yii awọn ilẹ iha Ila-oorun Europe melookan ti sún siwaju siha isọdominira nipa ti oṣelu. Bi o ti wu ki o ri, a gbọdọ gbà pe ni awọn ilẹ wọnyẹn iru isọdominira bẹẹ ti mu ọpọlọpọ iṣoro lilagbara lọwọ pẹlu rẹ̀.

2, 3. (a) Iru idadurolominira wo ni a kò nifẹẹ si? (b) Bawo ni a ṣe fi otitọ yii hàn niti gidi?

2 Bi oriṣiriṣi isọdominira ṣe jẹ eyi ti a nifẹẹ sí tó, iru isọdominira kan wà ti a kò nifẹẹ sí. Èwo niyẹn? Ominira kuro lọwọ Oluṣẹda eniyan, Jehofa Ọlọrun. Iyẹn kìí ṣe ibukun ṣugbọn ègún kan. Eeṣe? Nitori pe eniyan ni a kò dá lae lati gbegbeesẹ pẹlu ominira kuro lọdọ Oluṣẹda rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ̀ wolii Jeremiah ti a ṣayan loke yii ṣe fihàn lọna ṣíṣewẹ́kú. Ni èdè miiran, eniyan ni a dá lati wà ni itẹriba fun Oluṣẹda rẹ̀. Lati wà ni itẹriba fun Ẹlẹdaa wa tumọsi lati jẹ́ onigbọran sí i.

3 Otitọ yẹn ni a fi taratara mú ki o ṣe kedere si tọkọtaya eniyan akọkọ nipasẹ àṣẹ Jehofa fun wọn gẹgẹ bi a ṣe ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Genesisi 2:16, 17 pe: “Ninu gbogbo igi ọgbà ni ki iwọ ki ó maa jẹ: ṣugbọn ninu igi ìmọ̀ rere ati buburu nì, iwọ kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀: nitori pe ni ọjọ ti iwọ bá jẹ ninu rẹ̀ kiku ni iwọ ó ku.” Kíkọ̀ lati wà ni itẹriba fun Oluṣẹda rẹ̀ mu ẹṣẹ, ijiya, ati iku wa fun Adamu ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀.—Genesisi 3:19; Romu 5:12.

4, 5. (a) Ki ni o ti jẹ jade lati inu kíkọ̀ ti eniyan kọ̀ lati wà ni itẹriba si Ọlọrun? (b) Ofin iwarere wo ni kò ṣe e yẹra fun?

4 Kíkọ̀ ti ẹ̀dá eniyan kọ̀ lati wà ni itẹriba si Ọlọrun wa jẹ alaibọgbọnmu ati alaitọna niti iwarere bakan naa. Ninu ayé o ti yọrisi ailofin, iwa-ọdaran, iwa-ipa, ati iwa-palapala ibalopọ takọtabo ti ó gbodekan pẹlu awọn eso rẹ̀ ti awọn àrùn tí ibalopọ takọtabo ń tankalẹ. Yatọ si iyẹn, ìyọnu iwa-ọdaran awọn majeṣin ode-oni ti o gbodekan kọ́ ni a ṣokunfa ni pataki nitori kíkọ̀ ti awọn èwe kọ̀ lati wà ni itẹriba si Jehofa, ati si awọn òbí wọn ati si awọn ofin ilẹ bakan naa bi? Ẹmi idadurolominira yii ni a ri ninu ọ̀nà aibojumu ati ọ̀nà yẹpẹrẹ ti ọpọlọpọ eniyan ń gbà mura ati ninu awọn èdè ọ̀bùn ti wọn ń lò.

5 Ṣugbọn kò si ẹni ti o lè jajabọ kuro ninu ofin iwarere alaiṣeeyipada ti Ẹlẹdaa pe: “Ki a maṣe tàn yin jẹ; a kò lè gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan bá funrugbin, oun ni yoo sì ká. Nitori ti ẹni ti o bá funrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yoo ká idibajẹ.”—Galatia 6:7, 8.

6, 7. Ki ni gbongbo okunfa kíkọ̀ lati wà ni itẹriba, gẹgẹ bi a ti rii lati inu awọn apẹẹrẹ wo?

6 Ki ni gbongbo okunfa gbogbo kíkọ̀ lati wà ni itẹriba yii? Ki a sọ ọ lọna ti o rọrùn, imọtara-ẹni-nikan ati igberaga ni. Idi niyẹn ti Efa, obinrin akọkọ, fi jẹ ki ejo naa tan oun jẹ ti o si nipin-in ninu eso ti a kaleewọ naa. Ki a sọ pe oun ti jẹ́ ẹni ti o mọ ẹ̀tọ́ rẹ̀ ti o sì ni irẹlẹ ni, idẹwo naa lati dabi Ọlọrun—ni pipinnu fun araarẹ ohun ti o dara ati ohun ti o buru—ni kì yoo ti fà á lọkan mọra. Ki a sì sọ pe oun kìí ṣe onimọtara-ẹni-nikan ni, oun kì yoo ti fẹ ohun kan ti Oluṣẹda rẹ̀, Jehofa Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kà leewọ.—Genesisi 2:16, 17.

7 Laipẹ lẹhin isubu Adamu ati Efa, igberaga ati imọtara-ẹni-nikan sún Kaini lati pa arakunrin rẹ̀ Abeli. Bakan naa, imọtara-ẹni-nikan sún awọn angẹli kan lati gbegbeesẹ lọna idadurolominira, ni fifi ipo ipilẹṣẹ wọn silẹ ti wọn sì gbé ara eniyan wọ̀ ki wọn baa lè jadùn awọn igbadun ifẹkufẹẹ-ara. Igberaga ati imọtara-ẹni-nikan sún Nimrodu ó sì ti sami si eyi ti o pọ julọ ninu awọn oluṣakoso ayé lati ìgbà rẹ̀ wa.—Genesisi 3:6, 7; 4:6-8; 1 Johannu 3:12; Juda 6.

Idi Ti A Fi Jẹ Jehofa Ọlọrun ni Gbèsè Itẹriba

8-11. Ki ni awọn idi lilagbara mẹrin fun lilo itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun wa?

8 Eeṣe ti a fi jẹ Oluṣẹda wa, Jehofa Ọlọrun, ni gbese itẹriba? Lakọọkọ ná nitori pe oun jẹ́ Ọba-alaṣẹ Agbaye. Gbogbo ọla-aṣẹ fi ẹ̀tọ́ jẹ́ tirẹ̀. Oun ni Onidaajọ, Afunnilofin, ati Ọba wa. (Isaiah 33:22) A sì kọ ọ́ daradara nipa rẹ̀ pe: “Ohun gbogbo ni o wà nihooho ti a si ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹni ti awa ni iba lo.”—Heberu 4:13.

9 Siwaju sii, niwọn bi Oluṣẹda wa ti jẹ alagbara gbogbo, kò si ẹni ti ó lè fi aṣeyọrisirere takò ó; kò si ẹni ti o lè ṣaika iṣẹ-aigbọdọmaṣe rẹ̀ si lati wa ni itẹriba fun Un. Laipẹ laijinna, gbogbo awọn ti wọn kọ̀ jalẹ ni a o parun gẹgẹ bii Farao igbaani ati gẹgẹ bi yoo ṣe ṣẹlẹ si Satani Eṣu ni akoko ti o wọ̀ ni oju Ọlọrun.—Orin Dafidi 136:1, 11-15; Ìfihàn 11:17; 20:10, 14.

10 Itẹriba jẹ iṣẹ-aigbọdọmaṣe gbogbo ẹ̀dá ọlọgbọnloye nitori pe wọn walaaye fun ète ṣiṣiṣẹsin Oluṣẹda wọn. Ìfihàn 4:11 polongo pe: “Oluwa, iwọ ni ó yẹ lati gba ògo ati ọlá ati agbara: Nitori pe iwọ ni o dá ohun gbogbo, ati nitori ifẹ-inu rẹ ni wọn fi wà ti a sì dá wọn.” Oun ni Amọ̀kòkò Titobijulọ, oun sì ń sọ eniyan di ohun-eelo lati ṣiṣẹsin fun ète rẹ̀.—Isaiah 29:16; 64:8.

11 A kò gbọdọ gbojufo otitọ naa dá pe Oluṣẹda wa jẹ ọlọgbọn gbogbo, nitori naa ó mọ ohun ti o dara julọ fun wa. (Romu 11:33) Awọn ofin rẹ̀ jẹ́ ‘fun ire wa.’ (Deuteronomi 10:12, 13) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, “Ọlọrun jẹ́ ifẹ,” nitori naa oun fẹ́ kiki ohun ti o dara julọ fun wa. Ẹ wo iye awọn idi ti ń fagbaramuni ti a ní fun wíwà ni itẹriba si Oluṣẹda wa, Jehofa Ọlọrun!—1 Johannu 4:8, NW.

Jesu Kristi, Apẹẹrẹ Pipe ti Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun

12, 13. (a) Bawo ni Jesu Kristi ṣe fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn? (b) Awọn ọ̀rọ̀ Jesu wo ni o fi iṣarasihuwa onitẹriba rẹ̀ han?

12 Laisi tabi-tabi, Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo ti Jehofa, Jesu Kristi, fun wa ni apẹẹrẹ pípé nipa itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun. Aposteli Paulu ṣalaye eyi ninu Filippi 2:6-8, (NW) pe: “[Jesu], bi o tilẹ wà ni irisi Ọlọrun, kò fi iṣaro kankan fun ìjá-nǹkan-gbà, eyiini pe, oun nilati bá Ọlọrun dọgba. Bẹẹkọ, ṣugbọn ó sọ araarẹ dòfo ó sì mú irisi ẹrú ó sì wà ní jíjọ awọn eniyan. Ju eyiini lọ, nigba ti o rí araarẹ ni àwọ̀ ẹ̀dá eniyan, ó rẹ araarẹ silẹ [siwaju sii] ó sì di onigbọran titi de oju iku, bẹẹni, iku lori òpó-igi idaloro.” Nigba ti ó wà lori ilẹ̀-ayé, Jesu sọ leralera pe oun kò ṣe ohun kan lati inu atinuda ti oun funra oun; oun kò gbegbeesẹ lọna idadurolominira, ṣugbọn o maa ń wà ni itẹriba sí Baba rẹ̀ ọrun ní gbogbo ìgbà.

13 A kà ninu Johannu 5:19, 30 pe: “Nigba naa ni Jesu dahun, o sì wi fun wọn pe, Loootọ, loootọ ni mo wi fun yin, Ọmọ kò lè ṣe ohunkohun fun araarẹ, bikoṣe ohun ti o bá ri pe Baba ń ṣe: nitori ohunkohun ti o bá ń ṣe, wọnyi ni Ọmọ sì ń ṣe bẹẹ gẹgẹ. Emi kò lè ṣe ohun kan fun araami: bi mo ti ń gbọ́, mo ń dajọ: òdodo sì ni idajọ mi; nitori emi kò wá ifẹ ti emi tikaraami, bikoṣe ifẹ ti ẹni ti o rán mi.” Bẹ gẹgẹ, o gbadura leralera ni alẹ́ ọjọ ti a dà á pe: “Ki [ó] má ṣe bi emi ti ń fẹ́, bikoṣe bi iwọ ti fẹ.”—Matteu 26:39, 42, 44; tun wo Johannu 7:28; 8:28; 42.

Awọn Apẹẹrẹ Itẹriba Oniwa-bi-Ọlọrun Igbaani

14. Ni awọn ọ̀nà wo ni Noa gbà fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn?

14 Lára awọn apẹẹrẹ itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun ti eniyan ni akọkọbẹrẹ ni Noa wà. O fi itẹriba rẹ̀ hàn ni ọ̀nà mẹta. Lakọọkọ, nipa jíjẹ́ ọkunrin olododo, alailaleebu laaarin awọn alajọgbaye rẹ̀, ni ririn pẹlu Ọlọrun otitọ naa. (Genesisi 6:9) Lẹẹkeji, nipa kikan ọkọ̀ arki. “Bẹẹ ni Noa sì ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Ọlọrun paṣẹ fun un.” (Genesisi 6:22) Ẹẹkẹta, nipa kikede ikilọ Ikun-omi ti ń bọ̀ gẹgẹ bi “oniwaasu òdodo.”—2 Peteru 2:5.

15, 16. (a) Apẹẹrẹ didara wo ni Abrahamu fi lélẹ̀ ninu itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun? (b) Bawo ni Sara ṣe fi itẹriba hàn?

15 Abrahamu jẹ apẹẹrẹ titayọ miiran niti itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun. O fi itẹriba hàn nipa ṣiṣegbọran si ofin Ọlọrun pe: “Jade kuro ni ilẹ rẹ.” (Genesisi 12:1) Iyẹn tumọsi fifi ayika rẹ̀ onidẹra ni Uri silẹ (eyi ti kìí ṣe ilu-nla alainilaari kan, gẹgẹ bi a ṣe tọka rẹ̀ nipa awọn awari iwalẹpitan) lati rin kaakiri gẹgẹ bii darandaran alarinkiri ni ilẹ ajeji fun ọgọrun-un ọdun. Ni pataki julọ ni Abrahamu fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn nipa kikoju idanwo nla naa ti mimuratan lati fi ọmọkunrin rẹ̀ Isaaki lélẹ̀ gẹgẹ bi ẹbọ.—Genesisi 22:1-12.

16 Aya Abrahamu, Sara, fun wa ni apẹẹrẹ itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun didara miiran. Ririn kaakiri ni ilẹ ajeji kan laisi iyemeji ni ọpọlọpọ aibarade ninu, ṣugbọn kò si ibi kankan ti a ti kà nipa rẹ̀ pe o ṣaroye. O fi apẹẹrẹ itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun didara lélẹ̀ ni awọn ọ̀nà meji nigba ti Abrahamu fi i hàn gẹgẹ bi arabinrin rẹ̀ niwaju awọn alakooso abọriṣa. Ni ìgbà mejeeji o fọwọsowọpọ, àní bi o tilẹ jẹ pe o fẹrẹẹ di ọ̀kan ninu mẹmba awọn ẹlẹ́hàá wọn nitori eyi paapaa. Eyi ti ń jẹrii si itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun rẹ̀ ni ọ̀nà ti oun ń gbà tọka ninu araarẹ sí ọkọ rẹ̀, Abrahamu, gẹgẹ bi “oluwa mi,” ni fífihàn pe iyẹn jẹ ojulowo iṣarasihuwa ọkan-aya rẹ̀.—Genesisi 12:11-20; 18:12; 20:2-18; 1 Peteru 3:6.

17. Eeṣe ti a fi lè sọ pe Isaaki fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn?

17 Ẹ maṣe jẹ ki a gbojufo apẹẹrẹ itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun ti a fifun wa nipasẹ ọmọkunrin Abrahamu, Isaaki dá. Igbagbọ atọwọdọwọ awọn Ju fihàn pe Isaaki jẹ nǹkan bii ẹni ọdun 25 nigba ti Jehofa paṣẹ fun baba rẹ̀, Abrahamu, lati fi í lélẹ̀ gẹgẹ bi ẹbọ. Bi Isaaki bá fẹ́ ni, oun ti lè fi irọrun tako baba rẹ̀, ẹni ti o fi ọgọrun-un ọdun dagba jù ú lọ. Ṣugbọn bẹẹkọ. Bi o tilẹ jẹ pe Isaaki ṣe kayeefi nipa aisi ẹranko kan fun ẹbọ naa, oun fi ọkàn tutu juwọsilẹ fun gbigbe ti baba rẹ̀ gbé e sori pẹpẹ irubọ ti o si wá so ó tọwọ tẹsẹ lẹhin naa lati lè dènà tabi ṣakoso ihuwapada aláìmọ̀ọ́mọ̀ ṣe eyikeyii ti o ti lè ṣẹlẹ bi oun bá ti lo ọ̀bẹ idumbu naa.—Genesisi 22:7-9.

18. Bawo ni Mose ṣe fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun ti o jẹ awofiṣapẹẹrẹ hàn?

18 Ọpọ ọdun lẹhin naa, Mose fi apẹẹrẹ rere lélẹ̀ fun wa ninu itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun. Iyẹn dajudaju ni a fihàn nipa ṣiṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi ẹni ti “o ṣe ọlọkantutu ju gbogbo eniyan lọ ti ń bẹ lori ilẹ.” (Numeri 12:3) Fifi ti o fi igbọran mú àṣẹ Jehofa ṣẹ fun 40 ọdun ninu aginju, àní bi o tilẹ jẹ pe o ń ṣabojuto awọn eniyan ọlọtẹ kan ti iye wọn pọ tó million meji tabi mẹta, jẹrii siwaju sii sí itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun rẹ̀. Nipa bayii akọsilẹ naa sọ pe “bẹẹ ni Mose ṣe: Gẹgẹ bi eyi ti Oluwa palaṣẹ fun un, bẹẹ ni o ṣe.”—Eksodu 40:16.

19. Nipa awọn ọ̀rọ̀ wo ni Jobu fi itẹriba rẹ̀ fun Jehofa hàn?

19 Jobu jẹ ẹni ìtàn titayọ miiran ti o fi apẹẹrẹ titayọlọla kan lélẹ̀ fun wa ninu itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun. Lẹhin ti Jehofa ti yọnda fun Satani lati mú gbogbo ohun-ìní Jobu kuro, lati pa awọn ọmọ rẹ̀, ati lẹhin naa lati kọlù ú pẹlu “oówo kikankikan lati atẹlẹsẹ rẹ̀ lọ dé àtàrí rẹ̀,” aya Jobu sọ fun un pe: “Iwọ di iwa otitọ rẹ mú sibẹ! Bú Ọlọrun, ki o si kú.” Bi o tilẹ ri bẹẹ, Jobu fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun rẹ̀ hàn nipa sisọ fun un pe: “Iwọ sọrọ bi ọ̀kan ninu awọn obinrin alaimoye tii sọrọ; kinla! Awa o ha gba ire lọwọ Ọlọrun, ki a má sì gba ibi!” (Jobu 2:7-10) Ni fifi ẹmi-ironu ti ero-ori kan-naa hàn ni awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti a kọsilẹ ninu Jobu 13:15 pe: “Bi o tilẹ pa mi, sibẹ emi óò maa gbẹkẹle e.” Bi o tilẹ jẹ pe Jobu, niti tootọ, ni o ṣaniyan gidigidi nipa idalare oun funraarẹ, a kò gbọdọ gboju fò ó dá pe lakootan Jehofa sọ fun ọ̀kan ninu awọn ti a kà si olùtùnú rẹ̀ pe: “Mo binu si ọ ati si awọn ọ̀rẹ́ rẹ mejeeji, nitori pe ẹyin kò sọrọ niti emi, ohun ti o tọ́ bi Jobu iranṣẹ mi ti sọ.” Laiṣiyemeji, Jobu fun wa ni apẹẹrẹ itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun didara kan.—Jobu 42:7.

20. Ni awọn ọ̀nà wo ni Dafidi gbà fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn?

20 Lati mẹnukan kiki apẹẹrẹ kan sii lati inu Iwe Mimọ Lede Heberu, Dafidi wà nibẹ. Nigba ti Ọba Saulu ń dọdẹ Dafidi bi ẹni pe o jẹ́ ẹranko kan, Dafidi ni anfaani meji lati fopin si awọn iṣoro rẹ̀ nipa pipa Saulu. Sibẹ, itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun Dafidi dí i lọwọ ṣiṣe bẹẹ. Awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a kọsilẹ ni 1 Samueli 24:6 pe: “Eewọ ni fun mi lati ọ̀dọ̀ Oluwa wa bi emi bá ṣe nǹkan yii si oluwa mi, ẹni ti a ti fi ami-ororo Oluwa yan, lati nawọ mi si i, nitori pe ẹni-ami-ororo Oluwa ni.” (Tun wo 1 Samueli 26:9-11.) Oun bakan naa fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun rẹ̀ hàn nipa titẹwọgba ibawi nigba ti o bá ṣe awọn aṣiṣe tabi dẹṣẹ.—2 Samueli 12:13; 24:17; 1 Kronika 15:13.

Apẹẹrẹ Itẹriba Paulu

21-23. Ninu oniruuru awọn apẹẹrẹ wo ni aposteli Paulu gbà fi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun hàn?

21 Ninu Iwe Mimọ Kristian Lede Griki, a ni apẹẹrẹ itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun titayọ kan ninu aposteli Paulu. O ṣafarawe Ọ̀gá rẹ̀, Jesu Kristi, ninu eyi gẹgẹ bi o ti ṣe ninu awọn ọ̀ràn iṣẹ-ojiṣẹ aposteli rẹ̀ miiran. (1 Korinti 11:1) Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa Ọlọrun lò ó lọna ti o tubọ lagbara sii ju eyikeyii ninu awọn aposteli yooku lọ, Paulu kò fi idadurolominira gbegbeesẹ ri. Luku sọ fun wa pe nigba ti ibeere naa dide niti boya awọn Keferi ti a yipada ni a nilati kọla fun, “awọn arakunrin [ni Antioku] yan Paulu oun Barnaba, ati awọn miiran ninu wọn, ki wọn goke lọ si Jerusalemu, sọdọ awọn aposteli ati awọn agbaagba nitori ọ̀ràn yii.”—Iṣe 15:2.

22 Niti igbokegbodo ijihin-iṣẹ-Ọlọrun ti Paulu, a sọ fun wa ni Galatia 2:9 pe: “Ati nigba ti Jakọbu, ati Kefa, ati Johannu, awọn ẹni ti o dabi ọwọ̀n, woye ore-ọfẹ ti a fifun mi, wọn sì fi ọwọ́ ọ̀tún idapọ fun emi ati Barnaba, pe ki awa ki o maa lọ sọ̀dọ̀ awọn Keferi, ati sọdọ awọn onila.” Dipo ki o gbegbeesẹ lọna idadurolominira Paulu wá itọsọna.

23 Bakan naa, nigba ti Paulu wà ni Jerusalemu kẹhin, o tẹwọgba itọni ti a fifun un lati ọwọ́ awọn alagba nibẹ ni isopọ pẹlu lilọ si tẹmpili ati titẹle awọn ilana-iṣe ti Ofin ki gbogbo eniyan baa lè rii pe oun kìí ṣe apẹhinda kan niti Ofin Mose. Niwọn bi ṣiṣe bẹẹ rẹ̀ ti dabi ẹni pe o dopin lọna oníjàábá kan pẹlu awujọ eniyankeniyan kan ti a rusoke lodi si i, ǹjẹ́ wíwà ni itẹriba rẹ̀ si awọn alagba wọnni ha jẹ aṣiṣe kan bi? Ki a ma ri, gẹgẹ bi o ṣe hàn kedere lati inu ohun ti a kà ninu Iṣe 23:11 pe: “Ni òru ọjọ naa Oluwa duro ti i, o si wi pe, tujuka: nitori bi iwọ ti jẹrii fun mi ni Jerusalemu, bẹẹ ni iwọ kò lè ṣai jẹrii ni Romu pẹlu.”

24. Awọn apa itẹriba siwaju sii wo ni a o jiroro ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e?

24 Loootọ, Iwe Mimọ fun wa ni awọn idi lilagbara fun wíwà ni itẹriba wa ati awọn apẹẹrẹ tí ń taniji ti awọn wọnni ti wọn fi iru itẹriba bẹẹ hàn. Ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e, a o ṣagbeyẹwo awọn oniruuru ayika ninu eyi ti a ti lè wà ni itẹriba si Jehofa Ọlọrun, iranlọwọ fun ṣiṣe bẹẹ wa, ati awọn èrè ti ń jẹ jade.

Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Iru idadurolominira wo ni a kò nifẹẹ si?

◻ Ki ni gbongbo okunfa fun kíkọ̀ lati wa ni itẹriba?

◻ Fun awọn idi wo ni a fi jẹ Jehofa ni gbese itẹriba?

◻ Awọn apẹẹrẹ didara wo ni Iwe Mimọ fun wa nipa itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nimrodu, oluṣakoso ayé ti o wà ṣiwaju ìkún-omi akọkọ ti o ṣọ̀tẹ̀ lodisi itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Noa, apẹẹrẹ alailaleeebu ti itẹriba oniwa-bi-Ọlọrun.—Genesisi 6:14, 22

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́