Ẹ̀KỌ́ 65
Ẹ́sítà Gba Àwọn Èèyàn Ẹ̀ Nínú Ewu
Júù ni Ẹ́sítà, ìlú Ṣúṣánì tó wà nílẹ̀ ọba Páṣíà ló sì ń gbé. Lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Nebukadinésárì kó ìdílé Ẹ́sítà kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Mọ̀lẹ́bí Ẹ́sítà kan tó ń jẹ́ Módékáì ló sì tọ́ ọ dàgbà. Módékáì jẹ́ ìránṣẹ́ Ọba Ahasuérúsì tilẹ̀ Páṣíà.
Ọba Ahasuérúsì ń wá ayaba tuntun. Àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ mú àwọn arẹwà obìnrin tó wà nílùú náà wá fún ọba, Ẹ́sítà sì wà lára wọn. Nínú gbogbo wọn, Ẹ́sítà ni ọba yàn láti jẹ́ ayaba. Àmọ́, Módékáì sọ fún Ẹ́sítà pé kó má sọ fún ẹnikẹ́ni pé Júù lòun.
Ọkùnrin agbéraga kan tó ń jẹ́ Hámánì ni olórí àwọn ìjòyè. Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa tẹrí ba fún òun. Ṣùgbọ́n Módékáì ò ṣe bẹ́ẹ̀, torí náà, inú bí Hámánì débi pé ó fẹ́ pa á. Nígbà tí Hámánì gbọ́ pé Júù ni Módékáì, ó wá ọ̀nà láti pa gbogbo àwọn Júù tó wà nílẹ̀ náà. Hámánì sọ fún ọba pé: ‘Èèyàn burúkú ni àwọn Júù, àfi kó o pa wọ́n dànù.’ Ahasuérúsì wá sọ pé: ‘Ohun tó bá wù ẹ́ ni kó o ṣe fún wọn,’ ó sì fún Hámánì lágbára láti ṣe òfin. Hámánì wá ṣe òfin pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì. Àmọ́ Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí.
Ẹ́sítà ò gbọ́ nípa òfin yìí. Módékáì wá fi ẹ̀dà ìwé òfin náà ránṣẹ́ sí i, ó sì sọ pé: ‘Lọ bá ọba sọ̀rọ̀.’ Ẹ́sítà ní: ‘Wọ́n máa pa ẹnikẹ́ni tó bá lọ bá ọba láìjẹ́ pé ọba pè é. Ó ti tó ọgbọ̀n (30) ọjọ́ báyìí tí ọba ti pè mí kẹ́yìn! Àmọ́, mo máa lọ. Tí ọba bá na ọ̀pá àṣẹ sí mi, wọ́n ò ní pa mí. Ṣùgbọ́n tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa pa mí.’
Ẹ́sítà lọ sí ààfin ọba. Nígbà tí ọba rí i, ó na ọ̀pá àṣẹ ẹ̀ sí i. Ẹ́sítà sì wọlé lọ bá a, ọba wá béèrè pé: ‘Ẹ́sítà, kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ẹ?’ Ó dáhùn pé: ‘Mo fẹ́ kí ẹ̀yin àti Hámánì wá síbi àsè kan.’ Níbi àsè náà, Ẹ́sítà tún pè wọ́n síbi àsè míì. Níbi àsè kejì, ọba tún béèrè pé: ‘Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ẹ?’ Ẹ́sítà sọ pé: ‘Ẹnì kan fẹ́ pa èmi àtàwọn èèyàn mi. Jọ̀ọ́ gbà wá.’ Ọba béèrè pé: ‘Ta ló fẹ́ pa yín?’ Ó ní: ‘Hámánì ọkùnrin burúkú yìí ni.’ Ahasuérúsì bínú gan-an débi pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ní kí wọ́n lọ pa Hámánì.
Ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tó lè yí òfin tí Hámánì ṣe pa dà, kódà ọba pàápàá ò lè yí i pa dà. Torí náà, ọba fi Módékáì jẹ olórí àwọn ìjòyè, ó sì fún un lágbára láti ṣe òfin tuntun míì. Ó ṣòfin pé káwọn Júù gbèjà ara wọn tí wọ́n bá gbéjà kò wọ́n. Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì, àwọn Júù ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Látìgbà yẹn lọ, ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ ìṣẹ́gun náà.
“Wọ́n á . . . mú yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn àti àwọn orílẹ̀-èdè.”—Mátíù 10:18