Ẹ̀KỌ́ 82
Jésù Kọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Ẹ̀ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Gbàdúrà
Àwọn Farisí máa ń ṣe nǹkan torí káwọn èèyàn lè máa yìn wọ́n. Tí wọ́n bá ṣoore fáwọn èèyàn, ojú ayé lásán ni. Kódà, wọ́n tún máa ń gbàdúrà níta gbangba. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń há àwọn àdúrà tó gùn sórí, wọ́n á wá máa gba àdúrà yẹn sókè lójú ọ̀nà àti nínú sínágọ́gù. Ìdí nìyẹn tẹ́nu fi ya àwọn èèyàn nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má ṣe gbàdúrà bí àwọn Farisí. Wọ́n rò pé Ọlọ́run á gbọ́ àdúrà wọn torí bí wọ́n ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ tó pọ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń gbàdúrà, Jèhófà lò ń bá sọ̀rọ̀, kì í ṣe èèyàn. Má ṣe máa sọ ohun kan náà ṣáá tó o bá ń gbàdúrà. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé kó o sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ gangan.’
Jésù wá sọ pé, ‘Bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ máa gbàdúrà nìyí: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́. Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.” ’ Jésù tún sọ fún wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wọn lóúnjẹ tí wọ́n máa jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, pé kí Jèhófà dárí jì wọ́n, kó sì fún wọn láwọn nǹkan míì.
Jésù sọ pé: ‘Ẹ má ṣe dákẹ́ àdúrà. Gbogbo ìgbà ni kẹ́ ẹ máa bẹ Jèhófà Bàbá yín pé kó fún yín láwọn nǹkan rere. Gbogbo òbí ló máa ń fẹ́ fún àwọn ọmọ wọn lóhun tó dáa. Torí náà, tọ́mọ ẹ bá ní kó o fún òun ní búrẹ́dì, ṣé wàá fún un ní òkúta? Àbí tó bá ní kó o fún òun ní ẹja, ṣé wàá fún un ní ejò?’
Jésù wá sọ ẹ̀kọ́ tó fẹ́ kí wọ́n kọ́, ó ní: ‘Tẹ́ ẹ bá mọ bẹ́ ẹ ṣe ń fún àwọn ọmọ yín lẹ́bùn rere, ṣẹ́ ẹ wá rò pé Jèhófà, Bàbá yín tó wà lọ́run ò ní fún yín ní ẹ̀mí mímọ́ tẹ́ ẹ bá ní kó fún yín? Tiyín ni pé kẹ́ ẹ ṣáà ti béèrè lọ́wọ́ ẹ̀.’ Ṣó o máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù? Àwọn nǹkan wo lo máa ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣe fún ẹ?
“Ẹ máa béèrè, a sì máa fún yín; ẹ máa wá kiri, ẹ sì máa rí; ẹ máa kan ilẹ̀kùn, a sì máa ṣí i fún yín.”—Mátíù 7:7