Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 11
Apá yìí dá lórí ìtàn tó bẹ̀rẹ̀ láti Mátíù dé Ìfihàn. Inú ìdílé kan tí ò lówó ni wọ́n bí Jésù sí. Inú abúlé kékeré kan sì ni wọ́n ń gbé. Ó bá bàbá rẹ̀ ṣe iṣẹ́ káfíńtà. Jésù lẹni tó máa gba aráyé là. Jèhófà ti yàn án láti jẹ́ Ọba Ìjọba ọ̀run. Tó o bá jẹ́ òbí, ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ láti mọyì bí Jèhófà ṣe fara balẹ̀ yan irú ìdílé àti àyíká tí Jésù máa dàgbà sí. Tún ṣàyẹ̀wò bí Jèhófà ṣe dáàbò bo Jésù lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù tó fẹ́ pa á àti bí kò ṣe sí ohunkóhun tó lè dá iṣẹ́ Jèhófà dúró. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe yan Jòhánù láti múra ọ̀nà sílẹ̀ fún Jésù. Tẹnu mọ́ bí Jésù ṣe fi hàn pé àti kékeré lòun ti fẹ́ràn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà.