Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 13
Jésù wá sáyé kó lè kú nítorí àwa èèyàn aláìpé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù kú, ó ṣẹ́gun ayé. Jèhófà ò fi Jésù sílẹ̀, torí náà ó jí i dìde. Jálẹ̀ ìgbésí ayé Jésù, ó máa ń ran àwọn míì lọ́wọ́, ó sì máa ń dárí ji àwọn èèyàn tí wọ́n bá ṣe àṣìṣe. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó sì kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ pàtàkì tó fún wọn. Tó o bá jẹ́ òbí, ran ọmọ ẹ lọ́wọ́ kó lè mọ̀ pé àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe nínú iṣẹ́ yẹn lónìí.