ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sjj orin 152
  • Ilé Tó Máa Mú Ìyìn Wá Bá Ọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ilé Tó Máa Mú Ìyìn Wá Bá Ọ
  • “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Yin Jèhófà, Ọlọ́run Wa!
    Kọrin sí Jèhófà
  • Ẹ Yin Jèhófà Ọlọ́run Wa!
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Jẹ́ Ká Jọ Kọ Orin Ìjọba Náà
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Dara Pọ̀ Nínú Kíkọ Orin Ìjọba Náà!
    Kọrin sí Jèhófà
Àwọn Míì
“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
sjj orin 152

ORIN 152

Ilé Tó Máa Mú Ìyìn Wá Bá Ọ

Bíi Ti Orí Ìwé

(1 Àwọn Ọba 8:27; 1 Kíróníkà 29:14)

  1. 1. Jèhófà, ìwọ lo dá ọ̀run,

    Síbẹ̀, ọ̀run kò lè gbà ọ́.

    Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ilé yìí,

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kẹ́mìí rẹ wà níbí.

    Àwa tí a jẹ́ ènìyàn rẹ

    Ti kọ́ ibi ìjọsìn yìí.

    Ìjọsìn rẹ ń mú inú wa dùn;

    Jọ̀ọ́, tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.

    (ÀSOPỌ̀)

    Ìwọ náà lo fún wa

    Ní gbogbo ohun tá a ní.

    Inú ohun tó o fún wa

    La ti ń fún ọ, Bàbá.

    (ÈGBÈ)

    A dúpẹ́ fún gbogbo ‘hun tó o ṣe,

    Jèhófà, à ń kọrin yìn ọ́.

    O ti jẹ́ ká lè kọ́ ilé yìí

    Tó máa mú ìyìn wá bá ọ.

  2. 2. O mọ̀ pé a fẹ́ kọ́ ilé kan

    Tó máa mú ìyìn wá bá ọ,

    Tó máa ṣèrànwọ́ fẹ́gbẹ́ ará,

    Táá sì ran àwọn míì lọ́wọ́.

    A ti kọ́ ilé náà tán báyìí.

    Iṣẹ́ ṣì pọ̀ gan-an láti ṣe.

    Ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣiṣẹ́ tí

    Ọmọ rẹ gbé lé wa lọ́wọ́.

    (ÀSOPỌ̀)

    A fi àkókò wa

    Àti ohun ìní wa

    Bọlá fún ọ torí pé

    Ìwọ nìkan ló yẹ.

    (ÈGBÈ)

    A dúpẹ́ fún gbogbo ‘hun tó o ṣe,

    Jèhófà, à ń kọrin yìn ọ́.

    O ti jẹ́ ká lè kọ́ ilé yìí

    Tó máa mú ìyìn wá bá ọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́