ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 3
  • Jẹ́ Onínúure

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Onínúure
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jésù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
  • Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Jẹ́ Kí “Òfin Inú Rere” Máa Darí Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Bí a Ṣe Lè Máa Finú Rere Hàn Nínú Ayé Oníwà Òǹrorò Yìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Mú Inu Jehofa Dùn Nipa Fifi Inurere Hàn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 3

BÁ A ṢE LÈ BẸ̀RẸ̀ Ọ̀RỌ̀ WA

Jésù rọra ń fọwọ́ kan ọkùnrin kan tí kò ríran kó lè la ojú ẹ̀.

Jòh. 9:1-7

Ẹ̀KỌ́ 3

Jẹ́ Onínúure

Ìlànà: “Ìfẹ́ máa ń ní . . . inú rere.”—1 Kọ́r. 13:4.

Ohun Tí Jésù Ṣe

Jésù rọra ń fọwọ́ kan ọkùnrin kan tí kò ríran kó lè la ojú ẹ̀.

FÍDÍÒ: Jésù La Ojú Ọkùnrin Kan Tí Kò Ríran

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Jòhánù 9:1-7. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Ṣé Jésù kọ́kọ́ la ojú ọkùnrin náà ni àbí ó kọ́kọ́ wàásù fún un?—Wo Jòhánù 9:35-38.

  2. Kí lo rò pé ó mú kó wu ọkùnrin náà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Tá a bá ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹni tá à ń wàásù fún, ó máa wù ú láti gbọ́rọ̀ wa.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Máa fọ̀rọ̀ ro ara ẹ wò. Gbìyànjú láti mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹni tó o fẹ́ wàásù fún.

  1. Bi ara ẹ pé: ‘Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro ẹni náà? Kí ni mo lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́ kára lè tù ú?’ Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè fi inú rere hàn sí i látọkàn wá.

  2. Tẹ́nì kan bá sọ ìṣòro ẹ̀ fún ẹ tàbí tó sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀, má bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa nǹkan míì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun.

4. Máa sọ̀rọ̀ tó dáa lẹ́nu. Tí àánú ẹnì kan bá ń ṣe ẹ́ tó o sì fẹ́ ràn án lọ́wọ́, ó máa hàn nínú bó o ṣe ń bá a sọ̀rọ̀. Ronú dáadáa nípa nǹkan tó o fẹ́ sọ àti bó o ṣe máa sọ ọ́, má sì sọ̀rọ̀ tó lè bí i nínú.

5. Máa ṣoore. Tó o bá rí i pé ẹnì kan nílò ìrànlọ́wọ́, gbìyànjú kó o ràn án lọ́wọ́. Tá a bá fi inú rere hàn sáwọn èèyàn, ó lè mú kó wù wọ́n láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.

TÚN WO

Róòmù 12:15, 16; Gál. 6:10; Héb. 13:16

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́