A Késí Ọ Si Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùfẹ́ Òmìnira”
LATI November 1989, koko ẹkọ nipa ominira ni a ti mu ki o tayọ ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Awọn eniyan ilẹ orilẹ-ede ìlà-oòrùn Europe ni pataki ti ngbadun ominira ti oṣelu si i ju bi wọn ti gbadun rẹ̀ fun 40 ọdun ati jù bẹẹ lọ sẹhin.
Ṣugbọn ominira kan wà ti o ṣe pataki pupọpupọ ju ominira ti oṣelu eyikeyii. Awa le ka nipa rẹ̀ ninu Ọrọ Ọlọrun, Bibeli. Jesu Kristi sọ lẹẹkan rí pe: “Ẹ ó sì mọ otitọ, otitọ yoo si sọ yin di ominira.” (Johanu 8:32) Bẹẹni, awọn Kristẹni ti wọn ti ṣe ìyàsímímọ́ ni a ti dásílẹ̀ lominira kuro lọwọ ìbẹ̀rù eniyan ati kuro ninu òǹdè si ẹṣẹ ati iku, gẹgẹ bi a ti ka ni Roomu 6:18, 22. Awa tun ka pe “nibi ti ẹmi Jehofa bá wà, ominira wà nibẹ.” (2 Kọrinti 3:17, NW) Nitootọ, Ọrọ Ọlọrun nawọ ìfojúsọ́nà ti o kun fun ireti jade “pe iṣẹda funraarẹ ni a o tusilẹ kuro lọwọ isọdẹru si ìdibàjẹ́ wọn o si ni ogo ominira ti awọn ọmọ Ọlọrun.”—Roomu 8:21, NW.
Bi ẹnikẹni ba fẹ lati jere ominira Kristẹni ni akoko isinsinyi, oun gbọdọ ṣe isapa gidi. Kì í ṣe ọran wiwulẹ tẹ̀lé ipa-ọna rirọrun julọ rara. Lati maa baa lọ lati gbadun ominira yii si nbeere afikun isapa, loju-iwoye awọn ipá ti wọn nitẹsi lati jà wá lólè ominira yẹn: Satani Eṣu, Aye buburu rẹ, ati awọn ìtẹ̀sí tiwa funraawa ti o kun fun ẹṣẹ ti a jogún. Jehofa Ọlọrun ti pese iranlọwọ nipasẹ Ọrọ rẹ ti a mísí, nipasẹ ẹmi mimọ rẹ̀, ati nipasẹ eto-ajọ rẹ̀ ti a le foju rí.—Luuku 11:13.
Lati ran gbogbo awọn olufẹ ominira lọwọ lati fokun fun ominira ti o ti tẹ̀ wọn lọwọ, apejọpọ agbegbe ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ọdun yii bojuto ẹṣin-ọrọ naa “Awọn Olùfẹ́ Òmìnira” lọna ti o yẹ. Apejọpọ wọnyi yoo jẹ ọlọjọ mẹta ni gigun, ti yoo bẹrẹ ni owurọ ọjọ Friday ni 9.30 yoo sì maa baa lọ titi di 4.00 irọlẹ ọjọ Sunday. Gbogbo awọn ti wọn bá wá sibi awọn apejọpọ wọnyi ni a o tù lara nipa tẹmi ti a o si gbero nipa awọn àwíyé arunisoke, awọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò gbigbadunmọni, awọn aṣefihan gbigbeṣẹ, ati àwòkẹ́kọ̀ọ́ ti a gbekari Bibeli; bẹẹ ni awa ko nilati gbojufo awọn ayọ ti ibakẹgbẹ amọkanyọ pẹlu awọn ọrẹ atijọ ati titun, igbadun didarapọ pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun awọn miiran ninu kikọ orin Ijọba wa, ati ṣiṣajọpin ninu awọn adura atọkanwa itagbangba.
Njẹ ki gbogbo awọn iranṣẹ Jehofa ti o ti ṣèyàsímímọ́ maṣe jẹ ki ohunkohun dí wọn lọwọ lati wà lárọ̀ọ́wọ́tó ni owurọ ọjọ Friday nigba ti apejọpọ yii yoo bẹrẹ. Ki o si rii daju pe o wá kii ṣe pẹlu Bibeli ati iwe orin nikan ṣugbọn ki o tun mú kalamu ati iwe lọwọ lati ṣe akọsilẹ. Tun wa pẹlu imọlara àìní rẹ nipa tẹmi gẹgẹ bi apakan awọn eniyan olominira.—Matiu 5:3.
Awọn Ọgangan Ibi Apejọpọ Agbegbe 1991
November 8-10, 1991
IKOT AKAN 1 (Efik)
MGBOKO UMUORIA 1 (Igbo)
OTTA 1 (Gẹẹsi)
OYEDE 1 (Isoko)
ULI 1 (Igbo)
November 15-17, 1991
AKURE 1 (Yoruba)
IKOT AKAN 2 (Efik)
KADUNA (Gẹẹsi, Yoruba)
MGBOKO UMUORIA 2 (Igbo)
OTTA 2 (Yoruba)
OYEDE 2 (Isoko)
ULI 2 (Igbo)
November 22-24, 1991
AKURE 2 (Yoruba)
JOS (Gẹẹsi, Hausa)
MGBOKO UMUORIA 3 (Gẹẹsi)
OTTA 3 (Gẹẹsi)
ULI 3 (Igbo)
December 6-8, 1991
AKURE 3 (Yoruba)
BADAGRY (Gun)
IBADAN 1 (Yoruba)
IGWURUTA ALI 1 (Gẹẹsi, Ikwerre)
IKOT EKPENE 1 (Efik)
MGBOKO UMUORIA 4 (Igbo)
OTTA 4 (Yoruba)
ULI 4 (Igbo)
December 13-15, 1991
AKURE 4 (Gẹẹsi)
BENIN CITY 1 (Edo, Owan)
CALABAR 1 (Efik)
IBADAN 2 (Yoruba)
IGWURUTA ALI 2 (Gẹẹsi)
IKOT EKPENE 2 (Efik)
ILESHA 1 (Yoruba)
MGBOKO UMUORIA 5 (Igbo)
OTTA 5 (Gẹẹsi)
UBOGO 1 (Gẹẹsi, Okpe)
ULI 5 (Igbo)
UYO 1 (Gẹẹsi)
December 20-22, 1991
AGBOR 1 (Kwale, Aniocha)
BENIN CITY 2 (Edo, Ishan)
CALABAR 2 (Efik)
IBADAN 3 (Gẹẹsi)
IGWURUTA ALI 3 (Abua, Ogoni)
IKOT EKPENE 3 (Efik)
ILESHA 2 (Yoruba)
MGBOKO UMUORIA 6 (Igbo)
OK1TIPUPA 1 (Yoruba)
OTTA 6 (Yoruba)
UBOGO 2 (Ijaw, Itsekiri)
ULI 6 (Gẹẹsi)
UYO 2 (Efik)
January 3-5, 1992
AGBOR 2 (Gẹẹsi, Ika)
BENIN CITY 3 (Gẹẹsi)
CALABAR 3 (Gẹẹsi)
ILESHA 3 (Yoruba)
KATSINA ALA (Gẹẹsi, Tiv)
MGBOKO UMUORIA 7 (Igbo)
OKITIPUPA 2 (Yoruba)
OTTA 7 (Gẹẹsi)
UBOGO 3 (Urhobo)
ULI 7 (Igbo)
UYO 3 (Efik)
January 10-12, 1992
BENIN CITY 4 (Gẹẹsi)
MGBOKO UMUORIA 8 (Igbo)
OTTA 8 (Yoruba)
UBOGO 4 (Urhobo)
UYO 4 (Efik)
January 17-19, 1992
OTTA 9 (Yoruba)