Ẹ Kaabọ si Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀”
EYI akọkọ gan-an ninu awọn ọjọ iṣẹda ri ìṣẹ̀dá ìmọ́lẹ̀ ti ori ilẹ-aye. A kà pe Jehofa Ọlọrun sọ pe: “Ki ìmọ́lẹ̀ ki ó wà: ìmọ́lẹ̀ si wà.” (Jẹnẹsisi 1:3) Iyẹn ṣọkan délẹ̀ pẹlu ohun ti apọsiteli Johanu kọwe rẹ̀ pe: “Ọlọrun jẹ́ ìmọ́lẹ̀ kò sì sí okunkun rárá ni irẹpọ pẹlu rẹ̀.”—1 Johanu 1:5, NW.
Niwọn bi Ọmọkunrin Ọlọrun ti wà ni irẹpọ pẹlu Baba rẹ̀, kò yanilẹnu pe Jesu sọ nigba kan ri pe: “Emi ni imọlẹ ayé.” (Johanu 9:5) A lè jade kuro ninu okunkun ki a sì wá sinu ìmọ́lẹ̀ nipa lilo igbagbọ ninu Jehofa Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀. Jesu tun jẹrii sii pe: “Emi ni ìmọ́lẹ̀ ti o wá sí ayé, ki ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́ ki o maṣe wà ni okunkun.” (Johanu 12:46) Lọna ti o tọna, nigba naa, Jesu Kristi sọ nipa awọn ọmọlẹhin rẹ̀ tootọ pe: “Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. . . . Ẹ jẹ ki ìmọ́lẹ̀ yin ki o mọ́lẹ̀ tobẹẹ niwaju eniyan, ki wọn ki o lè maa ri iṣẹ rere yin, ki wọn ki o lè maa yin Baba yin ti ń bẹ ni ọrun logo.”—Matiu 5:14, 16.
Ibukun wo ni o jẹ lati ni otitọ, òye Ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi a ṣe mu un ṣe kedere nipasẹ “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu”! (Matiu 24:45-47, NW) A kò dà wá laamu mọ nipa igbagbọ ninu Mẹtalọkan; a kò pin wá lẹ́mìí mọ niti idi ti Ọlọrun olodumare ati onifẹẹ fi yọnda iwa buburu ati iwa ipa; a kò sí ninu iyemeji mọ niti ipo awọn oku. Ìmọ́lẹ̀ ti fun wa ni ireti, ireti Ijọba naa. Ó ti ṣi ohun ti Ọlọrun iyanu Ẹlẹdaa jẹ́ paya fun wa. Ìmọ́lẹ̀ otitọ ti fun wa ni ète ninu igbesi-aye, lati ṣiṣẹsin fun ète ti a titori rẹ̀ dá wa lakọọkọ, lati fogo fun Olùṣẹ̀dá wa, Jehofa Ọlọrun. Eyi ni a ń ṣe nipa jíjẹ́ olùtan ìmọ́lẹ̀. Jíjẹ́ olùtan ìmọ́lẹ̀ jẹ́ ọla ati anfaani ńláǹlà, ṣugbọn ó tun jẹ ẹru-iṣẹ wiwuwo kan. Lati mú iṣẹ-aigbọdọmaṣe yẹn ṣẹ, a nilati lo gbogbo iranlọwọ ti Jehofa pese. Nitori naa bawo ni o ti ṣe wẹku tó pe ki a pe awọn apejọpọ agbegbe wa ti 1992 ni Apejọpọ Agbegbe “Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀”!
Lati mu ijafafa wa ati imọriri ipa ti a ń kó gẹgẹ bi awọn olùtan ìmọ́lẹ̀ sunwọn sii, awa yoo fẹ́ lati lọ si ó keretan ọ̀kan lara awọn apejọpọ wọnyi, ki a wà nibẹ fun orin ibẹrẹ ki a sì duro titi di ìgbà adura ipari. Awa yoo fẹ lati fi afiyesi kínníkínní si gbogbo ohun ti a sọ lori pepele, ìbáà jẹ́ ninu ọrọ-asọye, ifọrọwanilẹnuwo, iriri, tabi awokẹkọọ. Kì í ṣe pe kikọ akọsilẹ fun wa ní ohun kan lati tọka si nigba ti o bá yá lati mu wa ranti nikan ni ṣugbọn ó tun ń ràn wa lọwọ gidigidi lati pa afiyesi pọ sori ohun ti a ń gbekalẹ. Bẹẹni, gbogbo wa lakooko itolẹsẹẹsẹ apejọpọ naa, yoo fẹ́ lati ‘fi iyè gidigidi si bi a ṣe ń fetisilẹ.’—Luuku 8:18, NW.
Awọn Ọgangan Ibi Apejọpọ Agbegbe 1992
NOVEMBER 6-8, 1992
AKURE 1 (Yoruba)
BENIN CITY 1 (Edo)
KADUNA (Gẹẹsi, Yoruba)
MGBOKO UMUORIA 1 (Igbo)
OTTA 1 (Yoruba)
ULI 1 (Igbo)
NOVEMBER 13-15, 1992
AKURE 2 (Yoruba)
BENIN CITY 2 (Gẹẹsi, Owan)
IGWURUTA ALI 1 (Abua, Igbo)
IKOT AKAN 1 (Efịk)
JOS (Gẹẹsi, Hausa)
MGBOKO UMUORIA 2 (Igbo)
OTTA 2 (Yoruba)
UBOGO 1 (Urhobo)
ULI 2 (Igbo)
NOVEMBER 20-22, 1992
AKURE 3 (Gẹẹsi)
BENIN CITY 3 (Edo)
IGWURUTA ALI 2 (Gẹẹsi, Ogoni)
IKOT AKAN 2 (Efịk)
MGBOKO UMUORIA 3 (Igbo)
OKITIPUPA 1 (Yoruba)
OTTA 3 (Yoruba)
UBOGO 2 (Urhobo)
ULI 3 (Igbo)
DECEMBER 4-6, 1992
AGBOR 1 (Gẹẹsi)
AKURE 4 (Yoruba)
BENIN CITY 4 (Gẹẹsi, Ishan)
CALABAR 1 (Efịk)
IGWURUTA ALI 3 (Gẹẹsi)
IKOT EKPENE 1 (Efịk)
MGBOKO UMORIA 4 (IGBO)
OKITIPUPA 2 (Yoruba)
OTTA 4 (Gẹẹsi)
UBOGO 3 (Urhobo)
ULI 4 (Igbo)
DECEMBER 11-13, 1992
AGBOR 2 (Gẹẹsi)
AKURE 5 (Yoruba)
CALABAR 2 (Gẹẹsi)
IGWURUTA ALI 4 (Gẹẹsi)
IKOT EKPENE 2 (Efịk)
MGBOKO UMUORIA 5 (Igbo)
OTTA 5 (Gẹẹsi)
OYEDE 1 (Isoko)
UBOGO 4 (Ijaw, Okpe)
ULI 5 (Igbo)
DECEMBER 18-20, 1992
AGBOR 3 (Igbo)
CALABAR 3 (Efịk)
IKOT EKPENE 3 (Efịk)
MGBOKO UMUORIA 6 (Igbo)
OTTA 6 (Yoruba)
OYEDE 2 (Isoko)
UBOGO 5 (Gẹẹsi, Itsekiri)
ULI 6 (Igbo)
JANUARY 1-3, 1993
BADAGRY (Gun)
MGBOKO UMUORIA 7 (Igbo)
OTTA 7 (Yoruba)
ULI 7 (Igbo)
UYO 1 (Gẹẹsi)
JANUARY 8-10, 1993
IBADAN 1 (Gẹẹsi)
ILESHA 1 (Yoruba)
KATSINA ALA (Gẹẹsi, Tiv)
MGBOKO UMUORIA 8 (Igbo)
OTTA 8 (Yoruba)
ULI 8 (Gẹẹsi)
UYO 2 (Efịk)
JANUARY 15-17, 1993
IBADAN 2 (Yoruba)
ILESHA 2 (Yoruba)
MGBOKO UMUORIA 9 (Gẹẹsi)
OTTA 9 (Gẹẹsi)
UYO 3 (Efịk)
JANUARY 22-24, 1993
IBADAN 3 (Yoruba)
ILESHA 3 (Yoruba)
OTTA 10 (Gẹẹsi)
UYO 4 (Efịk)