Wá sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun”
LÁBẸ́ Òfin Mose a béèrè pé kí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ní ìgbàanì kórajọpọ̀ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dọọdún fún àwọn àjọyọ̀ kan pàtó. Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn àkókò aláyọ̀ àti èyí tí ń gbéniró nípa tẹ̀mí.—Deuteronomi 16:16.
Bákan náà ní àwọn àkókò òde-òní àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ń kórajọpọ̀ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dọọdún: fún ọjọ́ àpéjọ àkànṣe, fún àpéjọ àyíká ọlọ́jọ́ méjì, àti fún àpéjọpọ̀ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta tàbí mẹ́rin. Nínú ọdún iṣẹ́-ìsìn 1994, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò kórajọpọ̀ fún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun.”
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò fi iyèméjì kankan sílẹ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì ìbẹ̀rù Ọlọrun. Irú oríṣi ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ ní a mẹ́nukàn níbẹ̀ ní ìgbà 200. Ìbẹ̀rù Ọlọrun jẹ́ ààbò, gẹ́gẹ́ bí a ti lè rí i nínú Owe 16:6: “Nípa ìbẹ̀rù Oluwa, ènìyàn a kúrò nínú ibi.” Họ́wù, à sọ fún wa nínú Orin Dafidi 111:10 pé ìbẹ̀rù Ọlọrun gan-an ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n!
A lè sọ pé apá-ìhà ìbẹ̀rù Ọlọrun méjì ni ó wà. Ohun kan ni pé, orísun irúfẹ́ ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́. A ń bẹ̀rù láti máṣe mú Ọlọrun bínú nítorí ìfẹ́ títayọ tí a ní fún un. (Owe 27:11) Òmíràn sì tún ni pé, ọgbọ́n wa yóò ṣèrànwọ́ láti tẹ ìbẹ̀rù Ọlọrun mọ́ wa lọ́kàn, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé Ọlọrun tún jẹ́ “ìná tíí jónirun” fún gbogbo àwọn tí ń hùwà àìtọ́.—Heberu 12:29.
Ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun” wa, àwa yóò gba ìtọ́ni àti ìṣírí púpọ̀ láti dàgbà nínú ìbẹ̀rù Ọlọrun. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ni a óò fifúnni nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé, àṣefihàn, àti àwòkẹ́kọ̀ọ́ kan, àti nípa sísọ àwọn ìrírí pẹ̀lú.
Àní gẹ́gẹ́ bí a ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì láti máṣe ṣánwọ́ lọ sí àwọn àpéjọ wọn, àwa bákan náà níláti fẹ́ láti sa ipá tiwa láti fikún ayọ̀ àti àṣeyọrísírere àwọn àpéjọpọ̀ wa. (Deuteronomi 16:17) A lè ṣe èyí nípa fífi ọ̀wọ̀ hàn fún tábìlì Jehofa. Báwo? Nípa títètè dé, nípa títẹ́tísílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ohun tí a ń sọ láti orí pèpéle, nípa fífi tọkàntara darapọ̀ nínú kíkọ àwọn orin. A kì yóò fẹ́ láti kópa nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tàbí kí a máa rìn kiri nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́. Àwa yóò tún fẹ́ láti ṣètìlẹ́yìn dé ìwọ̀n tí a bá lè ṣe é dé nípa fífínnú-fíndọ̀ yọ̀ọ̀da araawa fún iṣẹ́. Ìṣètò àpéjọpọ̀ ní ọ̀pọ̀ ẹka iṣẹ́ nínú, gbogbo èyí tí ń béèrè fún àwọn òṣìṣẹ́ láti ṣiṣẹ́ nínú wọn. Àwa yóò tún fẹ́ láti fi owó ṣètọrẹ dé ìwọ̀n tí Jehofa bá bùkún wa dé.
Ẹ jẹ́ kí ìránṣẹ́ Jehofa kọ̀ọ̀kan ṣe ìwéwèé nísinsìnyí láti wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a ó fi ṣe Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun” náà, láti ìgbà orin ìbẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ Friday títí dí ìgbà àdúrà ìparí ní ọ̀sán Sunday.
ÀWỌN Ọ̀GANGAN IBI ÀPÉJỌPỌ̀ ÀGBÈGBÈ 1994
November 4-6, 1994
IKOT AKAN 1 (Efik)
KADUNA (Gẹ̀ẹ́sì)
MGBOKO UMUORIA 1 (Igbo)
OTA 1 (Gẹ̀ẹ́sì)
UBOGO 1 (Ijaw)
UYO 1 (Efik)
November 11-13, 1994
IKOT AKAN 2 (Efik)
JOS (Gẹ̀ẹ́sì, Hausa)
MGBOKO UMUORIA 2 (Igbo)
OTA 2 (Gẹ̀ẹ́sì)
UBOGO 2 (Urhobo)
UYO 2 (Efik)
November 18-20, 1994
AGBOR 1 (Gẹ̀ẹ́sì)
IBADAN 1 (Yoruba)
IMALA 1 (Yoruba)
KATSINA ALA (Gẹ̀ẹ́sì, Tiv)
MGBOKO UMUORIA 3 (Igbo)
OTA 3 (Yoruba)
UBOGO 3 (Urhobo)
UYO 3 (Efik)
December 2-4, 1994
AGBOR 2 (Gẹ̀ẹ́sì)
BENIN CITY 1 (Gẹ̀ẹ́sì)
IBADAN 2 (Yoruba)
ILESHA 1 (Yoruba)
IMALA 2 (Yoruba)
MGBOKO UMUORIA 4 (Igbo)
OTA 4 (Yoruba)
UBOGO 4 (Urhobo)
ULI 1 (Gẹ̀ẹ́sì)
UYO 4 (Gẹ̀ẹ́sì)
December 9-11, 1994
AGBOR 3 (Gẹ̀ẹ́sì)
BENIN CITY 2 (Gẹ̀ẹ́sì)
IBADAN 3 (Gẹ̀ẹ́sì)
IGWURUTA ALI 1 (Gẹ̀ẹ́sì)
IMALA 3 (Gẹ̀ẹ́sì)
ILESHA 2 (Yoruba)
MGBOKO UMUORIA 5 (Igbo)
OTA 5 (Yoruba)
UBOGO 5 (Gẹ̀ẹ́sì)
ULI 2 (Igbo)
UYO 5 (Gẹ̀ẹ́sì)
December 16-18, 1994
AGBOR 4 (Gẹ̀ẹ́sì)
BADAGRY 1 (Gun)
BENIN CITY 3 (Gẹ̀ẹ́sì)
IBADAN 4 (Gẹ̀ẹ́sì)
IGWURUTA ALI 2 (Igbo)
ILESHA 3 (Gẹ̀ẹ́sì)
MGBOKO UMUORIA 6 (Igbo)
OTA 6 (Yoruba)
UBOGO 6 (Gẹ̀ẹ́sì)
ULI 3 (Igbo)
December 23-25, 1994
AGBANI 1 (Igbo)
AKURE 1 (Yoruba)
BADAGRY 2 (Yoruba)
BENIN CITY 4 (Gẹ̀ẹ́sì)
IGWURUTA ALI 3 (Abua)
IKOT EKPENE 1 (Efik)
MGBOKO UMUORIA 7 (Igbo)
OTA 7 (Yoruba)
OYEDE 1 (Isoko)
UBOGO 7 (Gẹ̀ẹ́sì)
ULI 4 (Igbo)
December 30-January 1, 1995
MGBOKO UMUORIA 8 (Gẹ̀ẹ́sì)
OTA 8 (Yoruba)
January 6-8, 1995
AGBANI 2 (Igbo)
AKURE 2 (Yoruba)
BADAGRY 3 (Gẹ̀ẹ́sì)
BENIN CITY 5 (Edo)
CALABAR 1 (Efik)
IGWURUTA ALI 4 (Ogoni)
IKOT EKPENE 2 (Efik)
ILORIN 1 (Yoruba)
MGBOKO UMUORIA 9 (Igbo)
OKITIPUPA 1 (Yoruba)
OTA 9 (Gẹ̀ẹ́sì)
OYEDE 2 (Isoko)
ULI 5 (Igbo)
January 13-15, 1995
AGBANI 3 (Gẹ̀ẹ́sì)
AKURE 3 (Yoruba)
BADAGRY 4 (Gẹ̀ẹ́sì)
CALABAR 2 (Efik)
IGWURUTA ALI 5 (Gẹ̀ẹ́sì)
IKOT EKPENE 3 (Efik)
ILORIN 2 (Gẹ̀ẹ́sì)
MGBOKO UMUORIA 10 (Gẹ̀ẹ́sì)
OKITIPUPA 2 (Yoruba)
OTA 10 (Gẹ̀ẹ́sì)
OYEDE 3 (Isoko)
ULI 6 (Igbo)
January 20-22, 1995
AGBANI 4 (Gẹ̀ẹ́sì)
AKURE 4 (Gẹ̀ẹ́sì)
BADAGRY 5 (Gẹ̀ẹ́sì)
CALABAR 3 (Gẹ̀ẹ́sì)
IKOT EKPENE 4 (Gẹ̀ẹ́sì)
MGBOKO UMUORIA 11 (Gẹ̀ẹ́sì)
OTA 11 (Gẹ̀ẹ́sì)
OYEDE 4 (Gẹ̀ẹ́sì)
ULI 7 (Gẹ̀ẹ́sì)