Wá Sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn”
ẸWO bí ẹṣin-ọ̀rọ̀ tí a yàn fún àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ọdún 1995: “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti dára tó! Dájúdájú ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ nìyí! Olùyin ta ni? Họ́wù, dájúdájú Jehofa Ọlọrun ni!
Jehofa jẹ́ aláìlábàádọ́gba, aláìlójúgbà, aláìláfiwé, aláìlẹ́gbẹ́ ní ọ̀nà tí ó pọ̀. Ó jẹ́ alágbára gbogbo, ọlọ́gbọ́n gbogbo, ẹni pípé nínú ìdájọ́-òdodo, àti ògidì àpẹẹrẹ ìfẹ́. Lékè gbogbo àwọn mìíràn, òun ni ó yẹ láti gba ìjọsìn àti ìyìn wa.
Dájúdájú a fẹ́ láti jẹ́ onídùnnú-ayọ̀ olùyìn ín! Láti ràn wá lọ́wọ́, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àtàtà ọlọ́jọ́-mẹ́ta, tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní Nigeria ní November 1995. Ó dájú pé àwọn ọjọ́ mẹ́ta wọ̀nyí yóò kún fún ìdùnnú-ayọ̀, gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jehofa yóò sì fẹ́ láti sa gbogbo ipá wọn láti pésẹ̀ láti ìgbà orin ìbẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ Friday títí di ìgbà orin àti àdúrà ìparí ní ọ̀sán Sunday.