A Mú Ọwọ́ Dí Jọjọ Pẹlu Ihinrere Naa
APỌSTELI Pọọlu wa ninu ipo iṣoro ti kii ṣajeji si awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wọn jẹ ojiṣẹ alakooko kikun—oun ko ni owo ti o tó lọwọ. Nitori naa ni Kọrinti o bẹrẹ iṣẹ rirẹlẹ ti pipagọ ti o ti kọ́ nigba ti o wa lọmọde. Iṣẹ naa le, ati nigba miiran awọn ọwọ rẹ ti le ṣẹjẹ lati inu didi awọn aṣọ àgọ́ ti ńhani lọwọ naa mu. Ekukáká ni owo ti nwọle fi npese ounjẹ ati aṣọ ibora, ṣugbọn oun nitẹẹlọrun, nitori nigba ti iṣẹ ounjẹ oojọ rẹ ba pari ni ọjọ kọọkan, o ko awọn irin iṣẹ rẹ kalẹ o si ṣe ohun ti o wa si Kọrinti fun lakọọkọ—o waasu ihinrere!—Filipi 4:11, 12.
Ni awọn ọjọ Isinmi, Pọọlu forile sinagọgu. Lootọ, Pọọlu kọkọ lọ sọdọ awọn olugbọ rẹ ara Kọrinti “ni ailera, ati ni ẹru, ati ni ọpọlọpọ ìwárìrì.” (1 Kọrinti 2:1, 3) Ṣugbọn oun ti a fun niṣiiri nipa idahunpada awọn kan si ihin-iṣẹ rẹ, Pọọlu nbaa lọ lati ‘fi ọrọ we ọrọ fun wọn ninu sinagọgu ni ọjọọjọ isinmi, o si nyi awọn Juu ati awọn Giriiki ni ọkan pada.’—Iṣe 18:1-4.
Bi o ti wu ki o ri, fun akoko kan, Pọọlu le ṣe diẹ si ju wiwaasu ni abọ akoko. Nigba naa ni Sila ati Timoti de lati Makedonia pẹlu ọrẹ ọlọlawọ ti o ‘wa fikun ohun ti o ṣe alaini.’ (2 Kọrinti 11:9; Filipi 4:15) Amunilọkanle tun ni irohin naa pe awọn ara ni Tẹsalonika nduro gbọnyingbọnyin laika inunibini si.—1 Tẹsalonika 3:6.
Ki ni ipa ti o ni lori Pọọlu? ‘Ọwọ Pọọlu bẹrẹ sii dí jọjọ fun ọrọ naa [“fi gbogbo akoko rẹ fun wiwaasu,” The Jerusalem Bible; Today’s English Version], o njẹrii fun awọn Juu lati fihan pe Jesu ni Kristi naa.” (Iṣe 18:5, NW) Bi o ti ni itura kuro ninu awọn ikimọlẹ iṣuna owo fun igba diẹ, Pọọlu ko le sinmi titi o fi pada sẹnu iwaasu alakooko kikun. O pada sẹnu iṣẹ yii pẹlu okun onitara, kii ṣe pe o nwaasu fun awọn Juu nikan ni ṣugbọn o tun lo akoko lati kọ akọkọ ninu awọn lẹta onimisi rẹ paapaa—lẹta si awọn ara Tẹsalonika!
Apẹẹrẹ fun Wa Lonii
Akọsilẹ iṣẹ aṣekara Pọọlu ni Kọrinti ni a ti pamọ ki o ba le fun gbogbo awọn Kristian niṣiiri lati jẹ awọn ti ọwọ wọn dí jọjọ fun ihinrere naa. Pọọlu mọ pe oluwa Jesu funraarẹ ti fi ọlanla ti jijẹ “imọlẹ aye” le awọn ọmo-ẹhin rẹ lọwọ. Wọn ko nilati fi imọlẹ yi pamọ. Jesu sọ fun wọn pe: “Ẹ jẹki imọlẹ yin ki o mọlẹ to bẹẹ niwaju eniyan, ki wọn ki o le maa ri iṣẹ rere yin, ki wọn ki o le maa yin Baba yin ti nbẹ ni ọrun logo.” (Matiu 5:14-16) Eyi tumọ si nini ìpín kikun ninu iṣẹ wiwaasu ti Jesu sọtẹlẹ. (Matiu 24:14; 28:19, 20; Iṣe 1:6-8) Wiwaasu ihinrere Ijọba yii jẹ idi pataki fun wíwà ijọ Kristian.
Awọn Kristian ijimiji, bii Pọọlu, fọwọ pataki mu iṣẹ iwaasu yii. Nipa bayii, nigba ti awọn ọta Ọlọrun ronu pe awọn ti pana otitọ nipa ṣiṣikà pa “Olori Aṣoju iye,” awọn ọmọlẹhin rẹ nbaa lọ gẹgẹ bi imọlẹ aye, ni wiwaasu kikankikan. (Iṣe 3:15) Ani inunibini paapaa ko fun awọn isapa wọn pa. Akọsilẹ Bibeli wipe: “Ati ni ojoojumọ ni tẹmpili ati ni ile [“lati ile de ile,” NW], wọn ko dẹkun kikọni, ati lati waasu Jesu Kristi.” (Iṣe 5:42) Ko si ohunkohun ti o le dá wọn duro!
Ni awọn akoko ode oni, awọn Kristian ti mu ọwọ wọn dí jọjọ bakan naa fun igbokegbodo jijẹrii. Siha opin ọgọrun un ọdun kọkandinlogun, awọn akẹkọọ Ọrọ Ọlọrun afitọkantọnkan ṣiṣẹ bẹrẹ si ri aini naa lati ṣajọpin otitọ Bibeli pẹlu awọn ẹlomiran. Zion’s Watch Tower Tract Society—eto-ajọ kan ti o ti gbooro jakejado agbaye—ni a sọ di ajọ ti o bofinmu ni 1884. Awọn Akẹkọọ Bibeli wọnyi, ti a mọ lati 1931 gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí Jehofa, ti kun ilẹ-aye niti gidi pẹlu imọ Ọrọ Ọlọrun. Igbokegbodo kikankikan wọn ti yọrisi ẹgbẹ ogun nla ti o ju million mẹrin lọ! Ati laiṣeyemeji iye wọn yoo maa baa lọ lati maa gbooro sii labẹ idari Jehofa.—Aisaya 60:22.
Iwọ Han Nṣe Ipa Tirẹ Bi?
Jesu wipe: “Ikore pọ, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nǹkan.” (Matiu 9:37, 38) Ni 1990 iye ti o fẹrẹẹ to million mẹwa awọn eniyan wa si Iṣe-iranti iku Kristi. Iru agbayanu ṣiṣeeṣe wo ni o wa fun ibisi ikore yika aye! Ṣugbọn nigba ti a nyọ ninu imugbooro ti nbaa lọ yii, ẹnikọọkan wa gbọdọ beere lọwọ araarẹ pe, ‘De iwọn wo ni mo nni ipin ninu iṣẹ titobilọba yii? Mo ha nṣe bẹẹ deedee—ni gbogbo ọsẹ bi o ba ṣeeṣe bi?’
Awọn alagba gbọdọ mu ipo iwaju ninu iṣẹ yii gẹgẹ bi “apẹẹrẹ fun agbo.” (1 Peteru 5:3) Lootọ, ọpọjulọ awọn alagba ni awọn iṣẹ ounjẹ oojọ. Bẹẹ ni o ri pẹlu apọsteli Pọọlu nigba ti o wa ni Kọrinti. Sibẹ, o ya akoko sọtọ fun igbokegbodo wiwaasu deedee. Ọpọlọpọ awọn alagba lonii ni a mu ọwọ wọn di jọjọ fun awọn igbokegbodo tẹmi lọna ti o farajọra ni awọn opin ọsẹ. Eyi le ni iyọrisi alagbara ti o si nfunni nisiiri lori gbogbo awọn ti o wa ninu ijọ. Ni awọn oṣu kan nigba ti a ba lo isapa akanṣe, iye awọn ijọ ti o pọ diẹ ni ọpọjulọ awọn akede wọn wà ninu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna. Ki ni aṣiiri rẹ? Awọn alagba mu ipo iwaju ninu iwaasu ati ninu ṣiṣe awọn eto iṣẹ-isin papa.
Awọn iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ bakan naa le ni ipa didara lori ijọ bi wọn ba ńnípìn-ín lọna deedee ninu iṣẹ-isin papa. Ẹ ranti pe, Iwe mimọ beere pe ki wọn ni “iwa agba, . . . awọn ọkunrin ti wọn nṣeranṣẹ ni iru ọna rere kan.” (1 Timoti 3:8, 13, NW) Iṣotitọ ninu iṣẹ-isin papa ṣe pataki fun arakunrin kan lati tootun gẹgẹ bi alagba tabi iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ.—Titu 1:8, 9.
Bi Pọọlu, awọn kan le din iṣẹ ounjẹ oojọ wọn ku ki wọn si tipa bayii ṣe aṣaaju-ọna. Iye awọn aṣaaju-ọna deedee, oluranlọwọ, ati akanṣe pọ sii lati 137,861 ni ọdun mẹwa pere sẹhin si 536,508 ni 1990. Dajudaju, kiki ibukun ati ifọwọsi Jehofa ni o le ti mu eyi wa. Bi o tilẹ jẹ pe, awọn aṣaaju-ọna gbọdọ ṣọra lati lo akoko lọna ọgbọn, kii wulẹ ṣe lati rohin akoko ti o pọ. Ẹyin aṣaaju-ọna, ẹ ha mura daradara ẹ ha si gbeṣẹ ninu iṣẹ-ojiṣẹ naa bi? Ẹ ha nsakun lati ṣe imusunwọnsi ti nbaa lọ ki iṣẹ-ojiṣẹ yin ba le jẹ amesojade nitootọ bi?
Awọn Ere Iṣẹ-ojiṣẹ Kan Ti O Wa Deedee
Iwọ ha mọriri isọfunni tí ńgbé iwalaaye ró ti a ngbejade loṣooṣu ninu Ilé-ìṣọ́nà ati alabaakẹgbẹ rẹ, Ji!? Laiṣeyemeji, iwọ ṣe bẹẹ. Imọriri rẹ ha ti sun ọ lati nipin-in ninu pinpin awọn iwe-irohin wọnyi kiri bi? Arabinrin kan ni Botswana ṣe bẹẹ. Oun tako otitọ tẹlẹri, ṣugbọn ọkọ rẹ nka awọn iwe-irohin naa fun. Laipẹ o yi ọkan pada o si di Ẹlẹrii. Bi o tilẹ jẹ pe ko lee kawe, o nṣaṣeyọri si rere gan an ninu fifi awọn iwe irohin sode, ni wiwipe, “Emi ko mọ iwe kà, ṣugbọn ọkọ mi nka awọn iwe-irohin wọnyi fun mi. Mo gbadun wọn, mo si ni idaniloju pe iwọ pẹlu yoo gbadun wọn.”
Eeṣe ti o ko fi ni ipin ọsọọsẹ ninu iṣẹ agbẹmila yii? Lọgan bi o ba ti doju ila awọn ohun abeere fun tẹmi, ijọ Kristian yoo layọ lati ran ọ lọwọ lati bẹrẹ. Bi o ti wu ki o ri, fifi iwe-irohin sode wulẹ jẹ ọna iṣẹ-isin kan ni. Ẹnikẹni ti a mu ọwọ rẹ dí jọjọ fun ihinrere naa ngbiyanju lati ṣe iṣẹ-ojiṣẹ ti o wa deedee. Fun apẹẹrẹ, Watch Tower Society tẹ awọn iwe ẹlẹhin lile jade ni araadọta ọkẹ, awọn wọnyi ni a si nfilọ awọn ara ita gẹgẹ bi orisun ounjẹ tẹmi rere ti o wa pẹ titi. Iwọ ha ti di ogboṣaṣa tó ninu iṣẹ-ojiṣẹ rẹ lati fi awọn iwe sode, iru gẹgẹ bii Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye?
Ki si ni nipa awọn eniyan ti wọn fi ifẹ han? Iwọ ha npa akọsilẹ rere mọ ki o ba le ṣe ipadabẹwo sọdọ wọn? Iru ibẹwo bẹẹ le ṣamọna si iha iṣẹ-isin ti nmu ọpọjulọ ayọ wa fun gbogbo eniyan—iṣẹ ikẹkọọ Bibeli inu ile. Ranti pe, Jesu pa a laṣe fun wa ni Matiu 28:19, 20 lati ‘sọ wọn di ọmọ ẹhin, baptisi wọn.’ Iyẹn tumọsi lati kẹkọọ Bibeli pẹlu wọn. Loootọ, bibẹrẹ ikẹkọọ kan niye igba beere fun ìtẹpẹlẹmọ́. Ẹlẹrii kan pade tọkọtaya agbalagba kan ti wọn fi tọkantọkan fohunṣọkan fun ikẹkọọ Bibeli inu ile. Ṣugbọn wọn nsun ikẹkọọ naa siwaju ni itotẹlera ọsẹ mẹta sira. Asẹhinwa asẹhinbọ ikẹkọọ naa ni a bẹrẹ. Lẹhin naa, fun akoko kan, tọkọtaya naa maa nfagile ikẹkọọ naa o fẹrẹẹ jẹ ni gbogbo ọsẹ mejimeji. Bi o ti wu ki o ri, nikẹhin, aya naa tẹsiwaju de ori ṣiṣe iribọmi. Arakunrin naa ranti pe, “Lẹhin didi ẹni ti a baptisi, oju rẹ lé ròrò fun omije ayọ, eyi ti o mu omije ayọ wa soju mi ati ti aya mi.” Bẹẹni, jijẹ ẹni ti a mu ọwọ rẹ dí jọjọ fun ihinrere naa nmu ayọ ti o kọyọyọ wa!
Mu Araarẹ Wà Larọọwọto!
Jesu Kristi ati apọsteli Pọọlu ti fi awọn apẹẹrẹ rere ti ifọkansin lelẹ fun wa lati ṣafarawe. A si ni ọpọlọpọ awọn apẹẹrẹ titobi laaarin awọn Ẹlérìí Jehofa ni akoko ode oni. Akoko naa ti to wayi fun gbogbo awọn ti wọn mọ ihinrere naa lati di agbekankan ṣiṣẹ ninu sisọ ọ di mimọ fun awọn ẹlomiran. Bibeli mu un dá wa loju pe iru làálàá bẹẹ “kii ṣe asan.”—1 Kọrinti 15:58.
Bi Pọọlu, ọpọjulọ ní awọn ohun aigbọdọmaṣe niti iṣuna owo lati kaju. Nitori eyi, o le ma ṣeeṣe fun ọpọlọpọ lati ṣe aṣaaju-ọna. Ṣugbọn pẹlu iranlọwọ Jehofa, gbogbo wa le tẹle amọran rere ti a fi funni ni Roomu 12:11: “Niti iṣẹ ṣiṣe, ẹ ma ṣe ọlẹ, ẹ maa ni igbona ọkan, ẹ maa sin Oluwa [“Jehofa,” NW].” Bi awọn ipo ba si yí pada lati yọnda fun akoko pupọ sii lati lò ninu iṣẹ-isin Jehofa, ẹnikẹni ti o ba nifẹẹ Jehofa yoo tete mu anfaani naa lò bii Pọọlu. Ẹ mu ọwọ yin dí jọjọ fun ihinrere naa! Ṣiṣe bẹẹ ki yoo mu awọn ibukun wa nisinsinyi nikan ṣugbọn ni ọjọ iwaju yoo yọrisi iye ainipẹkun pẹlu ayọ ati idunnu ti ko lopin!—Matiu 19:28, 29.