Jẹ́ Kí ‘Ọwọ́ Rẹ Dí Jọjọ’ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ
1 Nígbà tí a kà á pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ àgọ́ pípa nígbà tó wà ní Kọ́ríńtì, a lè ronú pé ìyẹn kò jẹ́ kó ní àǹfààní púpọ̀ láti wàásù. Ṣùgbọ́n, Ìṣe 18:5 ròyìn pé: “Ọwọ́ Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí dí jọjọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà, ó ń jẹ́rìí fún àwọn Júù láti fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn pé Jésù ni Kristi náà.” Kí nìdí tí ọwọ́ Pọ́ọ̀lù fi dí jọjọ bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní Kọ́ríńtì ló ti di onígbàgbọ́, Olúwa náà sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà ní ìlú náà tí a ṣì ní láti sọ di ọmọ ẹ̀yìn. (Ìṣe 18:8-11) Ǹjẹ́ àwa náà ní irú ìdí kan náà tó fi yẹ kí a jẹ́ kí ọwọ́ wa dí jọjọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? Bẹ́ẹ̀ ni. A lè rí ọ̀pọ̀ èèyàn sí i kí a sì fi òtítọ́ kọ́ wọn.
2 Lo Àkókò Púpọ̀ Sí I Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Lóṣù April: Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé góńgó rẹ ni pé wàá máa wàásù ìhìn rere náà lóṣooṣù. Ṣùgbọ́n àwọn oṣù kan máa ń wà tí a máa ń túbọ̀ ní àǹfààní láti jẹ́ kí ‘ọwọ́ wa dí jọjọ’ nínú iṣẹ́ yìí. Oṣù April, tó jẹ́ ìgbà tí ìgbòkègbodò máa ń pọ̀ gan-an lákòókò Ìṣe Ìrántí wà lára rẹ̀. Ǹjẹ́ ipò rẹ jẹ́ kí o ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí kí o mú kí ìsapá rẹ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọ̀ sí i ní sáà yìí? Ọ̀pọ̀ akéde tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. (2 Kọ́r. 9:6) Bí o bá ń ṣe gbogbo ohun tí agbára rẹ ká, rántí pé inú Jèhófà dùn sí iṣẹ́ ìsìn tí o ń fi gbogbo ọkàn rẹ ṣe. (Lúùkù 21:2-4) Ohun yòówù kí ipò rẹ jẹ́, fi í ṣe góńgó rẹ láti jẹ́ kí ‘ọwọ́ rẹ dí jọjọ’ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ lóṣù April yìí. Má sì ṣe gbàgbé láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ sílẹ̀ níparí oṣù kí a lè ká ohun tóo ṣe mọ́ ti àwọn èèyàn Jèhófà yòókù.
3 Ṣèbẹ̀wò Sọ́dọ̀ Àwọn Ẹni Tuntun Tó Wá sí Ìṣe Ìrántí: Ní Nàìjíríà lọ́dún tó kọjá, iye àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìdínlọ́gbọ̀n, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé ọgbọ̀n [575,530]. A ò tíì mọ àròpọ̀ iye àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí lọ́dún yìí. Síbẹ̀, ìròyìn fi hàn pé àgbàyanu ìrètí wà pé “ìkórè” ọ̀hún á gọntíọ. (Mát. 9:37, 38) Nítorí náà, bó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó, ṣètò láti bẹ àwọn olùfìfẹ́hàn tó wá sí Ìṣe Ìrántí wò kí o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Sísún irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ síwájú lè jẹ́ kí ‘ẹni burúkú náà já ọ̀rọ̀ Ìjọba náà tí a ti gbìn sínú ọkàn-àyà wọn gbà lọ.’ (Mát. 13:19) Ṣíṣe ìbẹ̀wò láìfi nǹkan falẹ̀ yóò fi hàn pé o ń jẹ́ kí ‘ọwọ́ rẹ dí jọjọ’ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.
4 Máa Bá A Lọ Láti Ran Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Lọ́wọ́: Ní oṣù February, a bẹ̀rẹ̀ sí sapá lákànṣe láti ran àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́. Bí àwọn kan bá wà tí a kò tíì ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ wọn, kí àwọn alàgbà ṣètò láti bẹ̀ wọ́n wò kí oṣù April tó parí. Àwọn alàgbà yóò sakun láti mọ ohun tó fa ìṣòro tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní àti bí a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ jù lọ láti tún bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà dáadáa. Ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ yìí ń fi hàn pé àwọn alàgbà ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹrù iṣẹ́ wọn ti jíjẹ́ olùṣọ́ àgùntàn “agbo Ọlọ́run.” (1 Pét. 5:2; Ìṣe 20:28) Ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1993, ojú ìwé 22 àti 23, pèsè àwọn àbá tó dára gan-an tí àwọn alàgbà lè lò nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó èyíkéyìí nínú àwọn ìṣòro pàtàkì márùn-ún tí ó lè máa bá àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ fínra. Bí a ṣe wòye rẹ̀, a ṣì lè mú kí àwọn kan tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lẹ́ẹ̀kan sí i lóṣù April yìí.
5 Ran Ọ̀pọ̀ Sí I Lọ́wọ́ Láti Di Akéde Tí Kò Tíì Ṣèrìbọmi: Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ ti tóótun láti di akéde ìhìn rere náà? Àwọn mìíràn tí o ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ńkọ́? Bí àwọn alàgbà bá fọwọ́ sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ oṣù April kọ́ ló dára pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kéde? Bí ẹnì kan bá ń tẹ̀ síwájú tó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè àti ìwé Ìmọ̀, a lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ nìṣó nínú ìwé kejì, ìyẹn ìwé Alafia ati Ãbo Tõtọ—Lati Orísun Wo? àti Ìsopọ̀ṣọ̀kan ninu Ijọsin. Ohun tóo fẹ́ ni pé kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ní òye tó pọ̀ dáadáa nípa òtítọ́, kí ó tóótun láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, kí ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ti ṣèyàsímímọ́, tó sì ti ṣèrìbọmi.—Éfé. 3:17-19; 1 Tím. 1:12; 1 Pét. 3:21.
6 Ojúlówó ìfẹ́ tóo bá ń fi hàn nígbà gbogbo sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti sọ òtítọ́ di tiwọn. Ẹlẹ́rìí kan pàdé tọkọtaya àgbàlagbà kan tí wọ́n fi tọkàntọkàn gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣùgbọ́n ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ni tọkọtaya náà fi yẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún léraléra. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó tún yá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọ̀sẹ̀ kẹ́ta-kẹ́ta ni tọkọtaya ọ̀hún máa ń yẹ ìkẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, èyí ìyàwó tẹ̀ síwájú débi ìrìbọmi. Arákùnrin náà sọ pé: “Lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ojú rẹ̀ kún fún omijé ayọ̀, ìyẹn sì mú kí omijé ayọ̀ jáde lójú èmi àti ìyàwó mi.” Bẹ́ẹ̀ ni o, jíjẹ́ kí ‘ọwọ́ wa dí jọjọ’ ní sísọ ìhìn rere ń mú ìdùnnú ńláǹlà wá!
7 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ń fi hàn pé àkókò òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bùṣe. Àkókò yìí ló yẹ kí gbogbo àwọn tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run máa jẹ́ kí ‘ọwọ́ wọn dí jọjọ’ ní sísọ ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú un dáni lójú pé irú òpò bẹ́ẹ̀ “kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.”—1 Kọ́r. 15:58.