Iṣẹ Ọkunrin
“¡Ropa, zapato, casa, y comida!” Awọn ọrọ wọnyi wá lati inu orin Spain atijọ kan ti o ṣetolẹsẹẹsẹ awọn ohun ipilẹ mẹrin ti a reti pe ki ọkunrin kan pese fun idile rẹ̀: aṣọ, bata, ile, ati ounjẹ. Ọpọjulọ awọn ọkunrin ti wọn mọ ẹru-iṣẹ niṣẹ nfi itẹlọrun gbiyanju lati gbe ẹru yẹn.
Bi o ti wu ki o ri, bi iwọ ba jẹ ọkunrin onidiile kan, iwọ ha bikita fun aini tẹmi ti o ṣe pataki julọ ti idile rẹ bi? Tabi iwọ, bi ọpọlọpọ awọn ọkunrin, ronu pe bibojuto awọn ọran nipa isin ninu ile kii ṣe iṣẹ ọkunrin niti gidi? Ninu ẹgbẹ́ awujọ kan a ko tilẹ reti pe awọn ọkunrin yoo wá akoko lati kọ awọn ọmọ wọn lẹkọọ nipa Ọlọrun ati Bibeli.
Ọrọ Ọlọrun ni pataki gbe ẹru-iṣẹ naa kari baale ile lati tẹ ifẹ fun Ọlọrun ati imọriri jijinlẹ fun awọn ilana atọrunwa mọ idile rẹ lọkan. Fun apẹẹrẹ, ni Efesu 6:4, Iwe mimọ gba awọn Kristẹni ọkunrin niyanju gẹgẹ bi o ti tẹle e yii: “Ẹyin baba, ẹ maṣe mu awọn ọmọ yin binu: ṣugbọn ẹ maa tọ́ wọn ninu ẹkọ ati ikilọ Oluwa [“Jehofa,” NW].”
Bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ ojulumọ pẹlu awọn ọrọ wọnyi, awọn diẹ le ma mọriri ni kikun pe iwe mimọ naa ni pataki ni a dari si baba, baale ile naa. Fun apẹẹrẹ, awọn eniyan ti wọn nsọ ede Spanish ati Portuguese le loye awọn ọrọ naa ti o wa ni Efesu 6:4 pe a dari rẹ̀ si baba ati iya. Ninu awọn ede wọnyi ọrọ naa fun “ẹyin baba” ati ọrọ naa fun “ẹyin obi” jẹ ọ̀kan naa. Bi o ti wu ki o ri, ni ẹsẹ 1 ninu Efesu ori 6, apọsiteli Pọọlu tọka si baba ati iya nipa lilo ọrọ Giriiki naa go·neuʹsin, lati inu go·neusʹ, ti o tumọ si “obi.” Ṣugbọn ni ẹsẹ 4 ọrọ Giriiki ti a lo ni pa·teʹres, ti o tumọ si “ẹyin baba.” Bẹẹni, ni Efesu 6:4, Pọọlu dari awọn ọrọ rẹ̀ si baale inu idile naa.
Dajudaju, bi ko ba si ọkunrin ninu idile naa lati mu ipo iwaju, nigba naa obinrin gbọdọ tẹrigba ẹru-iṣẹ yii. Pẹlu iranlọwọ Jehofa ọpọlọpọ awọn iya ti tọ́ awọn ọmọ wọn pẹlu aṣeyọri si rere ninu ibawi ati ilana ero ori ti Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti ọkunrin Kristẹni kan ba wà nibẹ, oun nilati mu ipo iwaju. Bi o ba ṣainaani ẹru-iṣẹ yii, o tubọ ṣoro sii fun iyooku mẹmba idile naa lati pa itolẹsẹẹsẹ rere ti ounjẹ tẹmi kan mọ. Iru ọkunrin kan bẹẹ sì nilati jihin fun Jehofa fun ainaani rẹ̀.
Awọn imọlara Ọlọrun lori ọran yii ni o ṣe kedere ninu awọn ohun ti Iwe mimọ beere fun ti a ṣalaye lẹsẹẹsẹ fun awọn alaboojuto ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ ninu ijọ Kristẹni. Bibeli tọka pato pe ẹnikan ti a yan fun iru ipo bẹẹ nilati jẹ “ẹni ti o kawọ ile araarẹ girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀ tẹriba pẹlu iwa agba gbogbo; (ṣugbọn bi eniyan ko ba mọ bi a tii ṣe ikawọ ile araarẹ, oun yoo ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?).”—1 Timoti 3:4, 5, 12; Titu 1:6.
Ọkunrin onidiile naa gbọdọ muratan lati fi awọn faaji ati ìdẹ̀ra ara ẹni rubọ nitori ire tẹmi awọn ọmọ rẹ̀. Nigba miiran oun le nilati din awọn akoko ti o nlo fun awọn igbokegbodo miiran kù ki o baa le ni akoko ti o jọju lati lo pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ deedee. (Deutaronomi 6:6, 7) Laika eyiini sí, oun ki yoo gbé iṣẹ ti Ọlọrun fifun un yii fun awọn ẹlomiran ṣe. Ifẹ rẹ̀ fun awọn ọmọ rẹ̀ ati aniyan rẹ̀ fun wọn yoo lọ rekọja pipese aṣọ, bata, ile, ati ounjẹ.
Ó jẹ ipenija gan an lati tọ́ ọmọ dagba “ninu ibawi ati ilana ero ori ti Jehofa.” Idi niyẹn ti ẹru-iṣẹ ipilẹṣẹ naa fi jẹ ti ọkunrin. Nigba ti Kristẹni baba naa ba ṣe iṣẹ rẹ̀ daradara, nigba naa o le wo awọn ọmọ rẹ̀ olubẹru Ọlọrun gẹgẹ bi ibukun lati ọdọ Jehofa. O le sọ pẹlu onisaamu naa pe: “Bi ọfa ti rí ni ọwọ alagbara, bẹẹ ni awọn ọmọ ewe. Ẹni ayọ ni ọkunrin naa ti apó rẹ̀ kún fún wọn: oju ki yoo ti wọn, nigba ti wọn ba nba ọta wọn sọrọ ni ẹnu ibode.”—Saamu 127:4, 5.